1พงศ์กษัตริย์ 9 – TNCV & YCB

Thai New Contemporary Bible

1พงศ์กษัตริย์ 9:1-28

องค์พระผู้เป็นเจ้า

(2พศด.7:11-22)

1เมื่อโซโลมอนทรงสร้างพระวิหารขององค์พระผู้เป็นเจ้า พระราชวัง และสิ่งอื่นๆ ทั้งหมดเสร็จสิ้นตามที่ประสงค์แล้ว 2องค์พระผู้เป็นเจ้าทรงปรากฏแก่โซโลมอนเป็นครั้งที่สอง เหมือนที่ได้ปรากฏมาแล้วที่กิเบโอน 3องค์พระผู้เป็นเจ้าตรัสกับโซโลมอนว่า

“เราได้ยินคำอธิษฐานและคำวิงวอนของเจ้าต่อเราแล้ว เราได้ชำระวิหารที่เจ้าสร้างขึ้นนี้ให้บริสุทธิ์ โดยสถาปนานามของเราไว้ที่นั่นชั่วนิรันดร์ ตาและใจของเราจะอยู่ที่นั่นเสมอไป

4“ส่วนเจ้า หากเจ้าดำเนินอยู่ต่อหน้าเราด้วยใจซื่อสัตย์สุจริตและชอบธรรมเหมือนอย่างดาวิดราชบิดาของเจ้า ทำตามคำบัญชาทั้งสิ้นของเรา และรักษากฎหมายกับบทบัญญัติของเรา 5เราก็จะสถาปนาราชบัลลังก์ของเจ้าเหนืออิสราเอลตลอดไปตามที่เราได้สัญญาไว้กับดาวิดราชบิดาของเจ้าว่า ‘เจ้าจะไม่ขาดคนครองบัลลังก์อิสราเอลเลย’

6“แต่หากเจ้าหรือลูกหลานของเจ้าละทิ้งเรา ไม่ได้ปฏิบัติตามคำบัญชาและกฎหมายที่เราได้ให้แก่เจ้า9:6 ภาษาฮีบรูเป็นพหูพจน์ทั้งสามครั้งในข้อนี้ หันไปปรนนิบัตินมัสการพระอื่นๆ 7เราก็จะตัดอิสราเอลออกจากดินแดนซึ่งเราได้ยกให้เขา เราจะทิ้งวิหารแห่งนี้ซึ่งเราได้ชำระให้บริสุทธิ์เพื่อนามของเรา อิสราเอลจะกลายเป็นที่เย้ยหยันและคำเปรียบเปรยในหมู่ประชาชาติ 8ถึงแม้ว่าบัดนี้วิหารจะตั้งเด่นตระหง่าน คนทั้งปวงที่ผ่านไปมาก็จะตกตะลึงและจะเยาะเย้ยว่า ‘ทำไมหนอองค์พระผู้เป็นเจ้าจึงทรงกระทำต่อวิหารและดินแดนนี้ถึงเพียงนี้?’ 9ผู้คนจะตอบว่า ‘เพราะพวกเขาได้ละทิ้งพระยาห์เวห์พระเจ้าของพวกเขา ผู้ทรงนำบรรพบุรุษของพวกเขาออกจากอียิปต์ หันไปฝักใฝ่ปรนนิบัตินมัสการพระอื่นๆ แทน ดังนั้นองค์พระผู้เป็นเจ้าจึงทรงนำเหตุร้ายทั้งหมดนี้มาสู่พวกเขา’ ”

พระราชกิจอื่นๆ ของโซโลมอน

(2พศด.8:1-18)

10ในตอนปลายของช่วงยี่สิบปีที่โซโลมอนทรงก่อสร้างพระวิหารขององค์พระผู้เป็นเจ้าและพระราชวังของพระองค์เอง 11กษัตริย์โซโลมอนทรงมอบเมืองยี่สิบแห่งในกาลิลีให้กษัตริย์ฮีรามแห่งไทระเป็นค่าตอบแทนสำหรับไม้สนซีดาร์ ไม้สนอื่นๆ และทองคำซึ่งกษัตริย์โซโลมอนทรงประสงค์ 12แต่เมื่อฮีรามเสด็จจากไทระมาทอดพระเนตรเมืองเหล่านี้ที่โซโลมอนมอบให้ก็ไม่พอพระทัยเลย 13ฮีรามตรัสว่า “น้องเอ๋ย เอาเมืองอะไรมายกให้พี่กันนี่” เมืองเหล่านั้นจึงได้ชื่อว่าดินแดนคาบูล9:13 คำว่าคาบูลมีเสียงคล้ายคำภาษาฮีบรูที่มีความหมายว่าไร้ค่า มาจนทุกวันนี้ 14ฮีรามได้ส่งทองคำมาให้โซโลมอนถึงประมาณ 4 ตัน9:14 ภาษาฮีบรูว่า120 ตะลันต์

15โซโลมอนทรงเกณฑ์แรงงานโยธามาก่อสร้างพระวิหารขององค์พระผู้เป็นเจ้า พระราชวัง ป้อมมิลโล9:15 หรือแนวเนินดินด้านตะวันออกเช่นเดียวกับข้อ 24 กำแพงกรุงเยรูซาเล็ม เมืองฮาโซร์ เมกิดโด และเกเซอร์ 16(ฟาโรห์กษัตริย์แห่งอียิปต์ทรงโจมตีและเข้ายึดเกเซอร์แล้วเผาทิ้ง ประหารชาวคานาอันผู้อาศัยอยู่ในเมือง ต่อมาได้ประทานเมืองนี้เป็นสินสมรสแก่ราชธิดาซึ่งเป็นมเหสีของโซโลมอน 17และโซโลมอนทรงซ่อมแซมเมืองเกเซอร์) ทรงสร้างเบธโฮโรนล่าง 18บาอาลัทและทัดโมร์9:18 คำภาษาฮีบรูอาจอ่านว่าทามาร์ก็ได้ในถิ่นกันดารในดินแดนยูดาห์ 19ทั้งยังทรงสร้างเมืองต่างๆ เพื่อเป็นคลังเสบียงของพระองค์ และสร้างเมืองสำหรับรถม้าศึกและม้า9:19 หรือพลรบ พระองค์ทรงสร้างทุกๆ สิ่งที่ทรงประสงค์ในเยรูซาเล็ม เลบานอน และที่ต่างๆทั่วอาณาเขตที่พระองค์ทรงปกครอง

20ส่วนบรรดาคนที่เหลืออยู่ที่เป็นชาวฮิตไทต์ ชาวอาโมไรต์ ชาวเปริสซี ชาวฮีไวต์ และชาวเยบุส (คนเหล่านี้ไม่ใช่ชาวอิสราเอล) 21คือลูกหลานที่เหลืออยู่ของคนเหล่านี้ซึ่งชนอิสราเอลไม่สามารถทำลายล้าง9:21 คำนี้ในภาษาฮีบรูหมายถึง สิ่งของหรือบุคคลที่ถวายแด่องค์พระผู้เป็นเจ้าแล้วไม่อาจเรียกคืนได้ มักจะต้องทำลายให้หมดสิ้นไปให้หมดสิ้นได้ โซโลมอนทรงเกณฑ์คนเหล่านี้มาเป็นแรงงานทาสจนถึงทุกวันนี้ 22แต่โซโลมอนไม่ได้ทรงเกณฑ์ให้พลเมืองอิสราเอลคนใดเป็นทาส แต่ให้เป็นพลรบ ข้าราชการ เจ้าหน้าที่ นายทัพ ผู้บัญชาการรถรบ และพลรถรบ 23และมีเจ้าหน้าที่ 550 คน เป็นผู้ควบคุมดูแลแรงงานโยธาในโครงการต่างๆ ของโซโลมอน

24หลังจากราชธิดาของฟาโรห์เสด็จจากเมืองดาวิดมายังพระราชวังที่โซโลมอนทรงสร้างให้ โซโลมอนก็ทรงสร้างป้อมมิลโล

25โซโลมอนทรงถวายเครื่องเผาบูชา และเครื่องสันติบูชาปีละสามครั้ง บนแท่นซึ่งทรงสร้างขึ้นถวายแด่องค์พระผู้เป็นเจ้า และเผาเครื่องหอมต่อหน้าองค์พระผู้เป็นเจ้าด้วย ก็เป็นอันเรียบร้อยตามภาระหน้าที่ซึ่งมีต่อพระวิหาร

26กษัตริย์โซโลมอนยังได้ทรงสร้างกองเรือขึ้นที่เอซีโอนเกเบอร์ ซึ่งใกล้เอลัทในเอโดม บนชายฝั่งทะเลแดง9:26 คือ ทะเลต้นกกด้วย 27และกษัตริย์ฮีรามประทานกะลาสีผู้ช่ำชองให้ร่วมทำงานในกองเรือกับคนของโซโลมอน 28พวกเขาเดินเรือไปที่เมืองโอฟีร์ แล้วนำทองคำกลับมาถวายกษัตริย์โซโลมอนหนักถึงประมาณ 14.5 ตัน9:28 ภาษาฮีบรูว่า420 ตะลันต์

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

1 Ọba 9:1-28

Olúwa farahan Solomoni

19.1-9: 2Ki 7.11-22.Nígbà tí Solomoni sì parí kíkọ́ ilé Olúwa àti ààfin ọba, tí ó sì ti ṣe gbogbo nǹkan tí ó ń fẹ́ láti ṣe, 2Olúwa sì farahàn Solomoni ní ìgbà kejì, bí ó ti farahàn án ní Gibeoni. 3Olúwa sì wí fún un pé:

“Èmi ti gbọ́ àdúrà rẹ àti ẹ̀bẹ̀ rẹ tí ìwọ ti bẹ̀ níwájú mi, mo ti ya ilé yìí sí mímọ́, tí ìwọ ti kọ́, nípa fífi orúkọ mi síbẹ̀ títí láé. Ojú mi àti ọkàn mi yóò wà níbẹ̀ nígbà gbogbo.

4“Bí ìwọ bá rìn níwájú mi ní ọkàn òtítọ́ àti ìdúró ṣinṣin, bí i Dafidi baba rẹ ti rìn, kí o sì ṣe gbogbo èyí tí mo ti paláṣẹ fún ọ àti kí o sì pa àṣẹ mi àti òfin mi mọ́, 5Èmi yóò fi ìdí ìtẹ́ ìjọba rẹ múlẹ̀ lórí Israẹli títí láé, bí mo ti ṣe ìlérí fún Dafidi baba rẹ nígbà tí mo wí pé, ‘Ìwọ kì yóò kùnà láti ní ọkùnrin kan lórí ìtẹ́ Israẹli.’

6“Ṣùgbọ́n tí ìwọ tàbí àwọn ọmọ rẹ bá yípadà kúrò lọ́dọ̀ mi, tí ẹ kò sì pa òfin mi mọ́ àti àṣẹ mi tí mo ti fi fún ọ, tí ẹ sì lọ láti sin ọlọ́run mìíràn, tí ẹ sì ń sìn wọ́n, 7nígbà náà ni èmi yóò ké Israẹli kúrò ní ilẹ̀ tí èmi fi fún wọn, èmi yóò sì kọ ilé yìí tí èmi ti yà sí mímọ́ fún orúkọ mi. Nígbà náà ni Israẹli yóò sì di òwe àti ìmúṣẹ̀sín láàrín gbogbo orílẹ̀-èdè. 8Àti ilé yìí tí ó ga, ẹnu yóò sì ya olúkúlùkù ẹni tí ó kọjá lẹ́bàá rẹ̀, yóò sì pòṣé, wọn ó sì wí pé, ‘Èéṣe tí Olúwa fi ṣe irú nǹkan yìí sí ilẹ̀ yìí àti ilé yìí?’ 9Àwọn ènìyàn yóò sì dáhùn wí pé, ‘Nítorí tí wọ́n ti kọ̀ Olúwa Ọlọ́run wọn sílẹ̀, tí ó mú àwọn baba wọn jáde láti Ejibiti wá, wọ́n sì ti gbá ọlọ́run mìíràn mú, wọ́n ń bọ wọ́n, wọ́n sì ń sìn wọ́n, ìdí nìyìí tí Olúwa ṣe mú gbogbo ìjàǹbá yìí wá sórí wọn.’ ”

Ojúṣe Solomoni mìíràn

10Lẹ́yìn ogún ọdún, nígbà tí Solomoni kọ́ ilé méjèèjì yìí tan: ilé Olúwa àti ààfin ọba. 11Solomoni ọba sì fi ogún ìlú ní Galili fún Hiramu ọba Tire, nítorí tí Hiramu ti bá a wá igi kedari àti igi firi àti wúrà gẹ́gẹ́ bí gbogbo ìfẹ́ rẹ̀. 12Ṣùgbọ́n nígbà tí Hiramu sì jáde láti Tire lọ wo ìlú tí Solomoni fi fún un, inú rẹ̀ kò sì dùn sí wọn. 13Ó sì wí pé, “Irú ìlú wo nìwọ̀nyí tí ìwọ fi fún mi, arákùnrin mi?” Ó sì pè wọ́n ní ilẹ̀ Kabulu títí fi di òní yìí. 14Hiramu sì ti fi ọgọ́fà (120) tálẹ́ǹtì wúrà ránṣẹ́ sí ọba.

15Ìdí àwọn asìnrú ti Solomoni ọba kójọ ni èyí; láti kọ́ ilé Olúwa àti ààfin òun tìkára rẹ̀; Millo, odi Jerusalẹmu, Hasori, Megido àti Geseri. 16Farao ọba Ejibiti sì ti kọlu Geseri, ó sì ti fi iná sun ún, ó sì pa àwọn ará Kenaani tí ń gbé ìlú náà, ó sì fi ta ọmọbìnrin rẹ̀, aya Solomoni lọ́rẹ. 17Solomoni sì tún Geseri kọ́, àti Beti-Horoni ìsàlẹ̀, 18Àti Baalati àti Tadmori ní aginjù, láàrín rẹ̀, 19Àti gbogbo ìlú ìṣúra tí Solomoni ní, àti ìlú kẹ̀kẹ́ rẹ̀, àti ìlú fún àwọn ẹlẹ́ṣin rẹ̀, àti èyí tí ó ń fẹ́ láti kọ́ ní Jerusalẹmu, ní Lebanoni àti ní gbogbo ilẹ̀ ìjọba rẹ̀ tí ó ń ṣe àkóso.

20Gbogbo ènìyàn tí ó kù nínú àwọn ará Amori ará Hiti, Peresi, Hifi àti Jebusi, àwọn ènìyàn wọ̀nyí kì í ṣe ará Israẹli, 21ìyẹn ni pé àwọn ọmọ wọn tí ó kù ní ilẹ̀ náà, tí àwọn ọmọ Israẹli kò le parun pátápátá, àwọn ni Solomoni bu iṣẹ́ ẹrú fún títí di òní yìí. 22Ṣùgbọ́n, Solomoni kò fi ẹnìkankan ṣe ẹrú nínú àwọn ọmọ Israẹli; àwọn ni ológun rẹ̀ àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, àti àwọn ìjòyè rẹ̀, àti àwọn balógun rẹ̀, àti àwọn olórí kẹ̀kẹ́ rẹ̀ àti ti àwọn ẹlẹ́ṣin rẹ̀. 23Àwọn sì tún ni àwọn olórí olùtọ́jú tí wọ́n wà lórí iṣẹ́ Solomoni, àádọ́ta-dín-lẹ́gbẹ̀ta (550), ní ń ṣe àkóso lórí àwọn ènìyàn tí ń ṣe iṣẹ́ náà.

24Lẹ́yìn ìgbà tí ọmọbìnrin Farao ti gòkè láti ìlú Dafidi wá sí ààfin tí Solomoni kọ́ fún un, nígbà náà ni ó kọ́ Millo.

25Nígbà mẹ́ta lọ́dún ni Solomoni ń rú ẹbọ sísun àti ẹbọ àlàáfíà lórí pẹpẹ tí ó tẹ́ fún Olúwa, ó sì sun tùràrí níwájú Olúwa pẹ̀lú wọn, bẹ́ẹ̀ ni ó parí ilé náà.

26Solomoni ọba sì túnṣe òwò ọkọ̀ ní Esioni-Geberi, tí ó wà ní ẹ̀bá Elati ní Edomu, létí Òkun Pupa. 27Hiramu sì rán àwọn ènìyàn rẹ̀, àwọn atukọ̀ tí ó mọ Òkun, pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́ Solomoni. 28Wọ́n sì dé ofiri, wọ́n sì mú irínwó ó lé ogún (420) tálẹ́ǹtì wúrà, tí wọ́n ti gbà wá fún Solomoni ọba.