Deuteronomi 15 – YCB & TNCV

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Deuteronomi 15:1-23

Ọdún ìyọ̀ǹda àti ìdáríjì

1Ní òpin ọdún méje méje, ẹ̀yin gbọdọ̀ máa yọ̀ǹda àwọn gbèsè. 2Báyìí ni kí ẹ máa ṣe é: Gbogbo ẹni tí wọ́n jẹ ní gbèsè gbọdọ̀ fojú fo gbèsè tí ó ti yá ará Israẹli ènìyàn rẹ̀. Kò gbọdọ̀ béèrè ohun náà, lọ́dọ̀ ará Israẹli ènìyàn rẹ̀ tàbí lọ́dọ̀ arákùnrin rẹ̀: nítorí pé a ti kéde àkókò Olúwa láti fojú fo gbèsè. 3Ẹ lè béèrè ìsanpadà lọ́dọ̀ àjèjì. Ṣùgbọ́n ẹ fa igi lé gbèsè yówù kó jẹ́ tí arákùnrin yín jẹ yín. 4Ṣùgbọ́n kò sí ẹni tí yóò tọ́ sí nínú yín, nítorí pé Ọlọ́run yín yóò bùkún un yín lọ́pọ̀lọpọ̀ nínú ilẹ̀ náà tí ó ń mú un yín lọ láti gbà bí ìní yín. 5Kìkì bí ẹ bá gbọ́rọ̀ sí àṣẹ Olúwa Ọlọ́run yín tí ẹ sì kíyèsára láti máa rìn nínú gbogbo àṣẹ wọ̀nyí, tí èmi ń pa fún un yín lónìí. 6Nítorí pé Olúwa Ọlọ́run yín yóò bùkún un yín bí ó ti ṣèlérí, ẹ̀yin yóò sì máa yá ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè ẹ kì yóò sì tọrọ. Ẹ ó ṣàkóso ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè, ṣùgbọ́n kò sí orílẹ̀-èdè tí yóò lè jẹ ọba lé e yín lórí.

715.7,8: Le 25.35.Bí tálákà kan bá wà láàrín àwọn arákùnrin yín ní èyíkéyìí àwọn ìlú, ilẹ̀ náà tí Olúwa yín yóò fún un yín. Ẹ má ṣe ṣe àìláàánú, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ má ṣe háwọ́ sí arákùnrin yín tí ó jẹ́ tálákà. 8Ṣùgbọ́n ẹ lawọ́ kí ẹ sì fi tọkàntọkàn yá wọn ní ohun tí wọ́n nílò. 9Ẹ ṣọ́ra kí èrò búburú kan má ṣe sí nínú àyà rẹ wí pé, “Ọdún keje tí í ṣe ọdún ìyọ̀ǹda gbèsè ti súnmọ́” nípa bẹ́ẹ̀, ojú rẹ a sì burú sí arákùnrin rẹ tálákà, tí ìwọ kò sì fun ní nǹkan, o kò sì fun ní nǹkan kan. Òun a si kígbe pe Olúwa nítorí rẹ, a si di ẹ̀ṣẹ̀ fún ọ. 10Fún un tọkàntọkàn, láìsí ìkùnsínú, nítorí èyí, Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò bùkún fún ọ nínú iṣẹ́ ọwọ́ rẹ, àti gbogbo ìdáwọ́lé rẹ. 11A kò lè fẹ́ tálákà kù ní ilẹ̀ náà ní ìgbà gbogbo, mo pàṣẹ fún un yín láti lawọ́ sí àwọn arákùnrin yín, sí àwọn tálákà àti sí àwọn aláìní, ní ilẹ̀ ẹ yín.

Ìdásílẹ̀ àwọn ẹrú

1215.12-18: El 21.2-11; Le 25.39-46.Bí Heberu ara yín kan, yálà ọkùnrin tàbí obìnrin bá ta ara rẹ̀ fún ọ, tí ó sì sìn ọ́ fún ọdún mẹ́fà. Ní ọdún keje, jẹ́ kí ó di òmìnira. 13Nígbà tí ó bá dá a sílẹ̀ má ṣe jẹ́ kí ó lọ lọ́wọ́ òfo. 14Fi tọkàntọkàn fún un láti inú agbo ewúrẹ́ rẹ, ilẹ̀ ìpakà rẹ, àti ibi ìfúntí rẹ. Fún un gẹ́gẹ́ bí Olúwa Ọlọ́run rẹ ti bùkún fún ọ tó. 15Ẹ rántí pé ẹ ti fi ìgbà kan jẹ́ ẹrú ní Ejibiti, Olúwa Ọlọ́run yín sì rà yín padà, ìdí nìyí tí mo fi pa àṣẹ yìí fún un yín lónìí.

16Ṣùgbọ́n bí ìránṣẹ́ rẹ bá sọ fún ọ pé, “Èmi kò fẹ́ fi ọ́ sílẹ̀” nítorí pé ó fẹ́ràn ìwọ àti ìdílé rẹ, tí ó sì tẹ́ ọ lọ́rùn, 17kí ìwọ kí ó mú ìlu kan lu etí rẹ̀ mọ́ ara ìlẹ̀kùn, yóò sì di ẹrú rẹ láéláé. Bẹ́ẹ̀ náà ni kí o ṣe sí ìránṣẹ́ ẹrúbìnrin rẹ.

18Má ṣe kà á sí ohun ìnira láti dá ẹrú rẹ sílẹ̀, nítorí ìsìnrú rẹ̀ fún ọ, ní ọdún mẹ́fà náà tó ìlọ́po méjì iṣẹ́ alágbàṣe, Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò bùkún fún ọ nínú gbogbo ìdáwọ́lé rẹ.

Àkọ́bí àwọn ẹran ọ̀sìn

1915.19-23: El 13.11,12; 22.30; 34.19; Nu 18.17,18.Gbogbo àkọ́bí tí o jẹ́ akọ nínú agbo màlúù rẹ ni kí o yà sọ́tọ̀ fún Olúwa, àti nínú agbo ewúrẹ́ bákan náà. Ẹ má ṣe fi àkọ́bí màlúù yín ṣiṣẹ́ rárá. Má ṣe rẹ́ irun àkọ́bí àgùntàn rẹ pẹ̀lú. 20Ní ọdọọdún ni kí ìwọ àti ìdílé rẹ máa jẹ ẹ́ níwájú Olúwa Ọlọ́run yín níbi tí Òun yóò yàn. 21Bí ẹran ọ̀sìn kan bá ní àbùkù: bóyá ó yarọ, tàbí fọ́jú, tàbí tí ó ní èyíkéyìí àbùkù tó burú. Ẹ kò gbọdọ̀ fi rú ẹbọ sí Olúwa Ọlọ́run yín. 22Ẹ jẹ ẹ́ ní ìlú u yín. Àti ẹni tí a kà sí mímọ́ àti aláìmọ́ ni ó lè jẹ ẹ́ bí ìgbà tí a ń jẹ èsúró tàbí àgbọ̀nrín. 2315.23: Gẹ 9.4; Le 7.26,27; 17.10-14; 19.26; De 12.16,23.Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò gbọdọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀; Ẹ dà á síta bí omi.

Thai New Contemporary Bible

เฉลยธรรมบัญญัติ 15:1-23

ปีแห่งการยกหนี้สิน

(ลนต.25:8-38)

1ทุกปลายปีที่เจ็ดท่านต้องยกหนี้สิน 2โดยทำดังนี้คือ เจ้าหนี้ทุกรายจะยกหนี้ให้พี่น้องร่วมชาติอิสราเอล ไม่เรียกร้องให้ใช้หนี้ เพราะเป็นวาระที่องค์พระผู้เป็นเจ้าทรงประกาศให้ยกเลิกพันธะหนี้สิน 3ท่านอาจทวงหนี้จากคนต่างด้าวได้ แต่จงยกหนี้ให้พี่น้องร่วมชาติ 4อย่างไรก็ตามจะไม่มีคนยากจนในหมู่พวกท่าน เพราะพระยาห์เวห์พระเจ้าของท่านจะทรงอวยพรท่านอย่างเหลือล้นในดินแดนซึ่งพระองค์ประทานให้ท่านครอบครองเป็นกรรมสิทธิ์ 5ถ้าเพียงแต่ท่านเชื่อฟังพระยาห์เวห์พระเจ้าของท่านอย่างครบถ้วน และใส่ใจปฏิบัติตามคำบัญชาทั้งปวงซึ่งข้าพเจ้าแจ้งท่านในวันนี้ 6เพราะพระยาห์เวห์พระเจ้าของท่านจะทรงอวยพรท่านตามที่ทรงสัญญาไว้ ท่านจะให้หลายชนชาติยืมแต่ไม่เคยต้องยืมจากใคร ท่านจะปกครองหลายชนชาติแต่จะไม่มีใครได้ปกครองท่าน

7หากมีคนยากจนท่ามกลางพี่น้องในเมืองใดของดินแดนซึ่งพระยาห์เวห์พระเจ้าของท่านกำลังจะประทานแก่ท่าน อย่านิ่งดูดายหรือไม่ยอมเห็นใจช่วยเหลือเขา 8จงใจกว้างเอื้อเฟื้อให้เขายืมตามที่เขาจำเป็น 9จงระวัง อย่ามีความคิดชั่วร้ายว่า “ปีที่เจ็ดซึ่งเป็นปีแห่งการยกหนี้สินใกล้จะมาถึงแล้ว” ก็เลยไร้น้ำใจไม่ยอมให้อะไรแก่พี่น้องผู้ยากไร้ เขาอาจร้องทูลองค์พระผู้เป็นเจ้าแล้วจะถือเป็นความผิดบาปของท่าน 10ท่านจงให้เขายืมด้วยใจกว้างขวางและอย่ามีใจคิดเสียดาย เพราะพระยาห์เวห์พระเจ้าของท่านจะทรงอวยพรท่านในกิจการงานทุกอย่างและทุกสิ่งที่ท่านทำ 11จะมีคนจนในแผ่นดินเสมอ ฉะนั้นข้าพเจ้าจึงกำชับให้ท่านเอื้อเฟื้อแก่พี่น้อง คนยากไร้ ผู้ขัดสนในดินแดนของท่าน

ปลดปล่อยทาส

(อพย.21:2-6; ลนต.25:38-55)

12หากพี่น้องชาวฮีบรูไม่ว่าชายหรือหญิง ขายตัวเป็นทาสและรับใช้ท่านมาครบหกปี ท่านต้องปล่อยเขาเป็นไทในปีที่เจ็ด 13และอย่าปล่อยเขาไปมือเปล่า 14จงมีน้ำใจให้ของจากฝูงสัตว์ ลานนวดข้าว และบ่อย่ำองุ่นแก่เขาด้วย จงแบ่งปันให้เขาตามที่พระยาห์เวห์พระเจ้าของท่านทรงอวยพรท่าน 15จงระลึกว่าท่านเคยเป็นทาสอยู่ในอียิปต์ และพระยาห์เวห์พระเจ้าของท่านทรงไถ่ท่าน ด้วยเหตุนี้ข้าพเจ้าจึงแจ้งพระบัญชานี้แก่ท่านในวันนี้

16แต่หากทาสของท่านกล่าวว่า “ข้าพเจ้าไม่อยากจากท่านไป” เพราะเขารักท่านและครอบครัวของท่าน และเขาอยู่กับท่านมีความสุขดี 17ก็จงใช้เหล็กแหลมเจาะติ่งหูเขาแนบกับประตู และเขาจะเป็นทาสของท่านตลอดไป กับทาสหญิงก็ทำเช่นเดียวกัน

18เมื่อท่านปล่อยทาสเป็นอิสระ อย่ารู้สึกเสียดาย เพราะตลอดหกปีที่เขารับใช้ท่าน ค่าแรงของเขามีค่าเป็นสองเท่าของค่าแรงลูกจ้าง และพระยาห์เวห์พระเจ้าของท่านจะทรงอวยพรทุกสิ่งที่ท่านทำ

ลูกหัวปีของสัตว์

19จงแยกสัตว์หัวปีตัวผู้ทุกตัวจากฝูงแพะแกะและฝูงวัวสำหรับถวายแด่พระยาห์เวห์พระเจ้าของท่าน อย่าเอาลูกวัวหัวปีไปใช้งาน และอย่าตัดขนลูกแกะหัวปี 20แต่ละปีท่านกับครอบครัวจะรับประทานสัตว์เหล่านี้ต่อหน้าพระยาห์เวห์พระเจ้าของท่านในสถานที่ซึ่งพระองค์จะทรงเลือก 21หากสัตว์หัวปีมีตำหนิเช่น ขาเก ตาบอด หรือมีอะไรผิดปกติ อย่านำมาถวายแด่พระยาห์เวห์พระเจ้าของท่าน 22ท่านจงรับประทานสัตว์เหล่านี้ในเมืองของท่านเอง แม้ผู้ที่เป็นมลทินตามระเบียบพิธีในขณะนั้นก็รับประทานได้เหมือนที่รับประทานเนื้อละมั่งหรือกวาง 23แต่อย่ารับประทานเลือด จงเทลงบนพื้นดินเหมือนเทน้ำ