Gẹnẹsisi 48 – YCB & NIRV

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Gẹnẹsisi 48:1-22

Manase àti Efraimu

1Lẹ́yìn ìgbà díẹ̀ si, a wí fún Josẹfu pé, “Baba rẹ ń ṣàìsàn,” nítorí náà, ó mú àwọn ọmọ rẹ̀ méjèèjì, Manase àti Efraimu lọ́wọ́ lọ pẹ̀lú rẹ̀. 2Nígbà tí a sọ fún Jakọbu pé, “Josẹfu ọmọ rẹ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ,” Israẹli rọ́jú dìde jókòó lórí ibùsùn rẹ̀.

348.3,4: Gẹ 28.13,14.Jakọbu wí fún Josẹfu pé, “Ọlọ́run Olódùmarè (Eli-Ṣaddai) fi ara hàn mí ní Lusi ní ilẹ̀ Kenaani, níbẹ̀ ni ó sì ti súre fún mi. 4Ó sì wí fún mi pé, ‘Èmi yóò mú kí o bí sí i, ìwọ yóò sì pọ̀ sí i, Èmi yóò sì sọ ọ́ di orílẹ̀-èdè ńlá, Èmi yóò sì fún ìwọ àti irú-ọmọ rẹ lẹ́yìn rẹ ní ilẹ̀ yìí gẹ́gẹ́ bí ohun ìní ayérayé.’

5“Nítorí náà báyìí, àwọn ọmọ rẹ méjèèjì tí a bí fún ọ ní ilẹ̀ Ejibiti, kí èmi kí ó tó tọ̀ ọ́ wá ní ìhín, ni mo sọ di ọmọ mi fúnra mi. Manase àti Efraimu yóò jẹ́ tèmi gẹ́gẹ́ bí Reubeni àti Simeoni ti jẹ́ tèmi. 6Àwọn ọmọ mìíràn tí ìwọ bá bí lẹ́yìn wọn yóò jẹ́ ọmọ rẹ. Ní ilẹ̀ tí wọn yóò jogún, orúkọ arákùnrin wọn ni a ó máa fi pè wọ́n. 748.7: Gẹ 35.16-19.Bí mo ti ń padà láti Padani, Rakeli kú ní ọ̀nà nígbà tí ó ṣì wà ní ilẹ̀ Kenaani, èyí tó mú ìbànújẹ́ bá mi, níbi tí kò jìnnà sí Efrata: Nítorí náà èmí sì sin ín sí ẹ̀bá ọ̀nà tí ó lọ sí Efrata” (tí ṣe Bẹtilẹhẹmu).

8Nígbà tí Israẹli rí àwọn ọmọ Josẹfu, ó béèrè wí pé, “Àwọn wo nìyí?”

9Josẹfu fún baba rẹ̀ lésì pé, “Wọ̀nyí ni àwọn ọmọkùnrin tí Ọlọ́run ti fi fún mi ní ìhín.”

Nígbà náà ni Israẹli wí pé, “Kó wọn wá sí ọ̀dọ̀ mi kí èmi kí ó ba à le súre fún wọn.”

10Báyìí, ojú Israẹli ti ń di bàìbàì nítorí ogbó, agbára káká sì ni ó fi ń ríran. Josẹfu sì kó àwọn ọmọ rẹ̀ súnmọ́ ọ̀dọ̀ rẹ̀, baba rẹ̀ fẹnukò wọ́n ni ẹnu, ó sì dì mọ́ wọn.

11Israẹli wí fún Josẹfu pé, “Èmi kò lérò rárá pé, mo tún le rí ojú rẹ mọ́ láéláé, ṣùgbọ́n Ọlọ́run tún fún mi ní àǹfààní, mo sì tún rí àwọn ọmọ rẹ pẹ̀lú.”

12Nígbà náà ni Josẹfu kó àwọn ọmọ náà kúrò ní orí eékún baba rẹ̀, ó wólẹ̀, ó sì tẹríba. 13Josẹfu sì mú àwọn méjèèjì, Efraimu ni o fi sí ọwọ́ ọ̀tún òun tìkára rẹ̀, èyí tí í ṣe ọwọ́ òsì fún Israẹli, ó sì fi Manase sí ọwọ́ òsì ara rẹ̀, èyí tí ó bọ́ sí ọwọ́ ọ̀tún Israẹli. 14Israẹli sì na ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ jáde, ó sì gbe lé Efraimu lórí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun ni àbúrò, ó sì fi ọwọ́ rẹ̀ tàsé ara wọn, ó sì na ọwọ́ òsì lé Manase lórí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Manase ni àkọ́bí.

15Nígbà náà ni ó súre fún Josẹfu wí pé,

“Ǹjẹ́ kí Ọlọ́run, ẹni tí baba mi

Abrahamu àti Isaaki rìn níwájú rẹ̀,

Ọlọ́run tí ó ti jẹ́ olùtọ́jú àti aláàbò

mi ní gbogbo ọjọ́ ayé mi títí di òní,

16Angẹli tí ó dá mi ní ìdè kúrò lọ́wọ́ gbogbo ewu,

kí ó súre fún àwọn ọmọkùnrin wọ̀nyí.

Kí a máa fi orúkọ mi pè wọ́n àti orúkọ àwọn baba mi

Abrahamu àti Isaaki,

kí wọn kí ó sì pọ̀ sí i lọ́pọ̀lọpọ̀

lórí ilẹ̀ ayé.”

17Nígbà tí Josẹfu rí i pé baba òun gbé ọwọ́ ọ̀tún lé Efraimu lórí, inú rẹ̀ bàjẹ́, ó sì gbá ọwọ́ baba rẹ̀ mú láti gbé ọwọ́ rẹ̀ kúrò lórí Efraimu lọ sí orí Manase. 18Josẹfu wí fun pé, “Rárá, baba mi, èyí ni àkọ́bí, orí rẹ̀ ni kí ìwọ kí o gbé ọwọ́ ọ̀tún rẹ lé.”

19Ṣùgbọ́n baba rẹ̀ kò gbà, ó wí pé, “Mo mọ̀, ọmọ mi, mo mọ̀. Òun náà yóò di orílẹ̀-èdè, òun náà yóò sì di ńlá. Ṣùgbọ́n àbúrò rẹ̀ yóò di ẹni ńlá jù ú lọ, irú-ọmọ rẹ yóò sì di ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè.” 2048.20: Hb 11.21.Ó súre fún wọn lọ́jọ́ náà pé,

“Ní orúkọ yín ni Israẹli yóò máa súre yìí pé:

‘Kí Ọlọ́run ṣe ọ́ bí i ti Efraimu àti Manase.’ ”

Ó sì gbé Efraimu gẹ́gẹ́ bí ẹ̀gbọ́n sí Manase.

21Nígbà náà ni Israẹli wí fún Josẹfu pé, “Ọjọ́ ikú mi súnmọ́ etílé, ṣùgbọ́n Ọlọ́run yóò wà pẹ̀lú yín, yóò sì mú un yín padà sí ilẹ̀ àwọn baba yín. 22Pẹ̀lúpẹ̀lú èmi yóò fún ọ ní ìpín kan ju ti àwọn arákùnrin rẹ lọ. Ilẹ̀ tí mo fi idà àti ọ̀kọ̀ mi gbà lọ́wọ́ àwọn ará Amori.”

New International Reader’s Version

Genesis 48:1-22

Ephraim and Manasseh

1Some time later Joseph was told, “Your father is sick.” So he took his two sons Manasseh and Ephraim along with him. 2Jacob was told, “Your son Joseph has come to you.” So Israel became stronger and sat up in bed.

3Jacob said to Joseph, “The Mighty God appeared to me at Luz in the land of Canaan. He blessed me there. 4He said to me, ‘I am going to give you children. I will make your family very large. I will make you a community of nations. And I will give this land to your children after you. It will belong to them forever.’

5“Now then, two sons were born to you in Egypt. It happened before I came to you here. They will be counted as my own sons. Ephraim and Manasseh will belong to me, in the same way that Reuben and Simeon belong to me. 6Any children born to you after them will belong to you. Any territory they receive will come from the land that will be given to Ephraim and Manasseh. 7As I was returning from Paddan, Rachel died. It made me very sad. She died in the land of Canaan while we were still on the way. We weren’t very far away from Ephrath. So I buried her body there beside the road to Ephrath.” Ephrath was also called Bethlehem.

8Israel saw Joseph’s sons. He asked, “Who are they?”

9“They are the sons God has given me here,” Joseph said to his father.

Then Israel said, “Bring them to me. I want to give them my blessing.”

10Israel’s eyes were weak because he was old. He couldn’t see very well. So Joseph brought his sons close to him. His father kissed them and hugged them.

11Israel said to Joseph, “I never thought I’d see your face again. But now God has let me see your children too.”

12Then Joseph lifted his sons off Israel’s knees. Joseph bowed down with his face to the ground. 13He placed Ephraim on his right, toward Israel’s left hand. He placed Manasseh on his left, toward Israel’s right hand. Then he brought them close to Israel. 14But Israel reached out his right hand and put it on Ephraim’s head. He did it even though Ephraim was the younger son. He crossed his arms and put his left hand on Manasseh’s head. He did it even though Manasseh was the older son.

15Then Israel gave Joseph his blessing. He said,

“May God bless these boys.

He is the God of my grandfather Abraham and my father Isaac.

They walked faithfully with him.

He is the God who has been my shepherd

all my life right up to this day.

16He is the Angel who has saved me from all harm.

May he bless these boys.

May they be called by my name.

May they also be called by the names of my grandfather Abraham and my father Isaac.

And may the number of them greatly increase

on the earth.”

17Joseph saw his father putting his right hand on Ephraim’s head. And Joseph didn’t like it. So he took hold of his father’s hand to move it over to Manasseh’s head. 18Joseph said to him, “No, my father. Here’s my older son. Put your right hand on his head.”

19But his father wouldn’t do it. He said, “I know, my son. I know. He too will become a nation. He too will become great. But his younger brother will be greater than he is. His children after him will become a group of nations.” 20On that day, Jacob gave them his blessing. He said,

“The people of Israel will bless others in your name.

They will say, ‘May God make you like Ephraim and Manasseh.’ ”

So he put Ephraim ahead of Manasseh.

21Then Israel said to Joseph, “I’m about to die. But God will be with all of you. He’ll take you back to the land of your fathers. 22But to you, Joseph, I am giving more land than your brothers. I’m giving you the land I took from the Amorites. I took it with my sword and bow.”