Gẹnẹsisi 37 – YCB & CCBT

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Gẹnẹsisi 37:1-36

Àlá Josẹfu

1Jakọbu sì gbé ilẹ̀ Kenaani ní ibi ti baba rẹ̀ ti gbé.

2Èyí ni àwọn ìtàn Jakọbu.

Nígbà tí Josẹfu di ọmọ ọdún mẹ́tà-dínlógún (17), ó ń ṣọ́ agbo ẹran pẹ̀lú àwọn arákùnrin rẹ̀, àwọn ọmọ Biliha àti Silipa aya baba rẹ̀ Josẹfu sì ń ròyìn àwọn aburú tí wọ́n ń ṣe fún baba wọn.

3Israẹli sì fẹ́ràn Josẹfu ju gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀ tókù lọ, nítorí ní ọjọ́ ogbó rẹ̀ ni ó bí i. O sì dá aṣọ aláràbarà tí ó kún fún onírúurú ọnà lára fún un. 4Nígbà tí àwọn arákùnrin rẹ̀ rí i pé baba àwọn fẹ́ràn rẹ̀ ju gbogbo wọn lọ, wọ́n kórìíra rẹ̀, wọ́n sì ń fi ẹ̀tanú bá a gbé, kò sì sí àlàáfíà láàrín wọn.

5Josẹfu lá àlá kan, nígbà tí ó sì sọ fún àwọn arákùnrin rẹ̀, wọ́n túbọ̀ kórìíra rẹ̀ sí i. 6O wí fún wọn pé, “Ẹ fetí sí àlá tí mo lá: 7Sá à wò ó, àwa ń yí ìtí ọkà nínú oko, ó sì ṣe ìtí ọkà tèmi sì dìde dúró ṣánṣán, àwọn ìtí ọkà tiyín sì dúró yí ìtí tèmi ká, wọ́n sì ń foríbalẹ̀ fún un.”

8Àwọn arákùnrin rẹ̀ wí fún un pé, “Ìwọ ń gbèrò àti jẹ ọba lé wa lórí bí? Tàbí ìwọ ó ṣe olórí wa nítòótọ́?” Wọn sì túbọ̀ kórìíra rẹ̀ sí i, nítorí àlá rẹ̀ àti nítorí ohun tí ó wí.

9O sì tún lá àlá mìíràn, ó sì tún sọ ọ́ fún àwọn arákùnrin rẹ̀. Ó wí pé, ẹ tẹ́tí sí mi, “Mo tún lá àlá mìíràn, wò ó, oòrùn, òṣùpá àti ìràwọ̀ mọ́kànlá ń foríbalẹ̀ fún mi.”

10Nígbà tí ó sọ fún baba rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ pẹ̀lú, baba rẹ̀ bá a wí pé, “irú àlá wo ni ìwọ lá yìí? Ṣé ìyá rẹ, pẹ̀lú èmi àti àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ yóò wá foríbalẹ̀ níwájú rẹ ni?” 1137.11,28: Ap 7.9.Àwọn arákùnrin rẹ̀ sì ń ṣe ìlara rẹ̀ ṣùgbọ́n baba rẹ̀ pa ọ̀rọ̀ náà mọ́ lọ́kàn rẹ̀.

Àwọn arákùnrin Josẹfu tà á

12Àwọn arákùnrin rẹ̀ sì da ẹran baba wọn lọ sí Ṣekemu. 13Israẹli sì wí fún Josẹfu pé, “Ṣé o mọ̀ pé, àwọn arákùnrin rẹ ń da ẹran ní Ṣekemu, wá, jẹ́ kí n rán ọ sí wọn.”

Josẹfu sì dáhùn pé, “Èmi nìyí.”

14O sì wí fún un pé, “Lọ wò bí àwọn arákùnrin rẹ àti àwọn agbo ẹran bá wà ní àlàáfíà, kí o sì wá jíṣẹ́ fún mi.” Ó sì rán Josẹfu lọ láti Àfonífojì Hebroni.

Nígbà tí Josẹfu dé Ṣekemu, 15Ọkùnrin kan sì rí i tí ó ń rìn kiri inú pápá, ó sì bi í pé, “Kín ni ò ń wá?”

16Ó sì dáhùn pé, “Àwọn arákùnrin mi ni mò ń wá, ǹjẹ́ o mọ ibi tí wọ́n wà pẹ̀lú agbo ẹran?”

17Ọkùnrin náà dáhùn pé, “Wọ́n ti kúrò ní ìhín, mo gbọ́ tí wọ́n ń wí pé, ‘Ẹ jẹ́ kí a lọ sí Dotani.’ ”

Josẹfu sì wá àwọn arákùnrin rẹ̀ lọ, ó sì rí wọn ní tòsí Dotani. 18Ṣùgbọ́n bí wọ́n sì ti rí i tí ń bọ̀ lókèèrè, kí ó sì tó dé ọ̀dọ̀ wọn, wọn gbìmọ̀ pọ̀ láti pa á.

19“Alálàá ni ń bọ̀ yìí,” ni wọ́n ń wí fún ara wọn. 20“Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a pa á. Kí a sì ju òkú rẹ̀ sínú kòtò, a ó sì wí pé, ẹranko búburú ni ó pa á, kí a máa wo ọ̀nà tí àlá rẹ̀ yóò gbà ṣẹ.”

21Nígbà tí Reubeni gbọ́ èyí, ó gbìyànjú láti gbà á sílẹ̀ ní ọwọ́ wọn, ó sì wí pé, “Ẹ má ṣe jẹ́ kí a gba ẹ̀mí rẹ̀, 22Ẹ má ṣe jẹ́ kí a ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀, ẹ má ṣe fọwọ́ kàn án, ẹ kúkú jù ú sínú kòtò láààyè nínú aginjù níbí.” Reubeni sọ èyí, kí ó ba à le gbà á kúrò lọ́wọ́ wọn, kí ó sì dá a padà lọ fún baba rẹ̀.

23Nítorí náà, nígbà tí Josẹfu dé ọ̀dọ̀ àwọn arákùnrin rẹ̀, wọ́n bọ́ ẹ̀wù rẹ̀—Ẹ̀wù ọlọ́nà, aláràbarà tí ó wọ̀— 24wọ́n mú un, wọ́n sì jù ú sínú kòtò. Kòtò náà sì ṣófo, kò sí omi nínú rẹ̀.

25Bí wọ́n sì ti jókòó láti jẹun, wọ́n gbójú sókè, wọ́n sì rí àwọn oníṣòwò ará Iṣmaeli tí wọ́n ń wọ́ bọ̀ láti Gileadi. Ìbákasẹ wọn sì ru tùràrí, ìkunra àti òjìá, wọ́n ń lọ sí Ejibiti.

26Juda wí fún àwọn arákùnrin rẹ̀ pé, “Èrè kí ni ó jẹ́ bí a bá pa arákùnrin wa tí a bo ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ mọ́lẹ̀ ti ọkàn wa sì ń dá wa lẹ́bi? 27Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á tà á fún àwọn ará Iṣmaeli, kí àwa má sì pa á, ṣè bí àbúrò wa ni, ẹran-ara wa àti ẹ̀jẹ̀ wa ní i ṣe.” Àwọn arákùnrin rẹ̀ sì fi ara mọ́ ohun tí ó sọ.

2837.28: Ap 7.9.Nítorí náà, nígbà tí àwọn oníṣòwò ara Midiani ń kọjá, àwọn arákùnrin Josẹfu fà á jáde láti inú kòtò, wọ́n sì tà á fún àwọn ará Iṣmaeli ní ogún owó wúrà, wọ́n sì mú Josẹfu lọ sí ilẹ̀ Ejibiti.

29Nígbà tí Reubeni padà dé ibi kòtò tí ó sì ri pé Josẹfu kò sí níbẹ̀ mọ́, ó fa aṣọ rẹ̀ ya pẹ̀lú ìbànújẹ́. 30Ó padà lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn arákùnrin rẹ̀, ó sì wí pé, “Ọmọdékùnrin náà kò sí níbẹ̀ mọ́! Níbo ni ẹ fẹ́ kí n wọ̀ báyìí?”

31Nígbà náà ni wọ́n mú aṣọ Josẹfu, wọ́n pa ewúrẹ́ kan, wọ́n sì tẹ aṣọ náà bọ inú ẹ̀jẹ̀ ewúrẹ́ náà. 32Wọ́n sì mú aṣọ ọlọ́nà aláràbarà náà padà sí ọ̀dọ̀ baba wọn, wọ́n sì wí pé, “A rí èyí he nínú oko, yẹ̀ ẹ́ wò, kí o sì mọ̀ bóyá ti ọmọ rẹ ni.”

33Ó sì dá a mọ̀, ó wí pé, “Háà! Aṣọ ọmọ mi ni, ẹranko búburú ti pa á jẹ, láìṣe àní àní, ó ti fa Josẹfu ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ.”

34Nígbà náà ni Jakọbu fa aṣọ rẹ̀ ya, ó sì wọ aṣọ ọ̀fọ̀, ó sì ṣọ̀fọ̀ ọmọ rẹ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọjọ́ 35Gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀ lọ́kùnrin, lóbìnrin wá láti tù ú nínú, ṣùgbọ́n kò gbà. Ó wí pé, “Rárá, nínú ọ̀fọ̀ yìí ni èmi yóò lọ sí isà òkú lọ́dọ̀ ọmọ mi.” Baba Josẹfu sì sọkún fún un.

36Ní gbogbo àkókò wọ̀nyí, àwọn ará Midiani ta Josẹfu ní Ejibiti fún Potiferi, ọ̀kan nínú àwọn ìjòyè Farao, tí í ṣe olórí ẹ̀ṣọ́.

Chinese Contemporary Bible (Traditional)

創世記 37:1-36

約瑟的夢

1雅各住在他父親寄居的迦南2以下是有關雅各一家的記載。

十七歲的少年約瑟跟哥哥們,就是雅各的妾辟拉悉帕生的兒子們一同放羊。他向父親報告哥哥們做的壞事。 3約瑟以色列年老時生的,以色列特別寵愛他,為他做了一件彩衣。 4約瑟的哥哥們見父親偏愛他,就懷恨在心,對他惡言相向。

5約瑟做了一個夢,並告訴了哥哥們,他們更恨他了。 6約瑟對哥哥們說:「你們聽聽我做的夢—— 7我們在田裡捆莊稼,我捆的莊稼站起來,你們捆的莊稼都圍著我捆的莊稼下拜。」 8他的哥哥們回答說:「難道你真想做我們的王統治我們嗎?」他們因約瑟的夢和他說的話而更恨他。

9後來,約瑟又做了一個夢,他又去對哥哥們說:「你們聽聽我做的另一個夢,我夢見太陽、月亮和十一顆星星都向我下拜。」 10約瑟把夢告訴了父親和哥哥們,他父親就責備他說:「你做的是什麼夢!難道你的父母弟兄都要來向你俯伏下拜嗎?」 11約瑟的哥哥們嫉恨他,他父親卻把這些話記在心裡。

12約瑟的哥哥們到示劍放父親的羊。 13以色列約瑟叫來,對他說:「你哥哥們在示劍放羊,我要派你去他們那裡。」約瑟說:「好的。」 14以色列說:「你去看看你哥哥們以及羊群是否平安,然後回來告訴我。」於是,約瑟就從希伯崙谷出發去示劍15有人見他在田野走迷了路,就問他:「你在找什麼?」 16約瑟回答說:「我在找我哥哥們,你知道他們在哪裡放羊嗎?」 17那人說:「他們已經走了,我聽他們說要到多坍去。」約瑟就趕往多坍,在那裡找到了他們。

18約瑟的哥哥們遠遠看見他走來,趁他還沒有到跟前,就合謀要害死他。 19他們彼此商量說:「看!做夢的來了。 20來吧!我們殺了他,把他扔在井裡,就說有野獸把他吃掉了,看他的夢怎麼實現。」 21呂便聽後想救約瑟的性命,就說:「我們不要害他性命。」 22他又說:「不要殺人流血,把他扔在這口井裡吧,不要下手害他。」呂便想救約瑟,把他交回給父親。 23這時候,約瑟來了,他們就脫去他身上的彩衣, 24把他扔到井裡。當時,那口井是乾的,沒有水。

25他們坐下來吃飯的時候,看見一隊從基列來的以實瑪利商人用駱駝馱著香料、乳香、沒藥去埃及26猶大對他的眾弟兄說:「我們殺死弟弟、掩蓋罪行有什麼益處呢? 27不如把他賣給以實瑪利人,不要下手害他,他畢竟是我們的弟弟,我們的骨肉啊!」其他弟兄都贊成他的意見。 28於是,那些米甸商人經過的時候,他們就把約瑟從井裡拉上來,以二百二十克銀子的價錢把他賣給了以實瑪利人。這些商人把他帶到埃及去了。

29呂便回到井邊發現約瑟不見了,就傷心地撕裂了身上的衣服, 30回到弟兄們那裡說:「那少年不見了,我現在怎麼辦?」 31他們宰了一隻公山羊,把血染在約瑟的彩衣上, 32拿去給父親,說:「我們撿到這件衣服,你看看是不是你兒子的?」 33雅各認出那件彩衣,說:「這是我兒子的衣服,一定是野獸把他吃了,約瑟一定被撕碎了!」 34雅各撕裂自己的衣服,束上麻布,為約瑟哀傷了好幾天。 35他的兒女都來安慰他,他卻不肯接受他們的安慰,說:「我一定會淒淒慘慘地下到陰間,去我兒子那裡。」約瑟的父親為他哀哭。

36那些米甸人把約瑟帶到埃及後,把他賣給了法老的內臣——護衛長波提乏