Esekiẹli 1 – YCB & KJV

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Esekiẹli 1:1-28

Ẹ̀dá alààyè àti ògo Olúwa

11.1: If 19.11.Ní ọjọ́ karùn-ún, oṣù kẹrin tí mo di ọmọ ọgbọ̀n ọdún tí mo wà láàrín àwọn ìgbèkùn ní etí odò Kebari, àwọn ọ̀run ṣí sílẹ̀, mo sì rí ìran Ọlọ́run.

2Ní ọjọ́ karùn-ún oṣù—tí ó jẹ́ ọdún karùn-ún ìgbèkùn ọba Jehoiakini— 3ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ àlùfáà Esekiẹli, ọmọ Busii wá, létí odò Kebari ni ilẹ̀ àwọn ará Babeli. Níbẹ̀ ni ọwọ́ Olúwa ti wà lára rẹ̀.

4Mo wò, mo sì rí ìjì tó ń jà bọ̀ láti ìhà àríwá ìkùùkuu tó nípọn pẹ̀lú mọ̀nàmọ́ná ti n bù yẹ̀rì pẹ̀lú ìmọ́lẹ̀ rokoṣo tó yí i ká. Àárín iná náà rí bí ìgbà tí irin bá ń bẹ nínú iná, 51.5,18: If 4.6.àti láàrín iná náà ni ohun tó dàbí ẹ̀dá alààyè mẹ́rin wà: Ìrísí wọn jẹ́ ti ènìyàn, 6ṣùgbọ́n ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn ní ojú mẹ́rin àti ìyẹ́ apá mẹ́rin. 7Ẹsẹ̀ wọn sì tọ́; àtẹ́lẹsẹ̀ wọn sì rí bí ti ọmọ màlúù, wọ́n sì tàn bí awọ idẹ dídán. 8Ní abẹ́ ìyẹ́ wọn ní ẹ̀gbẹ́ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin wọn ní ọwọ́ ènìyàn. Gbogbo àwọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ní ojú àti àwọn ìyẹ́, 9ìyẹ́ wọn kan ara wọn. Bẹ́ẹ̀ ní ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn kò padà lọ́nà ibi tí ó ń lọ; ṣùgbọ́n wọ́n ń lọ tààrà ni.

101.10: If 4.7.Báyìí ni ìrísí ojú àwọn ẹ̀dá alààyè yìí: ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní ojú ènìyàn, ní apá ọ̀tún wọn, wọ́n ní ojú kìnnìún ní ìhà ọ̀tún, wọ́n ní ojú màlúù ní ìhà òsì, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọ́n sì tún ní ojú ẹyẹ idì. 11Báyìí ni àpèjúwe ojú wọ́n. Ìyẹ́ wọn gbé sókè; ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní ìyẹ́ méjì, ìyẹ́ ọ̀kan sì kan ti èkejì ni ẹ̀gbẹ̀ẹ̀gbẹ́, ìyẹ́ méjì tó sì tún bo ara wọn. 12Olúkúlùkù wọn ń lọ tààrà. Níbikíbi tí èmi bá ń lọ, ni àwọn náà ń lọ, láì wẹ̀yìn bí wọ́n ti ń lọ. 13Ìrísí àwọn ẹ̀dá alààyè yìí dàbí ẹyin iná tí ń jó tàbí bí i iná fìtílà. Iná tó ń jó ń lọ sókè lọ sódò láàrín àwọn ẹ̀dá alààyè; iná yìí mọ́lẹ̀ rokoṣo, ó sì ń bù yẹ̀rì yẹ̀rì jáde lára rẹ̀. 14Àwọn ẹ̀dá alààyè yìí sì ń sáré lọ sókè lọ sódò bí i ìtànṣán àrá.

151.15: If 4.5.Bí mo ti ń wo àwọn ẹ̀dá alààyè yìí, mo rí kẹ̀kẹ́ ní ilẹ̀ ni ẹ̀gbẹ́ ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ẹ̀dá alààyè wọ̀nyí pẹ̀lú ojú rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin. 16Àpèjúwe àti ìrísí àwọn kẹ̀kẹ́ náà nìyìí: kẹ̀kẹ́ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin rí bákan náà, wọ́n sì ń tàn yinrin yinrin bí i kirisoleti, ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn kẹ̀kẹ́ yìí rí bí i ìgbà tí a fi kẹ̀kẹ́ bọ kẹ̀kẹ́ nínú. 17Àwọn kẹ̀kẹ́ yìí ń yí bí wọ́n ti ń yí, wọ́n ń lọ tààrà sí ibi tí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ẹ̀dá alààyè kọjú sí, kẹ̀kẹ́ wọn kò sì yapa bí àwọn ẹ̀dá náà ti n lọ. 18Àwọn ríìmù wọ́n ga, wọ́n sì ba ni lẹ́rù, àwọn ríìmù mẹ́rẹ̀ẹ̀rin sì jẹ́ kìkìdá ojú yíká.

19Bí àwọn ẹ̀dá bá ń rìn, kẹ̀kẹ́ ẹ̀gbẹ́ wọn náà yóò rìn, bí wọ́n fò sókè, kẹ̀kẹ́ náà yóò fò sókè. 20Ibikíbi tí ẹ̀mí bá ń lọ, kẹ̀kẹ́ wọn yóò sì bá wọn lọ, nítorí pé ẹ̀mí àwọn ẹ̀dá alààyè yìí wà nínú kẹ̀kẹ́ wọn. 21Bí àwọn ẹ̀dá yìí bá ń lọ, kẹ̀kẹ́ náà yóò lọ; bí wọ́n bá dúró jẹ́ẹ́ kẹ̀kẹ́ náà yóò dúró jẹ́ẹ́, bẹ́ẹ̀ sì ni bí àwọn ẹ̀dá yìí bá dìde nílẹ̀, àwọn kẹ̀kẹ́ yìí yóò dìde pẹ̀lú wọn, nítorí pé ẹ̀mí ẹ̀dá alààyè wọ̀nyí wà nínú àwọn kẹ̀kẹ́.

22Ohun tí ó dàbí òfúrufú ràn bo orí àwọn ẹ̀dá alààyè wọ̀nyí, ó ń tàn yinrin yinrin bí i yìnyín, ó sì ba ni lẹ́rù. 23Ìyẹ́ wọn sì tọ́ lábẹ́ òfúrufú, èkínní sí èkejì, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sì ní ìyẹ́ méjì méjì tí ó bo ara wọn. 241.24: El 43.2; If 1.15; 14.2; 19.6.Nígbà tí àwọn ẹ̀dá náà gbéra, mo gbọ́ ariwo ìyẹ́ wọn tó bolẹ̀ bí i ríru omi, bí i ohùn Olódùmarè, bí i híhó àwọn jagunjagun. Nígbà tí wọ́n dúró jẹ́ẹ́, wọ́n sì rẹ ìyẹ́ wọn sílẹ̀.

25Bí wọ́n ṣe dúró tí wọ́n sì rẹ ìyẹ́ wọn sílẹ̀, ohùn kan jáde láti inú òfúrufú tó rán bò wọ́n. 261.26: If 1.13; 4.2.Lókè àwọ̀ òfúrufú tó borí wọn yìí ni ohun tí ó ní ìrísí ìtẹ́. Ìtẹ́ náà dàbí òkúta safire, lókè ní orí ìtẹ́ ní ohun tó dàbí ènìyàn wà. 27Láti ibi ìbàdí ènìyàn náà dé òkè, o dàbí irin tí ń kọ yànrànyànràn. O dàbí pe kìkì iná ni, láti ibi ìbàdí rẹ dé ìsàlẹ̀ dàbí iná tó mọ́lẹ̀ yí i ká. 28Ìmọ́lẹ̀ tó yí i ká yìí dàbí ìrísí òṣùmàrè tó yọ nínú àwọsánmọ̀ ní ọjọ́ òjò, bẹ́ẹ̀ ni ìmọ́lẹ̀ tò yí i ká.

Báyìí ni ìrísí ògo Olúwa. Nígbà tí mo rí i, mo dojúbolẹ̀, mo sì gbọ́ ohùn ẹnìkan tó ń sọ̀rọ̀.

King James Version

Ezekiel 1:1-28

1Now it came to pass in the thirtieth year, in the fourth month, in the fifth day of the month, as I was among the captives by the river of Chebar, that the heavens were opened, and I saw visions of God.1.1 captives: Heb. captivity 2In the fifth day of the month, which was the fifth year of king Jehoiachin’s captivity, 3The word of the LORD came expressly unto Ezekiel the priest, the son of Buzi, in the land of the Chaldeans by the river Chebar; and the hand of the LORD was there upon him.1.3 Ezekiel: Heb. Jehezkel

4¶ And I looked, and, behold, a whirlwind came out of the north, a great cloud, and a fire infolding itself, and a brightness was about it, and out of the midst thereof as the colour of amber, out of the midst of the fire.1.4 infolding…: Heb. catching itself 5Also out of the midst thereof came the likeness of four living creatures. And this was their appearance; they had the likeness of a man. 6And every one had four faces, and every one had four wings. 7And their feet were straight feet; and the sole of their feet was like the sole of a calf’s foot: and they sparkled like the colour of burnished brass.1.7 straight…: Heb. a straight foot 8And they had the hands of a man under their wings on their four sides; and they four had their faces and their wings. 9Their wings were joined one to another; they turned not when they went; they went every one straight forward. 10As for the likeness of their faces, they four had the face of a man, and the face of a lion, on the right side: and they four had the face of an ox on the left side; they four also had the face of an eagle. 11Thus were their faces: and their wings were stretched upward; two wings of every one were joined one to another, and two covered their bodies.1.11 stretched…: or, divided above 12And they went every one straight forward: whither the spirit was to go, they went; and they turned not when they went. 13As for the likeness of the living creatures, their appearance was like burning coals of fire, and like the appearance of lamps: it went up and down among the living creatures; and the fire was bright, and out of the fire went forth lightning. 14And the living creatures ran and returned as the appearance of a flash of lightning.

15¶ Now as I beheld the living creatures, behold one wheel upon the earth by the living creatures, with his four faces. 16The appearance of the wheels and their work was like unto the colour of a beryl: and they four had one likeness: and their appearance and their work was as it were a wheel in the middle of a wheel. 17When they went, they went upon their four sides: and they turned not when they went. 18As for their rings, they were so high that they were dreadful; and their rings were full of eyes round about them four.1.18 and their rings: or, and their strakes 19And when the living creatures went, the wheels went by them: and when the living creatures were lifted up from the earth, the wheels were lifted up. 20Whithersoever the spirit was to go, they went, thither was their spirit to go; and the wheels were lifted up over against them: for the spirit of the living creature was in the wheels.1.20 of…: or, of life 21When those went, these went; and when those stood, these stood; and when those were lifted up from the earth, the wheels were lifted up over against them: for the spirit of the living creature was in the wheels.1.21 of…: or, of life 22And the likeness of the firmament upon the heads of the living creature was as the colour of the terrible crystal, stretched forth over their heads above. 23And under the firmament were their wings straight, the one toward the other: every one had two, which covered on this side, and every one had two, which covered on that side, their bodies. 24And when they went, I heard the noise of their wings, like the noise of great waters, as the voice of the Almighty, the voice of speech, as the noise of an host: when they stood, they let down their wings. 25And there was a voice from the firmament that was over their heads, when they stood, and had let down their wings.

26¶ And above the firmament that was over their heads was the likeness of a throne, as the appearance of a sapphire stone: and upon the likeness of the throne was the likeness as the appearance of a man above upon it. 27And I saw as the colour of amber, as the appearance of fire round about within it, from the appearance of his loins even upward, and from the appearance of his loins even downward, I saw as it were the appearance of fire, and it had brightness round about. 28As the appearance of the bow that is in the cloud in the day of rain, so was the appearance of the brightness round about. This was the appearance of the likeness of the glory of the LORD. And when I saw it, I fell upon my face, and I heard a voice of one that spake.