2พงศาวดาร 21 – TNCV & YCB

Thai New Contemporary Bible

2พงศาวดาร 21:1-20

1เยโฮชาฟัททรงล่วงลับไปอยู่กับบรรพบุรุษและถูกฝังไว้ด้วยกันในเมืองดาวิด แล้วเยโฮรัมโอรสของพระองค์ขึ้นครองราชย์แทน 2โอรสองค์อื่นๆ ของเยโฮชาฟัทกษัตริย์แห่งอิสราเอล21:2 คือ ยูดาห์ พบบ่อยๆ ใน 2พงศาวดารที่เป็นอนุชาของเยโฮรัมได้แก่ อาซาริยาห์ เยฮีเอล เศคาริยาห์ อาซาริยาฮู มีคาเอล และเชฟาทิยาห์ 3เยโฮชาฟัทราชบิดาได้ประทานเงิน ทองคำ และของมีค่าให้โอรสแต่ละองค์ และให้ครองเมืองป้อมปราการต่างๆ ในยูดาห์ แต่ทรงยกอาณาจักรให้แก่เยโฮรัมเพราะเป็นโอรสหัวปี

กษัตริย์เยโฮรัมแห่งยูดาห์

(2พกษ.8:16-24)

4เมื่อเยโฮรัมสถาปนาอาณาจักรของราชบิดาให้มั่นคงเป็นปึกแผ่นแล้ว ก็ประหารอนุชาทั้งปวงและเจ้านายบางองค์ของอิสราเอล 5ขณะขึ้นเป็นกษัตริย์เยโฮรัมทรงมีพระชนมายุ 32 พรรษา และทรงครองราชย์อยู่ในกรุงเยรูซาเล็มแปดปี 6เยโฮรัมทรงดำเนินตามอย่างบรรดากษัตริย์อิสราเอล ตามอย่างราชวงศ์อาหับเพราะทรงอภิเษกกับพระธิดาองค์หนึ่งของอาหับ พระองค์ทรงทำสิ่งที่ชั่วในสายพระเนตรขององค์พระผู้เป็นเจ้า 7แต่เนื่องจากพันธสัญญาที่ องค์พระผู้เป็นเจ้าทรงกระทำกับดาวิด องค์พระผู้เป็นเจ้าจึงไม่ทรงประสงค์จะทำลายล้างราชวงศ์ของดาวิด พระองค์ทรงสัญญาไว้ว่าจะรักษาดวงประทีปดวงหนึ่งไว้สำหรับดาวิดและวงศ์วานตลอดไป

8ในรัชกาลของเยโฮรัม เอโดมกบฏต่อยูดาห์และตั้งกษัตริย์ปกครองตนเอง 9เยโฮรัมจึงกรีธาทัพไปพร้อมด้วยทหารและรถม้าศึกทั้งหมด ชาวเอโดมโอบล้อมพระองค์กับผู้บัญชาการรถรบ แต่เยโฮรัมทรงตีฝ่าวงล้อมออกไปได้ในเวลากลางคืน 10เอโดมจึงกบฏต่อยูดาห์จนถึงทุกวันนี้

ครั้งนั้นลิบนาห์ก็กบฏด้วย เพราะเยโฮรัมได้ละทิ้งพระยาห์เวห์พระเจ้าของบรรพบุรุษของพระองค์ 11ทั้งยังทรงสร้างสถานบูชาบนที่สูงบนเนินเขาทั้งหลายของยูดาห์ และทรงชักนำชาวเยรูซาเล็มให้เอาใจออกห่างจากพระเจ้า และทำให้ยูดาห์หลงเจิ่นไป

12มีจดหมายจากผู้เผยพระวจนะเอลียาห์มาถึงเยโฮรัมความว่า

“พระยาห์เวห์พระเจ้าของดาวิดบรรพบุรุษของท่านตรัสดังนี้ว่า ‘เจ้าไม่ได้เจริญรอยตามเยโฮชาฟัทบิดาของเจ้าหรือกษัตริย์อาสาแห่งยูดาห์ 13แต่เดินตามรอยกษัตริย์อิสราเอล และเจ้าได้ชักนำชาวยูดาห์กับชาวเยรูซาเล็มให้นอกใจเราเช่นเดียวกับราชวงศ์อาหับ มิหนำซ้ำยังสังหารพี่น้องของเจ้าซึ่งเป็นคนในครัวเรือนบิดาของเจ้าและดีกว่าเจ้า 14ฉะนั้นองค์พระผู้เป็นเจ้าจะลงโทษคนของเจ้า บุตรกับภรรยาของเจ้าและทุกสิ่งที่เจ้ามีอย่างหนัก 15เจ้าเองจะป่วยหนักด้วยโรคลำไส้เรื้อรังจนกระทั่งลำไส้ของเจ้าทะลักออกมา’ ”

16องค์พระผู้เป็นเจ้าทรงดลใจชาวฟีลิสเตียและชาวอาหรับซึ่งอยู่ถัดจากชาวคูชให้เป็นศัตรูกับเยโฮรัม 17พวกเขาเข้ามาโจมตีและรุกรานยูดาห์ ริบเอาข้าวของมีค่าทั้งหมดในพระราชวังไป รวมทั้งบรรดาโอรสและมเหสีของเยโฮรัมด้วย ไม่มีโอรสองค์ใดเหลืออยู่เว้นแต่อาหัสยาห์21:17 ภาษาฮีบรูว่าเยโฮอาหาสเป็นอีกรูปหนึ่งของอาหัสยาห์โอรสองค์สุดท้อง

18หลังจากเหตุการณ์ทั้งหมดนี้ องค์พระผู้เป็นเจ้าทรงทรมานเยโฮรัมด้วยโรคลำไส้ซึ่งรักษาไม่ได้ 19เมื่อปลายปีที่สอง ลำไส้ของเยโฮรัมทะลักออกมาและพระองค์ก็สิ้นพระชนม์ด้วยความเจ็บปวดแสนสาหัส ประชาชนไม่ได้ก่อไฟถวายให้สมพระเกียรติเหมือนรัชกาลก่อนๆ

20เยโฮรัมมีพระชนมายุ 32 พรรษาเมื่อขึ้นเป็นกษัตริย์ และทรงครองราชย์อยู่ในกรุงเยรูซาเล็ม 8 ปี และสิ้นพระชนม์ไปโดยไม่มีใครโศกเศร้าเสียใจ พระศพถูกฝังไว้ในเมืองดาวิดแต่ไม่ใช่ในสุสานหลวง

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

2 Kronika 21:1-20

Jehoramu ọba Juda

121.1: 1Ọb 22.50.Nígbà náà Jehoṣafati sùn pẹ̀lú àwọn baba a rẹ̀, a sì sin ín pẹ̀lú wọn ní ìlú ńlá Dafidi. Jehoramu ọmọ rẹ̀ sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba. 2Àwọn arákùnrin Jehoramu ọmọ Jehoṣafati jẹ́ Asariah, Jehieli, Sekariah. Asariahu, Mikaeli àti Ṣefatia. Gbogbo àwọn wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Jehoṣafati ọba Israẹli. 3Baba wọn ti fún wọn ní ẹ̀bùn púpọ̀ ti fàdákà àti wúrà àti àwọn ohun èlò iyebíye pẹ̀lú àwọn ìlú ààbò ní Juda, Ṣùgbọ́n, ó ti gbé ìjọba fún Jehoramu nítorí òun ni àkọ́bí ọmọkùnrin.

Jehoramu Ọba Juda

4Nígbà tí Jehoramu fi ẹsẹ̀ rẹ̀ múlẹ̀ gidigidi lórí ìjọba baba a rẹ̀, ó sì fi idà pa gbogbo àwọn arákùnrin rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọbìnrin ọba Israẹli. 521.5-10: 2Ọb 8.17-22.Jehoramu jẹ́ ẹni ọdún méjìlélọ́gbọ̀n nígbà tí ó di ọba, ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún mẹ́jọ. 6Ó rìn ní ọ̀nà àwọn ọba Israẹli gẹ́gẹ́ bí ìdílé Ahabu ti ṣe, nítorí ó fẹ́ ọmọbìnrin Ahabu. Ó ṣe búburú lójú Olúwa. 7Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, nítorí tí májẹ̀mú tí Olúwa ti dá fún Dafidi kì í ṣe ìfẹ́ Olúwa láti pa ìdílé Dafidi run ó ti ṣe ìlérí láti tọ́jú fìtílà kan fún un àti àwọn àtẹ̀lé rẹ̀ títí láé.

8Ní àkókò Jehoramu, Edomu ṣọ̀tẹ̀ sí Juda, wọ́n sì gbé ọba tiwọn kalẹ̀. 9Bẹ́ẹ̀ ni, Jehoramu lọ síbẹ̀ pẹ̀lú àwọn ìjòyè rẹ̀ àti gbogbo àwọn kẹ̀kẹ́. Àwọn ará Edomu yí i ká àti àwọn alákòóso àwọn kẹ̀kẹ́ rẹ̀. Ṣùgbọ́n ó dìde ní òru ó sì ṣẹ́gun wọn ní òru. 10Títí di ọjọ́ òní ni Edomu ti wà ní ìṣọ̀tẹ̀ sí Juda.

Libina ṣọ̀tẹ̀ ní àkọ́kọ́ náà, nítorí tí Jehoramu ti kọ Olúwa sílẹ̀, Ọlọ́run àwọn baba a rẹ̀. 11Òun pẹ̀lú ti kọ́ àwọn ibi gíga lórí àwọn òkè Juda. Ó sì ti fà á kí àwọn ènìyàn Jerusalẹmu ó ṣe àgbèrè pẹ̀lú ara wọn. Ó sì ti jẹ́ kí wọn ó ṣáko lọ.

12Jehoramu gba ìwé láti ọwọ́ Elijah wòlíì, tí ó wí pé:

“Èyí ní ohun tí Olúwa, Ọlọ́run baba à rẹ Dafidi wí: ‘Ìwọ kò tí ì rìn ní ọ̀nà àwọn baba à rẹ Jehoṣafati tàbí Asa ọba Juda. 13Ṣùgbọ́n ìwọ ti rìn ní ọ̀nà àwọn ọba Israẹli, ìwọ sì ti tọ́ Juda àti àwọn ènìyàn Jerusalẹmu láti ṣe àgbèrè sí ara wọn, gẹ́gẹ́ bí ilé Ahabu ti ṣe. Ìwọ sì ti pa àwọn arákùnrin rẹ, ẹ̀yà ara ilé baba à rẹ, àwọn ọkùnrin tí ó dára jù ọ́ lọ. 14Bẹ́ẹ̀ ni nísinsin yìí, Ọlọ́run ti fẹ́rẹ lu àwọn ènìyàn rẹ, àwọn ọmọ rẹ, àwọn ìyàwó rẹ àti gbogbo ohun tí ó jẹ́ tìrẹ, pẹ̀lú àjàkálẹ̀-ààrùn ńlá. 15Ìwọ tìkára yóò ṣe àárẹ̀ pẹ̀lú àìsàn lílọ́ra ti ìfun, títí tí àìsàn náà yóò fi jẹ́ kí àwọn ìfun rẹ jáde sí ìta.’ ”

16Olúwa ru ìbínú àwọn ará Filistini àti àwọn Arabia tí wọ́n ń gbé ní ẹ̀bá àwọn ará Kuṣi sí Jehoramu. 17Wọ́n dojú ìjà kọ Juda, wọ́n gbà á, wọ́n sì kó gbogbo ọrọ̀ tí a rí ní ilé ọba pẹ̀lú, àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ àti àwọn ọmọkùnrin kankan kò kù sílẹ̀ fún un bí kò ṣe Ahasiah, àbíkẹ́yìn nínú àwọn ọmọ rẹ̀.

18Lẹ́yìn gbogbo èyí, Olúwa jẹ Jehoramu ní yà pẹ̀lú ààrùn tí kò ṣe é wòsàn nínú ìfun. 19Ní àkókò kan ní ìparí ọdún kejì, àwọn ìfun rẹ̀ jáde nítorí ààrùn náà ó sì kú nínú ìrora ńlá. Àwọn ènìyàn rẹ̀ kò dá iná láti fi bu ọlá fún un, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ṣe fún àwọn baba a rẹ̀.

2021.20: 2Ọb 8.17,24.Jehoramu jẹ́ ẹni ọdún méjìlélọ́gbọ̀n ní ìgbà tí ó di ọba, Ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún mẹ́jọ. Ó kọjá lọ, kò sí ẹni tí ó kábámọ̀. A sì sin ín si ìlú ńlá ti Dafidi. Ṣùgbọ́n kì í ṣe nínú ibojì àwọn ọba.