1 Kronika 9 – YCB & NIV

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

1 Kronika 9:1-44

19.1,2: Es 2.70; Ne 7.73; 11.3.Gbogbo Israẹli ni a kọ lẹ́sẹẹsẹ nínú ìtàn ìdílé láti ọ̀dọ̀ àwọn baba ńlá nínú ìwé àwọn ọba Israẹli. Àwọn ènìyàn Juda ni a kó ní ìgbèkùn lọ sí Babeli nítorí àìṣòótọ́ wọn.

Àwọn ènìyàn tí ó wà ní Jerusalẹmu

2Nísinsin yìí, àwọn tí ó kọ́kọ́ tún tẹ̀dó lórí ohun ìní wọn ní ìlú wọn ni díẹ̀ nínú àwọn ọmọ Israẹli, àwọn àlùfáà, àwọn ará Lefi àti àwọn Ìránṣẹ́ ilé Olúwa.

39.3-17: Ne 11.4-19.Àwọn tí ó wá láti Juda láti Benjamini àti láti Efraimu àti Manase tí ó ń gbé ní Jerusalẹmu jẹ́:

4Uttai ọmọ Ammihudu, ọmọ Omri, ọmọ Imri, ọmọ Bani, ìran ọmọ Peresi ọmọ Juda.

5Àti nínú ará Ṣilo:

Asaiah àkọ́bí àti àwọn ọmọ rẹ̀.

6Ní ti ará Sera:

Jeueli

Àwọn ènìyàn láti Juda sì jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin ó dín mẹ́wàá (690).

7Àti nínú àwọn ọmọ Benjamini ni:

Sallu ọmọ Meṣullamu, ọmọ Hodafiah; ọmọ Hasenuah;

8Ibinaiah ọmọ Jerohamu;

Ela ọmọ Ussi, ọmọ Mikri;

àti Meṣullamu ọmọ Ṣefatia; ọmọ Reueli, ọmọ Ibinijah.

9Àwọn ènìyàn láti Benjamini gẹ́gẹ́ bí a ti ṣe kọ ọ́ nínú ìran wọn nínú ìtàn ìdílé láti ọ̀dọ̀ baba ńlá wọn, tí ó jẹ́ ẹgbẹ̀rún ó dín mẹ́rìnlélógójì, (956). Gbogbo àwọn ọkùnrin yí jẹ́ àwọn olórí àwọn ìdílé.

10Ní ti àwọn àlùfáà:

Jedaiah; Jehoiaribi; Jakini;

11Asariah ọmọ Hilkiah, ọmọ Meṣullamu, ọmọ Sadoku, ọmọ Meraioti, ọmọ Ahitubu, olórí tí ó ń bojútó ilé Ọlọ́run;

12Adaiah ọmọ Jerohamu, ọmọ Paṣuri, ọmọ Malkiah;

àti Masai ọmọ Adieli, ọmọ Jahisera, ọmọ Meṣullamu ọmọ Meṣilemiti, ọmọ Immeri

13Àwọn àlùfáà, tí wọ́n jẹ́ àwọn olórí àwọn ìdílé, tí ó jẹ́ ẹgbẹ̀sán ó dín méjì (1,760). Wọ́n jẹ́ alágbára ọkùnrin, tí wọ́n lè dúró fún iṣẹ́ ìránṣẹ́ nínú ilé Ọlọ́run.

14Ní ti àwọn ará Lefi:

Ṣemaiah ọmọ Haṣubu, ọmọ Asrikamu, ọmọ Haṣabiah ará Merari;

15Bakibakari, Hereṣi, Galali àti Mattaniah, ọmọ Mika, ọmọ Sikri, ọmọ Asafu;

16Ọbadiah ọmọ Ṣemaiah, ọmọ Galali, ọmọ Jedutuni;

àti Berekiah ọmọ Asa, ọmọ Elkana, Tí ó ń gbé nínú àwọn ìlú àwọn ará Netofa.

17Àwọn olùtọ́jú ẹnu-ọ̀nà:

Ṣallumu, Akkubu, Talmoni, Ahimani àti arákùnrin wọn, Ṣalumu olóyè wọn, 18ti wà ní ipò ìdúró ní ẹnu-ọ̀nà ọba ní apá ìhà ìlà-oòrùn títí di àkókò yí. Wọ̀nyí ni àwọn olùtọ́jú ẹnu-ọ̀nà tí ó jẹ́ ti ìpàgọ́ àwọn ará Lefi.

19Ṣallumu ọmọ Kore ọmọ Ebiasafi, ọmọ Kora, àti àwọn olùtọ́jú ẹnu-ọ̀nà ẹlẹgbẹ́ rẹ̀. Láti ìdílé rẹ̀ (àwọn ará Korati) ni ó dúró fún ṣíṣọ́ ìloro ẹnu-ọ̀nà àgọ́ gẹ́gẹ́ bí baba wọn ti ń dúró fún ṣíṣọ́ àbáwọlé ibùgbé Olúwa.

20Ní ìgbà àkọ́kọ́ Finehasi ọmọ Eleasari jẹ́ olórí fún àwọn olùtọ́jú ẹnu-ọ̀nà, Olúwa sì wà pẹ̀lú rẹ̀.

21Sekariah, ọmọ Meṣelemiah jẹ́ olùtọ́jú ẹnu-ọ̀nà ní àbáwọlé sí àgọ́ ibi ìpàdé.

22Gbogbo rẹ̀ lápapọ̀, àwọn tí a yàn láti jẹ́ olùtọ́jú ẹnu-ọ̀nà ní àwọn ìloro jẹ́ igba ó-lé-méjìlá (212). A ka àwọn wọ̀nyí nípa ìdílé ní ìletò wọn.

Àwọn olùtọ́jú ẹnu-ọ̀nà ni a ti yàn sí ipò láti ọ̀dọ̀ Dafidi àti Samuẹli, aríran, nítorí òtítọ́ wọn. 23Àwọn àti àwọn ọmọ wọn ni ó wà fún ṣíṣọ́ ẹnu-ọ̀nà ilé Olúwa ilé tí a pè ní àgọ́. 24Àwọn olùtọ́jú ẹnu-ọ̀nà wà ní igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin: ìlà-oòrùn, ìwọ̀-oòrùn àríwá àti gúúsù. 25Àwọn arákùnrin wọn ní àwọn ìletò wọn ní láti wá ní àkókò dé àkókò láti pín iṣẹ́ ìsìn wọn fún àkókò ọjọ́ méje. 26Ṣùgbọ́n àwọn olórí alábojútó ẹnu-ọ̀nà mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tí wọ́n jẹ́ ará Lefi ni a yàn fún àwọn iyàrá àti àwọn àpótí ìṣúra ní ilé Ọlọ́run. 27Wọ́n á lo gbogbo òru ní dídúró yí ilé Ọlọ́run ká, nítorí wọ́n ní láti ṣọ́ ọ; Wọ́n sì ní àṣẹ sí kọ́kọ́rọ́ fún ṣíṣí i ní àràárọ̀.

28Díẹ̀ wà ní ìdí ohun èlò tí à ń lò fún ìsìn ilé Ọlọ́run; wọn a máa kà á nígbà tí wọ́n gbé e wọlé àti nígbà tí a kó wọn jáde. 29Àwọn mìíràn ni a yàn láti bojútó ohun èlò àti gbogbo ohun èlò ilé tí a yà sọ́tọ̀ fún Ọlọ́run, àti ìyẹ̀fun àti ọtí èso àjàrà àti òróró náà, tùràrí àti tùràrí olóòórùn dídùn. 30Ṣùgbọ́n díẹ̀ nínú àwọn àlùfáà ni ó ń bojútó pípò tùràrí olóòórùn dídùn papọ̀. 31Ará Lefi tí a sọ ní Mattitiah àkọ́bí ọmọkùnrin Ṣallumu ará Kora ni a yàn, tí ń ṣe alábojútó ohun tí a dín. 32Àti nínú àwọn arákùnrin wọn, nínú àwọn ọmọ Kohati tó ń ṣe ìtọ́jú àkàrà ìfihàn, láti máa pèsè rẹ̀ ní ọjọọjọ́ ìsinmi.

33Àwọn tí wọ́n jẹ́ ọkùnrin, olórí àwọn ìdílé Lefi dúró nínú àgọ́ ilé Olúwa, wọn kò sì ṣe lára iṣẹ́ ìsìn yòókù nítorí wọ́n ń ṣe iṣẹ́ náà lọ́sàn, lóru.

34Gbogbo wọ̀nyí jẹ́ olórí àwọn Lefi, olóyè gẹ́gẹ́ bí a ti ṣe kọ lẹ́sẹẹsẹ sínú ìtàn ìdílé láti ọ̀dọ̀ baba ńlá wọn, wọ́n sì ń gbé ní Jerusalẹmu.

Ìdílé àti Ìrandíran Saulu

35Jeieli baba Gibeoni ń gbé ní Gibeoni.

Orúkọ ìyàwó rẹ̀ a máa jẹ́ Maaka, 36Pẹ̀lú àkọ́bí ọmọkùnrin rẹ̀ jẹ́ Abdoni, tí wọ̀nyí sì ń tẹ̀lé Suri, Kiṣi, Baali, Neri, Nadabu. 37Gedori, Ahio, Sekariah àti Mikiloti. 38Mikiloti jẹ́ baba Ṣimeamu, àwọn náà ń gbé ní ẹ̀bá ìbátan wọn ní Jerusalẹmu.

39Neri jẹ́ baba Kiṣi, Kiṣi baba a Saulu, àti Saulu baba a Jonatani, àti Malikiṣua, Abinadabu àti Eṣi-Baali.

40Ọmọ Jonatani:

Meribu-Baali, tí ó jẹ́ baba Mika:

41Àwọn ọmọ Mika:

Pitoni. Meleki, Tarea àti Ahasi.

42Ahasi jẹ́ baba Jada, Jada jẹ́ baba Alemeti, Asmafeti, Simri, sì Simri jẹ́ baba Mosa. 43Mosa jẹ́ baba Binea; Refaiah jẹ́ ọmọ rẹ̀, Eleasa ọmọ rẹ̀ àti Aseli ọmọ rẹ̀.

44Aseli ní ọmọ mẹ́fà, pẹ̀lú wọ̀nyí ni orúkọ wọn:

Asrikamu, Bokeru, Iṣmaeli Ṣeariah, Ọbadiah àti Hanani, gbogbo wọ̀nyí ni ọmọ Aseli.

New International Version

1 Chronicles 9:1-44

1All Israel was listed in the genealogies recorded in the book of the kings of Israel and Judah. They were taken captive to Babylon because of their unfaithfulness.

The People in Jerusalem

2Now the first to resettle on their own property in their own towns were some Israelites, priests, Levites and temple servants.

3Those from Judah, from Benjamin, and from Ephraim and Manasseh who lived in Jerusalem were:

4Uthai son of Ammihud, the son of Omri, the son of Imri, the son of Bani, a descendant of Perez son of Judah.

5Of the Shelanites9:5 See Num. 26:20; Hebrew Shilonites.:

Asaiah the firstborn and his sons.

6Of the Zerahites:

Jeuel.

The people from Judah numbered 690.

7Of the Benjamites:

Sallu son of Meshullam, the son of Hodaviah, the son of Hassenuah;

8Ibneiah son of Jeroham; Elah son of Uzzi, the son of Mikri; and Meshullam son of Shephatiah, the son of Reuel, the son of Ibnijah.

9The people from Benjamin, as listed in their genealogy, numbered 956. All these men were heads of their families.

10Of the priests:

Jedaiah; Jehoiarib; Jakin;

11Azariah son of Hilkiah, the son of Meshullam, the son of Zadok, the son of Meraioth, the son of Ahitub, the official in charge of the house of God;

12Adaiah son of Jeroham, the son of Pashhur, the son of Malkijah; and Maasai son of Adiel, the son of Jahzerah, the son of Meshullam, the son of Meshillemith, the son of Immer.

13The priests, who were heads of families, numbered 1,760. They were able men, responsible for ministering in the house of God.

14Of the Levites:

Shemaiah son of Hasshub, the son of Azrikam, the son of Hashabiah, a Merarite; 15Bakbakkar, Heresh, Galal and Mattaniah son of Mika, the son of Zikri, the son of Asaph; 16Obadiah son of Shemaiah, the son of Galal, the son of Jeduthun; and Berekiah son of Asa, the son of Elkanah, who lived in the villages of the Netophathites.

17The gatekeepers:

Shallum, Akkub, Talmon, Ahiman and their fellow Levites, Shallum their chief 18being stationed at the King’s Gate on the east, up to the present time. These were the gatekeepers belonging to the camp of the Levites. 19Shallum son of Kore, the son of Ebiasaph, the son of Korah, and his fellow gatekeepers from his family (the Korahites) were responsible for guarding the thresholds of the tent just as their ancestors had been responsible for guarding the entrance to the dwelling of the Lord. 20In earlier times Phinehas son of Eleazar was the official in charge of the gatekeepers, and the Lord was with him. 21Zechariah son of Meshelemiah was the gatekeeper at the entrance to the tent of meeting.

22Altogether, those chosen to be gatekeepers at the thresholds numbered 212. They were registered by genealogy in their villages. The gatekeepers had been assigned to their positions of trust by David and Samuel the seer. 23They and their descendants were in charge of guarding the gates of the house of the Lord—the house called the tent of meeting. 24The gatekeepers were on the four sides: east, west, north and south. 25Their fellow Levites in their villages had to come from time to time and share their duties for seven-day periods. 26But the four principal gatekeepers, who were Levites, were entrusted with the responsibility for the rooms and treasuries in the house of God. 27They would spend the night stationed around the house of God, because they had to guard it; and they had charge of the key for opening it each morning.

28Some of them were in charge of the articles used in the temple service; they counted them when they were brought in and when they were taken out. 29Others were assigned to take care of the furnishings and all the other articles of the sanctuary, as well as the special flour and wine, and the olive oil, incense and spices. 30But some of the priests took care of mixing the spices. 31A Levite named Mattithiah, the firstborn son of Shallum the Korahite, was entrusted with the responsibility for baking the offering bread. 32Some of the Kohathites, their fellow Levites, were in charge of preparing for every Sabbath the bread set out on the table.

33Those who were musicians, heads of Levite families, stayed in the rooms of the temple and were exempt from other duties because they were responsible for the work day and night.

34All these were heads of Levite families, chiefs as listed in their genealogy, and they lived in Jerusalem.

The Genealogy of Saul

35Jeiel the father9:35 Father may mean civic leader or military leader. of Gibeon lived in Gibeon.

His wife’s name was Maakah, 36and his firstborn son was Abdon, followed by Zur, Kish, Baal, Ner, Nadab, 37Gedor, Ahio, Zechariah and Mikloth. 38Mikloth was the father of Shimeam. They too lived near their relatives in Jerusalem.

39Ner was the father of Kish, Kish the father of Saul, and Saul the father of Jonathan, Malki-Shua, Abinadab and Esh-Baal.9:39 Also known as Ish-Bosheth

40The son of Jonathan:

Merib-Baal,9:40 Also known as Mephibosheth who was the father of Micah.

41The sons of Micah:

Pithon, Melek, Tahrea and Ahaz.9:41 Vulgate and Syriac (see also Septuagint and 8:35); Hebrew does not have and Ahaz.

42Ahaz was the father of Jadah, Jadah9:42 Some Hebrew manuscripts and Septuagint (see also 8:36); most Hebrew manuscripts Jarah, Jarah was the father of Alemeth, Azmaveth and Zimri, and Zimri was the father of Moza. 43Moza was the father of Binea; Rephaiah was his son, Eleasah his son and Azel his son.

44Azel had six sons, and these were their names:

Azrikam, Bokeru, Ishmael, Sheariah, Obadiah and Hanan. These were the sons of Azel.