Gẹnẹsisi 23 – YCB & CCB

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Gẹnẹsisi 23:1-20

Ikú Sara

1Sara sì pé ọmọ ọdún mẹ́tà-dínláàádóje (127) 2ó sì kú ní Kiriati-Arba (ìyẹn ní Hebroni) ní ilẹ̀ Kenaani, Abrahamu lọ láti ṣọ̀fọ̀ àti láti sọkún nítorí Sara.

3Abrahamu sì dìde lẹ́gbẹ̀ẹ́ òkú aya rẹ̀, ó sì sọ fún àwọn ará Hiti wí pé, 423.4: Hb 11.9,13.“Èmi jẹ́ àtìpó àti àlejò láàrín yín, ẹ ta ilẹ̀ ìsìnkú fún mi kí èmi le sin òkú tí ó kú fún mi sí.”

5Àwọn ọmọ Hiti dá Abrahamu lóhùn pé, 6“Olúwa mi, gbọ́ tiwa, ó jẹ́ alágbára ọmọ-aládé láàrín wa, sin òkú rẹ sí ibojì tí ó dára jù nínú àwọn ibojì wa, kò sí ẹni tí yóò fi ibojì rẹ dù ọ́ láti sin òkú rẹ sí.”

7Nígbà náà ni Abrahamu dìde, ó sì tẹríba níwájú àwọn ará ilẹ̀ náà, àwọn ará Hiti. 8Ó sì wí fún wọn pé, “Bí ó bá ṣe pé, lóòótọ́ ni ẹ fẹ́ kí n sin òkú mi kúrò nílẹ̀, ẹ gbọ́ tèmi, ẹ bá mi bẹ Efroni ọmọ Sohari, 9kí ó ta ihò àpáta Makpela tí ó jẹ́ tirẹ̀ fún mi, èyí tí ó wà ni orí oko rẹ̀, kí ó tà á fún mi ni iye owó tí à ń ta irú rẹ̀ fún ilẹ̀ ìsìnkú láàrín yín.”

10Efroni ará Hiti sì wà níbẹ̀ pẹ̀lú, ó sì dá Abrahamu lóhùn lójú gbogbo àwọn ará ìlú tí ó wà níbẹ̀, lẹ́nu ibodè ìlú, 11pé, “Rárá, Olúwa mi, Gbọ́ tèmi; mo fún ọ ní ilẹ̀ náà àti ihò àpáta tí ó wà níbẹ̀. Mo fún ọ níwájú gbogbo àwọn ènìyàn mi. Sin òkú rẹ síbẹ̀.”

12Abrahamu sì tún tẹríba níwájú àwọn ènìyàn ìlú náà, 13Ó sì wí fún Efroni lójú gbogbo wọn pé, “Bí ìwọ bá fẹ́, gbọ́ tèmi, èmi yóò san owó ilẹ̀ náà, gbà á lọ́wọ́ mi kí n lè sin òkú mi síbẹ̀.”

14Efroni sì dá Abrahamu lóhùn pé, 15“Gbọ́ tèmi Olúwa mi, irínwó (400) òṣùwọ̀n owó fàdákà ni ilẹ̀ náà, ṣùgbọ́n kín ni ìyẹn já mọ láàrín àwa méjèèjì? Sá à sin òkú rẹ.”

1623.16,17: Ap 7.16.Abrahamu sì gbọ́ tí Efroni wí, Abrahamu sì wọn iye fàdákà náà fún Efroni, tí ó sọ ní etí àwọn ọmọ Hiti, irínwó òṣùwọ̀n ṣékélì fàdákà, tí ó kọjá lọ́dọ̀ àwọn oníṣòwò.

17Báyìí ni ilẹ̀ Efroni tí ó wà ni Makpela nítòsí Mamre—ilẹ̀ náà àti ihò àpáta tí ó wà nínú rẹ̀ àti gbogbo igi tí ó wà nínú ilẹ̀ náà ni a ṣe ètò rẹ̀ dájú, 18bí ohun ìní fún Abrahamu níwájú gbogbo ará Hiti tí ó wá sí ẹnu ibodè ìlú náà. 19Lẹ́yìn náà ni Abrahamu sin aya rẹ̀ Sara sínú ihò àpáta ní ilẹ̀ Makpela nítòsí Mamre (tí í ṣe Hebroni) ní ilẹ̀ Kenaani. 20Ilẹ̀ náà àti ihò àpáta tí ó wà nínú rẹ̀ ni àwọn ará Hiti fi fún Abrahamu gẹ́gẹ́ bí ohun ìní títí láé, bí ilẹ̀ ìsìnkú fún àwọn òkú tí ó bá kú fun un.

Chinese Contemporary Bible (Simplified)

创世记 23:1-20

亚伯拉罕买地葬撒拉

1撒拉享年一百二十七岁, 2迦南境内的基列·亚巴,即希伯仑去世。亚伯拉罕在那里痛哭,哀悼她。 3他从妻子尸体旁边站起来对人说: 4“我是寄居在你们这里的异乡人,请你们给我一块地,我好埋葬我的亡妻。” 5人回答说: 6“我主,请听我们说,你在我们中间是一位尊贵的王子,你可以选我们这里最好的坟地,没有人会反对你使用他的坟地埋葬你的妻子。” 7亚伯拉罕就向他们下拜,说: 8“如果你们真的准我安葬妻子,就请你们代我求琐辖的儿子以弗仑9请他当着你们的面,把他田地尽头的麦比拉洞按实价卖给我作坟地。”

10当时以弗仑正坐在人当中,于是他在城门口人聚集的地方当众答复亚伯拉罕说: 11“不可!我主,请听我说,我当着族人的面,把那块地和山洞送给你,你只管去安葬你的妻子!” 12亚伯拉罕向当地的人下拜, 13当众对以弗仑说:“你若愿意,请听我说,我要把地钱给你,请你收下,好让我安葬我的妻子。” 14以弗仑回答说: 15“我主,请听我说,四公斤半银子的地对你我来说算什么呢?去安葬你的妻子吧!” 16于是,亚伯拉罕就照以弗仑当众提出的价钱,按通用的重量单位秤了四公斤半银子给他。

17这样,以弗仑麦比拉、靠近幔利的那块地和山洞及地界内所有的树木, 18都归了亚伯拉罕。这是在城门口的人面前买下的。

19之后,亚伯拉罕把妻子撒拉安葬在迦南幔利附近、麦比拉田间的洞里。幔利就是希伯仑20这块人的地和其中的山洞从此成了亚伯拉罕家的坟地。