Hosea 4 – YCB & NIV

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Hosea 4:1-19

Ẹ̀sùn tí Ọlọ́run fi kan Israẹli

1Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa ẹ̀yin ọmọ Israẹli,

nítorí pé Olúwa fi ẹ̀sùn

kan ẹ̀yin tí ń gbé ní ilẹ̀ náà.

“Kò sí ìwà òtítọ́, kò sí ìfẹ́

Kò sí ìmọ̀ Ọlọ́run ní ilẹ̀ náà

2Àfi èpè, irọ́ pípa àti ìpànìyàn

olè jíjà àti panṣágà.

Wọ́n rú gbogbo òfin,

ìtàjẹ̀ sílẹ̀ sì ń gorí ìtàjẹ̀ sílẹ̀.

3Nítorí èyí, ilẹ̀ náà ń ṣọ̀fọ̀, gbogbo

olùgbé ibẹ̀ sì ń ṣòfò dànù.

Ẹranko igbó àti ẹyẹ ojú ọ̀run

àti ẹja inú omi ló ń kú.

4“Ṣùgbọ́n kí ẹnikẹ́ni má ṣe mú ẹ̀sùn wá,

kí ẹnìkan má sì ṣe fi ẹ̀sùn kan ẹnìkejì

nítorí àwọn ènìyàn rẹ̀ dàbí

àwọn ti ń fi ẹ̀sùn kan àlùfáà

5Ẹ ń ṣubú lọ́sàn án àti lóru

àwọn wòlíì yín sì ń ṣubú pẹ̀lú yín

Èmi ó pa ìyá rẹ run

6Àwọn ènìyàn mi ń ṣègbé nítorí pé wọn kò ní ìmọ̀.

“Nítorí pé ẹ ti kọ ìmọ̀ sílẹ̀.

Èmi náà kọ̀ yín ní àlùfáà mi;

nítorí pé ẹ ti kọ òfin Ọlọ́run yín sílẹ̀

Èmi náà yóò gbàgbé àwọn ọmọ yín.

7Bí àwọn àlùfáà ṣe ń pọ̀ sí i

bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe ń dẹ́ṣẹ̀ sí mi.

Wọ́n yí ògo mi padà sí ohun ìtìjú

8wọ́n ń jẹun nípa ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ènìyàn mi

Wọ́n sì ń gbádùn nínú ìwà búburú wọn.

9Yóò sì ṣe gẹ́gẹ́: bí ènìyàn ṣe rí náà ni àwọn àlùfáà rí

Èmi ó jẹ gbogbo wọn ní yà nítorí ọ̀nà wọn.

Èmi ó sì san án fún wọn gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ wọn.

10“Wọn ó máa jẹun ṣùgbọ́n wọn kò ní yó;

wọn ó ṣe àgbèrè ṣùgbọ́n, wọn kò ni pọ̀ sí i,

nítorí pé wọ́n ti kọ Olúwa

sílẹ̀ 11‘Wọ́n sì ti fi ara wọn’ fún àgbèrè,

wọ́n fi ara wọn fún wáìnì àtijọ́

àti tuntun èyí tó gba òye àwọn ènìyàn mi sọnù 12Wọ́n ń gba ìmọ̀ràn lọ́wọ́ ère igi

ọ̀pá igi sì ń dá wọn lóhùn.

Ẹ̀mí àgbèrè ti mú wọn ṣìnà

wọ́n sì jẹ́ aláìṣòótọ́ sí Ọlọ́run wọn.

13Wọ́n ń rú ẹbọ lórí àwọn òkè ńlá,

Wọ́n sì ń sun ọrẹ tùràrí lórí àwọn òkè kékeré

Lábẹ́ igi óákù, àti igi Poplari

àti igi ẹlimuati onírúurú igi tí ìbòjú rẹ̀ dára

Nítorí náà àwọn ọmọbìnrin yín yóò ṣe àgbèrè

àti àwọn àfẹ́sọ́nà yín yóò ṣe àgbèrè.

14“Èmi kò ní jẹ àwọn ọmọbìnrin yín

ní yà nígbà tí wọ́n bá ṣe àgbèrè

tàbí àwọn àfẹ́sọ́nà ọmọ yín,

nígbà tí wọ́n bá ṣe àgbèrè

nítorí pé àwọn ọkùnrin pàápàá ń bá alágbèrè kẹ́gbẹ́.

Wọ́n sì ń rú ẹbọ pẹ̀lú àwọn alágbèrè ojúbọ òrìṣà.

Nítorí náà, ènìyàn tí kò bá ní òye yóò parun!

15“Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé o ṣe àgbèrè ìwọ Israẹli

Ìdájọ́ yìí wà fún un yín Ẹ má ṣe jẹ́ kí Juda di ẹlẹ́bi.

“Ẹ má ṣe lọ sí Gilgali.

Ẹ má sì ṣe gòkè lọ sí Beti-Afeni

ẹ má sì búra pé, ‘Bí Olúwa ti wà láààyè nítòótọ́!’

16Àwọn ọmọ Israẹli ṣe agídí

bí alágídí ọmọ màlúù

Báwo wá ni Olúwa ṣe fẹ́ bọ́ wọn

bí àgùntàn ní pápá oko tútù?

17Efraimu ti darapọ̀ mọ́

òrìṣà Ẹ fi sílẹ̀!

18Bí ohun mímu wọn bá tilẹ̀ tán

wọ́n tún tẹ̀síwájú nínú àgbèrè

Àwọn olórí wọn fẹ́ràn ohun ìtìjú ju ohun ìyìn lọ.

19Ìjì ni yóò gbá wọn lọ.

Gbogbo ìrúbọ wọn yóò sì kó ìtìjú bá wọn.

New International Version

Hosea 4:1-19

The Charge Against Israel

1Hear the word of the Lord, you Israelites,

because the Lord has a charge to bring

against you who live in the land:

“There is no faithfulness, no love,

no acknowledgment of God in the land.

2There is only cursing,4:2 That is, to pronounce a curse on lying and murder,

stealing and adultery;

they break all bounds,

and bloodshed follows bloodshed.

3Because of this the land dries up,

and all who live in it waste away;

the beasts of the field, the birds in the sky

and the fish in the sea are swept away.

4“But let no one bring a charge,

let no one accuse another,

for your people are like those

who bring charges against a priest.

5You stumble day and night,

and the prophets stumble with you.

So I will destroy your mother—

6my people are destroyed from lack of knowledge.

“Because you have rejected knowledge,

I also reject you as my priests;

because you have ignored the law of your God,

I also will ignore your children.

7The more priests there were,

the more they sinned against me;

they exchanged their glorious God4:7 Syriac (see also an ancient Hebrew scribal tradition); Masoretic Text me; / I will exchange their glory for something disgraceful.

8They feed on the sins of my people

and relish their wickedness.

9And it will be: Like people, like priests.

I will punish both of them for their ways

and repay them for their deeds.

10“They will eat but not have enough;

they will engage in prostitution but not flourish,

because they have deserted the Lord

to give themselves 11to prostitution;

old wine and new wine

take away their understanding.

12My people consult a wooden idol,

and a diviner’s rod speaks to them.

A spirit of prostitution leads them astray;

they are unfaithful to their God.

13They sacrifice on the mountaintops

and burn offerings on the hills,

under oak, poplar and terebinth,

where the shade is pleasant.

Therefore your daughters turn to prostitution

and your daughters-in-law to adultery.

14“I will not punish your daughters

when they turn to prostitution,

nor your daughters-in-law

when they commit adultery,

because the men themselves consort with harlots

and sacrifice with shrine prostitutes—

a people without understanding will come to ruin!

15“Though you, Israel, commit adultery,

do not let Judah become guilty.

“Do not go to Gilgal;

do not go up to Beth Aven.4:15 Beth Aven means house of wickedness (a derogatory name for Bethel, which means house of God).

And do not swear, ‘As surely as the Lord lives!’

16The Israelites are stubborn,

like a stubborn heifer.

How then can the Lord pasture them

like lambs in a meadow?

17Ephraim is joined to idols;

leave him alone!

18Even when their drinks are gone,

they continue their prostitution;

their rulers dearly love shameful ways.

19A whirlwind will sweep them away,

and their sacrifices will bring them shame.