Gẹnẹsisi 29 – YCB & CCBT

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Gẹnẹsisi 29:1-35

Jakọbu dé Padani-Aramu

1Jakọbu sì tẹ̀síwájú nínú ìrìnàjò rẹ̀, ó sì dé ilẹ̀ àwọn ará ìlà-oòrùn. 2Ó sì rí kànga kan ní pápá, agbo àgùntàn mẹ́ta sì dúró láti mu omi ní ibi kànga náà, nítorí pé láti inú kànga náà ni wọ́n ti ń fi omi fún agbo àgùntàn. Òkúta tí a gbé dí ẹnu kànga náà sì tóbi gidigidi. 3Nígbà tí gbogbo agbo ẹran bá péjọpọ̀ sí ibẹ̀ tán ni àwọn darandaran yóò tó yí òkúta náà kúrò, tí wọn yóò sì fún àwọn ẹran náà ní omi, tí wọ́n bá sì ti ṣe bẹ́ẹ̀ tán, wọn yóò tún yí òkúta náà padà sí ẹnu kànga náà.

4Jakọbu béèrè lọ́wọ́ àwọn darandaran náà pé, “Ẹ̀yin arákùnrin mi níbo ni ẹ̀yin ti wá?”

Àwọn náà sì dáhùn pé, “Láti Harani ni.”

5Ó sì bi wọ́n pé, “Ǹjẹ́ ẹ mọ Labani ọmọ ọmọ Nahori?”

Wọ́n sì dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, àwa mọ̀ ọ́n.”

6Jakọbu béèrè pé, “Ṣe àlàáfíà ni ó wà?”

Wọ́n sì dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, àlàáfíà ni. Wò ó, Rakeli ọmọ rẹ̀ ni ó ń bọ̀ yìí pẹ̀lú agbo àgùntàn.”

7Ó sì wí pé, “Kíyèsi, ilẹ̀ ò tí ì ṣú, kò tì í tó àkókò fún àwọn ohun ọ̀sìn láti wọ̀. Ẹ fún àwọn ẹran wọ̀nyí ní omi, kí ẹ ba à le tètè dà wọ́n padà láti jẹun.”

8Wọ́n dá a lóhùn pé, “Àwa kì í yí òkúta kúrò ní ẹnu kànga láti pọn omi fún àwọn ẹran títí gbogbo àwọn darandaran àti àwọn ẹran yóò fi péjọ tán.”

9Bí wọ́n sì ti ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́ ni Rakeli dé pẹ̀lú agbo àgùntàn baba rẹ̀, nítorí darandaran ni òun náà. 10Nígbà tí Jakọbu rí Rakeli ọmọbìnrin Labani tí í ṣe ẹ̀gbọ́n ìyá rẹ̀, pẹ̀lú àgùntàn Labani, Jakọbu súnmọ́ kànga náà, ó sì yí òkúta kúrò lẹ́nu rẹ̀, ó sì fún àwọn ẹran arákùnrin ìyá rẹ̀ Labani ní omi. 11Jakọbu sì fẹnu ko Rakeli ní ẹnu. Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í sọkún. 12Jakọbu sì wí fún Rakeli pé ìbátan baba rẹ̀ ni òun, àti pé, òun jẹ́ ọmọ Rebeka. Rakeli sì sáré lọ sọ fún baba rẹ̀.

13Ní kété tí Labani gbúròó Jakọbu ọmọ arábìnrin rẹ̀, ó jáde lọ pàdé Jakọbu, ó dì mọ́ ọn, ó fi ẹnu kò ó ní ẹnu, ó sì mú un lọ sí ilé. Nígbà náà ni Jakọbu ròyìn ohun gbogbo fún un. 14Labani sì wí pé, “Ẹran-ara àti ẹ̀jẹ̀ ara mi ni ìwọ jẹ́.”

Jakọbu fẹ́ àwọn ọmọ Labani Lea àti Rakeli

Lẹ́yìn tí Jakọbu sì wà pẹ̀lú rẹ̀ fún odidi oṣù kan, 15Labani wí fún Jakọbu pé, “Bí a tilẹ̀ jẹ́ ìbátan, kò yẹ kí o máa ṣiṣẹ́ fún mi lásán láìgba ohun kankan. Sọ ohun tì ìwọ fẹ́ gbà fún iṣẹ́ tí ìwọ ń ṣe fún mi!”

16Wàyí o, Labani ní ọmọbìnrin méjì, orúkọ èyí ẹ̀gbọ́n ń jẹ́ Lea, orúkọ àbúrò sì ń jẹ́ Rakeli. 17Lea kò ní ẹwà púpọ̀, ṣùgbọ́n Rakeli ní ẹwà gidigidi. Ojú rẹ̀ sì fanimọ́ra. 18Jakọbu sì fẹ́ràn Rakeli, ó sì wí fún baba rẹ̀ pé, “Èmi yóò ṣiṣẹ́ sìn ọ fún ọdún méje, bí ìwọ yóò bá fún mi ní Rakeli ọmọ rẹ ní aya.”

19Labani sì dáhùn wí pé, “Ó kúkú sàn kí ń fi fún ọ, ju kí ń fi fún ẹlòmíràn lọ, nítorí náà wà ní ọ̀dọ̀ mi.” 20Jakọbu sì ṣiṣẹ́ sin Labani fún ọdún méje láti fẹ́ Rakeli. Àwọn ọdún wọ̀nyí sì dàbí ọjọ́ díẹ̀ lára rẹ̀, nítorí ó fẹ́ràn rẹ̀.

21Jakọbu sì wí fún Labani pé, “Mo ti parí àsìkò tí a jọ ṣe àdéhùn rẹ̀, nítorí náà fún mi ní aya mi, kí òun lè ṣe aya fún mi.”

22Labani sì pe gbogbo ènìyàn ibẹ̀ jọ, ó sì ṣe àsè ìyàwó fún wọ́n. 23Ṣùgbọ́n nígbà tí ó di òru, Labani mú Lea tọ Jakọbu lọ. Jakọbu sì bá a lòpọ̀. 24Labani sì fi Silipa ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ obìnrin fún Lea gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́.

25Sì kíyèsi, nígbà ti ilẹ̀ mọ́, Jakọbu rí i pé Lea ni! Ó sì wí fún Labani pé, “Èwo ni ìwọ ṣe sí mi yìí? Ṣe bí nítorí Rakeli ni mo ṣe ṣiṣẹ́ sìn ọ, èéṣe tí ìwọ tàn mi?”

26Labani sì dáhùn pé, “Kò bá àṣà wa mu láti fi àbúrò fún ọkọ ṣáájú ẹ̀gbọ́n rẹ̀. 27Mú sùúrù parí ọ̀sẹ̀ ìgbéyàwó yìí náà, nígbà náà ni èmi yóò fi àbúrò rẹ̀ fún ọ pẹ̀lú, bí ìwọ ó bá ṣiṣẹ́ sìn mi fún ọdún méje mìíràn.”

28Jakọbu sì gbà láti sin Labani fún ọdún méje mìíràn. Labani sì fi Rakeli ọmọ rẹ̀ fún un bí aya. 29Labani sì fi Biliha ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ obìnrin fún Rakeli bí ìránṣẹ́. 30Jakọbu sì bá Rakeli náà lòpọ̀. Ó sì fẹ́ràn Rakeli ju Lea lọ, ó sì ṣiṣẹ́ sin Labani fún ọdún méje mìíràn.

Àwọn ọmọ Jakọbu

31Nígbà tí Ọlọ́run sì ri pé, Jakọbu kò fẹ́ràn Lea, ó ṣí i ni inú ṣùgbọ́n Rakeli yàgàn. 32Lea sì lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kan, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Reubeni, nítorí ó wí pé, “Nítorí Ọlọ́run ti mọ ìpọ́njú mi, dájúdájú, ọkọ mi yóò fẹ́ràn mi báyìí.”

33Ó sì tún lóyún, ó bí ọmọkùnrin kan. Ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Simeoni, wí pé “Nítorí tí Olúwa ti gbọ́ pé a kò fẹ́ràn mi, ó sì fi èyí fún mi pẹ̀lú.”

34Ó sì tún lóyún, ó bí ọmọkùnrin kan, ó sì wí pé, “Nígbà yìí ni ọkọ mi yóò fi ara mọ́ mi, nítorí tí mo ti bí ọmọkùnrin mẹ́ta fún un,” nítorí náà ni ó ṣe pe orúkọ rẹ̀ ní Lefi.

35Ó sì tún lóyún, ó sì tún jẹ́ pé ọmọkùnrin ni ó bí, ó sì wí pé, “Nígbà yìí ni èmi yóò yin Olúwa.” Ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Juda. Ó sì dáwọ́ ọmọ bíbí dúró.

Chinese Contemporary Bible (Traditional)

創世記 29:1-35

雅各到達舅父家

1雅各繼續前行,來到東方人住的地方, 2看見田間有一口井,有三群羊臥在井邊,因為當地人用那口井的水飲羊。井口蓋著一塊大石頭。 3羊群聚集在井旁的時候,牧人就把石頭挪開飲羊,隨後再把石頭挪回原處。

4雅各問牧人:「弟兄們,你們是從哪裡來的?」他們說:「我們是從哈蘭來的。」 5雅各問道:「你們認識拿鶴的孫子拉班嗎?」他們說:「我們認識。」 6雅各又問:「他好嗎?」他們回答說:「很好。你看,他的女兒拉結帶著羊群來了。」 7雅各對他們說:「太陽還高,不到把羊關起來的時候,你們飲了羊,再放牠們去吃草吧!」 8他們說:「不行,要等所有的羊群到齊,有人挪開井口的石頭後,才能飲羊。」

9他們還在說話的時候,拉結就帶著她父親的羊群來到井邊,她是個牧羊女。 10雅各看見表妹拉結和舅父拉班的羊群來了,就上前把井口的石頭挪開,飲他舅父的羊。 11他親吻拉結,並放聲大哭。 12雅各告訴拉結自己是她父親的外甥,是利百加的兒子。拉結便跑去告訴她父親。

13拉班聽見外甥雅各來了,就跑去迎接他,擁抱他,親吻他,然後把他接到自己家裡。雅各把事情的經過告訴他。 14拉班高興地說:「你真是我的骨肉之親啊!」雅各拉班家裡住了一個月。

雅各娶妻

15一天,拉班對他說:「雖然我們是親戚,也不能讓你白白地替我工作。告訴我,你希望得到什麼報酬?」 16拉班有兩個女兒,大的叫利亞,小的叫拉結17利亞兩眼無神29·17 兩眼無神」或譯「兩眼很美麗」。,而拉結長得美麗出眾。 18雅各愛上了拉結,於是對拉班說:「我願意為你工作七年,請你把拉結許配給我。」 19拉班說:「把她嫁給你比嫁給外人好,你就留下來吧!」 20雅各為了拉結拉班工作了七年。因為他深愛拉結,所以這七年在他眼中就像短短的幾天。

21一天,雅各拉班說:「期限已經滿了,現在請把我妻子給我,我好和她同房。」 22於是,拉班就擺設宴席款待當地的人。 23到了晚上,拉班卻把女兒利亞送給雅各雅各和她同房。 24拉班又把自己的婢女悉帕送給女兒利亞做婢女。

25第二天早上,雅各才發現娶的是利亞,就對拉班說:「你對我做的是什麼事啊!我服侍你不就是為了拉結嗎?你為什麼騙我?」 26拉班說:「依照本地的習俗,妹妹不能比姐姐先出嫁。 27等這七天的婚期過了,我就把拉結也許配給你,你再替我工作七年。」

28雅各同意了。過了七天,拉班把女兒拉結嫁給雅各29又把自己的婢女辟拉送給拉結30雅各也和拉結同房,他深愛拉結,勝過愛利亞。他又替拉班工作了七年。

雅各的兒女

31耶和華看見利亞失寵,就使利亞生育,但拉結卻不生育。 32利亞懷孕生了一個兒子,給孩子取名叫呂便29·32 呂便」意思是「看,一個兒子」,此詞發音像希伯來文「他看見了我的痛苦」一詞的發音。。她說:「耶和華看見了我的痛苦,現在我丈夫一定會愛我。」 33她又懷孕生了一個兒子,就說:「耶和華聽見了我丈夫不愛我,所以又給我這個兒子。」於是,她給孩子取名叫西緬29·33 西緬」意思是「聽見」。34她又再度懷孕,生了一個兒子,就說:「這次我丈夫一定會依戀我,因為我給他生了三個兒子。」於是,他給孩子取名叫利未29·34 利未」意思是「聯合」。35後來,利亞再次懷孕,生了一個兒子,她說:「這次我要讚美耶和華!」於是,她給孩子取名叫猶大29·35 猶大」意思是「讚美」。。之後,利亞停止了生育。