เศคาริยาห์ 13 – TNCV & YCB

Thai New Contemporary Bible

เศคาริยาห์ 13:1-9

ชำระบาป

1“ในวันนั้นจะมีน้ำพุพุ่งขึ้นมาสำหรับพงศ์พันธุ์ดาวิดและชาวเยรูซาเล็ม เพื่อชำระเขาทั้งปวงจากบาปและมลทินของเขา

2“ในวันนั้นเราจะทำลายรูปเคารพทั้งปวงให้สิ้นชื่อจากทั่วดินแดนนั้น จะไม่มีใครนึกถึงรูปเคารพเหล่านั้นอีก” พระยาห์เวห์ผู้ทรงฤทธิ์ประกาศดังนั้น “เราจะกำจัดทั้งผู้พยากรณ์เท็จและวิญญาณโสโครกไปจากแผ่นดิน 3และหากผู้ใดยังขืนพยากรณ์ พ่อแม่ผู้ให้กำเนิดเขาเองจะกล่าวกับเขาว่า ‘เจ้าต้องตายเพราะเจ้าพูดเท็จในพระนามพระยาห์เวห์’ เมื่อเขาพยากรณ์ พ่อแม่ของเขาเองจะแทงเขา

4“ในวันนั้นผู้เผยพระวจนะทุกคนจะอับอายที่เห็นนิมิต จะไม่มีใครสวมเสื้อผ้าขนสัตว์แบบผู้เผยพระวจนะเพื่อตบตาประชาชนอีก 5เขาจะพูดว่า ‘ข้าพเจ้าไม่ใช่ผู้เผยพระวจนะ แต่เป็นชาวไร่ชาวนา อาศัยแผ่นดินเป็นที่ทำกินมาตั้งแต่หนุ่มๆ13:5 หรือชาวนา ชายคนหนึ่งขายข้าพเจ้ามาตั้งแต่หนุ่ม6หากมีใครถามเขาว่า ‘ก็แล้วรอยแผลเป็นพวกนี้บนตัวเจ้า13:6 หรือรอยแผลระหว่างมือทั้งสองของเจ้าหมายความว่าอะไร’ เขาจะตอบว่า ‘เป็นแผลที่ได้มาจากบ้านเพื่อน’ ”

คนเลี้ยงแกะถูกเล่นงาน ฝูงแกะกระจัดกระจาย

7พระยาห์เวห์ผู้ทรงฤทธิ์ประกาศว่า

“ดาบเอ๋ย จงตื่นขึ้น ห้ำหั่นคนเลี้ยงแกะของเรา

และคนใกล้ชิดของเรา

จงฟาดฟันคนเลี้ยงแกะ

และแกะจะกระจัดกระจายไป

และเราจะตวัดมือฟาดผู้เล็กน้อย”

8องค์พระผู้เป็นเจ้าประกาศว่า

“สองในสามของทั้งดินแดนจะถูกห้ำหั่นพินาศไป

เหลือไว้เพียงหนึ่งในสาม

9หนึ่งในสามนี้เราจะเอาไปใส่ในไฟ

เราจะถลุงพวกเขาเหมือนเงิน

และทดสอบพวกเขาเหมือนทองคำ

พวกเขาจะร้องเรียกนามของเรา

และเราจะตอบพวกเขา

เราจะกล่าวว่า ‘พวกเขาเป็นประชากรของเรา’

และพวกเขาจะกล่าวว่า ‘พระยาห์เวห์เป็นพระเจ้าของเรา’ ”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Sekariah 13:1-9

Ìwẹ̀nùmọ́ kúrò nínú ẹsẹ̀

1“Ní ọjọ́ náà ìsun kan yóò ṣí sílẹ̀ fún ilé Dafidi àti fún àwọn ará Jerusalẹmu, láti wẹ̀ wọ́n mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ àti àìmọ́ wọn.

2“Yóò sì ṣe ní ọjọ́ náà ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, ni èmi ó gé orúkọ àwọn òrìṣà kúrò ni ilẹ̀ náà, a kì yóò sì rántí wọn mọ́: àti pẹ̀lú èmi ó mú àwọn wòlíì èké àti àwọn ẹ̀mí àìmọ́ kúrò ni ilẹ̀ náà. 3Yóò sì ṣe, nígbà tí ẹnìkan yóò sọtẹ́lẹ̀ síbẹ̀, ni baba rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ tí ó bí í yóò wí fún un pé, ‘Ìwọ ki yóò yè: nítorí ìwọ ń sọ ọ̀rọ̀ èké ni orúkọ Olúwa.’ Àti baba rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ tí o bí í yóò gun un ni àgúnpa nígbà tí ó bá sọtẹ́lẹ̀.

4“Yóò sì ṣe ní ọjọ́ náà, ojú yóò tí àwọn wòlíì èké olúkúlùkù nítorí ìran rẹ̀, nígbà tí òun ba tí sọtẹ́lẹ̀; bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò sì wọ aṣọ wòlíì onírun rẹ̀ tí o fi ń tan ní jẹ. 5Ṣùgbọ́n òun o wí pé, ‘Èmi kí í ṣe wòlíì, àgbẹ̀ ni èmi; nítorí tí a ti fi mí ṣe ìránṣẹ́ láti ìgbà èwe mi wá.’ 6Ẹnìkan ó sì wí fún un pé, ‘Ọgbẹ́ kín ní wọ̀nyí ni ẹ̀yìn rẹ?’ Òun o sì dáhùn pé, ‘Wọ̀nyí ni ibi tí a ti sá mi ní ilé àwọn ọ̀rẹ́ mi.’

A lu olùṣọ́-àgùntàn, agbo ẹran fọ́nká

713.7: Mt 26.31; Mk 14.27.“Dìde, ìwọ idà, sí olùṣọ́-àgùntàn mi,

àti sí ẹni tí í ṣe ẹnìkejì mi,”

ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí:

“Kọlu Olùṣọ́-àgùntàn,

àwọn àgùntàn a sì túká:

èmi o sì yí ọwọ́ mi sí àwọn kéékèèkéé.

8Yóò sì ṣe, ni gbogbo ilẹ̀,” ni Olúwa wí,

“a ó gé apá méjì nínú rẹ̀ kúrò yóò sì kú;

ṣùgbọ́n apá kẹta yóò kù nínú rẹ̀.

9Èmi ó sì mú apá kẹta náà la àárín iná,

èmi yóò sì yọ́ wọn bí a ti yọ́ fàdákà,

èmi yóò sì dán wọn wò, bi a tí ń dán wúrà wò:

wọn yóò sì pé orúkọ mi,

èmi yóò sì dá wọn lóhùn:

èmi yóò wí pé, ‘Àwọn ènìyàn mi ni,’

àwọn yóò sì wí pé, ‘Olúwa ni Ọlọ́run wa.’ ”