2 Ọba 1 – YCB & CCB

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

2 Ọba 1:1-18

Ìdájọ́ Olúwa lórí Ahasiah

1Lẹ́yìn ikú Ahabu, Moabu ṣọ̀tẹ̀ sí Israẹli. 2Nísinsin yìí Ahasiah ti ṣubú láàrín fèrèsé láti òkè yàrá rẹ̀ tí ó wà ní Samaria, ó sì fi ara pa. Ó sì rán oníṣẹ́, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ lọ ṣe ìwádìí lọ́wọ́ Baali-Sebubu, òrìṣà Ekroni, bóyá èmi ó lè rí ìwòsàn ìfarapa yìí.”

3Ṣùgbọ́n angẹli Olúwa wí fún Elijah ará Tiṣibi pé, “Lọ sókè kí o lọ bá ìránṣẹ́ ọba Samaria kí o sì béèrè lọ́wọ́ wọn, ‘Ṣé nítorí pé kò sí Ọlọ́run ní Israẹli ni ẹ̀yìn fi jáde lọ ṣèwádìí lọ́wọ́ Baali-Sebubu òrìṣà Ekroni?’ 4Nítorí náà ohun tí Olúwa sọ ní èyí: ‘Ìwọ kò ní kúrò lórí ibùsùn tí o dùbúlẹ̀ lé. Dájúdájú ìwọ yóò kú!’ ” Bẹ́ẹ̀ ni Elijah lọ.

5Nígbà tí ìránṣẹ́ náà padà sí ọ̀dọ̀ ọba, ó béèrè ní ọwọ́ wọn pé, “Kí ni ó dé tí ẹ̀yin fi tètè padà wá?”

6Wọ́n dáhùn pé, “Ọkùnrin kan wá láti pàdé wa, ó sì wí fún wa pé, ‘Ẹ padà sí ọ̀dọ̀ ọba tí ó rán an yín kí ẹ sì wí fún un pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa wí: Ṣé nítorí wí pé kò sí Ọlọ́run ní Israẹli ni o fi ń rán àwọn ènìyàn láti lọ ṣe ìwádìí lọ́wọ́ Baali-Sebubu, òrìṣà Ekroni? Nítorí náà ìwọ kò ní fi orí ibùsùn tí ìwọ dùbúlẹ̀ lé sílẹ̀. Láìsí àní àní ìwọ yóò kùú!” ’ ”

7Ọba béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Irú ọkùnrin wo ni ó wá pàdé yín, tí ó sì sọ irú èyí fún un yín?”

8Wọ́n dáhùn pé, “Ó jẹ́ ọkùnrin tí ó wọ ẹ̀wù onírun lára pẹ̀lú ọ̀já àmùrè aláwọ tí ó gbà yíká ìbàdí rẹ̀.”

Ọba sì wí pé, “Elijah ará Tiṣibi ni.”

9Ó sì rán balógun pẹ̀lú àwọn ẹgbẹ́ ogun àádọ́ta rẹ̀. Balógun náà sì gòkè tọ Elijah lọ, ẹni tí ó jókòó ní orí òkè, wọ́n sì wí fún un pé, “Ènìyàn Ọlọ́run, ọba wí pé, ‘Sọ̀kalẹ̀ wá!’ ”

10Elijah sì dá balógun lóhùn pé, “Tí ó bá jẹ́ wí pé ènìyàn Ọlọ́run ni mí, kí iná kí ó sọ̀kalẹ̀ láti òkè ọ̀run wá kí ó sì jó ìwọ àti àwọn àádọ́ta ọkùnrin rẹ!” Nígbà náà iná náà sì sọ̀kalẹ̀ wá láti òkè ọ̀run ó sì jó balógun àti àwọn ènìyàn rẹ̀.

11Ọba sì tún rán balógun àádọ́ta pẹ̀lú àwọn ènìyàn àádọ́ta rẹ̀ sí Elijah. Balógun náà sì wí fún un pé, “Ènìyàn Ọlọ́run, èyí ni ohun tí ọba sọ, ‘Sọ̀kalẹ̀ kánkán!’ ”

12“Tí èmi bá jẹ́ ènìyàn Ọlọ́run,” Elijah sì dáhùn, “Ǹjẹ́ kí iná kí ó sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run kí ó sì jó ọ run àti àwọn àádọ́ta ènìyàn rẹ!” Nígbà náà iná Ọlọ́run sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run ó sì jó o run pẹ̀lú àwọn àádọ́ta ènìyàn rẹ̀.

13Bẹ́ẹ̀ ni ọba tún rán balógun kẹta pẹ̀lú àwọn àádọ́ta ọkùnrin. Balógun ẹ̀ẹ̀kẹ́ta lọ sí òkè, ó sì kúnlẹ̀ lórí orókún rẹ̀ níwájú Elijah. “Ènìyàn Ọlọ́run,” Ó sì bẹ̀bẹ̀ pé, “Ìwọ ènìyàn Ọlọ́run, jọ̀wọ́ jẹ́ kí ẹ̀mí mi àti ẹ̀mí àwọn àádọ́ta ìránṣẹ́ rẹ wọ̀nyí ṣọ̀wọ́n ní ojú rẹ! 14Wò ó, iná ti sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run láti jó àwọn balógun méjì àràádọ́ta àkọ́kọ́ pẹ̀lú àràádọ́ta wọn. Ṣùgbọ́n Nísinsin yìí ní ojúrere fún ẹ̀mí mi!”

15Angẹli Olúwa sọ fún Elijah pé, “Sọ̀kalẹ̀ lọ pẹ̀lú rẹ̀; má ṣe bẹ̀rù rẹ̀.” Bẹ́ẹ̀ ni Elijah dìde ó sì sọ̀kalẹ̀ lọ pẹ̀lú rẹ̀ sí ọ̀dọ̀ ọba.

16Ó sọ fún ọba pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa wí: Ṣé nítorí wí pé kò sí Ọlọ́run ní Israẹli fún ọ láti pè ni ìwọ fi rán ìránṣẹ́ lọ sí ọ̀dọ̀ Baali-Sebubu, òrìṣà Ekroni láti lọ ṣe ìwádìí? Nítorí pé o ṣe èyí, ìwọ kò ní dìde lórí ibùsùn tí o dùbúlẹ̀ lé láìsí àní àní ìwọ yóò kú!” 17Bẹ́ẹ̀ ó sì kú, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Olúwa tí Elijah ti sọ.

Nítorí Ahasiah kò ní ọmọ, Jehoramu jẹ ọba ní ọdún kejì tí Jehoramu ọmọ Jehoṣafati ọba Juda. 18Àti ní ti gbogbo àwọn ohun tí ó ṣẹlẹ̀ nígbà ìjọba Ahasiah, àti ohun tí ó ṣe, ṣe a kò ha kọ wọ́n sí inú ìwé ọdọọdún ti àwọn ọba Israẹli?

Chinese Contemporary Bible (Simplified)

列王纪下 1:1-18

耶和华责备亚哈谢

1亚哈死后,摩押背叛以色列2一天,亚哈谢撒玛利亚王宫的楼台上掉下来,受了伤,就派使者去求问以革伦的神明巴力·西卜,看自己能否痊愈。 3耶和华的天使对提斯比以利亚说:“你去截住撒玛利亚王的使者,对他们说,‘你们为什么去求问以革伦的神明巴力·西卜?难道以色列没有上帝吗?’ 4因此耶和华说,‘亚哈谢再也不能下床了,他必定死。’”以利亚就去了。

5以利亚将天使的话告诉王的使者后,他们便回去见王。王问他们:“你们为什么这么快就回来了?” 6他们答道:“有一个人在路上截住我们,要我们回来告诉你,耶和华对你说,‘你差人去求问以革伦的神明巴力·西卜,是因为以色列没有上帝吗?因此,你再也不能下床了,你必定死。’” 7王又问他们:“在路上截住你们、对你们说这些话的,是什么样的人?” 8他们答道:“那人身穿毛皮衣服,腰束皮带。”王说:“他是提斯比以利亚。”

9于是,王派一个五十夫长率领五十人去找以利亚。那时,以利亚正坐在山顶上。五十夫长到了那里,对他说:“上帝的仆人啊,王命令你下来。” 10以利亚说:“我若是上帝的仆人,愿火从天降下烧死你和你的五十个部下。”火立刻从天降下,烧死了五十夫长和他的五十个部下。 11亚哈谢王又派一个五十夫长率领五十人去以利亚那里,五十夫长对以利亚说:“上帝的仆人啊,王命令你马上下来。” 12以利亚说:“我若是上帝的仆人,愿火从天降下,烧死你和你的五十个部下。”上帝的火从天降下,烧死了五十夫长和他的五十个部下。

13王再次派一个五十夫长率领五十人前去。五十夫长上去,双膝跪在以利亚面前,哀求道:“上帝的仆人啊,求你饶了我和你的五十名仆人的性命。 14前两个五十夫长和他们的部下都被天上降下的火烧死了,现在求你饶我一命!” 15耶和华的天使对以利亚说:“不要害怕,跟他去吧!”以利亚就起来跟他去见王。 16以利亚对王说:“耶和华说,‘你差人去求问以革伦的神明巴力·西卜,是因为以色列没有上帝可以求问吗?因此,你再也不能下床了,你必定死。’”

17亚哈谢果然死了,正如耶和华借以利亚所说的。他没有儿子,他兄弟约兰继位,那年是犹大约沙法的儿子约兰执政第二年。 18亚哈谢其他的事都记在以色列的列王史上。