Ìṣe àwọn Aposteli 1 – YCB & CCB

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Ìṣe àwọn Aposteli 1:1-26

A mú Jesu lọ sí ọ̀run

11.1: Lk 1.1-4.Nínú ìwé mi ìṣáájú, Teofilu, ni mo ti kọ ní ti ohun gbogbo tí Jesu bẹ̀rẹ̀ sí ṣe àti kọ́ 2títí ó fi di ọjọ́ tí a gbà á lọ sókè ọ̀run, lẹ́yìn tí ó ti ti ipa Ẹ̀mí Mímọ́ pàṣẹ fún àwọn aposteli tí ó yàn 3Lẹ́yìn ìjìyà rẹ̀, ó fi ara rẹ̀ hàn fún wọn àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀rí tí ó dájú pé òun wà láààyè. Ó fi ara hàn wọ́n fún ogójì ọjọ́, ó sì sọ̀rọ̀ nípa ìjọba Ọlọ́run. 41.4: Lk 24.49.Ní àkókò kan bí ó sì ti ń jẹun pẹ̀lú wọn, ó pàṣẹ yìí fún wọn: “Ẹ má ṣe kúrò ní Jerusalẹmu, ṣùgbọ́n ẹ dúró de ìlérí tí Baba mi ṣe ìlérí, èyí tí ẹ̀yin tí gbọ́ lẹ́nu mi. 5Nítorí Johanu fi omi bamitiisi yín, ṣùgbọ́n ní ọjọ́ díẹ̀ sí i, a o fi Ẹ̀mí Mímọ́ bamitiisi yín.”

6Nítorí náà, nígbà tí wọ́n sì péjọpọ̀, wọn bi í léèrè pé, “Olúwa, láti ìgbà yí lọ ìwọ yóò ha mú ìjọba padà fún Israẹli bí?”

7Ó sì wí fún wọn pé, “Kì í ṣe tiyín ni láti mọ àkókò tàbí ìgbà tí Baba ti yàn nípa àṣẹ òun tìkára rẹ̀. 81.8: Lk 24.48-49.Ṣùgbọ́n ẹ̀yin yóò gba agbára, nígbà tí Ẹ̀mí Mímọ́ bá bà lé e yín: ẹ̀yin yóò sì máa ṣe ẹlẹ́rìí mi ni Jerusalẹmu, àti ní gbogbo Judea, àti ní Samaria, àti títí dé òpin ilẹ̀ ayé.”

91.9-12: Lk 24.50-53.Nígbà tí ó sì tí wí nǹkan wọ̀nyí, a gbà á sókè lójú wọn; ìkùùkuu àwọsánmọ̀ sì gbà á kúrò lójú wọn.

10Bí wọ́n sì ti tẹjúmọ́ ojú ọ̀run bí ó ti ń lọ sókè, lójijì, àwọn ọkùnrin méjì tí ó wọ aṣọ funfun dúró létí ọ̀dọ̀ wọn. 11Wọ́n sì wí pé, “Ẹ̀yin ara Galili, èéṣe tí ẹ̀yin fi dúró tí ẹ̀ ń wo ojú ọ̀run? Jesu yìí, tí a gbà sókè ọ̀run kúrò lọ́wọ́ yín, yóò padà bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹ ti rí tí ó ń lọ sì ọ̀run.”

A yan Mattia Rọ́pò Judasi

12Lẹ́yìn náà ni wọ́n padà sí Jerusalẹmu láti orí òkè ti a ń pè ni olifi, tí ó tó ìwọ̀n ìrìn ọjọ́ ìsinmi kan. 131.13: Mt 10.2-4; Mk 3.16-19; Lk 6.14-16.Nígbà tí wọn sì wọlé, wọn lọ sí iyàrá òkè, níbi tí wọ́n ń gbé. Àwọn tó wà níbẹ̀ ni:

Peteru, Jakọbu, Johanu àti Anderu;

Filipi àti Tomasi;

Bartolomeu àti Matiu;

Jakọbu ọmọ Alfeu, Simoni Sealoti, àti Judasi arákùnrin Jakọbu.

14Gbogbo àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú àwọn obìnrin àti Maria ìyá Jesu àti àwọn arákùnrin rẹ̀ fi ọkàn kan dúró láti máa gbàdúrà.

15Ní ọjọ́ wọ̀nyí ni Peteru sí dìde dúró láàrín àwọn ọmọ-ẹ̀yìn (iye àwọn ènìyàn wọ̀nyí jẹ́ ọgọ́fà) 161.16-19: Mt 27.3-10.ó wí pé, “Ẹ̀yin ará, ìwé mímọ́ kò lè ṣe kí ó má ṣẹ, èyí tí Ẹ̀mí Mímọ́ ti sọtẹ́lẹ̀ láti ẹnu Dafidi nípa Judasi, tí ó ṣe atọ́nà fún àwọn tí ó mú Jesu: 17Nítorí ọ̀kan nínú wa ni òun ń ṣe tẹ́lẹ̀, òun sì ní ìpín nínú iṣẹ́ ìránṣẹ́ yìí.”

18(Judasi fi èrè àìṣòótọ́ rẹ̀ ra ilẹ̀ kan; nígbà tí ó sì ṣubú ni ògèdèǹgbé, ó bẹ́ ní agbede-méjì, gbogbo ìfun rẹ̀ sì tú jáde. 19Ó si di mí mọ̀ fún gbogbo àwọn ti ń gbé Jerusalẹmu; nítorí náà ni wọ́n fi ń pè ilẹ̀ náà ni Alkedama ní èdè wọn, èyí sì ni, Ilẹ̀ Ẹ̀jẹ̀.)

201.20: Sm 69.25; 109.8.Peteru sì wí pé, “Nítorí a ti kọ ọ́ nípa rẹ̀ nínú Ìwé Saamu pé,

“ ‘Jẹ́ ki ibùgbé rẹ̀ di ahoro,

kí ẹnikẹ́ni má ṣe gbé inú rẹ̀,’

àti,

“ ‘Ipò rẹ̀ ni kí ẹlòmíràn kí ó gbà.’

21Nítorí náà, ó di dandan láti yan ọ̀kan nínú àwọn ọkùnrin wọ̀nyí ti ń bá wa rìn ni gbogbo àkókò tí Jesu Olúwa ń wọlé, tí ó sì jáde láàrín wa. 22Bẹ́ẹ̀ láti ìgbà bamitiisi Johanu títí ó fi di ọjọ́ náà ti a gbe é lọ sókè kúrò lọ́dọ̀ wa. Ó yẹ kí ọ̀kan nínú àwọn wọ̀nyí ṣe ẹlẹ́rìí àjíǹde rẹ̀ pẹ̀lú wa.”

23Wọn sì yan àwọn méjì, Josẹfu tí a ń pè ní Barsaba, (ẹni tí a sọ àpèlé rẹ̀ ni Justu) àti Mattia. 24Wọn sì gbàdúrà, wọn sì wí pé, “Olúwa, ìwọ mọ ọkàn gbogbo ènìyàn, fihàn wá nínú àwọn méjì yìí, èwo ni ìwọ yàn 25kí ó lè gba ipò nínú iṣẹ́ ìránṣẹ́ aposteli yìí, èyí tí Judasi kúrò nínú rẹ̀, ki òun kí ó lè lọ sí ipò ti ara rẹ̀.” 26Wọ́n sì dìbò fún wọn; ìbò sí mú Mattia; a sì kà á mọ́ àwọn aposteli mọ́kànlá.

Chinese Contemporary Bible (Simplified)

使徒行传 1:1-26

应许圣灵降临

1提阿非罗啊,在前一封信中,我从耶稣的生平和教导开始, 2一直谈到祂借着圣灵吩咐了自己选立的使徒,然后被接回天上。 3祂受难后用许多确凿的证据证实自己活着,在四十天之内屡次向使徒显现,与他们谈论上帝的国。 4有一次,耶稣和他们在一起吃饭的时候,叮嘱他们:“你们不要离开耶路撒冷,要在那里等候我对你们说过的天父的应许。 5因为从前约翰用水给你们施洗,但再过几天,你们要受圣灵的洗。”

6他们跟耶稣在一起的时候问祂:“主啊,你要在这时候复兴以色列国吗?” 7耶稣回答说:“天父照祂的权柄定下的时间、日期不是你们可以知道的。 8但圣灵降临在你们身上后,你们必得到能力,在耶路撒冷犹太全境和撒玛利亚,直到地极,做我的见证人。”

9耶稣说完这番话,就在他们眼前被提升天,被一朵云彩接去,离开了他们的视线。 10祂上升时,他们都定睛望着天空,忽然有两个身穿白衣的人站在他们身旁, 11说:“加利利人啊!你们为什么站在这里望着天空呢?这位离开你们被接到天上的耶稣,你们看见祂怎样升天,将来祂还要怎样回来。”

选立新使徒

12于是,他们从橄榄山回到耶路撒冷。橄榄山距离耶路撒冷不远,约是安息日允许走的路程1:12 按犹太人的传统,在安息日只能走约一公里远。13他们进城后,来到楼上自己住的房间。当时有彼得约翰雅各安得烈腓力多马巴多罗买马太亚勒腓的儿子雅各、激进党人西门雅各的儿子犹大14他们和耶稣的母亲玛丽亚、耶稣的弟弟们及几个妇女在一起同心合意地恒切祷告。

15那时,约有一百二十人在聚会,彼得站起来说: 16“弟兄们,关于带人抓耶稣的犹大,圣灵借着大卫的口早已预言,这经文必须要应验。 17这人原本是我们中间的一员,与我们同担使徒的职分。”

18犹大用作恶得来的钱买了一块田,他头朝下栽倒在那里,肚破肠流。 19这消息很快传遍了耶路撒冷,当地人称那块田为“亚革大马”,就是“血田”的意思。

20彼得继续说:“诗篇上写道,‘愿他的家园一片荒凉,无人居住’,又说,‘愿别人取代他的职位。’ 21-22所以,我们必须另选一个人代替犹大,与我们一同为主耶稣的复活做见证。他必须是从主耶稣接受约翰的洗礼起一直到主升天,始终与我们在一起的人。”

23被提名的有别号巴撒巴又叫犹士都约瑟马提亚两个人。 24-25大家便祷告说:“主啊!你洞悉人的内心,求你指明这两个人中你要拣选哪一个来担负使徒的职分。犹大丢弃了这职分,去了他该去的地方。” 26然后,他们抽签,抽中了马提亚,就把他列入十一使徒中。