2พงศาวดาร 35 – TNCV & YCB

Thai New Contemporary Bible

2พงศาวดาร 35:1-27

โยสิยาห์ทรงฉลองปัสกา

(2พกษ.23:21-23)

1โยสิยาห์ทรงฉลองปัสกาถวายแด่องค์พระผู้เป็นเจ้าในกรุงเยรูซาเล็ม มีการฆ่าแกะปัสกา ในวันที่สิบสี่เดือนที่หนึ่ง 2พระองค์ทรงแต่งตั้งปุโรหิตให้เข้าประจำหน้าที่ และสนับสนุนให้รับใช้ในงานพระวิหารขององค์พระผู้เป็นเจ้า 3พระองค์ตรัสกับคนเลวีผู้สั่งสอนชนอิสราเอลทั้งปวงและผู้ชำระตนถวายแก่ องค์พระผู้เป็นเจ้าแล้วนั้นว่า “จงเก็บหีบพันธสัญญาอันบริสุทธิ์ศักดิ์สิทธิ์ไว้ในพระวิหารซึ่งโซโลมอนโอรสของกษัตริย์ดาวิดแห่งอิสราเอลสร้างขึ้น ไม่ต้องหามขึ้นบ่า บัดนี้จงปรนนิบัติพระยาห์เวห์พระเจ้าของท่านและปรนนิบัติอิสราเอลประชากรของพระองค์ 4จงเตรียมตัวทำหน้าที่ตามครอบครัวเป็นหมู่เหล่า ตามที่กษัตริย์ดาวิดแห่งอิสราเอลและโซโลมอนราชโอรสกำหนดไว้เถิด

5“ให้คนเลวีแต่ละกลุ่มประจำหน้าที่ในวิสุทธิสถานเพื่อปรนนิบัติพี่น้องร่วมชาติตามกลุ่มครอบครัวแต่ละกลุ่มที่ได้แบ่งไว้ 6จงฆ่าแกะปัสกา ชำระตน และเตรียมลูกแกะเพื่อพี่น้องร่วมชาติของท่าน ซึ่งเป็นการปฏิบัติตามที่องค์พระผู้เป็นเจ้าทรงบัญชาไว้ผ่านทางโมเสส”

7โยสิยาห์ทรงเตรียมลูกแกะลูกแพะเพื่อเป็นเครื่องบูชาปัสกาสามหมื่นตัว และวัวผู้สามพันตัว จากทรัพย์สินส่วนพระองค์สำหรับประชาชนทุกคนที่นั่น

8ข้าราชบริพารของกษัตริย์ก็มอบของด้วยความสมัครใจแก่ประชาชน ปุโรหิต และคนเลวี ส่วนฮิลคียาห์ เศคาริยาห์ และเยฮีเอล เจ้าหน้าที่พระวิหารของพระเจ้ามอบลูกแกะลูกแพะ 2,600 ตัว และวัวผู้ 300 ตัวแก่ปุโรหิตเป็นเครื่องบูชาปัสกา 9บรรดาผู้นำของคนเลวีได้แก่ โคนานิยาห์ กับเชไมอาห์และเนธันเอลน้องชายของเขา และฮาชาบิยาห์ เยอีเอล และโยซาบาดมอบลูกแกะลูกแพะปัสกาห้าพันตัวกับวัวผู้ห้าร้อยตัวแก่คนเลวี

10เมื่อเตรียมทุกอย่างเรียบร้อย และปุโรหิตทั้งหลายเข้าประจำที่ของตน พร้อมทั้งคนเลวีได้เข้ากลุ่มปฏิบัติงานตามหมู่เหล่าดังที่กษัตริย์ตรัสบัญชาไว้แล้ว 11ก็ฆ่าลูกแกะปัสกา ส่งเลือดให้ปุโรหิตประพรม ขณะที่คนเลวีถลกหนังสัตว์ 12พวกเขาแยกเครื่องเผาบูชาเพื่อมอบให้ตระกูลต่างๆ เพื่อให้ประชาชนถวายแด่องค์พระผู้เป็นเจ้าตามที่บันทึกไว้ในบทบัญญัติของโมเสส พวกเขาก็ทำอย่างเดียวกันกับวัวผู้ 13พวกเขาย่างสัตว์ปัสกาตามที่ระบุไว้ และต้มของถวายอันบริสุทธิ์ในหม้อ กระทะ ภาชนะต่างๆ แล้วรีบนำออกไปให้ประชากรทั้งปวงรับประทาน 14หลังจากนั้นคนเลวีก็จัดเตรียมสำหรับตนเองกับปุโรหิต เพราะปุโรหิตวงศ์วานอาโรนง่วนอยู่กับการถวายเครื่องเผาบูชาและไขมันเครื่องบูชาจนค่ำ ดังนั้นคนเลวีจึงจัดเตรียมอาหารสำหรับตนเองและปุโรหิตวงศ์วานของอาโรน

15เหล่านักดนตรีวงศ์วานของอาสาฟเข้าประจำที่ตามที่ดาวิด อาสาฟ เฮมาน และเยดูธูนผู้ทำนาย ส่วนพระองค์ของดาวิดกำหนดไว้ ยามเฝ้าประตูแต่ละประตูไม่จำเป็นต้องละจากจุดปฏิบัติงาน เพราะพี่น้องเลวีของเขาเตรียมอาหารไว้ให้

16ครั้งนั้นงานรับใช้องค์พระผู้เป็นเจ้าทั้งสิ้นในการฉลองปัสกาและถวายเครื่องเผาบูชาบนแท่นบูชาแด่องค์พระผู้เป็นเจ้าได้สำเร็จลุล่วงตามที่กษัตริย์โยสิยาห์ทรงบัญชา 17ชนอิสราเอลซึ่งอยู่ที่นั่นร่วมฉลองปัสกา และต่อด้วยเทศกาลขนมปังไม่ใส่เชื้ออีกเจ็ดวัน 18นับตั้งแต่ครั้งผู้เผยพระวจนะซามูเอล ไม่เคยมีการฉลองปัสกาในอิสราเอลเหมือนครั้งนั้นเลย ไม่มีกษัตริย์องค์ใดของอิสราเอลฉลองปัสกาเหมือนโยสิยาห์ร่วมกับปุโรหิต คนเลวี ชนยูดาห์และอิสราเอลทั้งปวงที่อาศัยอยู่กับประชาชนในกรุงเยรูซาเล็ม 19การฉลองนี้มีขึ้นในปีที่สิบแปดแห่งรัชกาลโยสิยาห์

การสิ้นพระชนม์ของโยสิยาห์

(2พกษ.23:28-30)

20หลังจากที่โยสิยาห์ทรงจัดระเบียบพระวิหารเรียบร้อยแล้ว กษัตริย์เนโคแห่งอียิปต์ยกทัพมาที่คารเคมิชริมแม่น้ำยูเฟรติส และโยสิยาห์กรีธาทัพออกไปรบกับพระองค์ 21แต่เนโคส่งผู้นำสาส์นมายังโยสิยาห์ความว่า “กษัตริย์ยูดาห์ ท่านและข้าพเจ้ามีเรื่องราวบาดหมางอะไรกันหรือ? ข้าพเจ้าไม่ได้ยกทัพมาโจมตีท่านในครั้งนี้ แต่ข้าพเจ้ามารบกับศัตรูที่ขับเคี่ยวกันอยู่ พระเจ้าได้ตรัสสั่งให้ข้าพเจ้ารีบเร่ง ดังนั้นจงอย่าขัดขวางพระเจ้าผู้สถิตกับข้าพเจ้า มิฉะนั้นพระองค์จะทรงทำลายท่าน”

22แต่โยสิยาห์ไม่ยอมถอยทัพ กลับปลอมตัวเข้าสู่สงครามในที่ราบเมกิดโด โยสิยาห์ไม่ยอมฟังพระบัญชาของพระเจ้าที่ตรัสผ่านเนโค

23พลธนูยิงถูกกษัตริย์โยสิยาห์ พระองค์ทรงร้องบอกทหารว่า “พาเราออกไปที เราบาดเจ็บมาก” 24พวกเขาจึงประคองพระองค์ลงจากรถม้าศึกของพระองค์ แล้วขึ้นรถม้าศึกอีกคันกลับสู่เยรูซาเล็ม โยสิยาห์ก็สิ้นพระชนม์ พระศพถูกฝังไว้ในสุสานบรรพบุรุษของพระองค์ ทั่วทั้งยูดาห์และกรุงเยรูซาเล็มพากันไว้อาลัย

25เยเรมีย์แต่งบทเพลงคร่ำครวญไว้อาลัยแด่โยสิยาห์ และคณะนักร้องชายหญิงทุกคนยังคงขับร้องเพลงไว้อาลัยโยสิยาห์ตราบจนทุกวันนี้ซึ่งกลายเป็นประเพณีในอิสราเอล และมีบันทึกไว้ในประมวลบทเพลงคร่ำครวญ

26เหตุการณ์อื่นๆ ในรัชกาลโยสิยาห์และพระราชกิจที่ทรงทุ่มเทตามบทบัญญัติขององค์พระผู้เป็นเจ้า 27เหตุการณ์ทั้งสิ้นตั้งแต่ต้นจนจบบันทึกอยู่ในจดหมายเหตุกษัตริย์แห่งอิสราเอลและยูดาห์

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

2 Kronika 35:1-27

Josiah ṣe ìrántí àjọ ìrékọjá

135.1-19: 2Ọb 23.21-23.Síwájú sí i, Josiah ṣe ìrántí àjọ ìrékọjá sí Olúwa ní Jerusalẹmu, Ọ̀dọ́-àgùntàn àjọ ìrékọjá náà ni wọ́n sì pa ní ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kìn-ín-ní. 2Ó sì yàn àwọn àlùfáà sí iṣẹ́ wọn, ó sì gbà wọ́n ní ìyànjú ní ìsìn ilé Olúwa. 3Ó sì wí fún àwọn ọmọ Lefi, ẹni tí ń kọ́ gbogbo àwọn Israẹli ẹni tí a ti yà sí mímọ́ fún Olúwa pé ẹ gbé àpótí ẹ̀rí ìyàsọ́tọ̀ sí ilé Olúwa tí Solomoni ọmọ Dafidi ọba Israẹli ti kọ́. Kò gbọdọ̀ jẹ́ ẹrù àgbéká ní èjìká rẹ̀. Nísinsin yìí ẹ sin Olúwa Ọlọ́run yín àti àwọn ènìyàn rẹ̀ Israẹli. 4Ẹ múra sílẹ̀ nípa ìdílé ní ẹsẹẹsẹ yín gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ tí a kọ́ láti ọwọ́ Dafidi ọba Israẹli àti gẹ́gẹ́ bí ọmọ rẹ̀ Solomoni.

5“Dúró ní ibi mímọ́ pẹ̀lú àkójọpọ̀ àwọn ọmọ Lefi fún ọ̀kọ̀ọ̀kan ìpín àwọn ìdílé àwọn ẹgbẹ́ ará ìlú, àwọn ènìyàn tí ó dùbúlẹ̀. 6Ẹ pa ẹran àjọ ìrékọjá náà, ẹ ya ara yín sọ́tọ̀ kí ẹ sì pèsè ẹran fún àwọn ẹgbẹ́ arákùnrin yín, kí ẹ sì ṣe ohun tí Olúwa paláṣẹ láti ọwọ́ Mose.”

7Josiah sì pàṣẹ fún gbogbo àwọn ènìyàn tí ó dùbúlẹ̀ tí ó wà níbẹ̀ iye rẹ̀ jẹ ẹgbàá-mẹ́dógún ọ̀dọ́-àgùntàn àti ọmọ ewúrẹ́ fún ẹbọ ìrékọjá, àti pẹ̀lú ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n akọ màlúù (3,000) gbogbo wọ̀nyí jẹ́ ohun ìní láti ọ̀dọ̀ ọba.

8Àwọn ìjòyè rẹ̀ fi tinútinú ta àwọn ènìyàn náà ní ọrẹ àti àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Lefi. Hilkiah, Sekariah àti Jehieli, àti àwọn olórí ilé Ọlọ́run, fún àwọn àlùfáà ní ẹgbẹ̀tàlá (2,600) ẹbọ àjọ ìrékọjá àti ọ̀ọ́dúnrún ẹran ọ̀sìn (300). 9Àti pẹ̀lú Konaniah àti pẹ̀lú Ṣemaiah àti Netaneli, àti àwọn arákùnrin rẹ̀, àti Haṣabiah, Jeieli àti Josabadi olórí àwọn ọmọ Lefi, ó sì pèsè ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ẹbọ ìrékọjá (500) àti ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n orí ẹran ọ̀sìn fún àwọn ọmọ Lefi.

10Nítorí náà, a múra ìsìn náà sílẹ̀, àwọn àlùfáà sì dúró ní ipò wọn pẹ̀lú àwọn ọmọ Lefi nípa iṣẹ́ wọn gẹ́gẹ́ bí ọba ti pa á láṣẹ. 11Ní ti àjọ ìrékọjá a sì pa ẹran, àwọn àlùfáà sì wọ́n ẹ̀jẹ̀ náà tí wọ́n gbé sí ọwọ́ wọn, nígbà tí àwọn ọmọ Lefi sì bọ ẹranko. 12Wọ́n sì ya àwọn ẹbọ sísun sí apá kan láti fi wọ́n fún gẹ́gẹ́ bí ìpín àwọn ìdílé àwọn ènìyàn láti rú ẹbọ sí Olúwa. Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ sínú ìwé Mose. Wọ́n sì ṣe bákan náà pẹ̀lú àwọn ẹran ọ̀sìn. 13Wọ́n sì fi sun àjọ ìrékọjá lórí iná gẹ́gẹ́ bí ìlànà, wọ́n sì bọ ẹbọ mímọ́ nínú ìkòkò, nínú ọpọ́n àti nínú agbada, wọ́n sì pín wọn kíákíá fún gbogbo àwọn ènìyàn. 14Lẹ́yìn èyí, wọ́n sì múra sílẹ̀ fún ara wọn àti fún àwọn àlùfáà nítorí àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Aaroni, ni wọ́n rú ẹbọ sísun àti ọ̀rá títí di àṣálẹ́. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ Lefi sì múra sílẹ̀ fún ara wọn àti fún àwọn ọmọ Aaroni àlùfáà.

15Àwọn akọrin, àwọn ọmọ Asafu, ni wọ́n wà ní ipò wọn tí a sì paláṣẹ fún wọn láti ọwọ́ Dafidi, Asafu, Hemani àti Jedutuni àwọn aríran ọba àti àwọn olùṣọ́nà ní olúkúlùkù ẹnu-ọ̀nà kò gbọdọ̀ fi ojú ọ̀nà wọn sílẹ̀, nítorí àwọn ẹgbẹ́ ọmọ lefi ti múra sílẹ̀ fún wọn.

16Bẹ́ẹ̀ ni àsìkò náà gbogbo àwọn ìsìn Olúwa ni wọ́n gbé jáde fún iṣẹ́ ìrántí àjọ ìrékọjá àti láti rú ẹbọ sísun lórí pẹpẹ Olúwa, gẹ́gẹ́ bí ọba Josiah ti pa á láṣẹ. 17Àwọn ọmọ Israẹli tí ó gbé kalẹ̀ ṣe ìrántí àjọ ìrékọjá ní àkókò náà àti àjọ àkàrà àìwú fún ọjọ́ méje. 18Àjọ ìrékọjá náà kò sì tí ì sí èyí tí ó dàbí i rẹ̀ ní Israẹli títí dé ọjọ́ wòlíì Samuẹli, kò sì sí ọ̀kan lára àwọn ọba Israẹli tí ó pa irú àjọ ìrékọjá bẹ́ẹ̀ mọ́ gẹ́gẹ́ bí Josiah ti ṣe, pẹ̀lú àwọn àlùfáà àwọn ọmọ Lefi àti gbogbo àwọn Juda àti Israẹli tí ó wà níbẹ̀ pẹ̀lú gbogbo ènìyàn Jerusalẹmu. 19Àjọ ìrékọjá yìí ni a ṣe ìrántí ní ọdún kejì-dínlógún ìjọba Josiah.

Ikú Josiah

20Lẹ́yìn gbogbo èyí nígbà tí Josiah ti tún ilẹ̀ náà ṣetán, Neko ọba Ejibiti gòkè lọ láti bá Karkemiṣi jà lórí odo Eufurate, Josiah sì jáde lọ láti pàdé rẹ̀ ní ibi ìjà. 21Ṣùgbọ́n Neko rán ìránṣẹ́ sí i wí pé, “Ìjà wo ni ó ń bẹ láàrín èmi àti ìwọ, ọba Juda? Kì í ṣe ìwọ ni èmi tọ̀ wá ní àkókò yìí, ṣùgbọ́n, ilé pẹ̀lú èyí ti mo bá níjà. Ọlọ́run ti sọ fún mi láti yára àti láti dúró nípa ṣíṣe ìdènà Ọlọ́run, ẹni tí ó wà pẹ̀lú mi, kí òun má bá a pa ọ́ run.”

22Josiah, kò yípadà kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, ṣùgbọ́n ó pa ara rẹ̀ dà kí ó le bá a jà, kó sì fi etí sí ọ̀rọ̀ Neko láti ẹnu Ọlọ́run wá, ó sì wá jagun ní Àfonífojì Megido.

23Tafàtafà sì ta ọfà sí ọba Josiah, ó sì sọ fún àwọn ìjòyè pé, “Ẹ gbé mi kúrò, èmi ti gba ọgbẹ́ gidigidi.” 24Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì gbé e jáde kúrò nínú kẹ̀kẹ́ náà, wọ́n sì gbé e sínú kẹ̀kẹ́ mìíràn, wọ́n sì gbé e wá sí Jerusalẹmu, níbi tí ó ti kú, wọ́n sì sin ín sínú ọ̀kan nínú àwọn ibojì àwọn baba rẹ̀, gbogbo Juda àti gbogbo Jerusalẹmu sì ṣọ̀fọ̀ Josiah.

25Jeremiah sì pohùnréré ẹkún fún Josiah, gbogbo àwọn akọrin ọkùnrin àti gbogbo àwọn akọrin obìnrin sì ń sọ ti Josiah nínú orin ẹkún wọn ní Israẹli títí di òní. Èyí sì di àṣà ní Jerusalẹmu, a sì kọ ọ́ sínú àwọn orin ẹkún.

26Ìyókù iṣẹ́ ìjọba Josiah àti ìwà rere rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí èyí tí a ti kọ sínú ìwé òfin Olúwa. 27Gbogbo iṣẹ́ náà, láti ìbẹ̀rẹ̀ títí dé òpin ni a kọ sínú ìwé àwọn ọba Israẹli àti Juda.