Gẹnẹsisi 9 – YCB & CCB

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Gẹnẹsisi 9:1-29

Májẹ̀mú Ọlọ́run pẹ̀lú Noa

19.1: Gẹ 1.28.Ọlọ́run sì súre fún Noa àti àwọn ọmọ rẹ̀ wí pé, “Ẹ máa bí sí i, kí ẹ sì pọ̀ ní iye, kí ẹ sì kún ayé. 2Ẹ̀rù yín yóò mú ojo wà lára gbogbo ẹranko àti gbogbo ẹyẹ ojú ọ̀run, àti gbogbo àwọn ẹ̀dá tí ń rìn nílẹ̀; àti gbogbo ẹja Òkun; a fi wọ́n lé e yín lọ́wọ́. 3Gbogbo ohun tó wà láààyè tí ó sì ń rìn, ni yóò jẹ́ oúnjẹ fún un yín, bí mo ṣe fi ewéko fún un yín náà ni mo fi ohun gbogbo fún un yín.

49.4: Le 7.26,27; 17.10-14; De 12.16,23.“Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò gbọdọ̀ jẹ ẹran tòun-tẹ̀jẹ̀ rẹ̀. 5Nítòótọ́ ẹ̀jẹ̀ yín, àní ẹ̀mí yín, ni èmi yóò sì béèrè; lọ́wọ́ gbogbo ẹranko ni èmí yóò béèrè rẹ̀, àti lọ́wọ́ ènìyàn, lọ́wọ́ arákùnrin olúkúlùkù ènìyàn ni èmi yóò béèrè ẹ̀mí ènìyàn.

69.6: Ek 20.13; Gẹ 1.26.“Ẹnikẹ́ni tí ó bá ta ẹ̀jẹ̀ ènìyàn sílẹ̀,

láti ọwọ́ ènìyàn ni a ó gbà ta ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sílẹ̀.

Nítorí ní àwòrán Ọlọ́run

ni Ọlọ́run dá ènìyàn.

79.7: Gẹ 1.28.Ṣùgbọ́n ní tiyín, ẹ máa bí sí i, kí ẹ sì máa pọ̀ sí i, ẹ máa gbá yìn lórí ilẹ̀, kí ẹ sì pọ̀ sí i lórí rẹ̀.”

8Ọlọ́run sì wí fún Noa àti àwọn ọmọ rẹ̀ pé: 9“Mo dá májẹ̀mú mi pẹ̀lú yín àti pẹ̀lú àwọn ìran yín tí ń bọ̀ lẹ́yìn. 10Àti pẹ̀lú gbogbo ẹ̀dá alààyè tí ó wà pẹ̀lú yín, ìbá à ṣe ẹyẹ, ẹja, ẹran ọ̀sìn, ẹranko igbó, gbogbo ohun tí ó jáde kúrò nínú ọkọ̀ pẹ̀lú yín, àní gbogbo ẹ̀dá alààyè ní ayé. 11Mo dá májẹ̀mú mi pẹ̀lú yín, láéláé, Èmi kì yóò fi ìkún omi pa ayé run kúrò mọ láéláé, a kì yóò fi omi pa ayé run.”

12Ọlọ́run sì wí pé, “Èyí ni ààmì májẹ̀mú tí mo ń dá yìí láàrín èmi àti ẹ̀yin àti ẹ̀dá alààyè tí ó wà pẹ̀lú yín, májẹ̀mú àtìrandíran tó ń bọ̀: 13Mo ti fi òṣùmàrè sí àwọsánmọ̀, yóò sì jẹ́ ààmì májẹ̀mú láàrín èmi àti ayé. 14Nígbàkúgbà tí mo bá mú kí òjò ṣú, tí òṣùmàrè bá farahàn ní àwọsánmọ̀. 15Èmi yóò rántí májẹ̀mú mi, tí ó wà láàrín èmi àti ẹ̀yin àti gbogbo ẹ̀dá alààyè, kì yóò sì tún sí ìkún omi mọ́ láti pa gbogbo ẹ̀dá run. 16Nígbàkígbà tí òṣùmàrè bá yọ ní àwọsánmọ̀, èmi yóò rí i, èmi yóò sì rántí májẹ̀mú ayérayé tí ń bẹ láàrín Ọlọ́run àti gbogbo ẹ̀dá alààyè tí ń bẹ ní ayé.”

17Ọlọ́run sì wí fún Noa pé, “Èyí ni ààmì májẹ̀mú tí mo ti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ láàrín èmi àti gbogbo alààyè ní ayé.”

Àwọn ọmọ Noa

18Àwọn ọmọ Noa tí ó jáde nínú ọkọ̀ ni Ṣemu, Hamu àti Jafeti. (Hamu ni baba Kenaani). 19Láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Noa mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yìí ni gbogbo ènìyàn ti tàn ká gbogbo ilẹ̀ ayé.

20Noa bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ àgbẹ̀, ó sì gbin ọgbà àjàrà. 21Ó mu àmupara nínú ọtí wáìnì àjàrà rẹ̀, ó sì tú ara rẹ̀ sí ìhòhò, ó sì sùn nínú àgọ́ rẹ̀. 22Hamu tí í ṣe baba Kenaani sì rí baba rẹ̀ ní ìhòhò bẹ́ẹ̀ ni ó sì lọ sọ fún àwọn arákùnrin rẹ̀ méjèèjì ní ìta. 23Ṣùgbọ́n Ṣemu àti Jafeti mú aṣọ lé èjìká wọn, wọ́n sì fi ẹ̀yìn rìn, wọ́n sì bo ìhòhò baba wọn. Wọ́n kọjú sẹ́yìn kí wọn kí ó má ba à rí ìhòhò baba wọn.

24Nígbà tí Noa kúrò ní ojú ọtí, tí ó sì mọ ohun tí ọmọ rẹ̀ kékeré ṣe sí i. 25Ó wí pé:

“Ègún ni fún Kenaani.

Ìránṣẹ́ àwọn ìránṣẹ́ ni yóò máa ṣe

fún àwọn arákùnrin rẹ̀.”

26Ó sì tún wí pé;

“Olùbùkún ni Olúwa, Ọlọ́run Ṣemu

Kenaani yóò máa ṣe ẹrú fún Ṣemu.

27Ọlọ́run yóò mú Jafeti gbilẹ̀,

Jafeti yóò máa gbé ní àgọ́ Ṣemu

Kenaani yóò sì jẹ́ ẹrú fún un.”

28Noa wà láààyè fún irínwó ọdún ó-dínàádọ́ta (350) lẹ́yìn ìkún omi. 29Àpapọ̀ ọjọ́ ayé Noa jẹ́ ẹgbẹ̀rún-dín-ní-àádọ́ta ọdún, (950) ó sì kú.

Chinese Contemporary Bible (Simplified)

创世记 9:1-29

上帝与挪亚立约

1上帝赐福给挪亚和他的儿子们,对他们说:“你们要生养众多,遍布地面。 2你们要管理所有地上的走兽、空中的飞鸟、地上的爬虫和海里的鱼,它们都必惧怕你们。 3凡是活着的动物都可作你们的食物,就像菜蔬和谷物一样。 4只是你们不可吃带血的肉,因为血就是生命。 5凡是杀人害命的,无论人或兽,我必向他们追讨血债。凡杀人的,我必追讨他的血债。 6凡杀害人的,也必被人杀害,因为人是上帝照着自己的形象造的。 7你们要生养众多,使地上人口兴旺。”

8上帝又对挪亚和他的儿子们说: 9“我要跟你们和你们的后代, 10以及所有和你们在一起、从方舟出来的飞禽走兽和牲畜等各种动物立约。 11我与你们立约,不再叫洪水淹没一切生灵,也不再让洪水毁灭大地。” 12上帝说:“我与你们及各种生灵立世代永存的约,我要给这个约一个记号。 13我把彩虹放在云中,作为我跟大地立约的记号。 14我使云彩覆盖大地的时候,会有彩虹在云中出现。 15这样我会记得我与你们及一切生灵所立的约,水就不会再泛滥淹灭所有生灵。 16当我看见彩虹在云中出现的时候,就会记得我与地上一切生灵立的永约。” 17上帝对挪亚说:“彩虹是我与地上一切生灵立约的记号。”

挪亚和他的儿子

18挪亚一起出方舟的有他的儿子雅弗迦南的父亲。 19挪亚这三个儿子的后代遍布天下。

20挪亚做了农夫,他是第一个栽种葡萄园的人。 21一天,他喝葡萄酒喝醉了,赤裸着身体躺在帐篷里。 22迦南的父亲看见他父亲赤身露体,便去告诉外面的两个弟兄。 23于是,雅弗拿了一件衣服搭在肩上,倒退着走进帐篷,把衣服盖在父亲身上,他们背着脸不看父亲赤裸的身体。

24挪亚酒醒后,知道了小儿子做的事, 25就说:

迦南该受咒诅,

必做他弟兄的仆人的仆人。”

26又说:

的上帝耶和华当受称颂!

迦南要做的仆人。

27愿上帝扩张雅弗的疆界,

愿他住在的帐篷里,

迦南做他的仆人。”

28洪水以后,挪亚又活了三百五十年。 29挪亚一生共活了九百五十岁。