Deuteronomi 18 – YCB & TNCV

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Deuteronomi 18:1-22

Ọrẹ fún àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Lefi

118.1-8: Nu 18.20-24.Àwọn àlùfáà tí wọ́n jẹ́ ọmọ Lefi, àní gbogbo ẹ̀yà Lefi, wọn kì yóò ní ìpín tàbí ogún láàrín Israẹli, wọn yóò máa jẹ nínú ọrẹ ẹbọ tí a fi iná ṣe sí Olúwa, nítorí òun ni ogún un tiwọn. 2Wọn kì yóò ní ìní láàrín àwọn arákùnrin wọn; Ọlọ́run ni yóò jẹ́ ìní i tiwọn, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe ìlérí fún wọn.

3Gbogbo èyí ni yóò jẹ́ ìpín àwọn àlùfáà láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn tí ó fi akọ màlúù tàbí àgùntàn rú ẹbọ; wọn yóò fi èjìká àti ẹ̀rẹ̀kẹ́ méjèèjì àti gbogbo inú fún àlùfáà. 4Àkọ́so irúgbìn ọkà rẹ, ti wáìnì àti ti òróró rẹ, àti àkọ́rẹ́ irun àgùntàn rẹ ni ìwọ yóò fi fún wọn. 5Nítorí Olúwa Ọlọ́run rẹ ti yàn wọ́n àti àwọn ọmọ wọn láti inú gbogbo ẹ̀yà láti dúró àti láti ṣe ìránṣẹ́ ní orúkọ Olúwa títí láé.

6Tí ọmọ Lefi kan bá sì wá láti ibikíbi nínú àwọn ìlú u yín ní Israẹli, níbi tí ó ń gbé ṣe àtìpó, tí ó sì wá gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ̀ sí ibi tí Ọlọ́run yóò yàn. 7Nígbà náà ni ó lè máa ṣe ìránṣẹ́ ní orúkọ Olúwa Ọlọ́run rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ Lefi arákùnrin rẹ̀ ti ń dúró ṣe iṣẹ́ ìsìn níwájú Olúwa níbẹ̀. 8Wọn yóò ní ìpín kan láti jẹ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti gba owó nípa títa ogún baba rẹ̀.

Ohun ìríra

9Nígbà tí o bá wọ ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò fi fún ọ, ìwọ kò gbọdọ̀ kọ́ láti tẹ̀lé àwọn ọ̀nà ìríra àwọn orílẹ̀-èdè náà tí ó wà níbẹ̀. 1018.10,11: Ek 22.18; Le 19.26,31; 20.6,27.Má ṣe jẹ́ kí a rí ẹnikẹ́ni láàrín yín tí ó fi ọmọ rẹ̀ ọkùnrin tàbí ọmọ rẹ̀ obìnrin la iná já (fi ọmọ rẹ rú ẹbọ) kí ẹnikẹ́ni má ṣe lọ fọ àfọ̀ṣẹ, tàbí ṣẹ́ oṣó, tàbí túmọ̀ àwọn ààmì nǹkan tí ń bọ̀, tàbí àjẹ́, 11tàbí afògèdè, tàbí jẹ́ a bá iwin gbìmọ̀ tàbí oṣó tàbí abókùúsọ̀rọ̀. 12Ẹnikẹ́ni tó bá ṣe nǹkan wọ̀nyí jẹ́ ìríra sí Olúwa, àti nítorí àwọn ìwà ìríra wọ̀nyí ni Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò fi lé àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyí jáde kúrò níwájú rẹ. 1318.13: Mt 5.48.O ní láti jẹ́ aláìlẹ́gàn níwájú Olúwa Ọlọ́run rẹ.

Wòlíì

14Àwọn orílẹ̀-èdè tí ìwọ yóò gba ilẹ̀ tí wọ́n ń gbé, wọ́n fetí sí tí àwọn tí ó ń ṣe oṣó tàbí ṣe àfọ̀ṣẹ. Ṣùgbọ́n, ní ti ìwọ, Olúwa Ọlọ́run rẹ kò fi ààyè gbà ọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀. 1518.15-19: Ap 3.22,23; 7.37.Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò gbé wòlíì kan dìde gẹ́gẹ́ bí èmi láàrín àwọn arákùnrin rẹ. Tìrẹ ni kí o gbọ́. 16Nítorí èyí ni ohun tí ìwọ béèrè lọ́wọ́ Olúwa Ọlọ́run rẹ ní Horebu ní ọjọ́ àjọ, nígbà tí ìwọ wí pé, “Kí àwa má ṣe gbọ́ ohùn Olúwa Ọlọ́run wa tàbí rí iná ńlá yìí mọ́. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́ àwa yóò kú.”

17Olúwa sì wí fún mi pé, “Ohun tí wọ́n sọ dára. 18Èmi yóò gbé wòlíì kan dìde fún wọn láàrín àwọn arákùnrin wọn bí ìwọ, Èmi yóò fi ọ̀rọ̀ mi sí i ní ẹnu, yóò sì sọ fún wọn gbogbo ohun tí mo ti paláṣẹ fún un. 1918.19: Ap 3.23.Ẹnikẹ́ni tí kò bá sì tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ mi tí wòlíì náà yóò sọ ní orúkọ mi, èmi fúnra à mi yóò sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀. 20Ṣùgbọ́n bí wòlíì kan bá kùgbù sọ ọ̀rọ̀ kan tí èmi kò paláṣẹ fún un láti sọ ní orúkọ mi tàbí wòlíì tí ó sọ̀rọ̀ ní orúkọ ọlọ́run mìíràn, irú wòlíì bẹ́ẹ̀ ní láti kú.”

21Ṣùgbọ́n ìwọ lè wí ní ọkàn rẹ pé, “Báwo ni àwa yóò ṣe mọ ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run kò sọ?” 22Nígbà tí ohun tí wòlíì bá sọ ní orúkọ Olúwa kò bá wá sí ìmúṣẹ tàbí jẹ́ òtítọ́, ìyẹn ni ọ̀rọ̀ tí Olúwa kò sọ, irú wòlíì bẹ́ẹ̀ tí sọ láìwádìí. Kí ẹ má ṣe bẹ̀rù rẹ̀.

Thai New Contemporary Bible

เฉลยธรรมบัญญัติ 18:1-22

ส่วนแบ่งของปุโรหิตและคนเลวี

1ปุโรหิตชาวเลวีรวมทั้งคนในเผ่าเลวีทั้งหมดจะไม่ได้รับส่วนแบ่งหรือมีกรรมสิทธิ์ร่วมกับอิสราเอล พวกเขาจะยังชีพด้วยเครื่องบูชาซึ่งเผาด้วยไฟถวายแด่องค์พระผู้เป็นเจ้าเพราะนั่นเป็นส่วนกรรมสิทธิ์ของพวกเขา 2พวกเขาจะไม่ครอบครองทรัพย์สมบัติใดในหมู่พี่น้อง เพราะองค์พระผู้เป็นเจ้าทรงเป็นกรรมสิทธิ์ของเขาตามที่ทรงสัญญาไว้กับพวกเขา

3เมื่อประชาชนถวายวัวผู้หรือแกะเป็นเครื่องบูชา บรรดาปุโรหิตจะได้โคนขาหน้า เนื้อแก้ม และเนื้อท้องเป็นส่วนแบ่ง 4จงมอบผลิตผลรุ่นแรก คือเมล็ดข้าว เหล้าองุ่นใหม่ น้ำมัน และขนแกะที่ตัดครั้งแรกให้แก่พวกเขา 5เพราะพระยาห์เวห์พระเจ้าของท่านทรงเลือกสรรพวกเขาและวงศ์วานของพวกเขาจากทุกเผ่าให้มาปฏิบัติหน้าที่รับใช้ในพระนามของพระยาห์เวห์เสมอไป

6หากชนเลวีคนใดปรารถนาจะย้ายถิ่นฐานจากเมืองใดในอิสราเอลมายังสถานที่ซึ่งองค์พระผู้เป็นเจ้าจะทรงเลือก เขาก็ทำได้ 7และให้เขาปฏิบัติหน้าที่ในพระนามของพระยาห์เวห์พระเจ้าของเขาได้เช่นเดียวกับญาติพี่น้องเลวีทั้งปวงซึ่งปฏิบัติหน้าที่อยู่ต่อหน้าองค์พระผู้เป็นเจ้า 8เขามีสิทธิ์ได้รับส่วนแบ่งจากเครื่องบูชาและของถวายอย่างเท่าเทียมกัน แม้จะได้รับเงินจากการขายทรัพย์สินของครอบครัวแล้วก็ตาม

การกระทำอันน่ารังเกียจ

9เมื่อท่านเข้าสู่ดินแดนซึ่งพระยาห์เวห์พระเจ้าของท่านประทาน อย่าเลียนแบบการกระทำอันน่าชิงชังของชนชาติทั้งหลายที่นั่น 10อย่าให้ผู้ใดในพวกท่านยกบุตรชายบุตรสาวเป็นเครื่องบูชาด้วยไฟ18:10 หรือให้บุตรชายบุตรสาวลุยไฟ เป็นหมอดูหรือนักคาถาอาคม แปลความหมายลางบอกเหตุต่างๆ เป็นพ่อมดแม่มด 11หรือทำเวทมนตร์ หรือเป็นคนทรง หรือเป็นหมอผี หรือไปปรึกษาคนที่ตายแล้ว 12องค์พระผู้เป็นเจ้าทรงรังเกียจคนที่ทำสิ่งเหล่านี้ และที่พระยาห์เวห์พระเจ้าของท่านทรงขับไล่ชนชาติเหล่านั้นออกไปต่อหน้าท่านก็เพราะธรรมเนียมปฏิบัติอันน่าชิงชังเหล่านี้ 13ท่านจะต้องไม่มีที่ติต่อหน้าพระยาห์เวห์พระเจ้าของท่าน

ผู้เผยพระวจนะ

14ชนชาติต่างๆ ซึ่งท่านจะขับไล่ออกไปจากดินแดนนั้นฟังคำของนักคาถาอาคมและหมอดู แต่ส่วนท่านพระยาห์เวห์พระเจ้าของท่านไม่ทรงอนุญาตให้ท่านทำเช่นนั้น 15พระยาห์เวห์พระเจ้าของท่านจะทรงตั้งผู้เผยพระวจนะเหมือนข้าพเจ้าขึ้นมาคนหนึ่งสำหรับท่าน จากท่ามกลางพี่น้องของท่านเอง ท่านต้องรับฟังเขา 16เพราะท่านเองได้ทูลขอจากพระยาห์เวห์พระเจ้าของท่านที่ภูเขาโฮเรบในวันชุมนุมนั้น เมื่อท่านกล่าวว่า “ขออย่าให้เราได้ยินพระสุรเสียงของพระยาห์เวห์พระเจ้าของเรา หรืออย่าให้เราเห็นเปลวไฟใหญ่นั้นอีกเลย มิฉะนั้นเราจะต้องตาย”

17องค์พระผู้เป็นเจ้าตรัสกับข้าพเจ้าว่า “ที่พวกเขากล่าวมาก็ดี 18เราจะตั้งผู้เผยพระวจนะขึ้นมาคนหนึ่งเหมือนเจ้าในหมู่พี่น้องของเขา เราจะใส่ถ้อยคำของเราไว้ในปากของเขา เขาจะแจ้งทุกสิ่งที่เราสั่งเขาแก่เหล่าประชากร 19ถ้าผู้ใดไม่ยอมฟังคำพูดของเราซึ่งผู้เผยพระวจนะนั้นกล่าวในนามของเรา เราเองจะจัดการกับผู้นั้น 20แต่ผู้เผยพระวจนะคนใดซึ่งแอบอ้างนามของเราทั้งๆ ที่เราไม่ได้สั่งให้เขาพูด หรือผู้เผยพระวจนะที่กล่าวในนามพระอื่นๆ จะต้องมีโทษถึงตาย”

21ท่านอาจจะกล่าวกับตนเองว่า “แล้วเราจะรู้ได้อย่างไรว่าถ้อยคำนี้ไม่ได้มาจากองค์พระผู้เป็นเจ้า?” 22หากสิ่งที่ผู้เผยพระวจนะประกาศในพระนามของพระยาห์เวห์ไม่เกิดขึ้นหรือเป็นจริง แสดงว่าองค์พระผู้เป็นเจ้าไม่ได้ตรัสถ้อยคำนั้น ผู้เผยพระวจนะนั้นกุขึ้นมาเอง ท่านอย่าไปเกรงกลัวเขา