Gẹnẹsisi 31 – YCB & BPH

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Gẹnẹsisi 31:1-55

Jakọbu sá kúrò lọ́dọ̀ Labani

1Jakọbu sì gbọ́ pé àwọn ọmọ Labani ń wí pé, “Jakọbu ti gba gbogbo ohun ìní baba wa, ó sì ti kó ọrọ̀ jọ fún ara rẹ̀ lára àwọn ohun tí í ṣe ti baba wa.” 2Jakọbu sì ṣàkíyèsí pé ìwà Labani sí òun ti yí padà sí ti àtẹ̀yìnwá.

3Nígbà náà ni Olúwa wí fún Jakọbu pé, “Padà lọ sí ilẹ̀ àwọn baba à rẹ, sí ọ̀dọ̀ àwọn ará rẹ, èmi ó sì wà pẹ̀lú rẹ.”

4Jakọbu sì ránṣẹ́ pe Rakeli àti Lea sí pápá níbi tí àwọn ohun ọ̀sìn rẹ̀ wà. 5Ó sì wí fún wọn pé, “Mo rí i wí pé ìwà baba yín sí mi ti yí padà sí ti tẹ́lẹ̀, ṣùgbọ́n Ọlọ́run baba mi wà pẹ̀lú mi. 6Ẹ sá à mọ̀ pé, mo ti fi gbogbo agbára mi ṣiṣẹ́ fún baba yín, 7Síbẹ̀síbẹ̀ baba yín ti rẹ́ mi jẹ ní ẹ̀ẹ̀mẹwàá ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni ó sì ti yí owó iṣẹ́ mi padà. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run kò jẹ́ kí ó le è pa mi lára. 8Tí ó bá wí pé, ‘Àwọn ẹran onílà ni yóò dúró fún owó iṣẹ́ rẹ,’ nígbà náà ni gbogbo àwọn ẹran ń bí onílà; bí ó bá sì wí pé, ‘Àwọn ẹran onítótòtó ni yóò dúró fún owó iṣẹ́ rẹ’ nígbà náà ni gbogbo ẹran ń bi onítótòtó. 9Bẹ́ẹ̀ ni Ọlọ́run gba ẹran baba yín, ó sì fi fún mi.

10“Ní àsìkò tí àwọn ẹran ń gùn, mo la àlá mo sì ri pé àwọn òbúkọ tí wọ́n ń gun àwọn ẹran jẹ́ onítótòtó, onílà àti alámì. 11Angẹli Ọlọ́run wí fún mi nínú àlá náà pé, ‘Jakọbu.’ Mo sì wí pé, ‘Èmi nìyí.’ 12Ó sì wí pé, ‘Gbé ojú rẹ sókè kí o sì wò ó, gbogbo àwọn òbúkọ tí ó ń gun àwọn ẹran jẹ́ onítótòtó, onílà àti alámì, nítorí mo ti rí gbogbo ohun ti Labani ń ṣe sí ọ. 1331.13: Gẹ 28.18-22.Èmi ni Ọlọ́run Beteli, níbi tí ìwọ ti ta òróró sí ọ̀wọ́n, ìwọ sì jẹ́ ẹ̀jẹ́ láti sìn mi. Nísinsin yìí, kúrò ní ilẹ̀ yìí kíákíá kí o sì padà sí ilẹ̀ ibi tí a gbé ti bí ọ.’ ”

14Nígbà náà ni Rakeli àti Lea dáhùn pé, “Ìpín wo ní a ní nínú ogún baba wa? 15Àjèjì ha kọ́ ni ó kà wá sí? Kì í ṣe torí pé ó tà wá nìkan, ṣùgbọ́n ó ti ná gbogbo owó tí ó gbà lórí wa tán. 16Dájúdájú gbogbo ọrọ̀ ti Ọlọ́run gbà lọ́wọ́ baba wa fún ọ, tiwa àti ti àwọn ọmọ wa ní í ṣe. Nítorí náà ohun gbogbo tí Ọlọ́run bá pàṣẹ fun ọ láti ṣe ni kí ìwọ kí ó ṣe.”

17Nígbà náà ni Jakọbu gbé àwọn ọmọ àti aya rẹ̀ gun ìbákasẹ. 18Ó sì da gbogbo agbo ẹran rẹ̀ ṣáájú pẹ̀lú gbogbo ọrọ̀ tí ó ti kójọ ni Padani-Aramu, láti lọ sí ọ̀dọ̀ Isaaki baba rẹ̀ ni ilẹ̀ Kenaani.

19Nígbà tí Labani sì lọ láti rẹ́run àgùntàn, Rakeli sì jí àwọn ère òrìṣà ilé baba rẹ̀. 20Síwájú sí i, Jakọbu tan Labani ará Aramu, nítorí kò sọ fún un wí pé òun ń sálọ. 21Ó sì sálọ pẹ̀lú ohun gbogbo tí ó ni, ó sì la odò kọjá (Eufurate), ó sì kọrí sí àwọn ilẹ̀ olókè ti Gileadi.

Labani lépa Jakọbu

22Ní ọjọ́ kẹta ni Labani gbọ́ pé Jakọbu ti sálọ. 23Ó sì mú àwọn arákùnrin rẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀, ó sì lépa Jakọbu, ó sì lépa wọn fún ọjọ́ méje, ó sì bá wọn ní òkè Gileadi. 24Ọlọ́run sì yọ sí Labani ará Aramu lójú àlá ní òru, ó sì wí fun un pé, “Ṣọ́ra, má ṣe sọ ohunkóhun fún Jakọbu, ìbá à ṣe rere tàbí búburú.”

25Jakọbu ti pa àgọ́ rẹ̀ si orí òkè kan, nígbà tí Labani bá a. Labani àti àwọn tí ó wá pẹ̀lú rẹ̀ sì pàgọ́ tì wọ́n sí ilẹ̀ òkè Gileadi. 26Nígbà náà ni Labani wí fún Jakọbu pé, “Èwo ni ìwọ ṣe yìí? Tí ìwọ sì tàn mi, ó sì kó àwọn ọmọbìnrin mi bi ìgbèkùn tí a fi idà mú. 27Èéṣe tí ìwọ yọ́ lọ tí ìwọ sì tàn mi? Kí ló dé tí ìwọ kò sọ fún mi pé ìwọ ń lọ, kí èmi fi ayọ̀ àti orin, pẹ̀lú ìlù àti ohun èlò orin sìn ọ́. 28Ìwọ kò tilẹ̀ jẹ́ kí èmi fi ẹnu ko àwọn ọmọ ọmọ mi lẹ́nu, pẹ̀lú àwọn ọmọbìnrin mi pé ó dìgbà? Ìwọ ṣiwèrè ní ohun tí ìwọ ṣe yìí. 29Mo ní agbára láti ṣe ọ ni ibi, ṣùgbọ́n ní òru àná, Ọlọ́run baba rẹ sọ fún mi pé, kí èmi ṣọ́ra, kí èmi má ṣe sọ ohun kan fún Jakọbu, ìbá à ṣe rere tàbí búburú. 30Nísinsin yìí, ìwọ ti lọ nítorí ìwọ fẹ́ láti padà lọ sí ilé baba rẹ, ṣùgbọ́n èéṣe tí ìwọ fi jí àwọn òrìṣà mi?”

31Jakọbu dá Labani lóhùn pé, “Ẹ̀rù ni ó bà mi nítorí, mo rò pé ìwọ le fi tipátipá gba àwọn ọmọbìnrin rẹ lọ́wọ́ mi. 32Ṣùgbọ́n bí o bá ri ẹnikẹ́ni pẹ̀lú ère rẹ, kí ẹni náà di òkú. Ó tún wí pé, Níwájú gbogbo ìbátan wa báyìí, wò ó fúnrarẹ̀, bí o bá rí ohunkóhun tí í ṣe tìrẹ, mú un.” Jakọbu kò sì mọ̀ pé, Rakeli ni ó jí àwọn òrìṣà náà.

33Labani sì lọ sínú àgọ́ Jakọbu àti ti Lea àti ti àwọn ìránṣẹ́bìnrin méjèèjì, kò sì rí ohunkóhun. Lẹ́yìn ìgbà tí ó jáde nínú àgọ́ Lea ni ó lọ sí àgọ́ Rakeli. 34Rakeli sì gbé àwọn òrìṣà náà sínú gàárì ìbákasẹ, ó sì jókòó lé e lórí. Labani sì wá gbogbo inú àgọ́, kò sì rí ohunkóhun.

35Rakeli sì wí fún baba rẹ̀ pé, “Má ṣe bínú pé èmi ò le dìde dúró níwájú rẹ baba à mi, ohun tí ó fà á ni pé, mò ń ṣe nǹkan oṣù lọ́wọ́.” Ó sì wá àgọ́ kiri, kò sì rí àwọn òrìṣà ìdílé náà.

36Inú sì bí Jakọbu, ó sì pe Labani ní ìjà pé, “Kí ni ẹ̀ṣẹ̀ mi? Ẹ̀ṣẹ̀ wo ni mo ṣẹ̀ ọ tí ìwọ fi ń lépa mi bí ọ̀daràn? 37Nísinsin yìí tí ìwọ ti tú gbogbo ẹrù mi wò, kí ni ohun tí í ṣe tirẹ̀ tí ìwọ rí? Kó wọn kalẹ̀ báyìí níwájú gbogbo ìbátan rẹ àti tèmi, kí wọn kí ó sì ṣe ìdájọ́ láàrín àwa méjèèjì.

38“Mo ti wà lọ́dọ̀ rẹ fún ogún ọdún, àwọn àgùntàn tàbí ewúrẹ́ rẹ kò sọnù bẹ́ẹ̀ n kò pa ọ̀kan jẹ rí nínú àwọn àgbò rẹ. 39Èmi kò mú ọ̀kankan wá fún ọ rí nínú èyí tí ẹranko búburú fàya, èmi ni ó fi ara mọ́ irú àdánù bẹ́ẹ̀. Ẹrankẹ́ran tí wọ́n bá sì jí lọ, lọ́sàn án tàbí lóru, ìwọ ń gba owó rẹ̀ lọ́wọ́ mi 40Báyìí ni mo wà; oòrùn ń pa mi lọ́sàn án, òtútù ń pa mi lóru, mo sì ń ṣe àìsùn. 41Báyìí ni ohun gbogbo rí fún ogún ọdún tí mo fi wà nínú ilé rẹ. Ọdún mẹ́rìnlá ni mo fi sìn ọ́ fún àwọn ọmọbìnrin rẹ méjèèjì, mo sì sìn ọ fún ọdún mẹ́fà fún àwọn ẹran ọ̀sìn, lẹ́ẹ̀mẹ́wàá ni o sì yí owó iṣẹ́ mi padà. 42Bí ó bá ṣe pé Ọlọ́run àwọn baba mi, Ọlọ́run Abrahamu àti ẹ̀rù Isaaki kò wà pẹ̀lú mi ni, ìwọ ìbá ti lé mi jáde lọ́wọ́ òfo. Ṣùgbọ́n, Ọlọ́run ti rí gbogbo ìpọ́njú mi àti iṣẹ́ àṣekára tí mo fi ọwọ́ mi ṣe, ó sì kìlọ̀ fún ọ lóru àná.”

43Labani sì dá Jakọbu lóhùn, “Tèmi ni àwọn obìnrin wọ̀nyí, ọmọ mi ni àwọn ọmọ wọ̀nyí pẹ̀lú, àwọn agbo ẹran yìí, tèmi ni wọ́n pẹ̀lú. Gbogbo ohun tí o rí wọ̀nyí, tèmi ni. Kí ni mo wá le ṣe sí àwọn ọmọbìnrin wọ̀nyí àti àwọn ọmọ wọn tí wọn bí? 44Wá, jẹ́ kí a dá májẹ̀mú pẹ̀lú ara wa, èyí yóò sì jẹ́ ẹ̀rí ní àárín wa.”

45Jakọbu sì mú òkúta kan ó sì gbé e dúró bí ọ̀wọ́n. 46Ó sì wí fún àwọn ìbátan rẹ̀ pé, “Ẹ kó àwọn òkúta díẹ̀ jọ.” Wọ́n sì kó òkúta náà jọ bí òkìtì wọ́n sì jẹun níbẹ̀. 47Labani sì pe orúkọ rẹ̀ ní Jegari-Sahaduta, ṣùgbọ́n Jakọbu pè é ni Galeedi.

48Labani sì wí pé, “Òkìtì yìí jẹ́ ẹ̀rí láàrín èmi àti ìwọ ní òní.” Ìdí nìyí tí a fi pe orúkọ rẹ̀ ni Galeedi. 49Ó tún pè é ni Mispa nítorí, ó wí pé, “Kí Olúwa kí ó máa ṣọ́ èmi àti ìwọ nígbà tí a bá yà kúrò lọ́dọ̀ ara wa tán. 50Bí o bá fìyà jẹ àwọn ọmọbìnrin mi, tàbí tí o fẹ́ aya mìíràn yàtọ̀ sí wọn, rántí pé, Ọlọ́run ń bẹ láàrín wa bí ẹlẹ́rìí bí ẹnikẹ́ni kò tilẹ̀ sí.”

51Labani tún sọ síwájú fún Jakọbu pé, “Òkìtì àti ọ̀wọ̀n tí mo gbé kalẹ̀ láàrín èmi àti ìwọ yìí, 52yóò jẹ́ ẹ̀rí wí pé èmi kò ni ré ọ̀wọ̀n àti òkìtì yìí kọjá láti bá ọ jà àti pé ìwọ pẹ̀lú kì yóò kọjá òkìtì tàbí ọ̀wọ̀n yìí láti ṣe mí ní ibi. 53Ǹjẹ́ kí Ọlọ́run Abrahamu àti Ọlọ́run Nahori, àti Ọlọ́run baba wọn ṣe ìdájọ́ láàrín wa.”

Jakọbu sì fi ẹ̀rù Isaaki baba rẹ̀ búra. 54Jakọbu sì rú ẹbọ níbẹ̀ ni orí òkè, ó sì pe àwọn ẹbí rẹ̀ láti jẹun. Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n ti jẹun, ibẹ̀ náà ni wọ́n sùn ní ọjọ́ náà.

55Ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, Labani fi ẹnu ko àwọn ọmọ ọmọ rẹ̀ lẹ́nu àti àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ pẹ̀lú, ó sì súre fún wọn. Labani sì padà lọ sí ilé.

Bibelen på hverdagsdansk

1. Mosebog 31:1-54

Jakob flygter fra Laban

1Men efterhånden blev Jakob klar over, at Labans sønner var ved at blive utilfredse. „Jakob har snydt os,” knurrede de. „Han er blevet rig på vores fars bekostning.” 2Han bemærkede også, at Labans holdning over for ham ikke var som før. 3Da sagde Herren til Jakob: „Vend tilbage til dit fædreland og din familie. Jeg vil være med dig.”

4Jakob sendte så bud til Rakel og Lea om, at de skulle komme ud på marken, hvor han passede hjorden, så han kunne diskutere sagen med dem. 5„Jeg kan mærke på jeres far, at han har ændret holdning over for mig,” begyndte han. „Men mine fædres Gud har velsignet mig. 6I ved, hvor hårdt jeg har arbejdet for jeres far, 7men han har narret mig, brudt vores aftale og ændret min løn mindst ti gange. Alligevel har Gud bevaret mig, så jeres far ikke har kunnet gøre mig noget ondt. 8Når Laban lovede mig de brogede dyr, fødte hjorden broget afkom, og når han ændrede mening og lovede mig de stribede dyr, så blev lammene stribede. 9På den måde gjorde Gud mig rig på hans bekostning.”

10„I parringstiden havde jeg en drøm,” fortsatte Jakob. „I drømmen så jeg, at alle bukkene, der parrede sig med gederne, var stribede, plettede eller brogede. 11Da kaldte Guds engel på mig i drømmen.

‚Jakob!’ sagde han.

‚Ja,’ svarede jeg.

12Så sagde englen: ‚Læg mærke til, at det kun er de stribede, plettede og brogede bukke, der parrer sig med gederne i din hjord. Jeg har nemlig set, hvordan Laban har behandlet dig. 13Jeg er den Gud, du mødte ved Betel—det sted, hvor du salvede mindestenen med olivenolie og aflagde løftet om at tjene mig. Gør dig klar til at forlade dette sted og vende tilbage til det land, du kom fra.’ ”

14Rakel og Lea svarede: „Ja, hvorfor ikke? Har vi måske nogen fremtid her? Far vil næppe lade os arve noget. 15Han har behandlet os som fremmede kvinder, fordi han solgte os og selv brugte de penge, han fik for os. 16Al den rigdom, som Gud har taget fra far og givet dig, tilhører faktisk os og vores børn. Gør du kun, som Gud har sagt, du skal gøre.”

17-21Så mens Laban var væk hjemmefra nogle dage for at klippe sine får, satte Jakob sine børn og sine koner op på kamelerne og drog af sted. Han drev hjorden—alt det småkvæg, han havde samlet sig i Paddan-Aram—foran sig og begyndte tilbagerejsen til Kana’ans land, hvor hans far, Isak, boede. Han drog af sted med alt, hvad han ejede, uden at Laban vidste noget om det, og satte over Eufratfloden på vej mod bjergområdet ved Gilead. Rakel tog endog sin fars husguder med sig!

22Først to dage senere31,22 Hebraisk „på den tredje dag”, hvilket svarer til „to dage senere” på dansk. fik Laban at vide, at Jakob var flygtet. 23Han satte straks efter ham med nogle af sine mænd og indhentede ham efter syv dage i Gileads bjerge. 24Om natten viste Gud sig i en drøm for aramæeren Laban og advarede ham: „Pas på, at du ikke siger så meget som ét ondt ord til Jakob!” 25Jakob havde slået lejr i Gileads bjerge. Laban slog lejr i nærheden og opsøgte Jakob.

26„Hvad ligner det at snige sig af sted på den måde?” begyndte Laban. „Mig har du narret, og mine døtre har du bortført, som om de var krigsfanger! 27Du gav mig ingen chance for at holde et ordentligt afskedsgilde med sang og musik, og hvad dertil hører. 28Du gav mig ikke lov til at kysse mine døtre og børnebørn farvel. Du har opført dig rigtig tarveligt! 29Jeg kunne med lethed gøre det af med dig, men sidste nat viste din fars Gud sig for mig og sagde: ‚Pas på, hvad du siger til Jakob!’ 30Jeg kan godt forstå, at du har hjemve og længes efter at tage tilbage til din familie. Men var det virkelig nødvendigt at stjæle mine husguder?”

31„Jeg indrømmer, at jeg skyndte mig af sted,” svarede Jakob. „Jeg var bange for, at du ville tage dine døtre fra mig. 32Hvad dine husguder angår, så skal den, som har taget dem, dø! Hvis du finder noget her, som tilhører dig, vil jeg omgående give dig det tilbage. Det skal disse mænd være vidner på!” Jakob vidste nemlig ikke, at Rakel havde stjålet husguderne.

33Laban begyndte eftersøgningen i Jakobs telt. Så fortsatte han i Leas og i de to tjenestepigers telte—uden at finde noget. Til sidst kom han til Rakels telt. 34Rakel havde taget husguderne og gemt dem i sin kamelsadel og sad nu oven på dem i sit telt. Derfor fandt Laban dem ikke, skønt han gennemsøgte teltet grundigt. 35Rakel havde sagt til ham: „Undskyld mig, far, at jeg ikke rejser mig for dig, men jeg har min menstruation.” Laban fandt altså ikke sine husguder.

36Så blev Jakob vred og konfronterede Laban. „Hvad fandt du så?” spurgte han. 37„Hvorfor beskylder du mig for at have stjålet fra dig? Hvad har jeg begået, siden du jager mig, som om jeg var en forbryder? Nu da du har ledt overalt i min lejr, hvad har du så fundet, som tilhører dig? Læg det kun frem, så alle kan se, hvem af os, der har ret. Lad vores folk dømme os to imellem.” 38Så fortsatte han: „I 20 år har jeg været hos dig og taget mig af dine får og geder, så de har fået levedygtigt afkom. I al den tid har jeg aldrig taget en eneste af dine væddere. 39Og hvis nogle af dine får blev angrebet eller dræbt af rovdyr, kom jeg ikke bare og fortalte dig det. Nej, jeg tog selv tabet på mig og erstattede det. Du krævede endog erstatning for dyr, der blev stjålet—hvad enten det var min fejl eller ej. 40Jeg arbejdede samvittighedsfuldt for dig i dagens hede og udholdt nattens kulde, og ofte fik jeg ikke lukket et øje. 41I 20 lange år arbejdede jeg for dig—de 14 for at betale for dine to døtre, og de seks for at erhverve mig en hjord. Ti gange ændrede du mening for at snyde mig for min løn. 42Hvis ikke min farfar Abrahams og min far Isaks vældige Gud havde været med mig, ville du såmænd have sendt mig af sted med tomme hænder! Men Gud har bemærket din ondskab og mit ærlige arbejde—og i nat advarede han dig.”

Jakobs pagt med Laban

43Laban svarede Jakob: „Dine to koner er mine døtre, deres børn er mine børnebørn, og hjorden har du fra mig. Alt, hvad du har, har du fået af mig. Men hvad kan jeg gøre imod mine egne døtre og børnebørn? 44Lad os slutte en fredspagt og bevidne det med en stenhøj.”

45Så tog Jakob en sten og rejste den som et monument, 46og han befalede sine mænd at samle flere sten og bygge en stenhøj. Derefter spiste de sammen ved stenhøjen. 47-48Laban kaldte højen Jegar-Sahaduta,31,47-48 Det betyder „vidnehøj” på aramæisk. Jakob kaldte den Galed.31,47-48 Det tilsvarende hebraiske ord. „Den skal være et vidne imellem os, hvis en af os overskrider denne grænse,” sagde Laban. 49„Den skal også kaldes Mitzpa,31,49 På hebraisk ordspil med „holde øje med”. Mitzpa betyder vagttårn. for herefter skal Herren selv holde øje med os. 50Selvom ingen andre ser det, hvis du behandler mine døtre dårligt eller tager andre koner, så ser Gud det!” 51-52Laban fortsatte: „Denne stenhøj skal stå imellem os som et vidne om vores gensidige løfte: At vi ikke vil overskride denne grænse med onde hensigter. 53Må vores forfædres Gud—din farfar Abrahams og min farfar Nakors Gud—straffe den af os, som bryder pagten.”

Så svor Jakob ved sin far Isaks mægtige Gud, at han ville overholde pagten, 54hvorefter han ofrede til Gud og indbød sine mænd til et festmåltid. Efter måltidet overnattede de der i bjergene.