Gẹnẹsisi 17 – YCB & CCB

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Gẹnẹsisi 17:1-27

Májẹ̀mú Ilà abẹ́ kíkọ

1Ní ìgbà tí Abramu di ẹni ọ̀kàn-dínlọ́gọ́rùnún (99) ọdún, Olúwa farahàn án, ó sì wí pé, “Èmi ni Ọlọ́run alágbára (Eli-Ṣaddai), máa rìn níwájú mi, kí o sì jẹ́ aláìlábùkù. 2Èmi yóò sì fi ìdí májẹ̀mú mi múlẹ̀ pẹ̀lú rẹ. Èmi yóò sì sọ ọ́ di púpọ̀ gidigidi.”

3Abramu sì dojúbolẹ̀, Ọlọ́run sì wí fún un pé. 4“Ní ti èmi, májẹ̀mú mi pẹ̀lú rẹ nìyí. Ìwọ yóò di baba orílẹ̀-èdè púpọ̀. 517.5: Ro 4.17.A kì yóò pe orúkọ rẹ̀ ní Abramu mọ́, bí kò ṣe Abrahamu, nítorí, mo ti sọ ọ́ di baba orílẹ̀-èdè púpọ̀. 6Èmi yóò mú ọ bí si lọ́pọ̀lọpọ̀, ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè ni èmi yóò sì mú ti ara rẹ jáde wá, àwọn ọba pẹ̀lú yóò sì ti inú rẹ jáde. 717.7: Lk 1.55; Ga 3.16.Èmi yóò sì gbé májẹ̀mú mi kalẹ̀ láàrín tèmi tìrẹ, ní májẹ̀mú ayérayé àti láàrín irú-ọmọ rẹ ní ìran-ìran wọn, láti máa ṣe Ọlọ́run rẹ àti ti irú-ọmọ rẹ lẹ́yìn rẹ. 817.8: Ap 7.5.Gbogbo ilẹ̀ Kenaani níbi tí ìwọ ti ṣe àjèjì ni èmi yóò fi fún ọ àti fún irú-ọmọ rẹ lẹ́yìn rẹ láéláé, Èmi yóò sì jẹ́ Ọlọ́run wọn.”

9Nígbà náà ni Ọlọ́run wí fún Abrahamu pé, “Ìwọ máa pa májẹ̀mú mi mọ́, ìwọ àti irú-ọmọ rẹ lẹ́yìn rẹ àti àwọn ìran tí ó ń bọ̀. 1017.10: Ap 7.8.Èyí ni májẹ̀mú mi pẹ̀lú rẹ àti ìran rẹ lẹ́yìn rẹ, májẹ̀mú tí ẹ̀yin yóò máa pamọ́. Gbogbo ọkùnrin yín ni a gbọdọ̀ kọ ní ilà. 1117.11-14: Gẹ 17.24; 21.4.Ẹ̀yin yóò kọ ara yín ní ilà, èyí ni yóò jẹ́ ààmì májẹ̀mú láàrín tèmi tiyín. 12Ní gbogbo ìran tí ń bọ̀ lẹ́yìn, gbogbo ọkùnrin ni a gbọdọ̀ kọ ni ilà ní ọjọ́ kẹjọ tí a bí wọn, àti àwọn tí a bí ní ilé rẹ, tàbí tí a fi owó rà lọ́wọ́ àwọn àjèjì, àwọn tí kì í ṣe ọmọ rẹ̀. Èyí yóò sì jẹ́ májẹ̀mú láéláé tí yóò wà láàrín Èmi àti irú-ọmọ rẹ. 13Ìbá à ṣe ẹni tí a bí nínú ilé rẹ, tàbí ẹni tí o fi owó rà, a gbọdọ̀ kọ wọ́n ní ilà; májẹ̀mú mí lára yín yóò jẹ́ májẹ̀mú ayérayé. 14Gbogbo ọmọkùnrin tí kò bá kọ ilà, tí a kò kọ ní ilà abẹ́, ni a ó gé kúrò láàrín àwọn ènìyàn rẹ̀, nítorí pé ó da májẹ̀mú mi.”

15Ọlọ́run wí fún Abrahamu pé, “Ní ti Sarai, aya rẹ̀, ìwọ kì yóò pè é ní Sarai mọ́, bí kò ṣe Sara. 16Èmi yóò bùkún fún un, Èmi yóò sì fun ọ ní ọmọkùnrin kan nípasẹ̀ rẹ̀. Èmi yóò bùkún un, yóò sì di ìyá àwọn orílẹ̀-èdè, àwọn ọba àwọn orílẹ̀-èdè yóò sì ti ara rẹ̀ jáde wá.”

17Abrahamu sì dojúbolẹ̀, ó rẹ́rìn-ín, ó sì wí fún ara rẹ̀ pé, “A ó ha bí ọmọ fún ẹni ọgọ́rùn-ún (100) ọdún? Sara tí í ṣe ẹni àádọ́rùn-ún (90) ọdún yóò ha bímọ bí?” 18Abrahamu sì wí fún Ọlọ́run pé, “Sá à jẹ́ kí Iṣmaeli kí ó wà láààyè lábẹ́ ìbùkún rẹ.”

19Nígbà náà ni Ọlọ́run wí pé, “Mo gbọ́, ṣùgbọ́n Sara aya rẹ̀ yóò bí ọmọkùnrin kan fún ọ, ìwọ yóò sì pe orúkọ rẹ̀ ní Isaaki, èmi yóò fi ìdí májẹ̀mú mi múlẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀ ní májẹ̀mú ayérayé àti àwọn irú-ọmọ rẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀. 20Ṣùgbọ́n ní ti Iṣmaeli, mo gbọ́ ohun tí ìwọ wí, èmi yóò bùkún fún un nítòótọ́, èmi ó sì mú un bí sí i, yóò sì pọ̀ sí i, òun yóò sì jẹ́ baba fún àwọn ọmọ ọba méjìlá, bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò sì sọ ọ́ di orílẹ̀-èdè ńlá. 21Ṣùgbọ́n èmi yóò fi ìdí májẹ̀mú mi múlẹ̀ pẹ̀lú Isaaki, ẹni tí Sara yóò bí fún ọ ni ìwòyí àmọ́dún.” 22Nígbà tí ó ti bá Abrahamu sọ̀rọ̀ tán, Ọlọ́run sì gòkè lọ kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀.

23Ní ọjọ́ náà gan an ni Abrahamu mú Iṣmaeli ọmọ rẹ̀ àti àwọn ẹrú tí a bí ní ilé rẹ̀ àti àwọn tí ó fi owó rà, ó sì kọ wọ́n ní ilà. Bẹ́ẹ̀ ni ó sì kọ gbogbo ọkùnrin tí ń bẹ ní ilé rẹ̀ ní ilà gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Ọlọ́run. 24Abrahamu jẹ́ ẹni ọ̀kàn-dínlọ́gọ́rùnún (99) ọdún nígbà tí a kọ ọ́ ní ilà. 25Iṣmaeli ọmọ rẹ̀ jẹ́ ẹni ọdún mẹ́tàlá (13). 26Ní ọjọ́ náà gan an ni a kọ Abrahamu ní ilà pẹ̀lú Iṣmaeli ọmọ rẹ̀ ọkùnrin. 27Àti gbogbo ọkùnrin tí ó wà ní ilé Abrahamu, ìbá à ṣe èyí tí a bí ní ilé rẹ̀ tàbí èyí tí a fi owó rà lọ́wọ́ àlejò ni a kọ ní ilà pẹ̀lú rẹ̀.

Chinese Contemporary Bible (Simplified)

创世记 17:1-27

上帝再次与亚伯兰立约

1亚伯兰九十九岁那年,耶和华向他显现说:“我是全能的上帝。你要遵行我的旨意,做纯全无过的人。 2我要与你立约,我要使你子孙极其兴旺。” 3亚伯兰就俯伏在地,上帝又对他说: 4“我要与你立约,你必成为许多民族的始祖。 5以后你的名字不再叫亚伯兰,要改为亚伯拉罕17:5 亚伯拉罕”意思是“万族之父”。,因为我要立你为万族之父。 6我要使你的子孙极其兴旺,许多民族和君王必从你而出。 7我要和你并你的子子孙孙立永恒的约,我要做你和你子孙的上帝。 8我要把你现在寄居的整个迦南赐给你和你的后裔永远作产业,我也必做他们的上帝。”

9上帝又对亚伯拉罕说:“你和你的子孙世世代代都要遵守我的约。 10你们所有的男子都要受割礼,这是我与你和你的子孙所立的约,你们要遵守。 11你们都要割包皮,作为我与你们立约的记号。 12你们世世代代的男子在出生后的第八日都要接受割礼。在你家里出生的和用钱从外族人那里买来的奴仆也要受割礼。 13不论是在你家里生的,还是你用钱买来的男子,都要接受割礼,这样你们的肉体上就有我永恒之约的记号。 14任何没有接受割礼的男子,要将他从民中铲除,因为他违背了我的约。”

15上帝对亚伯拉罕说:“你的妻子以后不要叫撒莱,她的名字要叫撒拉16我必赐福给她,让她为你生一个儿子。她必成为万族的母亲,万民的君王必从她而出。” 17亚伯拉罕就俯伏在地,笑了起来,心想:“我一百岁了,还能有孩子吗?撒拉已经九十岁了,还能生养吗?” 18亚伯拉罕对上帝说:“愿以实玛利蒙你赐福。” 19上帝说:“不,你妻子撒拉必为你生一个儿子,你要给他取名叫以撒,我必向他和他的后代坚守我的约,直到永远。 20至于以实玛利,我已听见你的祈求,我必赐福给他,使他的后代极其兴旺昌盛。他必做十二个族长的父亲,我必使他成为大国。 21撒拉必在明年这时候给你生以撒,我必向他坚守我的约。” 22上帝说完以后,便离开亚伯拉罕上升而去。

23亚伯拉罕就在那天照着上帝的吩咐,为儿子以实玛利和家中所有的男子,不论是在家中出生的,还是买回来的,都行了割礼。 24亚伯拉罕接受割礼的时候九十九岁。 25他的儿子以实玛利接受割礼的时候十三岁。 26他们父子二人就在那天接受了割礼。 27亚伯拉罕家里所有的男子,包括家中出生的和买回来的,都一起接受了割礼。