Jobu 14 – YCB & AKCB

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Jobu 14:1-22

Jobu tẹ̀síwájú nínú àròyé rẹ̀

1“Ènìyàn tí a bí nínú obìnrin,

ọlọ́jọ́ díẹ̀ ni, ó sì kún fún ìpọ́njú.

2Ó jáde wá bí ìtànná ewéko, a sì ké e lulẹ̀;

ó sì ń fò lọ bí òjìji, kò sì dúró pẹ́.

3Ìwọ sì ń ṣíjú rẹ wò irú èyí ni?

Ìwọ sì mú mi wá sínú ìdájọ́ pẹ̀lú rẹ?

4Ta ni ó lè mú ohun mímọ́ láti inú àìmọ́ jáde wá?

Kò sí ẹnìkan!

5Ǹjẹ́ a ti pinnu ọjọ́ rẹ̀,

iye oṣù rẹ̀ ń bẹ ní ọwọ́ rẹ;

Ìwọ ti pààlà rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ní òun kò le kọjá rẹ̀.

6Yípadà kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, kí ó lè

sinmi, títí yóò fi pé ọjọ́ rẹ̀ bí alágbàṣe.

7“Nítorí pé ìrètí wà fún igi, bí a bá

ké e lulẹ̀, pé yóò sì tún sọ,

àti pé ẹ̀ka rẹ̀ tuntun kì yóò gbẹ.

8Bí gbòǹgbò rẹ̀ tilẹ̀ di ogbó nínú ilẹ̀,

tí kùkùté rẹ̀ si kú ni ilẹ̀;

9Síbẹ̀ nígbà tí ó bá gbóòórùn omi,

yóò sọ, yóò sì yọ ẹ̀ka jáde bí irúgbìn.

10Ṣùgbọ́n ènìyàn kú, a sì dàánù;

Àní ènìyàn jọ̀wọ́ ẹ̀mí rẹ̀ lọ́wọ́: Òun kò sì sí mọ́.

Àgékúrú ọjọ́ ọmọ ènìyàn

11“Bí omi ti í tán nínú ipa odò,

àti bí odò ṣì tí í fà tí sì gbẹ,

12bẹ́ẹ̀ ni ènìyàn dùbúlẹ̀ tí kò sì dìde mọ́;

títí ọ̀run kì yóò fi sí mọ́,

wọ́n kì yóò jí, a kì yóò jí wọn kúrò lójú oorun wọn.

13“Háà! ìwọ ìbá fi mí pamọ́ ní ipò òkú,

kí ìwọ kí ó fi mí pamọ́ ní ìkọ̀kọ̀,

títí ìbínú rẹ yóò fi rékọjá,

ìwọ ìbá lànà ìgbà kan sílẹ̀ fún mi, kí ó si rántí mi!

14Bí ènìyàn bá kú yóò sì tún yè bí?

Gbogbo ọjọ́ ìgbà tí a là sílẹ̀

fún mi ni èmi dúró dè, títí àmúdọ̀tún mi yóò fi dé.

15Ìwọ ìbá pè, èmi ìbá sì dá ọ lóhùn;

ìwọ ó sì ní ìfẹ́ sì iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.

16Ṣùgbọ́n nísinsin yìí ìwọ ń kaye ìṣísẹ̀ mi;

ìwọ kò fa ọwọ́ rẹ kúrò nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mi?

17A fi èdìdì di ìrékọjá mi sínú àpò,

ìwọ sì rán àìṣedéédéé mi pọ̀.

18“Àti nítòótọ́ òkè ńlá tí ó ṣubú, ó dasán,

a sì ṣí àpáta kúrò ní ipò rẹ̀.

19Omi a máa yinrin òkúta, ìwọ a sì

mú omi sàn bo ohun tí ó hù jáde lórí ilẹ̀,

ìwọ sì sọ ìrètí ènìyàn dí òfo.

20Ìwọ ṣẹ́gun rẹ̀ láéláé, òun sì kọjá lọ!

Ìwọ pa awọ ojú rẹ̀ dà, o sì rán an lọ kúrò.

21Àwọn ọmọ rẹ̀ bọ́ sí ipò ọlá, òun kò sì mọ̀;

wọ́n sì rẹ̀ sílẹ̀, òun kò sì kíyèsi i lára wọn.

22Ṣùgbọ́n ẹran-ara rẹ̀ ni yóò rí

ìrora. Ọkàn rẹ̀ ni yóò sì máa ní ìbìnújẹ́ nínú rẹ̀.”

Akuapem Twi Contemporary Bible

Hiob 14:1-22

1“Nnipa a ɔbea awo wɔn

nna yɛ tiaa bi na ɔhaw ahyɛ mu mma.

2Ɔfefɛw te sɛ nhwiren na etwintwam;

ɔte sɛ sunsuma a ɛretwa mu akɔ, ɔntena hɔ nkyɛ.

3Woma wʼani kɔ saa onipa yi so?

Wode no bɛba wʼanim abebu no atɛn ana?

4Hena na obetumi ayi nea ɛyɛ kronkron afi fi mu?

Obiara nni hɔ.

5Woahyehyɛ onipa nkwa nna;

woahyɛ nʼasram dodow ato hɔ

na woahyɛ no bere a ɔrentumi ntra.

6Enti yi wʼani fi ne so na ɔnyɛ nea ɔpɛ,

kosi sɛ obewie nʼadwuma sɛ ɔpaani.

7“Dua mpo anidaso wɔ hɔ ma no:

Sɛ wotwa a, ɛbɛfefɛw bio,

na ne mman foforo no rempenpan.

8Ne ntin betumi anyin akyɛ asase mu

na ne dunsin nso awu wɔ dɔte mu,

9nanso, onya nsu a ɛfefɛw,

na eyiyi mman sɛ dua a wɔatɛw.

10Nanso sɛ nnipa wu a wɔde no hyɛ fam;

ɔhome nea etwa to a, na afei onni hɔ bio.

11Sɛnea nsu tu yera wɔ po mu no,

anaa sɛnea suka mu yowee no,

12saa ara na onipa tɔ fam na ɔnsɔre bio;

enkosi sɛ ɔsoro betwa mu no, nnipa rensɔre

na wɔrennyan wɔn mfi wɔn nna mu.

13“Sɛ anka wode me besie ɔda mu

de me ahintaw kosi sɛ wʼabufuw betwa mu!

Sɛ anka wobɛhyɛ me bere

na afei woakae me!

14Sɛ onipa wu a ɔbɛba nkwa mu bio ana?

Mʼaperedi nna mu nyinaa

mɛtwɛn akosi sɛ me foforoyɛ bɛba.

15Wobɛfrɛ na megye wo so;

wʼani begyina abɔde a wo nsa ayɛ.

16Afei wobɛkan mʼanammɔntu

na worenni me bɔne akyi.

17Wɔbɛsɔ me bɔne ano wɔ kotoku mu,

na woakata mʼamumɔyɛ so.

18“Nanso sɛnea mmepɔw so hohoro na ɛpompono

na ɔbotan nso twe fi ne sibea no,

19sɛnea nsu yiyi abo ho

na osuhweam twe dɔte kɔ no

saa ara na wosɛe onipa anidaso.

20Wutintim ne so prɛko pɛ, na otwa mu kɔ;

wosakra ne nipasu na wugya no kwan.

21Sɛ wɔhyɛ ne mmabarima anuonyam a, onnim;

na sɛ wɔbrɛ wɔn ase a, onhu.

22Ɔno ara were mu yaw na ɔtee

na ɔno ara ne ho na ogyam.”