Gẹnẹsisi 36 – YCB & NASV

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Gẹnẹsisi 36:1-43

Àwọn ìránṣẹ́ Esau

1Wọ̀nyí ni ìran Esau, ẹni tí a ń pè ní Edomu.

236.2: Gẹ 26.34; 28.9.Nínú àwọn ọmọbìnrin Kenaani ni Esau ti fẹ́ àwọn ìyàwó rẹ̀: Adah ọmọbìnrin Eloni ará Hiti àti Oholibama, ọmọbìnrin Ana, ọmọ ọmọ Sibeoni ará Hifi. 336.3: Gẹ 28.9.Ó sì tún fẹ́ Basemati ọmọ Iṣmaeli arábìnrin Nebaioti.

4Adah bí Elifasi fún Esau, Basemati sì bí Reueli, 5Oholibama pẹ̀lú sì bí Jeuṣi, Jalamu, àti Kora. Àwọn wọ̀nyí ni ọmọ tí Esau bí ní Kenaani.

6Esau sì mú àwọn aya rẹ̀, àwọn ọmọkùnrin rẹ̀, àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ àti gbogbo àwọn ará ilé rẹ̀, àwọn ohun ọ̀sìn rẹ̀ àti àwọn ẹran ọ̀sìn mìíràn àti gbogbo ohun ìní mìíràn tí ó ní, ni Kenaani, ó sì kó lọ sí ilẹ̀ mìíràn, jìnà sí ibi tí Jakọbu arákùnrin rẹ̀ wà. 7Ohun ìní wọn pọ̀ ju èyí tí àwọn méjèèjì lè máa gbé ní ojú kan lọ. Ilẹ̀ tí wọ́n wà kò le gba àwọn méjèèjì nítorí àwọn ohun ọ̀sìn wọn. 8Báyìí ni Esau tí a tún mọ̀ sí Edomu tẹ̀dó sí àwọn orílẹ̀-èdè olókè tí Seiri.

9Èyí ni ìran Esau baba àwọn ará Edomu ní àwọn orílẹ̀-èdè olókè Seiri.

10Wọ̀nyí ni orúkọ àwọn ọmọ Esau:

Elifasi ọmọ Adah aya Esau àti Reueli, ọmọ Basemati tí í ṣe aya Esau pẹ̀lú.

11Àwọn ọmọ Elifasi ni ìwọ̀nyí:

Temani, Omari, Sefi, Gatamu, àti Kenasi. 12Elifasi ọmọ Esau sì tún ní àlè tí a ń pè ní Timna pẹ̀lú, òun ló bí Amaleki fún un. Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ ọmọ Adah aya Esau.

13Àwọn ọmọ Reueli:

Nahati, Sera, Ṣamma àti Missa. Àwọn ni ọmọ ọmọ Basemati aya Esau.

14Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Oholibama ọmọbìnrin Ana ọmọ ọmọ Sibeoni: tí ó bí fún Esau:

Jeuṣi, Jalamu àti Kora.

15Àwọn wọ̀nyí ni olórí nínú àwọn ọmọ Esau:

Àwọn ọmọ Elifasi, àkọ́bí Esau:

Temani, Omari, Sefi, Kenasi, 16Kora, Gatamu àti Amaleki. Àwọn wọ̀nyí ló jẹ́ olórí ìdílé tí ó ti ọ̀dọ̀ Elifasi ní Edomu wá, wọ́n jẹ́ ọmọ ọmọ Adah.

17Wọ̀nyí sì ni àwọn ọmọ Esau, ọmọ Rueli:

Nahati olórí, Sera olórí, Ṣamma olórí, Missa olórí; Àwọn wọ̀nyí ló jẹ́ olórí ìdílé tí ó ti ọ̀dọ̀ Reueli jáde ní Edomu. Ọmọ ọmọ Basemati aya Esau ni wọ́n jẹ́.

18Àwọn ọmọ Oholibama aya Esau:

Jeuṣi, Jalamu, àti Kora, àwọn wọ̀nyí ló jẹ́ olórí ìdílé tí ó ti ọ̀dọ̀ Oholibama ọmọ Ana, ìyàwó Esau wá.

19Àwọn wọ̀nyí ni ọmọ Esau (Edomu). Àwọn wọ̀nyí ni olórí wọn.

2036.20-28: 1Ki 1.38-42.Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Seiri ará Hori tí ó ń gbé ní ilẹ̀ náà:

Lotani, Ṣobali, Sibeoni, Ana, 21Diṣoni, Eseri, àti Diṣani, àwọn wọ̀nyí olórí ènìyàn Hori, àwọn ọmọ Seiri ni ilẹ̀ Edomu.

22Àwọn ọmọ Lotani:

Hori àti Homamu: Timna sì ni arábìnrin Lotani.

23Àwọn ọmọ Ṣobali:

Alifani, Manahati, Ebali, Ṣefo àti Onamu.

24Àwọn ọmọ Sibeoni:

Aiah àti Ana. Èyí ni Ana tí ó rí ìsun omi gbígbóná ní inú aginjù bí ó ti ń da àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ Ṣebeoni baba rẹ̀.

25Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Ana:

Diṣoni àti Oholibama (Àwọn ọmọbìnrin ni wọn).

26Àwọn ọmọ Diṣoni ni:

Hemdani, Eṣbani, Itrani àti Kerani.

27Àwọn ọmọ Eseri:

Bilhani, Saafani àti Akani.

28Àwọn ọmọ Diṣani ni:

Usi àti Arani.

29Àwọn wọ̀nyí ni olórí ìdílé Hori:

Lotani, Ṣobali, Sibeoni, Ana, 30Diṣoni Eseri, àti Diṣani.

Àwọn ni olórí ìdílé àwọn ará Hori gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn ní ilẹ̀ Seiri.

Àwọn aláṣẹ Edomu

3136.31-43: 1Ki 1.43-53.Àwọn wọ̀nyí ni ọba tí ó jẹ ní Edomu kí ó tó di pé ọba kankan jẹ lórí Israẹli:

32Bela ọmọ Beori jẹ ní Edomu. Orúkọ ìlú rẹ̀ ni Dinhaba.

33Nígbà tí Bela kú, Jobabu ọmọ Sera ti Bosra sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.

34Nígbà tí Jobabu kú, Huṣamu láti ilẹ̀ Temani sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.

35Nígbà tí Huṣamu kú, Hadadi ọmọ Bedadi tí ó kọlu Midiani ní ìgbẹ́ Moabu, ó sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀. Orúkọ ìlú rẹ̀ ni Afiti.

36Nígbà tí Hadadi sì kú, Samla láti Masreka, ó sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.

37Samla sì kú, Saulu ti Rehoboti, létí odò sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.

38Nígbà tí Saulu kú, Baali-Hanani ọmọ Akbori jẹ ọba ní ipò rẹ̀.

39Nígbà tí Baali-Hanani ọmọ Akbori kú, Hadadi ni ó jẹ ọba ní ipò rẹ̀. Orúkọ ìlú rẹ̀ ni Pau, orúkọ ìyàwó sì ni Mehetabeeli ọmọbìnrin Matiredi, ọmọbìnrin Mesahabu.

40Àwọn wọ̀nyí ni orúkọ àwọn baálẹ̀ tí ó ti ọ̀dọ̀ Esau jáde wá, ní orúkọ ìdílé wọn, bí ìpínlẹ̀ wọn ti rí:

baálẹ̀ Timna, baálẹ̀ Alfa, baálẹ̀ Jeteti.

41baálẹ̀ Oholibama, baálẹ̀ Ela, baálẹ̀ Pinoni,

42baálẹ̀ Kenasi, baálẹ̀ Temani, baálẹ̀ Mibsari,

43Magdieli, àti Iramu.

Àwọn wọ̀nyí ni baálẹ̀ Edomu, gẹ́gẹ́ bí wọn ti tẹ̀dó sí ilẹ̀ tí wọ́n gbà.

Èyí ni Esau baba àwọn ará Edomu.

New Amharic Standard Version

ዘፍጥረት 36:1-43

የዔሳው ዝርያዎች

36፥10-14 ተጓ ምብ – 1ዜና 1፥35-37

36፥20-28 ተጓ ምብ – 1ዜና 1፥38-42

1ኤዶም የተባለው የዔሳው ትውልድ ይህ ነው፦

2ዔሳው ከከነዓን ሴቶች አገባ፤ እነርሱም፦ የኬጢያዊው የዔሎን ልጅ ዓዳን፣ የኤዊያዊው የፅብዖን ልጅ ዓና የወለዳት አህሊባማ፣ 3እንዲሁም የነባዮት እኅት የሆነችው የእስማኤል ልጅ ቤሴሞት ነበሩ።

4ዓዳ ለዔሳው ኤልፋዝን ወለደችለት፤ ቤሴሞት ደግሞ ራጉኤልን ወለደችለት። 5እንደዚሁም አህሊባማ የዑስን፣ የዕላምንና ቆሬን ወለደችለት፤ እነዚህ ዔሳው በከነዓን አገር የወለዳቸው ልጆች ናቸው።

6ዔሳው ሚስቶቹን፣ ወንዶችና ሴቶች ልጆቹን፣ ቤተ ሰቦቹን በሙሉ እንደዚሁም የቀንድ ከብቶቹንና ሌሎቹንም እንስሳት ሁሉ በከነዓን ምድር ያፈራውን ሀብት እንዳለ ይዞ ከወንድሙ ከያዕቆብ ራቅ ወዳለ ቦታ ሄደ። 7ብዙ ሀብት ስለ ነበራቸው አብረው መኖር አልቻሉም፤ የነበሩበትም ስፍራ ከከብቶቻቸው ብዛት የተነሣ ሊበቃቸው አልቻለም። 8ስለዚህ ኤዶም የተባለው ዔሳው መኖሪያውን በተራራማው አገር በሴይር አደረገ።

9በሴይር ተራራማ አገር የሚኖሩ የኤዶማውያን አባት፣ የዔሳው ዝርያዎች እነዚህ ናቸው፤

10የዔሳው ልጆች ስም፦

የዔሳው ሚስት የዓዳ ልጅ ኤልፋዝና የዔሳው ሚስት የቤሴሞት ልጅ ራጉኤል፤

11የኤልፋዝ ልጆች፦

ቴማን፣ ኦማር፣ ስፎ፣ ጎቶምና ቄኔዝ፤ 12የዔሳው ልጅ ኤልፋዝ ትምናዕ የምትባል ቁባት ነበረችው፤ እርሷም አማሌቅን ወለደችለት፤ የዔሳው ሚስት የዓዳ የልጅ ልጆች እነዚህ ናቸው።

13የራጉኤል ልጆች፦

ናሖት፣ ዛራ፣ ሣማና ሚዛህ፤ እነዚህ ደግሞ የዔሳው ሚስት የቤሴሞት የልጅ ልጆች ናቸው።

14የፅብዖን የልጅ ልጅ፣ የዓና ልጅ የዔሳው ሚስት አህሊባማ ለዔሳው የወለደቻቸው ልጆች፦

የዑስ፣ የዕላማና ቆሬ።

15ከዔሳው ዝርያዎች እነዚህ የነገድ አለቆች ነበሩ፤

የዔሳው የበኵር ልጅ የኤልፋዝ ልጆች፦

አለቃ ቴማን፣ አለቃ ኦማር፣ አለቃ ስፎ፣ አለቃ ቄኔዝ፣ 16አለቃ ቆሬ፣36፥16 ከማሶሬቲኩ ጽሑፍ ጋር ተመሳሳይ ሲሆን በኦሪተ ሳምራውያን ግን (በተጨማሪ ዘፍ 36፥11 እና 1ዜና 1፥36 ይመ) ውስጥ “ቆሬ” የሚለው ቃል የለም። አለቃ ጎቶምና አለቃ አማሌቅ፤ እነዚህ በኤዶም ምድር ከኤልፋዝ የተገኙ የነገድ አለቆች፣ የዓዳ የልጅ ልጆች ነበሩ።

17የዔሳው ልጅ ራጉኤል ልጆች፦

አለቃ ናሖት፣ አለቃ ዛራ፣ አለቃ ሣማና አለቃ ሚዛህ፤ እነዚህ በኤዶም ምድር ከራጉኤል የተገኙ የነገድ አለቆች፣ የዔሳው ሚስት የቤሴሞት የልጅ ልጅ ነበሩ።

18የዔሳው ሚስት የአህሊባም ልጆች፦

አለቃ የዑስ፣ አለቃ የዕላማና፣ አለቃ ቆሬ፤ እነዚህ ከዓና ልጅ፣ ከዔሳው ሚስት ከአህሊባማ የተገኙ የነገድ አለቆች ነበሩ።

19እነዚህም ኤዶም የተባለው የዔሳው ልጆችና የነገድ አለቆቻቸው ነበሩ።

20በዚያች ምድር ይኖሩ የነበሩ የሖሪው የሴይር ልጆች እነዚህ ነበሩ፦

ሎጣን፣ ሦባል፣ ፅብዖን፣ ዓና፣ 21ዲሶን፣ ኤጽርና ዲሳን፤ እነዚህ በኤዶም የነበረው የሴይር ልጆች፣ የሖሪውያን የነገድ አለቆች ነበሩ።

22የሎጣን ልጆች፦

ሖሪና ሔማም36፥22 ሔማም የሚለው የዕብራይስጥ ቃል ሖማም ለሚለው ቃል አማራጭ ትርጕም ነው (1ዜና 1፥39 ይመ)።፤ የሎጣንም እኅት ቲምናዕ ትባል ነበር።

23የሦባል ልጆች፦

ዓልዋን፣ ማኔሐት፣ ዔባል፣ ስፎና አውናም፤

24የፅብዖን ልጆች፦

አያና ዓና፤ ይህ ዓና የአባቱን የፅብዖንን አህዮች ሲጠብቅ፣ የፍል ውሃ ምንጮችን36፥24 ከቩልጌት ጋር ተመሳሳይ ሲሆን ሱርስቱ ግን የተገኘ ውሃ ይለዋል፤ በዕብራይስጥ የዚህ ቃል ትርጕም አይታወቅም። በምድረ በዳ ያገኘ ሰው ነው።

25የዓና ልጆች፦

ዲሶንና የዓና ሴት ልጅ አህሊባማ፤

26የዲሶን36፥26 በዕብራይስጥ ዲሳን፣ የዲሶን አማራጭ ትርጕም ነው። ልጆች፦

ሔምዳን፣ ኤስባን፣ ይትራንና ክራን፤

27የኤጽር ልጆች፦

ቢልሐን፣ ዛዕዋንና ዓቃን፤

28የዲሳን ልጆች፦

ዑፅና አራን።

29የሖሪውያን የነገድ አለቆች እነዚህ ነበሩ፦

ሎጣን፣ ሦባል፣ ፅብዖን፣ ዓና፣ 30ዲሶን፣ ኤጽርና ዲሳን፤ እነዚህ በሴይር ምድር እንደየነገዳቸው የሖሪውያን የነገድ አለቆች ነበሩ።

የኤዶም ነገሥታት

36፥31-43 ተጓ ምብ – 1ዜና 1፥43-54

31ንጉሥ በእስራኤል ከመንገሡ በፊት፣36፥31 ወይም እስራኤላዊ መንግሥት በእነርሱ ላይ ከመንገሡ በፊት በኤዶም የነገሡ ነገሥታት እነዚህ ነበሩ፦

32የቢዖር ልጅ ባላቅ በኤዶም ነበር፤ የከተማውም ስም ዲንሃባ ይባል ነበር።

33ባላቅ ሲሞት፣ የባሶራው የዛራ ልጅ ኢዮባብ በምትኩ ነገሠ።

34ኢዮባብ ሲሞት፣ የቴማኒው ሑሳም በምትኩ ነገሠ።

35ሑሳም ሲሞት፣ የምድያምን ሰዎች በሞዓብ ምድር ድል ያደረጋቸው የባዳድ ልጅ ሃዳድ በምትኩ ነገሠ፤ የከተማውም ስም ዓዊት ይባል ነበር።

36ሃዳድ ሲሞት፣ የመሥሬቃው ሠምላ በምትኩ ነገሠ።

37ሠምላ ሲሞት፣ በወንዙ36፥37 የኤፍራጥስ ወንዝ ሊሆን ይችላል። አጠገብ ያለው የርሆቦቱ ሳኦል በምትኩ ነገሠ።

38ሳኦል ሲሞት፣ የዓክቦር ልጅ በኣልሐናን በምትኩ ነገሠ።

39የዓክቦር ልጅ በኣልሐናን ሲሞት፣ ሃዳር በምትኩ ነገሠ፤ የከተማውም ስም ፋዑ ይባል ነበር፤ የሚስቱም ስም መሄጣብኤል ሲሆን፣ እርሷም የሜዛሃብ ልጅ መጥሬድ የወለደቻት ነበረች።

40ከዔሳው የተገኙት የነገድ አለቆች ስም፣ እንደየነገዳቸውና እንደየአገራቸው ይህ ነው፦

ቲምናዕ፣ ዓልዋ፣ የቴት፣

41አህሊባማ፣ ኤላ፣ ፊኖን፣

42ቄኔዝ፣ ቴማን፣ ሚብሳር፣

43መግዲኤልና ዒራም።

እነዚህ፣ በያዙት ምድር እንደየይዞታቸው ከኤዶም የተገኙ የነገድ አለቆች ነበሩ።

ይህም ዔሳው፣ የኤዶማውያን አባት ነው።