Efesu 1 – Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn YCB

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Efesu 1:1-23

1Paulu, aposteli Jesu Kristi nípa ìfẹ́ Ọlọ́run,

Sí àwọn ènìyàn mímọ́ tí ó wà ní Efesu, àti sí àwọn olóòtítọ́ nínú Kristi Jesu:

2Oore-ọ̀fẹ́ sí yín àti àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba wá àti Jesu Kristi Olúwa.

Ìbùkún ti Ẹ̀mí Mímọ́ nínú Kristi

31.3: 2Kọ 1.3.Ògo ni fún Ọlọ́run àti Baba Jesu Kristi Olúwa wa, ẹni tí ó ti bùkún wa láti inú ọ̀run wá pẹ̀lú àwọn ìbùkún ẹ̀mí gbogbo nínú Kristi. 4Àní, gẹ́gẹ́ bí o ti yàn wá nínú rẹ̀ ṣáájú ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé, láti jẹ́ mímọ́ àti aláìlábùkù níwájú rẹ̀ nínú ìfẹ́ 5Ẹni tí Ó ti yàn wá tẹ́lẹ̀ sí ìsọdọmọ nípa Jesu Kristi fún ara rẹ̀, ní ìbámu ìdùnnú ìfẹ́ rẹ̀ 61.6: Kl 1.13.fún ìyìn ògo oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀, èyí tí Ó ti fi fún wa nínú Àyànfẹ́ rẹ̀: 71.7: Kl 1.14.Nínú rẹ̀ ni àwa rí ìràpadà gba nípa ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ àti ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa, ní ìbámu pẹ̀lú ọrọ̀ oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run 8èyí tí ó fún wa lọ́pọ̀lọpọ̀ pẹ̀lú gbogbo ọgbọ́n àti ìmòye, 9Ó ti sọ ohun ìjìnlẹ̀ ìfẹ́ rẹ̀ di mí mọ̀ fún wa gẹ́gẹ́ bí ìdùnnú rere rẹ̀, èyí ti o pinnu nínú Kristi, 101.10: Ga 4.4.èyí tí yóò jẹ jáde ní kíkún àkókò, láti ṣe àkójọpọ̀ àwọn ohun tí ọ̀run àti ti ayé lábẹ́ Kristi.

11Nínú rẹ̀ ni a yàn wá fẹ́ lẹ́yìn tí ó ti yàn wá tẹ́lẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìpinnu ẹni tí ń ṣiṣẹ́ ohun gbogbo ní ìbámu ìfẹ́ rẹ̀, 12kí àwa kí ó le wà fún ìyìn ògo rẹ̀, àwa tí a ti ni ìrètí ṣáájú nínú Kristi. 13Àti ẹ̀yin pẹ̀lú darapọ̀ nínú Kristi nígbà tí ẹ̀yin gbọ́ ọ̀rọ̀ òtítọ́ náà àní ìhìnrere ìgbàlà yin. Nígbà tí ẹ̀yin gbàgbọ́, a fi Ẹ̀mí Mímọ́ ṣe èdìdì ayé yin nínú rẹ, èyí tí a ti ṣe ìlérí rẹ̀ tẹ́lẹ̀, 141.14: 2Kọ 1.22.èyí tí ó jẹ́ ìdánilójú àṣansílẹ̀ ogún wa títí yóò fi di àkókò ìràpadà àwọn tí í ṣe ti Ọlọ́run sí ìyìn ògo rẹ̀.

Ìdúpẹ́ àti àdúrà

151.15: Kl 1.9.Nítorí ìdí èyí, nígbà tí mo ti gbúròó ìgbàgbọ́ ti ń bẹ láàrín yín nínú Jesu Olúwa, àti ìfẹ́ yín sí gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́. 161.16: Kl 1.3.Èmi kò sì sinmi láti máa dúpẹ́ nítorí yín, àti láti máa rántí yín nínú àdúrà mi; 17Mo sì ń béèrè nígbà gbogbo pé kí Ọlọ́run Jesu Kristi Olúwa wa, Baba ògo, lè fún yín ni Ẹ̀mí nípa ti ọgbọ́n àti ti ìfihàn kí ẹ̀yin kí ó tún lè mọ̀ ọ́n sí i. 181.18: De 33.3.Mo tún ń gbàdúrà bákan náà wí pé kí ojú ọkàn yín lè mọ́lẹ̀; kí ẹ̀yin lè mọ ohun tí ìrètí ìpè rẹ̀ jẹ́, àti ọrọ̀ ògo rẹ̀ èyí tí í ṣe ogún àwọn ènìyàn mímọ́, 19àti aláìlẹ́gbẹ́ títóbi agbára rẹ̀ fún àwa tí a gbàgbọ́. Gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ agbára rẹ̀, 201.20: Sm 110.1.èyí tí ó fi sínú Kristi, nígbà tí o ti jí dìde kúrò nínú òkú, tí ó sì mú un jókòó lọ́wọ́ ọ̀tún nínú àwọn ọ̀run. 211.21: Kl 1.6; 2.10,15.Ó gbéga ju gbogbo ìjọba, àti àṣẹ, àti agbára, àti òye àti gbogbo orúkọ tí a ń dá, kì í ṣe ni ayé yìí nìkan, ṣùgbọ́n ni èyí tí ń bọ̀ pẹ̀lú. 221.22: Sm 8.6; Kl 1.18.Ọlọ́run sì ti fi ohun gbogbo sábẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀, ó sì fi í ṣe orí lórí ohun gbogbo fún ìjọ, 231.23: Ro 12.5; Kl 2.17.èyí tí i ṣe ara rẹ̀, ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ẹni tí ó kún ohun gbogbo ní gbogbo ọ̀nà.