Jobu 17 – YCB & NRT

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Jobu 17:1-16

Ìdáhùn Jobu

1“Ẹ̀mí mi bàjẹ́,

ọjọ́ mi ni a ti gé kúrú,

isà òkú dúró dè mí.

2Nítòótọ́ àwọn ẹlẹ́yà wà lọ́dọ̀ mi,

ojú mi sì tẹ̀mọ́ ìmúnibínú wọn.

3“Fi fún mi Olúwa, ìlérí tí ìwọ fẹ́;

ta ni yóò le ṣe ààbò fún mi?

4Nítorí pé ìwọ ti sé wọ́n láyà kúrò nínú òye;

nítorí náà ìwọ kì yóò gbé wọn lékè.

5Ẹni tí ó sọ ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn dídún fún àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ fún èrè,

òun ni ojú àwọn ọmọ rẹ̀ yóò mú òfo.

6“Ọlọ́run ti sọ mi di ẹni òwe fún àwọn ènìyàn;

níwájú wọn ni mo dàbí ẹni ìtutọ́ sí ní ojú.

7Ojú mí ṣú bàìbàì nítorí ìbìnújẹ́,

gbogbo ẹ̀yà ara mi sì dàbí òjìji.

8Àwọn olódodo yóò yanu sí èyí,

ẹni aláìṣẹ̀ sì bínú sí àwọn àgàbàgebè.

9Olódodo pẹ̀lú yóò di ọ̀nà rẹ̀ mú,

àti ọlọ́wọ́ mímọ́ yóò máa lera síwájú.

10“Ṣùgbọ́n bí ó ṣe ti gbogbo yín,

ẹ yípadà, kí ẹ si tún padà nísinsin yìí;

èmi kò le rí ọlọ́gbọ́n kan nínú yín.

11Ọjọ́ tí èmi ti kọjá, ìrò mi ti fà yá,

àní ìrò ọkàn mi.

12Àwọn ènìyàn wọ̀nyí ń ṣọ́ òru di ọ̀sán;

wọ́n ní, ìmọ́lẹ̀ súnmọ́ ibi tí òkùnkùn dé.

13Bí mo tilẹ̀ ní ìrètí, ipò òku ní ilé mi;

mo ti tẹ́ ibùsùn mi sínú òkùnkùn.

14Èmi ti wí fún ìdíbàjẹ́ pé, ìwọ ni baba mi,

àti fún kòkòrò pé, ìwọ ni ìyá mi àti arábìnrin mi,

15ìrètí mi ha dà nísinsin yìí?

Bí ó ṣe ti ìrètí mi ni, ta ni yóò rí i?

16Yóò sọ̀kalẹ̀ lọ sínú ipò òkú,

nígbà tí a jùmọ̀ sinmi pọ̀ nínú erùpẹ̀ ilẹ̀?”

New Russian Translation

Иов 17:1-16

1Надломлен мой дух,

кончаются мои дни,

ждет меня могила.

2Поистине, рядом со мной – насмешники,

и мои глаза смотрят на их издевательства.

Иов просит Бога быть его защитником

3Заступись за меня Сам перед Собой.

Кто другой за меня поручится?

4Ты закрыл их разум от понимания,

поэтому и не дашь им торжествовать.

5У того, кто друзей оговаривает за плату, –

дети ослабеют глазами.

6Бог сделал меня присказкой для людей,

тем, кому люди плюют в лицо.

7Помутились от горя мои глаза,

и все тело мое стало как тень.

8Ужаснутся этому праведные,

и невинные вознегодуют на безбожников.

9Но своего пути будет держаться праведный,

и тот, чьи руки чисты, будет больше и больше утверждаться.

10Ну, а вы – попробуйте снова,

и я не найду среди вас мудреца.

Смерть – единственная надежда Иова

11Мои дни прошли, надежды разбиты,

желания сердца мертвы.

12Они ночь превращают в день.

«Свет, – говорят они, – тьме сродни».

13Если я жду себе дом в мире мертвых,

если я во мгле расстелю постель,

14и скажу могиле: «Ты мне отец»,

а червям: «Ты мне мать, ну, а ты – сестра»,

15то где же моя надежда?

Кто надежду мою увидит?

16Сойдет ли она к воротам мира мертвых?

Разве вместе в прах мы ляжем?