Efesu 3 – YCB & HHH

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Efesu 3:1-21

Paulu jẹ́ oníwàásù sí àwọn aláìkọlà

1Nítorí èyí náà ni èmi Paulu ṣe di òǹdè Jesu Kristi nítorí ẹ̀yin aláìkọlà.

23.2: Kl 1.25.Lóòtítọ́ ẹ̀yin tilẹ̀ ti gbọ́ ti iṣẹ́ ìríjú oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run, tí a fi fún mi fún yín; 3bí ó ti ṣe pé nípa ìfihàn ni ó ti fi ohun ìjìnlẹ̀ hàn fún mi gẹ́gẹ́ bí mo ti kọ ṣáájú ni ṣókí, 4Nígbà tí ẹ̀yin bá kà á, nípa èyí tí ẹ̀yin o fi lè mọ òye mi nínú ìjìnlẹ̀ Kristi. 5Èyí tí a kò í tí ì fihàn àwọn ọmọ ènìyàn rí nínú ìran mìíràn gbogbo, bí a ti fi wọ́n hàn nísinsin yìí fún àwọn aposteli rẹ̀ mímọ́ àti àwọn wòlíì nípa Ẹ̀mí; 63.6: Kl 1.27.pé, àwọn aláìkọlà jẹ́ àjùmọ̀jogún àti ẹ̀yà ara kan náà, àti alábápín ìlérí nínú Kristi Jesu nípa ìhìnrere.

7Ìránṣẹ́ èyí tí a fi mi ṣe gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run tí a fi fún mi, gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ agbára rẹ̀. 8Fún èmi tí o kéré jùlọ nínú gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́, ní a fi oore-ọ̀fẹ́ yìí fún, láti wàásù àwámárídìí ọ̀rọ̀ Kristi fún àwọn aláìkọlà; 93.9: Kl 1.26.àti láti mú kí gbogbo ènìyàn rí ohun tí iṣẹ́ ìríjú ohun ìjìnlẹ̀ náà jásí, èyí tí a ti fi pamọ́ láti ìgbà àtijọ́ nínú Ọlọ́run, ẹni tí ó dá ohun gbogbo nípa Jesu Kristi: 10Kí a bá à lè fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ onírúurú ọgbọ́n Ọlọ́run hàn nísinsin yìí fún àwọn ìjòyè àti àwọn alágbára nínú àwọn ọ̀run, nípasẹ̀ ìjọ, 11gẹ́gẹ́ bí ìpinnu ayérayé tí ó ti pinnu nínú Kristi Jesu Olúwa wa: 12Nínú ẹni tí àwa ní ìgboyà, àti ọ̀nà pẹ̀lú ìgbẹ́kẹ̀lé nípa ìgbàgbọ́ wa nínú rẹ̀. 13Nítorí náà, mo bẹ̀ yín kí àárẹ̀ má ṣe mú yín ni gbogbo wàhálà mi nítorí yín, èyí tí ṣe ògo yín.

Àdúrà fún àwọn ará Efesu

14Nítorí ìdí èyí ni mo ṣe ń fi eékún mi kúnlẹ̀ fún Baba Olúwa wa Jesu Kristi. 15Orúkọ ẹni tí a fi ń pe gbogbo ìdílé tí ń bẹ ni ọ̀run àti ní ayé. 16Kí òun kí ó lè fi agbára rẹ̀ fún ẹni inú yín ní okun, nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́. 17Kí Kristi lè máa gbé inú ọkàn yín nípa ìgbàgbọ́; pé bí ẹ ti ń fi gbòǹgbò múlẹ̀ tí ẹ sì ń fi ẹsẹ̀ múlẹ̀ nínú ìfẹ́; 18kí ẹ̀yin lè ní agbára láti mọ̀ pẹ̀lú gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́, ohun tí ìbú, àti gígùn, àti jíjìn, àti gíga ìfẹ́ Kristi jẹ́. 19Àti láti mọ̀ ìfẹ́ Kristi yìí tí ó ta ìmọ̀ yọ, kí a lè fi gbogbo ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ Ọlọ́run kún yín.

20Ǹjẹ́ ẹni tí o lè ṣe lọ́pọ̀lọpọ̀ ju gbogbo èyí tí a ń béèrè tàbí tí a ń rò lọ, gẹ́gẹ́ bí agbára tí ń ṣiṣẹ́ nínú wa. 21Òun ni kí a máa fi ògo fún nínú ìjọ àti nínú Kristi Jesu láti ìrandíran gbogbo àní, ayé àìnípẹ̀kun, Àmín.

Habrit Hakhadasha/Haderekh

אגרת פולוס השליח אל האפסיים 3:1-21

1אני, פולוס, עבד ישוע המשיח, נמצא כאן בבית־הסוהר בגללכם. 2‏-3אתם ודאי יודעים שאלוהים הטיל עלי את המשימה המיוחדת להראות לכם, הגויים, את חסדו, כפי שכבר ציינתי בקצרה באחד ממכתבי. אלוהים עצמו גילה לי את תוכניתו הסודית האומרת שגם הגויים כלולים בחסדו זה.

4אני מספר לכם את כל זאת כדי שתבינו כיצד אני יודע את סוד המשיח. 5בדורות הראשונים הסתיר אלוהים מעמו את הסוד הזה, אך עתה גילהו לשליחיו ונביאיו באמצעות רוח הקודש.

6זהו הסוד: על־ידי הבשורה היהודים והגויים הם יורשים שווים של העושר המיועד לבני־האלוהים; הם חברים שווי־זכויות בקהילת האלוהים, ושותפים בהבטחותיו שניתנו על־ידי המשיח לכל המאמינים בו (במשיח). 7אלוהים העניק לי את הזכות הנפלאה לספר לכולם על אודות תוכניתו זאת, ונתן לי את הכישרון והיכולת לעשות זאת כהלכה. 8אכן, לי, הצעיר מכל המאמינים, העניק אלוהים את הזכות והחסד לבשר לגויים את הבשורה של עושר המשיח – עושר שהוא מעל ומעבר לכושר הבנתנו – 9ולהסביר לכל האנשים שאלוהים הוא גם מושיעם של הגויים, כפי שבורא־הכול תכנן מבראשית. 10מדוע? כדי שכל הכוחות, השרים והשליטים אשר בשמים יראו את חכמתו הנפלאה של אלוהים, וכל בני־משפחתו, יהודים וגויים, ייראו מאוחדים בקהילתו, 11בדרך שבה תמיד תכנן זאת על־ידי ישוע המשיח אדוננו.

12עתה אנו יכולים לבוא ישר אל נוכח האלוהים, ללא חשש ובטוחים שישמח לבואנו, בזכות אמונתנו בישוע המשיח.

13לפיכך אל תדאגו על סבלי למענכם אלא התעודדו והתגאו בכך! 14בחשבי על תוכנית נפלאה זאת אני כורע ברך לפני האלוהים, אבי אדוננו ישוע המשיח, 15אשר על שמו נקראו כל המשפחות בארץ ובשמים, 16ואני מתפלל שבאמצעות רוח הקודש הוא יעניק לכם כוח וגבורה פנימיים מתוך אוצרו הנהדר והאין־סופי. 17אני מתפלל שהמשיח באמת ישכון בלבבכם על־ידי אמונתכם ושתתחזקו באהבה, 18כדי שתוכלו לתפוש ולהבין, יחד עם שאר המאמינים, עד כמה עצומה, רבה, עמוקה וחובקת היא אהבת המשיח, 19וכדי שתתנסו בעצמכם באהבה נפלאה זאת, שהיא מעל ומעבר להבנתנו. וכך תימלאו כולכם באלוהים עצמו.

20אלוהים יכול להרבות את חסדו אלינו, ולפעול בנו מעל ומעבר למה שאנו מסוגלים לתאר או לבקש. 21כל הכבוד והתהילה לאלוהים בקרב המאמינים ובישוע המשיח, לדור ודור עד עולם.