Efesu 2 – YCB & NUB

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Efesu 2:1-22

Ìṣọdààyè nínú Kristi

1Ní ti ẹ̀yin, ẹ̀yin ni ó sì ti sọ di ààyè, nígbà ti ẹ̀yin ti kú nítorí ìrékọjá àti àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín, 22.2: Kl 1.13.nínú èyí tí ẹ̀yin ti gbé rí, àní bí ìlànà ti ayé yìí, gẹ́gẹ́ bí aláṣẹ agbára ojú ọ̀run, ẹ̀mí tí n ṣiṣẹ́ ni ìsinsin yìí nínú àwọn ọmọ aláìgbọ́ràn. 3Nínú àwọn ẹni tí gbogbo wa pẹ̀lú ti wà rí nínú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara wa, a ń mú ìfẹ́ ara àti ti inú ṣẹ, àti nípa ìṣẹ̀dá àwa sì ti jẹ́ ọmọ ìbínú, gẹ́gẹ́ bí àwọn ìyókù pẹ̀lú. 4Ṣùgbọ́n Ọlọ́run, ẹni tí í ṣe ọlọ́rọ̀ ni àánú, nítorí ìfẹ́ ńlá rẹ̀ tí ó fi fẹ́ wa, 5nígbà tí àwa tilẹ̀ ti kú nítorí ìrékọjá wa, ó sọ wá di ààyè pẹ̀lú Kristi, oore-ọ̀fẹ́ ni a ti fi gbà yín là. 6Ọlọ́run sì ti jí wa dìde pẹ̀lú Kristi, ó sì ti mú wa jókòó pẹ̀lú rẹ̀ nínú àwọn ọ̀run nínú Kristi Jesu. 7Pé ni gbogbo ìgbà tí ń bọ̀ kí ó bà á lè fi ọ̀rọ̀ oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀ tí o pọ̀ rékọjá hàn fún wa nínú ìṣeun rẹ̀ sì wà nínú Kristi Jesu. 82.8: Ga 2.16.Nítorí oore-ọ̀fẹ́ ní a fi gbà yín là nípa ìgbàgbọ́. Èyí kì í ṣe nípa agbára ẹ̀yin fúnrayín: ẹ̀bùn Ọlọ́run ni: 9Kì í ṣe nípa àwọn iṣẹ́, kí ẹnikẹ́ni má ba à ṣògo. 10Nítorí àwa ni iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ tí a ti dá nínú Kristi Jesu fún àwọn iṣẹ́ rere, èyí tí Ọlọ́run ti pèsè tẹ́lẹ̀, fún wa láti ṣe.

Ọ̀kan nínú Kristi

11Nítorí náà ẹ rántí pé, nígbà àtijọ́ rí, ẹ̀yin tí ẹ ti jẹ́ Kèfèrí nípa ti ìbí, tí àwọn tí a ń pè ní “aláìkọlà” láti ọwọ́ àwọn tí ń pe ara wọn “akọlà” (Èyí ti a fi ọwọ́ ènìyàn ṣe sí ni ni ara)— 122.12: Isa 57.19.Ẹ rántí pé ni àkókò náà ẹ̀yin wà láìní Kristi, ẹ jẹ́ àjèjì sí Israẹli, àti àjèjì sí àwọn májẹ̀mú ìlérí náà, láìní ìrètí, àti láìní Ọlọ́run ni ayé. 13Ṣùgbọ́n nísinsin yìí nínú Kristi Jesu ẹ̀yin tí ó ti jìnà réré nígbà àtijọ́ rí ni a mú súnmọ́ tòsí, nípa ẹ̀jẹ̀ Kristi.

14Nítorí òun ni àlàáfíà wa, ẹni tí o ti ṣe méjèèjì ni ọ̀kan, tí ó sì ti wó ògiri ìkélé ti ìkórìíra èyí tí ń bẹ láàrín yín. 15Ó sì ti fi òpin sí ọ̀tá náà nínú ara rẹ̀, àní sí òfin àti àṣẹ wọ̀n-ọn-nì tí ń bẹ nínú ìlànà, kí ó lè sọ àwọn méjèèjì di ẹni tuntun kan nínú ara rẹ̀, kí ó sì ṣe ìlàjà 16àti kí ó lè mú àwọn méjèèjì bá Ọlọ́run làjà nínú ara kan nípa àgbélébùú; nípa èyí tí yóò fi pa ìṣọ̀tá náà run. 172.17: Isa 57.19.Ó sì ti wá, ó sì ti wàásù àlàáfíà fún ẹ̀yin tí o jìnnà réré, àti àlàáfíà fún àwọn tí o súnmọ́ tòsí. 18Nítorí nípa rẹ̀ ni àwa méjèèjì ti ni àǹfààní sọ́dọ̀ baba nípa Ẹ̀mí kan.

19Ǹjẹ́ nítorí náà ẹ̀yin kì í ṣe àlejò àti àjèjì mọ́, ṣùgbọ́n àjùmọ̀jogún ọmọ ìbílẹ̀ pẹ̀lú àwọn ènìyàn mímọ́, àti àwọn ará ilé Ọlọ́run; 20a sì ń gbé yín ró lórí ìpìlẹ̀ àwọn aposteli, àti àwọn wòlíì, pẹ̀lú Jesu Kristi fúnrarẹ̀ gẹ́gẹ́ bí pàtàkì òkúta igun ilé; 21Nínú rẹ ni gbogbo ilé náà, tí a ń kọ wà papọ̀ ṣọ̀kan tí ó sì ń dàgbàsókè láti di tẹmpili mímọ́ kan nínú Olúwa: 22Nínú rẹ̀ ni a ń gbé ẹ̀yin pẹ̀lú ró pẹ̀lú fún ibùjókòó Ọlọ́run nínú Ẹ̀mí rẹ̀.

Swedish Contemporary Bible

Efesierbrevet 2:1-22

Nytt liv i gemenskapen med Kristus

1Ni var döda i era överträdelser och synder, 2då ni levde på den nuvarande världens vis. Ni följde härskaren över luftens rike, den andemakt som nu verkar i olydnadens människor. 3På det sättet levde vi allihop förut. Vi följde våra mänskliga impulser och lät kroppens begär och våra egna tankar styra oss. Av naturen var vi vredens barn, precis som alla andra.

4Men vår Gud som är rik på barmhärtighet har älskat oss så mycket 5att han gjorde oss levande tillsammans med Kristus, trots att vi var döda genom våra överträdelser. Det är av nåd som ni är räddade. 6Han har uppväckt oss med honom och gett oss en plats i himlen i Kristus Jesus, 7för att i kommande tidsåldrar visa sin överväldigande rika nåd i godheten mot oss i Kristus Jesus.

8Ni är alltså räddade av nåd genom tron, inte av er själva, utan det är en gåva från Gud, 9inte på grund av gärningar, och därför kan heller ingen skryta. 10Vi är hans verk, skapade i Kristus Jesus till goda gärningar, som Gud från början planerade att vi skulle göra.

Alla är ett i gemenskapen med Kristus

11Kom därför ihåg att ni som var födda hedningar och kallades oomskurna av dem som kallas omskurna, utifrån den fysiska omskärelse som människor utför, 12kom ihåg att ni på den tiden var utan Kristus, utan medborgarskap i Israel, utan delaktighet i förbunden och deras löfte, utan hopp och utan Gud här i världen. 13Men nu har ni i Kristus, ni som en gång var långt borta, kommit nära genom Kristus blod.

14Han är nämligen vår fred, han som gjorde de två till ett och rev ner fiendskapens skiljemur. 15Han har i sin kropp tillintetgjort lagen med dess bud och föreskrifter, för att i sig skapa en ny människa av de två, och därmed stifta fred. 16I denna enda kropp försonade han de båda med Gud genom korset, där han dödade fiendskapen. 17Han kom med evangeliet om fred för er som var långt borta, och fred för dem som var nära. 18Och nu kan vi båda genom honom komma inför Fadern, i en och samma Ande.

19Alltså är ni inte längre gäster och främlingar, utan har samma medborgarskap som de heliga och tillhör Guds husfolk. 20Ni är byggda på apostlarnas och profeternas2:20 Detta syftar antagligen på de profeter som verkade i församlingarna. Se 3:5. grund, med Kristus Jesus själv som hörnsten. 21Det är i honom som hela huset fogas samman, så att det byggs upp till ett heligt tempel i Herren. 22I honom fogas också ni samman till en boning åt Gud i Anden.