2โครินธ์ 6 – TNCV & YCB

Thai New Contemporary Bible

2โครินธ์ 6:1-18

1ในฐานะผู้ร่วมงานของพระเจ้า เราวิงวอนท่านว่าอย่าสักแต่รับพระคุณของพระเจ้า 2เพราะพระองค์ตรัสว่า

“ในวาระแห่งความโปรดปรานเราได้ฟังเจ้า

และในวันแห่งความรอดเราได้ช่วยเจ้า”6:2 อสย.49:8

ข้าพเจ้าขอบอกท่านว่าบัดนี้คือวาระแห่งความโปรดปรานของพระเจ้า บัดนี้คือวันแห่งความรอด

ความทุกข์ยากที่เปาโลเผชิญ

3เราไม่ทำให้ใครสะดุดเพื่อไม่ให้พันธกิจของเราเสียความเชื่อถือ 4แทนที่จะเป็นเช่นนั้น ในฐานะผู้รับใช้ของพระเจ้าเราพิสูจน์ตัวเองในทุกทาง ไม่ว่าในการอดทนอดกลั้น ในความทุกข์ร้อน ความยากเข็ญและความลำเค็ญ 5ในการถูกเฆี่ยนตี การถูกจองจำและการจลาจล ในการตรากตรำทำงาน การอดหลับอดนอน และความหิวโหย 6ในความบริสุทธิ์ ความเข้าใจ ความอดทน และความกรุณา ในพระวิญญาณบริสุทธิ์ และในความรักจริงใจ 7ในคำพูดสัตย์จริง และในฤทธานุภาพของพระเจ้า ด้วยอาวุธแห่งความชอบธรรมทั้งในมือขวาและมือซ้าย 8ทั้งในยามทรงเกียรติและไร้เกียรติ ในยามที่เขาว่าชั่วและในยามที่เขาว่าดี จริงแท้แต่ถูกมองว่าเป็นคนหลอกลวง 9เป็นที่รู้จักแต่ถูกมองว่าไม่มีใครรู้จัก กำลังจะตายแต่เราก็ยังมีชีวิตอยู่ต่อไป ถูกเฆี่ยนตีแต่ก็ยังไม่ถึงตาย 10ทุกข์โศกแต่ก็ยังชื่นชมยินดีเสมอ ยากจนแต่ก็ยังทำให้หลายคนมั่งคั่ง และไม่มีอะไรแต่ก็ยังเป็นเจ้าของทุกสิ่ง

11พี่น้องชาวโครินธ์ เราพูดกับท่านอย่างตรงไปตรงมาและเปิดใจของเราให้แก่ท่าน 12เราไม่ได้เป็นฝ่ายระงับความรักจากท่าน แต่ท่านเป็นฝ่ายระงับจากเรา 13เพื่อเป็นการแลกเปลี่ยนอย่างยุติธรรม เราขอพูดกับท่านเสมือนพูดกับบุตรว่าจงเปิดใจของท่านด้วย

อย่าเข้าเทียมแอกกับผู้ไม่เชื่อ

14อย่าเข้าเทียมแอกกับผู้ไม่เชื่อเพราะความชอบธรรมกับความชั่วจะมีอะไรร่วมกันได้? หรือความสว่างกับความมืดจะมีสามัคคีธรรมอะไรกันเล่า? 15พระคริสต์กับเบลีอัล6:15 ภาษากรีกว่าเบลีอาร์เป็นอีกรูปหนึ่งของเบลีอัลจะกลมเกลียวอะไรกันได้? ผู้เชื่อกับผู้ไม่เชื่อจะมีอะไรร่วมกันได้เล่า? 16วิหารของพระเจ้ากับวิหารของรูปเคารพจะมีข้อตกลงอะไรกันได้? เพราะเราเป็นวิหารของพระเจ้าผู้ทรงพระชนม์อยู่ตามที่พระเจ้าตรัสว่า “เราจะอยู่กับพวกเขาและดำเนินท่ามกลางพวกเขา และเราจะเป็นพระเจ้าของพวกเขาและพวกเขาจะเป็นประชากรของเรา”6:16 ลนต.26:12ยรม.32:38 อสค. 37:27

17“ดังนั้นจงออกมาจากพวกเขา

และแยกตัวออก องค์พระผู้เป็นเจ้าตรัส

อย่าแตะต้องสิ่งมลทิน

แล้วเราจะรับเจ้า”6:17 อสย.52:11 อสค. 20:34,41

18“เราจะเป็นบิดาของพวกเจ้า

และพวกเจ้าจะเป็นบุตรชายบุตรสาวของเรา

องค์พระผู้เป็นเจ้าผู้ทรงฤทธิ์ตรัสดังนี้แหละ”6:18 2ซมอ.7:14; 7:8

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

2 Kọrinti 6:1-18

1Gẹ́gẹ́ bí alábáṣiṣẹ́pọ̀ nínú Ọlọ́run, ǹjẹ́, àwa ń rọ̀ yín kí ẹ má ṣe gba oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run lásán. 26.2: Isa 49.8.Nítorí o wí pé,

“Ní àkókò ìtẹ́wọ́gbà mi, èmi tí gbọ́ ohùn rẹ,

àti ọjọ́ ìgbàlà, èmi sì ti ràn ọ́ lọ́wọ́.”

Èmi wí fún ọ, nísinsin yìí ní àkókò ìtẹ́wọ́gbà, nísinsin yìí ni ọjọ́ ìgbàlà.

Àwọn wàhálà Paulu

3Àwa kò sì gbé ohun ìkọ̀sẹ̀ kankan si ọ̀nà ẹnikẹ́ni, ki iṣẹ́ ìránṣẹ́ wa má ṣe di ìṣọ̀rọ̀-òdì-sí. 46.4: 2Kọ 4.8-11; 11.23-27.Ṣùgbọ́n dípò bẹ́ẹ̀, ni ọnà gbogbo, àwa ń fi ara wa hàn bí àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ sùúrù, nínú ìpọ́njú, nínú àìní, nínú wàhálà, 56.5: Ap 16.23.nípa nínà, nínú túbú, nínú ìrúkèrúdò, nínú iṣẹ́ àṣekára, nínú àìsàn, nínú ìgbààwẹ̀. 6Nínú ìwà mímọ́, nínú ìmọ̀, nínú ìpamọ́ra, nínú ìṣeun, nínú Ẹ̀mí Mímọ́, nínú ìfẹ́ àìṣẹ̀tàn. 76.7: 2Kọ 10.4; Ro 13.12; Ef 6.11-12.Nínú ọ̀rọ̀ òtítọ́, nínú agbára Ọlọ́run, nínú ìhámọ́ra òdodo ní apá ọ̀tún àti ní apá òsì. 8Nípa ọlá àti ẹ̀gàn, nípa ìyìn búburú àti ìhìnrere: bí ẹlẹ́tàn, ṣùgbọ́n a jásí olóòtítọ́, 96.9: Ro 8.36.bí ẹni tí a kò mọ̀, ṣùgbọ́n a mọ̀ wá dájúdájú; bí ẹni tí ń kú lọ, ṣùgbọ́n a ṣì wà láààyè; bí ẹni tí a nà, ṣùgbọ́n a kò sì pa wá, 106.10: Ro 8.32; 1Kọ 3.21.bí ẹni tí ó kún fún ìbànújẹ́, ṣùgbọ́n àwa ń yọ̀ nígbà gbogbo; bí tálákà, ṣùgbọ́n àwa ń sọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ dí ọlọ́rọ̀; bí ẹni tí kò ní nǹkan, ṣùgbọ́n àwa ni ohun gbogbo.

116.11: El 33.22; Isa 60.5.Ẹ̀yin ará Kọrinti, a ti bá yín sọ òtítọ́ ọ̀rọ̀, a ṣí ọkàn wa páyà sí yín. 12Àwa kò fa ìfẹ́ wa sẹ́hìn fún yín, ṣùgbọ́n ẹ̀yin fa ìfẹ́ yín sẹ́hìn kúrò lọ́dọ̀ wa. 13Ní sísán padà, ní ọ̀nà tí ó dára, èmi ń sọ bí ẹni pé fún àwọn ọmọdé, ẹ̀yin náà ẹ ṣí ọkàn yín páyà pẹ̀lú.

Má ṣe dàpọ̀ pẹ̀lú àwọn aláìgbàgbọ́

14Ẹ má ṣe fi àìdọ́gba dàpọ̀ pẹ̀lú àwọn aláìgbàgbọ́: nítorí ìdàpọ̀ kín ni òdodo ní pẹ̀lú àìṣòdodo? Ìdàpọ̀ kín ni ìmọ́lẹ̀ sì ní pẹ̀lú òkùnkùn? 15Ìrẹ́pọ̀ kín ni Kristi ní pẹ̀lú Beliali? Tàbí ìpín wó ni ẹni tí ó gbàgbọ́ ní pẹ̀lú aláìgbàgbọ́? 166.16: 1Kọ 10.21; 3.16; Ek 25.8; 29.45; Le 26.12; El 37.27; Jr 31.1.Ìrẹ́pọ̀ kín ni tẹmpili Ọlọ́run ní pẹ̀lú òrìṣà? Nítorí ẹ̀yin ní tẹmpili Ọlọ́run alààyè; gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti wí pé:

“Èmi á gbé inú wọn,

èmi o sì máa rìn láàrín wọn,

èmi ó sì jẹ́ Ọlọ́run wọn,

wọn yóò sì jẹ́ ènìyàn mi.”

176.17: Isa 52.11.Nítorí náà,

“Ẹ jáde kúrò láàrín wọn,

kí ẹ sì yá ara yín si ọ̀tọ̀,

ni Olúwa wí.

Ki ẹ má ṣe fi ọwọ́ kan ohun àìmọ́;

Èmi ó sì gbà yín.”

18Àti,

6.18: Ho 1.10; Isa 43.6.“Èmi o sì jẹ́ Baba fún yín,

Ẹ̀yin ó sì jẹ́ ọmọkùnrin mi àti ọmọbìnrin mi!

ní Olúwa Olódùmarè wí.”