Gẹnẹsisi 32 – YCB & BPH

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Gẹnẹsisi 32:1-32

Jakọbu gbáradì láti pàdé Esau

1Jakọbu sì ń bá ọ̀nà tirẹ̀ lọ, àwọn angẹli Ọlọ́run sì pàdé rẹ̀. 2Nígbà tí Jakọbu rí wọn, ó wí pé, “Àgọ́ Ọlọ́run ni èyí!” Ó sì pe orúkọ ibẹ̀ ni Mahanaimu.

3Jakọbu sì rán àwọn oníṣẹ́ ṣáájú ara rẹ̀ sí Esau arákùnrin rẹ̀ ni ilẹ̀ Seiri ní orílẹ̀-èdè Edomu. 4Ó pàṣẹ fún wọn pé, “Èyí ni ẹ̀yin yóò wí fún Esau olúwa mi, Jakọbu ìránṣẹ́ rẹ̀ wí pé, ‘Mo ti ṣe àtìpó lọ́dọ̀ Labani títí ó fi di àsìkò yìí 5Mo ní màlúù, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àgùntàn àti ewúrẹ́. Mo tún ni àwọn ìránṣẹ́kùnrin àti ìránṣẹ́bìnrin. Mo ń ránṣẹ́ yìí sí olúwa mi kí èmi le è rí ojúrere rẹ.’ ”

6Nígbà tí àwọn ìránṣẹ́ náà padà tọ Jakọbu wà, wọ́n wí pé “Esau arákùnrin rẹ ti múra láti wá pàdé rẹ pẹ̀lú irínwó (400) ọkùnrin.”

7Pẹ̀lú ìbẹ̀rù àti ìbànújẹ́ ni Jakọbu fi pín àwọn ènìyàn tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ sí ìpín méjì, ó sì pín àwọn ẹran ọ̀sìn, agbo ẹran àti ìbákasẹ bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú. 8Nítorí ó rò ó nínú rẹ̀ pé, “Bí Esau bá kọjú ogun sí ìpín kan, ìpín kejì yóò sá àsálà.”

9Nígbà náà ni Jakọbu gbàdúrà pe, “Ọlọ́run Abrahamu baba mi, àti Ọlọ́run Isaaki baba mi, Olúwa tí ó wí fún mi pé, ‘Padà sí orílẹ̀-èdè rẹ àti sọ́dọ̀ àwọn ìbátan rẹ, Èmi yóò sì ṣe ọ́ ní rere,’ 10Èmi kò tilẹ̀ yẹ fún àánú àti òtítọ́ tí o ń fihàn fún ìránṣẹ́ rẹ. Nítorí pé, kìkì ọ̀pá mi ni mo mu kúrò ni ilé kọjá Jordani yìí, ṣùgbọ́n nísinsin yìí, èmi ti di ẹgbẹ́ méjì. 11Jọ̀wọ́ Olúwa gbà mí lọ́wọ́ Esau arákùnrin mi, nítorí ẹ̀rù ń bà mí pé yóò wá dojú ìjà kọ mí àti àwọn ìyàwó pẹ̀lú àwọn ọmọ mi. 1232.12: Gẹ 22.17.Ṣùgbọ́n ìwọ ti ṣèlérí pé, ‘Èmi yóò mú ọ gbilẹ̀, èmi yóò sì mú kí àwọn ìran rẹ dà bì í yanrìn Òkun tí ẹnikẹ́ni kò le è kà.’ ”

13Ó sì lo òru ọjọ́ náà níbẹ̀. Ó mú ẹ̀bùn fún Esau arákùnrin rẹ̀ nínú ohun ìní rẹ̀. 14Igba ewúrẹ́ (200), ogún (20) òbúkọ, igba (200) àgùntàn, ogún (20) àgbò, 15Ọgbọ̀n (30) abo ìbákasẹ pẹ̀lú ọmọ wọn, ogójì (40) abo màlúù àti akọ màlúù mẹ́wàá (10), ogún (20) abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ àti akọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ mẹ́wàá (10). 16Ó sì fi wọ́n lé àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́ ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ lọ ṣáájú mi, kí ẹ sì jẹ́ kí àlàfo wà láàrín ọ̀wọ́ agbo ẹran kọ̀ọ̀kan sí èkejì.”

17Ó pàṣẹ fún èyí tí ó ṣáájú pé, “Nígbà tí arákùnrin mi Esau bá pàdé rẹ tí ó sì béèrè ẹni tí ìwọ í ṣe àti ibi tí ìwọ ń lọ àti ẹni tí ó ni agbo ẹran tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ, 18Nígbà náà ni ìwọ yóò wí pé, ‘Ti ìránṣẹ́ rẹ Jakọbu ni wọ́n. Ẹ̀bùn ni ó sì fi wọ́n ṣe fún Esau olúwa mi, òun pàápàá ń bọ̀ lẹ́yìn wa.’ ”

19Jakọbu sì pàṣẹ bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ fún ọ̀wọ́ kejì àti ẹ̀kẹta àti àwọn tókù tí ó tẹ̀lé agbo ẹran pé, “Ohun kan ṣoṣo yìí náà ni kí ẹ sọ fún Esau nígbà tí ẹ bá pàdé rẹ̀. 20Kí ẹ rí i dájú wí pé, ẹ sọ fún un pé, ‘Jakọbu ìránṣẹ́ rẹ̀ ń bọ̀ lẹ́yìn wa.’ ” Èrò Jakọbu ni láti fi àwọn ẹ̀bùn wọ̀nyí tu Esau lójú pé bóyá inú Esau yóò dùn sí òun nígbà tí àwọn bá pàdé. 21Nítorí náà ẹ̀bùn Jakọbu ṣáájú rẹ̀ lọ, Jakọbu pàápàá sì lo òru ọjọ́ náà nínú àgọ́.

Jakọbu bá Ọlọ́run ja ìjàkadì

22Ó sì dìde ní òru ọjọ́ náà, ó mú àwọn aya rẹ̀ méjèèjì, àwọn ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀ méjèèjì, àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ mọ́kọ̀ọ̀kànlá, wọ́n sì kọjá ní ìwọdò Jabbok. 23Lẹ́yìn ìgbà tí ó ti rán wọn kọjá odò tán sí òkè odò, ó sì rán àwọn ohun ìní rẹ̀ kọjá pẹ̀lú. 2432.24-26: Ho 12.3,4.Ó sì ku Jakọbu nìkan, ọkùnrin kan sì bá a ja ìjàkadì títí ó fi di àfẹ̀mọ́júmọ́. 25Ṣùgbọ́n nígbà tí ọkùnrin náà rí i pé òun kò le borí Jakọbu, ó fọwọ́ kàn án ní ọ̀ọ́kán ibi tí eegun itan ti bẹ̀rẹ̀, egungun náà sì yẹ̀ kúrò lórí ike, bí ó ti ń ja ìjàkadì. 26Nígbà náà ni ọkùnrin náà wí fún un pé, “Jẹ́ kí ń máa lọ, nítorí ojúmọ́ ti mọ́.”

Ṣùgbọ́n Jakọbu dá a lóhùn pé, “Èmi kò ní jẹ́ kí o lọ, àyàfi bí o bá súre fún mi.”

27Ọkùnrin náà béèrè orúkọ rẹ̀.

Ó sì wí fún un pé, “Jakọbu ni òun ń jẹ́.”

2832.28: Gẹ 35.10.Nígbà náà ni ọkùnrin náà wí pé, “Orúkọ rẹ kì yóò jẹ́ Jakọbu mọ́ bí kò ṣe Israẹli, nítorí pé ìwọ ti bá Ọlọ́run àti ènìyàn jà, o sì borí.”

2932.29: On 13.17,18.Jakọbu sì bẹ ọkùnrin náà pé, “Sọ orúkọ rẹ fún mi.”

Ṣùgbọ́n ọkùnrin náà sá à dáhùn pé, “Èéṣe tí o ń béèrè orúkọ mi?” Lẹ́yìn náà ó súre fún Jakọbu níbẹ̀.

30Jakọbu sì pe orúkọ ibẹ̀ ní Penieli pé, “Mo rí Ọlọ́run ní ojúkojú, síbẹ̀ a dá ẹ̀mí mi sí.”

31Bí ó sì ti ń kọjá Penieli, oòrùn ràn bá a, ó sì ń tiro nítorí itan rẹ̀. 32Ìdí nìyí tí àwọn ọmọ Israẹli kì í fi í jẹ iṣan tí ó wà ní ọ̀ọ́kán ibi tí eegun itan ti bẹ̀rẹ̀ títí di òní olónìí, nítorí níbi iṣan náà ni a ti fọwọ́ kan ibi tí egungun itan Jakọbu ti bẹ̀rẹ̀.

Bibelen på hverdagsdansk

1. Mosebog 32:1-33

Jakob frygter mødet med Esau

1Tidligt næste morgen kyssede Laban sine døtre og børnebørn farvel, gav dem sin velsignelse og rejste hjem igen. 2Da Jakob fortsatte sin rejse, kom Guds engle ham i møde. 3Da han fik øje på dem, udbrød han: „Gud har selv slået lejr her!” Derfor kaldte han stedet Mahanajim.32,3 Det betyder: „to lejre”.

4-5Jakob sendte nu nogle folk i forvejen med besked til Esau, hans bror, som havde sin lejr i Seirs bjerge i Edom: „Din tjener Jakob hilser dig ærbødigst! Indtil for nylig har jeg boet hos vores onkel Laban. 6Jeg har samlet mig en pæn flok køer, æsler, får, geder og mange slaver, både mænd og kvinder. Jeg har sendt disse folk i forvejen, for at du kan vide, at jeg snart kommer, og jeg håber, at du vil tage godt imod mig.”

7Sendebudene kom tilbage med følgende besked: „Vi tog hen til din bror, og nu er han på vej herhen med 400 mand!” 8Jakob blev grebet af panik, og han besluttede at dele sin husstand og sine husdyr i to lejre, 9for han tænkte: „Hvis Esau angriber den ene gruppe, kan den anden vel reddes.”

10Derefter bad han følgende bøn: „Åh, min farfar Abrahams og min far Isaks Gud. Åh Herre, du sagde jo, at jeg skulle vende tilbage til mit land og min slægt, og du lovede at være med mig og hjælpe mig! 11Jeg er overhovedet ikke værdig til den trofasthed og uendelige godhed, du gang på gang har vist mig. Da jeg i sin tid gik hjemmefra og satte over Jordanfloden, ejede jeg ikke stort andet end min rejsestav, men nu ejer jeg de her to store lejre. 12Åh, Herre, red mig fra Esau. Jeg er bange for, at han kommer og slår mig ihjel tillige med mine koner og børn. 13Men du har jo lovet at være med mig og gøre mine efterkommere talrige som sandet på stranden, der umuligt kan tælles!”

14Jakob blev på det sted om natten, og han udvalgte følgende dyr som en gave til Esau: 15200 geder, 20 bukke, 200 får, 20 væddere, 1630 hunkameler med føl, 40 køer, 10 tyre, 20 hunæsler og 10 hanæsler. 17Så gav han sine slaver besked på at gå i forvejen med dyrene og sørge for en vis afstand mellem hver enkelt gruppe af dyr. 18Til den mand, som førte den første gruppe, sagde han: „Når I møder Esau, og han spørger: ‚Hvor skal I hen? Hvem er jeres herre? Hvis er dyrene?’ 19skal I svare: ‚De tilhører din tjener Jakob og er en gave til hans herre, Esau. Han kommer selv bagefter.’ ” 20Dernæst sagde Jakob til de andre mænd, der skulle drive hver deres gruppe af dyr til Esau: „I skal alle sige det samme til Esau, når I ser ham. 21Og husk at sige: ‚Din tjener Jakob kommer lige bagved!’ ” Hans plan var at formilde Esau, før han mødte ham ansigt til ansigt. „Måske han så tager venligt imod mig,” tænkte han. 22Så blev gaverne sendt i forvejen, mens Jakob blev tilbage og gik til ro i lejren.

Jakob kæmper med Herren

23-24Senere på natten stod Jakob op og førte sine to koner, deres slavepiger og sine 11 sønner over floden Jabbok. Derefter bragte han også alle sine ejendele i sikkerhed på den anden side af floden. 25Men selv blev han alene tilbage. En mand kom hen til ham, og de begyndte en brydekamp, der varede indtil daggry. 26Da manden indså, at han ikke kunne få overtaget over Jakob, gav han ham et slag på hoften, så den gik af led. 27Så sagde han: „Lad mig gå, for det begynder at blive lyst!”

Men Jakob gispede: „Jeg slipper dig ikke, med mindre du velsigner mig!”

28„Hvad er dit navn?” spurgte manden.

„Jakob,” svarede han.

29„Du skal ikke længere hedde Jakob—men Israel,32,29 Det betyder sandsynligvis: „han udfordrer Gud”. ” sagde manden. „For du har udfordret både Gud og mennesker, og du har vist din styrke.”

30„Hvad er dit navn?” spurgte Jakob ham.

„Hvorfor spørger du?” svarede manden. Så velsignede han ham der.

31Jakob kaldte stedet Peniel,32,31 Det betyder: „Guds ansigt”. for han sagde: „Jeg har set Gud ansigt til ansigt—uden at miste livet!” 32Solen stod op, idet Jakob forlod Peniel, og han haltede på grund af slaget på hoften. 33Derfor undlader Israels folk den dag i dag at spise musklen ved hofteskålen. Det var nemlig der, Jakob blev ramt.