Gẹnẹsisi 35 – YCB & CCBT

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Gẹnẹsisi 35:1-29

Jakọbu padà sí Beteli

135.1: Gẹ 28.11-17.Nígbà náà ni Ọlọ́run wí fún Jakọbu pé, “Gòkè lọ sí Beteli kí o sì tẹ̀dó síbẹ̀, kí ó mọ pẹpẹ níbẹ̀ fún Ọlọ́run tó farahàn ọ́ nígbà tí o ń sálọ kúrò níwájú Esau arákùnrin rẹ.”

2Nítorí náà, Jakọbu wí fún gbogbo ará ilé rẹ̀ pé, “Ẹ mú gbogbo àjèjì òrìṣà tí ó wà lọ́dọ̀ yín kúrò, kí ẹ ya ara yín sí mímọ́, kí ẹ sì pààrọ̀ aṣọ yín. 3Nígbà náà ni kí ẹ wá, kí ẹ jẹ́ kí a lọ sí Beteli, níbi tí n ó ti mọ pẹpẹ fún Ọlọ́run, tí ó dá mi lóhùn ní ọjọ́ ìpọ́njú mi tí ó sì ti ń pẹ̀lú mi níbi gbogbo tí mo ń lọ.” 4Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n fún Jakọbu ní gbogbo àjèjì òrìṣà tí ó wà lọ́wọ́ wọn, àti yẹtí etí wọn, Jakọbu sì bo gbogbo wọn mọ́lẹ̀ sábẹ́ igi óákù ní Ṣekemu. 5Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ ìrìnàjò wọn. Ìbẹ̀rù Ọlọ́run sì ń bẹ lára gbogbo ìlú tí ó yí wọn ká, wọ́n kò sì lépa àwọn ọmọ Jakọbu.

6Jakọbu àti gbogbo àwọn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ sì dé sí Lusi (Beteli) tí ó wà ní ilẹ̀ Kenaani. 7Níbẹ̀ ni ó sì mọ pẹpẹ kan tí ó pè ní El-Beteli (Ọlọ́run Beteli), nítorí níbẹ̀ ni Ọlọ́run ti gbé fi ara hàn án nígbà tí ó ń sálọ fún arákùnrin rẹ̀.

8Kò pẹ́ lẹ́yìn èyí ni Debora, olùtọ́jú Rebeka kú, a sì sin ín sábẹ́ igi óákù ní ìsàlẹ̀ Beteli: Nítorí náà a sọ ọ́ ní Aloni-Bakuti (Óákù Ẹkún).

935.9-11: Gẹ 32.28.35.9-12: Gẹ 17.4-8.Lẹ́yìn tí Jakọbu padà dé láti Padani-Aramu, Ọlọ́run tún fi ara hàn án, ó sì súre fún un. 10Ọlọ́run sì wí fun un pé, “Jakọbu ni orúkọ rẹ̀, a kì yóò pè ọ́ ní Jakọbu (alọ́nilọ́wọ́gbà) mọ́ bí kò ṣe Israẹli (ẹni tí ó bá Ọlọ́run jìjàkadì, tí ó sì ṣẹ́gun).” Nítorí náà, ó sọ orúkọ rẹ̀ ní Israẹli.

11Ọlọ́run sì wí fún un pé, “Èmi ni Ọlọ́run alágbára (Eli-Ṣaddai); máa bí sí i, kí o sì máa pọ̀ sí i. Orílẹ̀-èdè àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè ni yóò ti ọ̀dọ̀ rẹ̀ wá, àwọn ọba yóò sì jáde wá láti ara rẹ̀. 12Gbogbo ilẹ̀ tí mo fi fún Abrahamu àti Isaaki ni èmi yóò fún ọ pẹ̀lú, àti fún àwọn ìran rẹ tí ó ń bọ̀ lẹ́yìn.” 13Nígbà náà ni Ọlọ́run gòkè lọ kúrò ní ibi tí ó ti ń bá a sọ̀rọ̀.

1435.14,15: Gẹ 28.18,19.Jakọbu sì fi òkúta ṣe ọ̀wọ̀n kan sí ibi tí Ọlọ́run ti bá a sọ̀rọ̀ ó sì ta ọrẹ ohun mímu (wáìnì) ní orí rẹ̀, ó sì da òróró olifi sí orí rẹ̀ pẹ̀lú. 15Jakọbu sì pe orúkọ ibi tí Ọlọ́run ti bá a sọ̀rọ̀ ní Beteli.

Ikú Rakeli àti Isaaki

16Nígbà náà ni wọ́n ń tẹ̀síwájú nínú ìrìnàjò wọn láti Beteli. Nígbà tí ó sì ku díẹ̀ kí wọn dé Efrata, Rakeli bẹ̀rẹ̀ sí ní rọbí, ó sì ní ìdààmú púpọ̀. 17Bí ó sì ti ń rọbí pẹ̀lú ìrora yìí, agbẹ̀bí wí fún un pé “Má bẹ̀rù nítorí ọmọkùnrin mìíràn ni ó ń bọ̀ yìí.” 18Bí o sì ti fẹ́ gbé ẹ̀mí mi (torí pé ó ń kú lọ), ó pe ọmọ rẹ̀ náà ní Bene-Oni (ọmọ ìpọ́njú mi). Ṣùgbọ́n Jakọbu sọ ọmọ náà ní Benjamini (ọmọ oókan àyà mi).

19Báyìí ni Rakeli kú, a sì sin ín sí ọ̀nà Efrata (Bẹtilẹhẹmu). 20Jakọbu sì mọ ọ̀wọ̀n (ọ̀wọ́n) kan sí ibojì rẹ̀, ọ̀wọ̀n náà sì tọ́ka sí ojú ibojì Rakeli títí di òní.

21Israẹli sì ń bá ìrìnàjò rẹ̀ lọ, ó sì pa àgọ́ rẹ̀ sí Migida-Ederi (ilé ìṣọ́ Ederi). 2235.22: Gẹ 49.4.Nígbà tí Israẹli sì ń gbé ní ibẹ̀, Reubeni wọlé tọ Biliha, àlè (ìyàwó tí a kò fi owó fẹ́ lọ́wọ́ àwọn òbí rẹ̀) baba rẹ̀ lọ, ó sì bá a lòpọ̀, Israẹli sì gbọ́ ọ̀rọ̀ náà.

Jakọbu sì bí ọmọkùnrin méjìlá:

23Àwọn ọmọ Lea:

Reubeni tí í ṣe àkọ́bí Jakọbu,

Simeoni, Lefi, Juda, Isakari àti Sebuluni.

24Àwọn ọmọ Rakeli:

Josẹfu àti Benjamini.

25Àwọn ọmọ Biliha ìránṣẹ́bìnrin Rakeli:

Dani àti Naftali.

26Àwọn ọmọ Silipa ìránṣẹ́bìnrin Lea:

Gadi àti Aṣeri.

Àwọn wọ̀nyí ni ọmọ tí Jakọbu bí ní Padani-Aramu.

2735.27: Gẹ 13.18.Jakọbu sì padà dé ilé lọ́dọ̀ Isaaki baba rẹ̀ ni Mamre ní tòsí i Kiriati-Arba (Hebroni). Níbi tí Abrahamu àti Isaaki gbé. 28Ẹni ọgọ́sàn-án (180) ọdún ni Isaaki. 29Isaaki sì kú láìpẹ́ lẹ́yìn ìpadàbọ̀ Jakọbu, a sì sin ín pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ̀ ní ọjọ́ ogbó rẹ̀. Esau àti Jakọbu ọmọ rẹ̀ sì sin ín.

Chinese Contemporary Bible (Traditional)

創世記 35:1-29

雅各遷往伯特利

1上帝對雅各說:「你到伯特利去住,你要在那裡為上帝築一座壇,祂在你逃避你哥哥以掃時曾向你顯現。」 2於是,雅各吩咐家人和所有的隨從:「你們要除掉你們當中的外族神像,沐浴更衣,潔淨自己。 3我們要上伯特利去,在那裡為上帝築一座壇,祂在我遭遇患難時聽了我的禱告,一路都與我同在。」 4他們把所有外族的神像和自己的耳環都交給雅各雅各把這些東西埋在示劍的橡樹下。

5他們就出發了,上帝使恐懼籠罩周圍的城邑,沒有人敢追趕他們。 6雅各和所有的隨從來到迦南路斯,也就是伯特利7他在那裡建造了一座壇,稱那地方為伊勒·伯特利35·7 伊勒·伯特利」意思是「伯特利的上帝」。,因為在他逃避哥哥的時候,上帝曾在那裡向他顯現。 8後來利百加的奶媽底波拉死了,葬在伯特利山谷下面的橡樹下,那棵樹叫亞倫·巴古35·8 亞倫·巴古」意思是「哭泣的橡樹」。

9雅各巴旦·亞蘭回來後,上帝又向他顯現,賜福給他。 10上帝對他說:「你叫雅各,但從今以後不要再叫雅各了,你要改名叫以色列。」這樣雅各改名為以色列11上帝又說:「我是全能的上帝,你要生養眾多,一國,甚至多國必從你而出,許多君王必出自你的子孫。 12我要把賜給亞伯拉罕以撒的土地賜給你和你的後代。」 13上帝說完就離開雅各升上天去。 14雅各在上帝跟他說話的地方立了一根石柱,又在柱子上奠酒、澆油, 15稱那地方為伯特利

拉結和以撒去世

16他們從伯特利繼續前行,離以法他還有一段路時,拉結難產。 17在難產的痛苦中,接生婆對她說:「不要害怕,你又添了一個兒子!」 18拉結臨死前給兒子取名叫便·俄尼35·18 便·俄尼」意思是「我在苦難中生的兒子」。雅各卻叫他便雅憫35·18 便雅憫」意思是「右手之子」,「右手」希伯來文有幸運或力量的意思。19拉結死後就葬在通往以法他的路旁,以法他伯利恆20雅各在她的墳上立了石碑,至今還在。 21以色列繼續前行,在以得塔附近搭起了帳篷。 22以色列在那裡居住時,呂便和父親的妾辟拉通姦,以色列也知道這件事。

雅各有十二個兒子。 23利亞生了雅各的長子呂便西緬利未猶大以薩迦西布倫24拉結生了約瑟便雅憫25拉結的婢女辟拉生了拿弗他利26利亞的婢女悉帕生了迦得亞設。他們都是雅各的兒子,是在巴旦·亞蘭出生的。

27雅各來到他父親以撒住的幔利,即基列·亞巴,也就是亞伯拉罕以撒寄居的地方。基列·亞巴就是希伯崙28以撒共活了一百八十歲, 29年紀老邁,壽終正寢。他的兒子以掃雅各把他安葬了。