Joẹli 1 – YCB & CCB

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Joẹli 1:1-20

1Ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó tọ Joẹli ọmọ Petueli wá.

Ìṣígun Eṣú

2Ẹ gbọ́ èyí ẹ̀yin àgbàgbà;

ẹ fi etí sílẹ̀ gbogbo ẹ̀yin ènìyàn ará ilẹ̀ náà.

Ǹjẹ́ irú èyí ha wà ní ọjọ́ yín,

tàbí ní ọjọ́ àwọn baba yín?

3Ẹ sọ ọ́ fún àwọn ọmọ yín,

ki àwọn ọmọ yín sọ fún àwọn ọmọ wọn,

ki àwọn ọmọ wọn sọ fún àwọn ìran mìíràn.

4Èyí tí eṣú tí agénijẹ jẹ kù

ní ọ̀wọ́ eṣú ńláńlá ti jẹ,

èyí tí ọ̀wọ́ eṣú ńláńlá jẹ kù

ní eṣú kéékèèkéé jẹ

Èyí tí eṣú kéékèèkéé jẹ kù

ni eṣú apanirun mìíràn jẹ.

5Ẹ jí gbogbo ẹ̀yin ọ̀mùtí kí ẹ sì sọkún

ẹ hu gbogbo ẹ̀yin ọ̀mu-wáìnì;

ẹ hu nítorí wáìnì tuntun

nítorí a gbà á kúrò lẹ́nu yín.

61.6: If 9.8.Nítorí orílẹ̀-èdè kan ti ṣígun sí ilẹ̀ mìíràn

ó ní agbára púpọ̀, kò sì ní òǹkà;

ó ní eyín kìnnìún

ó sì ní èrìgì abo kìnnìún.

7Ó ti pa àjàrà mi run,

ó sì ti ya ẹ̀ka igi ọ̀pọ̀tọ́ mi kúrò,

ó ti bò èèpo rẹ̀ jálẹ̀, ó sì sọ ọ́ nù;

àwọn ẹ̀ka rẹ̀ ni a sì sọ di funfun.

8Ẹ pohùnréré ẹkún bí wúńdíá

tí a fi aṣọ ọ̀fọ̀ dí ni àmùrè, nítorí ọkọ ìgbà èwe rẹ̀.

9A ké ọrẹ jíjẹ́ àti ọrẹ mímu kúrò

ní ilé Olúwa;

àwọn àlùfáà ń ṣọ̀fọ̀, àwọn

ìránṣẹ́ Olúwa,

10Oko di ìgboro, ilẹ̀ ń ṣọ̀fọ̀,

nítorí a fi ọkà ṣòfò:

ọtí wáìnì tuntun gbẹ, òróró ń bùṣe.

11Kí ojú kí ó tì yín, ẹ̀yin àgbẹ̀;

ẹ pohùnréré ẹkún ẹ̀yin olùtọ́jú àjàrà,

nítorí alikama àti nítorí ọkà barle;

nítorí ìkórè oko ṣègbé.

12Àjàrà gbẹ, igi ọ̀pọ̀tọ́ sì rọ̀ dànù;

igi pomegiranate, igi ọ̀pẹ pẹ̀lú,

àti igi apiili, gbogbo igi igbó ni o rọ:

Nítorí náà ayọ̀ ọmọ ènìyàn gbẹ kúrò lọ́dọ̀ wọn.

Ìpè fún ìrònúpìwàdà

13Ẹ di ara yín ni àmùrè,

sí pohùnréré ẹkún ẹ̀yin àlùfáà:

ẹ pohùnréré ẹkún, ẹ̀yin ìránṣẹ́ pẹpẹ:

ẹ wá, fi gbogbo òru dùbúlẹ̀ nínú aṣọ ọ̀fọ̀,

ẹ̀yin ìránṣẹ́ Ọlọ́run mi: nítorí tí a dá ọrẹ-jíjẹ àti ọrẹ

mímu dúró ní ilé Ọlọ́run yín.

14Ẹ yà àwẹ̀ kan sí mímọ́,

ẹ pe àjọ kan tí o ní ìrònú,

ẹ pe àwọn àgbàgbà,

àti gbogbo àwọn ará ilẹ̀ náà

jọ sí ilé Olúwa Ọlọ́run yín,

kí ẹ sí ké pe Olúwa.

15A! Fún ọjọ́ náà,

nítorí ọjọ́ Olúwa kù sí dẹ̀dẹ̀,

yóò de bí ìparun láti ọwọ́ Olódùmarè.

16A kò ha ké oúnjẹ kúrò níwájú

ojú wá yìí,

ayọ̀ àti inú dídùn kúrò nínú ilé

Ọlọ́run wá?

17Irúgbìn bàjẹ́ nínú ebè wọn,

a sọ àká di ahoro, a wó àká palẹ̀;

nítorí tí a mú ọkà rọ.

18Àwọn ẹranko tí ń kérora tó!

Àwọn agbo ẹran dààmú,

nítorí tí wọ́n kò ni pápá oko;

nítòótọ́, àwọn agbo àgùntàn jìyà.

19Olúwa, sí ọ ni èmi o ké pè,

nítorí iná tí run pápá oko tútù aginjù,

ọwọ́ iná sí ti jó gbogbo igi igbó.

20Àwọn ẹranko igbó gbé ojú sókè sí ọ pẹ̀lú:

nítorí tí àwọn ìṣàn omi gbẹ,

iná sí ti jó àwọn pápá oko aginjù run.

Chinese Contemporary Bible (Simplified)

约珥书 1:1-20

1以下是耶和华对毗土珥的儿子约珥所说的话。

严重的蝗灾

2长老们啊,请听我说!

地上的所有居民啊,要留心听!

在你们或你们祖先的时代可曾发生过这样的事?

3要把这事告诉你们的子子孙孙,

传到世世代代!

4蝗虫吃剩的,蝻子来吃;

蝻子吃剩的,蚱蜢来吃;

蚱蜢吃剩的,蚂蚱来吃1:4 蝗虫蝻子蚱蜢蚂蚱”四个词希伯来语的确切意思很难考证。

5醉汉啊,醒过来哭泣吧!

贪杯的人啊,哀号吧!

你们再无美酒可饮了。

6有一群凶猛的蝗虫侵犯我的国土,

它们不计其数,

有雄狮的獠牙和母狮的利齿。

7它们毁坏我的葡萄树和无花果树,

剥光树皮,

只留下光秃的树枝。

8我的子民啊,你们要像死了未婚夫的少女,

穿上丧服痛哭哀号。

9耶和华殿中的素祭1:9 素祭就是献上五谷、面粉之类的供物,参见利未记2章。和奠祭1:9 奠祭就是献上新酿的酒。都停止了,

事奉耶和华的祭司都哀伤。

10田园荒废,遍地凄凉,

五谷尽毁,

再也没有新酒和油了。

11农夫啊,你们要忧伤!

照料葡萄园的人啊,

你们要哀号!

因为田间的大麦和小麦全毁了。

12葡萄树枯死,

无花果树凋残,

石榴树、棕树、苹果树等田野的一切树木枯干。

人间的欢乐消逝了。

13祭司啊,穿着丧服痛哭吧;

在祭坛前事奉的人啊,要哀号;

我上帝的仆人啊,要披上麻衣过夜;

因为再无素祭和奠祭献到你们上帝的殿中了。

14你们要定一个禁食的日子,

举行庄严的聚会,

召集全国的长老和人民,

到你们的上帝耶和华的殿中,

向耶和华呼求。

15太可怕了!耶和华的日子近了,

那是全能者施行毁灭的日子。

16我们的粮食断绝了,

我们上帝殿中的欢乐消失了。

17种子在土里腐烂,

五谷干死,仓库荒废,

谷仓被拆毁。

18牲畜哀鸣,

牛群因找不到草场而四处乱窜,

羊群也受苦。

19耶和华啊,我向你呼求,

因为火焰吞灭了旷野的草场,

烈火烧光了田野的树木。

20田野的走兽向你呼求,

因为溪水已经枯干,

火也烧尽了旷野的草场。