Deuteronomi 20 – YCB & TNCV

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Deuteronomi 20:1-20

Lílọ sí ogun

1Nígbà tí o bá lọ sí ogun pẹ̀lú ọ̀tá rẹ, tí o sì rí ẹṣin àti àwọn kẹ̀kẹ́ ogun àti ológun tí ó jù ọ́ lọ, má ṣe bẹ̀rù u wọn, nítorí Olúwa Ọlọ́run rẹ tí ń mú ọ jáde wá láti ilẹ̀ Ejibiti, yóò wà pẹ̀lú rẹ. 2Nígbà tí o bá fẹ́ lọ jagun, àlùfáà yóò wá síwájú, yóò sì bá ọmọ-ogun sọ̀rọ̀, 3yóò sì wí pé, “Gbọ́, ìwọ Israẹli, lónìí ò ń jáde lọ sójú ogun sí ọ̀tá rẹ. Ẹ má ṣe jẹ́ kí ọkàn yín ṣojo tàbí bẹ̀rù; ẹ má ṣe jáyà tàbí kí ẹ fi ààyè fún ìjayà níwájú u wọn. 4Nítorí Olúwa Ọlọ́run yín ní bá yín lọ, láti bá àwọn ọ̀tá yín jà fún yín, láti gbà yín là.”

5Àwọn olórí ogun yóò sì wí fún àwọn ènìyàn pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó kọ́ ilé tuntun tí kò sì tì ì yà á sọ́tọ̀? Jẹ́ kí ó lọ ilé, tàbí ó lè kú sójú ogun kí ẹlòmíràn sì gbà á. 6Ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni tí ó gbin ọgbà àjàrà kan tí kò sì tí ì bẹ̀rẹ̀ sí ń gbádùn rẹ̀? Jẹ́ kí ó lọ ilé, tàbí kí ó kú sójú ogun kí ẹlòmíràn sì gbádùn rẹ̀. 7Ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni tí ó wá ògo obìnrin kan tí kò ì tí ì fẹ́ ẹ? Jẹ́ kí ó lọ ilé, tàbí kí ó kú sójú ogun kí ẹlòmíràn sì fẹ́ ẹ.” 8Nígbà náà ni olórí yóò tún fi kún un pé “Ǹjẹ́ ọkùnrin kankan ń bẹ̀rù tàbí páyà? Jẹ́ kí ó lọ ilé nítorí kí arákùnrin rẹ̀ má ba à wá tún dáyà fò ó.” 9Nígbà tí olórí ogun bá ti dákẹ́ ọ̀rọ̀ sísọ sí àwọn ènìyàn, wọn yóò yan olórí ogun lórí i rẹ̀.

10Nígbà tí ó bá súnmọ́ iwájú láti dojúkọ ìlú kan láti bá a jà, nígbà náà ni kí ó fi àlàáfíà lọ̀ ọ́. 11Tí wọ́n bá dá ọ lóhùn àlàáfíà, tí wọ́n sì ṣí ìlẹ̀kùn, gbogbo àwọn tó wà níbẹ̀ yóò máa jẹ́ olùsìn fún ọ, wọn ó sì máa sìn ọ́. 12Tí wọ́n bá kọ̀ láti bá ọ ṣe àlàáfíà ṣùgbọ́n tí wọ́n bá gbóguntì ọ́, nígbà náà ni kí ìwọ gbà á. 13Nígbà tí Olúwa Ọlọ́run rẹ bá fi lé ọ lọ́wọ́, kí ẹ̀yin kí ó fi ojú idà pa gbogbo àwọn ọkùnrin tí ó wà níbẹ̀. 14Ní ti obìnrin, àwọn ọmọdé, ohun ọ̀sìn àti gbogbo ohun tí ó kù nínú ìlú náà, o lè mú ìwọ̀nyí gẹ́gẹ́ bí ìkógun fún ara rẹ. O sì lè lo ìkógun tí Olúwa Ọlọ́run rẹ fi fún ọ láti ọ̀dọ̀ àwọn ọ̀tá rẹ. 15Báyìí ni ìwọ yóò ṣe sí gbogbo ìlú tí wọ́n wà ní ọ̀nà jíjìn sí ọ tí wọn kò sì tara àwọn orílẹ̀-èdè tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹ̀ rẹ.

16Ṣùgbọ́n, nínú àwọn ìlú ti àwọn orílẹ̀-èdè tí Olúwa Ọlọ́run rẹ ń fún ọ gẹ́gẹ́ bí ogún, má ṣe dá ohun ẹlẹ́mìí kankan sí. 17Pa wọ́n run pátápátá, àwọn ọmọ Hiti, ọmọ Amori, ọmọ Kenaani, ọmọ Peresi, ọmọ Hifi, ọmọ Jebusi gẹ́gẹ́ bí Olúwa Ọlọ́run rẹ ti pa á láṣẹ fún ọ. 18Bí kò ṣe bẹ́ẹ̀, wọn yóò kọ́ ọ láti tẹ̀lé gbogbo ohun ìríra tí wọ́n ń ṣe nínú sí sin àwọn ọlọ́run wọn, ìwọ yóò sì ṣẹ̀ sí Olúwa Ọlọ́run rẹ.

19Nígbà tí o bá dó ti ìlú kan láti ọjọ́ pípẹ́, ẹ bá wọn jà láti gbà á, má ṣe pa àwọn igi ibẹ̀ run nípa gbígbé àáké lé wọn, nítorí o lè jẹ èso wọn. Má ṣe gé wọn lulẹ̀. Nítorí igi igbó ha á ṣe ènìyàn bí, tí ìwọ ó máa dó tì rẹ̀. 20Ṣùgbọ́n ìwọ lè gé àwọn igi tí o mọ̀ pé wọn kì í ṣe igi eléso lulẹ̀ kí o sì lò wọ́n láti kọ́ ìṣọ́ sí ìlú tí ó ń bá ọ jagun, títí tí yóò fi ṣubú.

Thai New Contemporary Bible

เฉลยธรรมบัญญัติ 20:1-20

การออกศึก

1เมื่อท่านออกรบและเห็นศัตรูมีม้า รถม้าศึก และกองทัพยิ่งใหญ่เหนือกว่าท่าน อย่ากลัวพวกเขาเลย เพราะว่าพระยาห์เวห์พระเจ้าของท่านผู้นำท่านออกมาจากอียิปต์นั้นจะสถิตกับท่าน 2ก่อนจะออกรบ ปุโรหิตจะเดินมาข้างหน้าและกล่าวแก่กองทัพว่า 3“อิสราเอลเอ๋ย จงฟังเถิด วันนี้ท่านกำลังจะไปรบกับศัตรู ไม่ต้องขวัญหนีดีฝ่อหรือหวาดกลัว อย่าหวาดหวั่นพรั่นพรึงหรือตื่นตระหนกตกใจ 4เพราะพระยาห์เวห์พระเจ้าของท่านเสด็จไปกับท่าน พระองค์ทรงต่อสู้กับศัตรูเพื่อท่านและจะประทานชัยชนะแก่ท่าน”

5แล้วแม่ทัพนายกองจะกล่าวแก่กองทัพว่า “มีใครบ้างที่เพิ่งสร้างบ้านใหม่ แต่ยังไม่ได้ทำพิธีถวาย? ถ้ามีจงกลับไปบ้าน เพราะท่านอาจจะตายในสงคราม แล้วคนอื่นจะมาทำพิธีถวายแทน 6มีใครบ้างเพิ่งปลูกสวนองุ่น แต่ยังไม่ได้กินผลเลย? ถ้ามีจงกลับบ้าน ท่านอาจจะตายในสงครามแล้ว คนอื่นมากินแทน 7มีใครบ้างที่เพิ่งหมั้นและยังไม่ได้แต่งงาน? ถ้ามีจงกลับบ้านแต่งงานเสียเถิด มิฉะนั้นท่านอาจจะตายในสงครามและคนอื่นมาแต่งงานกับคู่หมั้นของท่านแทน” 8แล้วแม่ทัพนายกองกล่าวเสริมว่า “มีใครใจเสาะหรือหวาดหวั่นบ้าง? ถ้ามีจงกลับบ้านไปก่อนที่จะทำให้คนอื่นเสียขวัญไปด้วย” 9เมื่อแม่ทัพนายกองกล่าวจบแล้ว ก็จะประกาศรายชื่อผู้นำทัพ

10เมื่อท่านประชิดเมืองใด ก่อนอื่นจงยื่นข้อเสนอให้เขายอมเจรจา 11หากเมืองนั้นยอมรับข้อเสนอและเปิดประตูเมืองให้ ชาวเมืองทั้งหมดจะถูกเกณฑ์แรงงานเป็นคนรับใช้ของท่าน 12หากเขาไม่ยอมเจรจาอย่างสันติและต่อสู้กับท่าน ท่านจงล้อมเมืองนั้น 13เมื่อพระยาห์เวห์พระเจ้าของท่านมอบเมืองนั้นไว้ในมือของท่าน จงลงดาบฆ่าชายทุกคนในเมืองนั้น 14แต่ท่านอาจจะยึดผู้หญิง เด็ก ฝูงสัตว์ และทรัพย์สินต่างๆ ในเมืองนั้นเป็นของท่าน ท่านนำของที่ยึดได้จากศัตรูซึ่งพระยาห์เวห์พระเจ้าของท่านประทานให้ไปใช้ได้ 15ข้อปฏิบัติเหล่านี้ใช้เฉพาะเมืองไกลๆ ไม่ใช่เมืองที่เป็นของประเทศใกล้เคียง

16ส่วนเมืองต่างๆ ในประเทศที่พระยาห์เวห์พระเจ้าของท่านทรงยกให้เป็นกรรมสิทธิ์ อย่าไว้ชีวิต จงทำลายทุกสิ่งที่มีลมหายใจ 17จงทำลายล้าง20:17 คำนี้ในภาษาฮีบรูหมายถึงสิ่งของหรือบุคคลที่ถวายแด่องค์พระผู้เป็นเจ้าแล้วไม่อาจเรียกคืนได้ มักจะต้องทำลายให้หมดสิ้นไปชาวฮิตไทต์ ชาวอาโมไรต์ ชาวคานาอัน ชาวเปริสซี ชาวฮีไวต์ และชาวเยบุสให้หมดสิ้นตามที่พระยาห์เวห์พระเจ้าของท่านทรงบัญชาไว้ 18มิฉะนั้นพวกเขาจะสอนให้ท่านทำสิ่งที่น่าชิงชังโดยการกราบไหว้พระต่างๆ ตามเขา และท่านจะทำบาปต่อพระยาห์เวห์พระเจ้าของท่าน

19เมื่อท่านบุกล้อมเมืองอยู่นานเพื่อยึดเมือง อย่าโค่นต้นไม้ทิ้งเพราะท่านจะได้รับประทานผลของมัน ไม่ต้องโค่นต้นไม้ ต้นไม้ในท้องทุ่งเป็นมนุษย์หรือท่านจึงต้องล้อมทำลาย? 20แต่ท่านอาจจะโค่นต้นไม้ซึ่งไม่ได้ใช้เป็นอาหารเพื่อใช้ทำเครื่องล้อมเมืองของศัตรูจนกว่าเมืองจะแตก