Jobu 11 – YCB & KSS

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Jobu 11:1-20

Sofari fi ẹ̀sùn irọ́ pípa àti àìṣòótọ́ kan Jobu

1Ìgbà náà ni Sofari, ará Naama, dáhùn, ó sì wí pé:

2“A ha lè ṣe kí a máa dáhùn sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀rọ̀?

A ha lè fi gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí da ènìyàn láre?

3Ṣé àmọ̀tán rẹ le mú ènìyàn pa ẹnu wọn mọ́ bí?

Ṣé ẹnikẹ́ni kò ní bá ọ wí bí ìwọ bá yọ ṣùtì sí ni?

4Ìwọ sá à ti wí fún Ọlọ́run pé,

‘ìṣe mi jẹ́ aláìléérí, èmi sì mọ́ ní ojú rẹ.’

5Ṣùgbọ́n Ọlọ́run ìbá jẹ́ sọ̀rọ̀,

kí ó sì ya ẹnu rẹ̀ sí ọ;

6Kí ó sì fi àṣírí ọgbọ́n hàn ọ́ pé, ó pọ̀ ju òye ènìyàn lọ;

Nítorí náà, mọ̀ pé Ọlọ́run ti

gbàgbé àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ kan.

7“Ìwọ ha le ṣe àwárí ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run bí?

Ìwọ ha le ṣe àwárí ibi tí Olódùmarè dé bi?

8Ó ga ju àwọn ọ̀run lọ; kí ni ìwọ le è ṣe?

Ó jì ju jíjìn isà òkú lọ; kí ni ìwọ le mọ̀?

9Ìwọ̀n rẹ̀ gùn ju ayé lọ,

ó sì ní ibú ju Òkun lọ.

10“Bí òun bá rékọjá, tí ó sì sé ọnà,

tàbí tí ó sì mú ni wá sí ìdájọ́, ǹjẹ́, ta ni ó lè dí i lọ́wọ́?

11Òun sá à mọ ẹlẹ́tàn ènìyàn;

àti pé ṣé bí òun bá rí ohun búburú, ṣé òun kì i fi iyè sí i?

12Ṣùgbọ́n òmùgọ̀ ènìyàn ki yóò di ọlọ́gbọ́n,

bi ko ti rọrùn fún ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó láti bí ènìyàn.

13“Bí ìwọ bá fi ọkàn rẹ fún un,

tí ìwọ sì na ọwọ́ rẹ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀,

14Bí ìwọ bá gbé ẹ̀ṣẹ̀ tí ń bẹ ní ọwọ́ rẹ jù sọnù,

tí ìwọ kò sì jẹ́ kí aburú gbé nínú àgọ́ rẹ.

15Nígbà náà ni ìwọ ó gbé ojú rẹ sókè láìní àbàwọ́n,

àní ìwọ yóò dúró ṣinṣin, ìwọ kì yóò sì bẹ̀rù,

16Nítorí pé ìwọ ó gbàgbé ìṣòro rẹ,

ìwọ ó sì rántí rẹ̀ bí omi tí ó ti sàn kọjá lọ.

17Ọjọ́ ayé rẹ yóò sì mọ́lẹ̀ ju ọ̀sán gangan lọ,

bí òkùnkùn tilẹ̀ bò ọ́ mọ́lẹ̀ nísinsin yìí, ìwọ ó dàbí òwúrọ̀.

18Ìwọ ó sì wà láìléwu, nítorí pé ìrètí wà;

àní ìwọ ó rin ilé rẹ wò, ìwọ ó sì sinmi ní àlàáfíà.

19Ìwọ ó sì dùbúlẹ̀ pẹ̀lú, kì yóò sì sí ẹni tí yóò dẹ́rùbà ọ́,

àní ènìyàn yóò máa wá ojúrere rẹ.

20Ṣùgbọ́n ojú ìkà ènìyàn yóò mófo;

gbogbo ọ̀nà àbáyọ ni yóò nù wọ́n,

ìrètí wọn a sì dàbí ẹni tí ó jọ̀wọ́ ẹ̀mí rẹ̀ lọ́wọ́.”

Kurdi Sorani Standard

ئەیوب 11:1-20

وەڵامی یەکەمی چۆفەر

1چۆفەری نەعماتیش وەڵامی دایەوە:

2«ئایا ئەم هەموو قسانە شایانی وەڵام نین،

یاخود پیاوی زۆربڵێ ئەستۆپاک دەبێت؟

3ئایا قسە پووچەکانت خەڵکی بێدەنگ دەکات،

یان گاڵتە دەکەیت و کەس نییە شەرمەزارت بکات؟

4بە خودا دەڵێیت ”باوەڕم بێگەردە و

من لەبەرچاوی تۆدا پاکم،“

5بەڵام خۆزگە خودا دەدوا و

لێوەکانی بەرامبەر بە تۆ دەکردەوە و

6نهێنییەکانی دانایی بۆت ئاشکرا دەکرد،

چونکە دانایی لایەکی ئاشکرا و لایەکی شاردراوەشی هەیە،

جا دەتزانی کە خودا لە تاوانەکەی خۆت کەمتر سزای داویت.

7«ئایا دەتوانیت لە نهێنییەکانی خودا بگەیت؟

ئایا دەتوانیت بگەیتە سنووری خودای هەرە بەتوانا؟

8ئەو لە ئاسمان بەرزترە، ئیتر تۆ چی دەکەیت،

لە جیهانی مردووان قووڵترە، ئیتر تۆ چی دەزانیت؟

9پێوانەکەی لە زەوی درێژترە و

لە دەریاش پانترە.

10«ئەگەر هات و تۆی خستە بەندیخانەوە و

تۆی بردە دادگا، کێ ڕێی لێ دەگرێت؟

11بێگومان ئەو دەزانێت خراپەکاران کێن و

خراپەکاری دەبینێت، وا دەزانیت ئاگای لێ نییە؟

12بەڵام پیاوێکی بێ ئەقڵ نابێتە تێگەیشتوو

هەتا جاشکی کەرەکێوی وەک مرۆڤ لەدایک نەبێت.

13«ئەگەر تۆ دڵی خۆت ئامادە بکەیت و

دەستی خۆتی بۆ پان بکەیتەوە،

14ئەگەر ئەو خراپەیەی لەناو دەستتە دووری بخەیتەوە و

نەهێڵیت ستەم لەناو چادرەکەت نیشتەجێ بێت،

15ئەو کاتە بەبێ کەموکوڕی شەرم ناکەیت و

چەسپاو دەبیت و ناترسیت.

16چەرمەسەری لەبیر دەکەیت و

وەک ئاوێکی تێپەڕیو یادی دەکەیتەوە.

17ژیانت لە نیوەڕۆ ڕۆشنتر دەبێت و

تاریکی وەک ڕووناکی بەیانی لێدێت.

18دڵنیا دەبیت، چونکە ئومێدت هەیە،

دەوروبەرەکەت دەپشکنیت و بە ئاسوودەییەوە پشوو دەدەیت.

19خۆت مات دەکەیت و کەس نییە هەراسانت بکات و

زۆر کەس لە ڕووی تۆ دەپاڕێنەوە.

20بەڵام چاوی بەدکاران کوێر دەبن و

پەناگا نامێنێت بۆ دەربازبوون؛

ئاواتیان ڕۆح سپاردنە.»