เยเรมีย์ 14 – TNCV & YCB

Thai New Contemporary Bible

เยเรมีย์ 14:1-22

การกันดารอาหาร ความแห้งแล้ง และสงคราม

1พระดำรัสขององค์พระผู้เป็นเจ้ามาถึงเยเรมีย์เกี่ยวกับความแห้งแล้งว่า

2“ยูดาห์คร่ำครวญ

เมืองต่างๆ ซึมเซา

พวกเขาร่ำไห้ให้กับดินแดน

และมีเสียงร้องระงมขึ้นจากเยรูซาเล็ม

3บรรดาขุนนางส่งคนใช้ออกไปหาน้ำ

พวกคนใช้ไปที่บ่อ

แต่ไม่มีน้ำ

คนใช้ถือเหยือกเปล่ากลับมา

อย่างอับอายและสิ้นหวัง

คลุมศีรษะตัวเองด้วยความรันทด

4ผืนแผ่นดินแตกระแหง

เพราะขาดฝน

ชาวนาอับอายและสิ้นหวัง

และคลุมศีรษะตัวเองด้วยความรันทด

5แม้แต่กวางในท้องทุ่ง

ก็ทิ้งลูกของมันที่เพิ่งเกิด

เพราะไม่มีหญ้า

6ลาป่ายืนเคว้งบนเนินโล่งเตียน

และหอบเหมือนหมาใน

ตาของมันพร่ามัว

เพราะไม่มีหญ้ากิน”

7ข้าแต่องค์พระผู้เป็นเจ้า แม้ว่าบาปของข้าพระองค์ทั้งหลายปรักปรำตัวเอง

แต่ขอทรงโปรดช่วยเพื่อเห็นแก่พระนามของพระองค์

เพราะข้าพระองค์ทั้งหลายเสื่อมทรามยิ่งนัก

เราได้ทำบาปต่อพระองค์

8ข้าแต่องค์ผู้ทรงเป็นความหวังของอิสราเอล

พระผู้ช่วยให้รอดของพวกเขาในยามทุกข์ลำเค็ญ

เหตุใดทรงเป็นเช่นคนแปลกหน้าในแผ่นดินนี้

เป็นเช่นคนเดินทางซึ่งแวะพักแรมเพียงคืนเดียว?

9เหตุใดทรงเป็นดั่งคนที่งงงวย

เหมือนนักรบที่หมดเรี่ยวหมดแรงจะช่วย?

ข้าแต่องค์พระผู้เป็นเจ้า พระองค์ทรงอยู่ท่ามกลางข้าพระองค์ทั้งหลาย

และผู้คนเรียกข้าพระองค์ทั้งหลายตามพระนามของพระองค์

ขออย่าทรงทอดทิ้งเหล่าข้าพระองค์!

10องค์พระผู้เป็นเจ้าตรัสเกี่ยวกับชนชาตินี้ว่า

“พวกเขารักที่จะหลงเตลิด

พวกเขาไม่ยั้งเท้าบ้างเลย

ฉะนั้นองค์พระผู้เป็นเจ้าจึงไม่ยอมรับพวกเขา

บัดนี้พระองค์จะทรงระลึกถึงความชั่วช้าของพวกเขา

และลงโทษพวกเขาเพราะบาปทั้งหลาย”

11แล้วองค์พระผู้เป็นเจ้าตรัสกับข้าพเจ้าว่า “อย่าอธิษฐานเผื่อความอยู่เย็นเป็นสุขของชนชาตินี้ 12แม้พวกเขาถืออดอาหาร เราจะไม่ฟังคำอ้อนวอนของเขา แม้เขาถวายเครื่องเผาบูชาและธัญบูชา เราก็จะไม่รับ แต่เราจะทำลายพวกเขาด้วยสงคราม การกันดารอาหาร และโรคระบาด”

13แต่ข้าพเจ้ากราบทูลว่า “ข้าแต่พระยาห์เวห์องค์เจ้าชีวิตบรรดาผู้เผยพระวจนะพร่ำบอกพวกเขาว่า ‘เจ้าจะไม่เห็นสงครามหรือการทนทุกข์กับการกันดารอาหาร แท้ที่จริงเราจะให้สันติสุขที่ยั่งยืนแก่เจ้าในสถานที่แห่งนี้’ ”

14องค์พระผู้เป็นเจ้าจึงตรัสกับข้าพเจ้าว่า “บรรดาผู้เผยพระวจนะพยากรณ์เท็จโดยอ้างชื่อของเรา เราไม่ได้ใช้พวกเขาไป ไม่ได้แต่งตั้ง และไม่ได้พูดกับเขา เขาเผยพระวจนะเป็นนิมิต คำพยากรณ์เท็จ การกราบไหว้รูปเคารพ14:14 หรือนิมิตเท็จ คำพยากรณ์อันไร้ค่า และภาพหลอนในใจของเขาเอง 15ฉะนั้นองค์พระผู้เป็นเจ้าตรัสว่า เราจะลงโทษผู้เผยพระวจนะเหล่านี้ ซึ่งเผยพระวจนะในนามของเรา ทั้งๆ ที่เราไม่ได้ใช้พวกเขาไป พวกเขาก็ยังพูดว่า ‘สงครามหรือการกันดารอาหารจะไม่มาแผ้วพานดินแดนนี้’ พวกเขาเองนั่นแหละจะตายด้วยสงครามและการกันดารอาหาร 16ส่วนผู้คนที่ฟังเขาพยากรณ์เท็จนั้นจะถูกเหวี่ยงออกมากลางถนนสายต่างๆ ของเยรูซาเล็มเนื่องมาจากสงครามและการกันดารอาหาร จะไม่มีใครมาฝังศพพวกเขาหรือภรรยา บุตรชาย บุตรสาวของเขา เราจะเทหายนะลงมาเหนือพวกเขาอย่างสาสม

17“จงบอกพวกเขาว่า

“ ‘ขอให้น้ำตาของเราไหลริน

ไม่หยุดหย่อนทั้งวันทั้งคืน

เพราะธิดาพรหมจารีของเราคือประชากรของเรา

ถูกตีและนอนซมด้วยบาดแผลฉกรรจ์

18หากเราออกไปที่ทุ่งกว้าง

ก็เห็นร่างบรรดาผู้ถูกปลิดชีวิตด้วยดาบ

หากเข้าไปในเมือง

ก็เห็นศพผู้เป็นเหยื่อการกันดารอาหาร

ทั้งผู้เผยพระวจนะและปุโรหิต

ได้ไปยังดินแดนที่ตนไม่รู้จัก’ ”

19พระองค์ทรงทอดทิ้งยูดาห์เสียสิ้นแล้วหรือ?

ทรงเกลียดชังศิโยนหรือ?

เหตุใดทรงทรมานเรา

จนเยียวยาไม่หาย?

ข้าพระองค์ทั้งหลายหวังว่าจะได้รับสันติสุข

แต่ไม่มีอะไรดี

หวังว่าจะได้รับการบำบัดรักษา

แต่มีเพียงความอกสั่นขวัญแขวน

20ข้าแต่องค์พระผู้เป็นเจ้า ข้าพระองค์ทั้งหลายทราบถึงความชั่วร้ายของข้าพระองค์ทั้งหลาย

และความผิดของเหล่าบรรพบุรุษ

ข้าพระองค์ทั้งหลายได้ทำบาปต่อพระองค์จริงๆ

21เพื่อเห็นแก่พระนามของพระองค์ ขออย่าทรงเกลียดชังข้าพระองค์ทั้งหลายเลย

ขออย่าให้บัลลังก์อันทรงเกียรติของพระองค์เสื่อมศักดิ์ศรี

โปรดทรงระลึกถึงพันธสัญญาที่ทรงมีต่อข้าพระองค์ทั้งหลาย

และอย่าทิ้งพันธสัญญานั้น

22มีรูปเคารพอันไร้ค่าของบรรดาประชาชาติองค์ไหนบ้างที่ประทานฝนให้ได้?

หรือท้องฟ้าเทฝนลงมาเอง?

เปล่าเลย แต่เป็นพระองค์นั่นแหละ ข้าแต่พระยาห์เวห์พระเจ้าของเรา

ฉะนั้นข้าพระองค์ทั้งหลายจึงหวังในพระองค์

เพราะพระองค์ทรงเป็นผู้ทำสิ่งทั้งปวงเหล่านี้

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Jeremiah 14:1-22

Àjàkálẹ̀-ààrùn, ìyàn àti idà

1Èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa sí Jeremiah nípa ti àjàkálẹ̀-ààrùn:

2“Juda káàánú,

àwọn ìlú rẹ̀ kérora

wọ́n pohùnréré ẹkún fún ilẹ̀ wọn,

igbe wọn sì gòkè lọ láti Jerusalẹmu.

3Àwọn ọlọ́lá ènìyàn rán àwọn ìránṣẹ́ wọn lọ bu omi,

wọ́n lọ sí ìdí àmù

ṣùgbọ́n wọn kò rí omi.

Wọ́n padà pẹ̀lú ìkòkò òfìfo;

ìrẹ̀wẹ̀sì àti àìnírètí bá wọn,

wọ́n sì bo orí wọn.

4Ilẹ̀ náà sán

nítorí pé kò sí òjò ní ilẹ̀ náà;

ìrètí àwọn àgbẹ̀ di òfo,

wọ́n sì bo orí wọn.

5Kódà, abo àgbọ̀nrín tí ó wà lórí pápá

fi ọmọ rẹ̀ tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ bí sílẹ̀,

torí pé kò sí koríko.

6Àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó dúró lórí òkè òfìfo

wọ́n sì ń mí ẹ̀fúùfù bí ìkookò

ojú wọn kò ríran

nítorí pé kò sí koríko jíjẹ.”

7Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀ṣẹ̀ wa jẹ́rìí lòdì sí wa,

wá nǹkan kan ṣe sí i Olúwa, nítorí orúkọ rẹ.

Nítorí ìpadàsẹ́yìn wa ti pọ̀jù,

a ti ṣẹ̀ sí ọ.

8Ìrètí Israẹli;

ìgbàlà rẹ lásìkò ìpọ́njú,

èéṣe tí ìwọ dàbí àlejò ní ilẹ̀ náà

bí arìnrìn-àjò tí ó dúró fún bí òru ọjọ́ kan péré?

9Èéṣe tí ìwọ dàbí ẹni tí a dààmú,

bí jagunjagun tí kò le ran ni lọ́wọ́?

Ìwọ wà láàrín wa, Olúwa,

orúkọ rẹ ni a sì ń pè mọ́ wa;

má ṣe fi wá sílẹ̀.

10Báyìí ni Olúwa sọ nípa àwọn ènìyàn wọ̀nyí:

“Wọ́n fẹ́ràn láti máa rìn kiri;

wọn kò kó ọkàn wọn ní ìjánu.

Nítorí náà Olúwa kò gbà wọ́n;

yóò wá rántí ìwà búburú wọn báyìí,

yóò sì fi ìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn jẹ wọ́n.”

11Nígbà náà ni Olúwa sọ fún mi pé, “Má ṣe gbàdúrà fún àlàáfíà àwọn ènìyàn wọ̀nyí. 1214.12: If 6.8.Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n gbààwẹ̀, èmi kò ní tẹ́tí sí igbe wọn. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n rú ẹbọ sísun àti ẹbọ ìyẹ̀fun, èmi ò nígbà wọ́n. Dípò bẹ́ẹ̀, èmi ó fi idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀-ààrùn pa wọ́n run.”

13Ṣùgbọ́n mo sọ pé, “Háà! Olúwa Olódùmarè. Àwọn wòlíì ń sọ fún wọn pé, ‘ẹ kò ni rí idà tàbí ìyàn. Dájúdájú èmi ó fún yín ní àlàáfíà tí yóò tọ́jọ́ níbí yìí?’ ”

14Nígbà náà Olúwa sọ fún mi pé, “àwọn wòlíì ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ èké ní orúkọ mi. Èmi kò rán wọn, tàbí yàn wọ́n tàbí bá wọn sọ̀rọ̀. Ìran èké ni wọ́n ń rí sí i yín. Àsọtẹ́lẹ̀ èké ni wọ́n ń sọ fún un yín nípa ìran ìrírí, àfọ̀ṣẹ, ìbọ̀rìṣà àti ìtànjẹ ọkàn wọn. 15Nítorí náà, èyí ni Olúwa sọ nípa àwọn wòlíì tí wọ́n ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ lórúkọ mi. Èmi kò rán wọn, síbẹ̀ wọ́n sì ń sọ pé, ‘idà kan tàbí ìyàn, kì yóò dé ilẹ̀ yìí.’ Àwọn wòlíì kan náà yóò parẹ́ nípa idà àti ìyàn. 16Bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn ènìyàn tí wọ́n ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ fún ni a ó lé sí òpópónà Jerusalẹmu torí idà àti ìyàn. Wọn kò ní i rí ẹni tí yóò sìn wọ́n tàbí ìyàwó wọn, àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin wọn. Èmi yóò mú ìdààmú tí ó yẹ bá ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin wọn.

17“Kí ìwọ kí ó sì sọ ọ̀rọ̀ yìí fún wọn pé:

“ ‘Jẹ́ kí ojú mi kí ó sun omijé

ní ọ̀sán àti ní òru láìdá;

nítorí tí a ti ṣá wúńdíá,

ọmọ ènìyàn mi ní ọgbẹ́ ńlá

pẹ̀lú lílù bolẹ̀.

18Bí mo bá lọ sí orílẹ̀-èdè náà,

Èmi yóò rí àwọn tí wọ́n fi idà pa.

Bí mo bá lọ sí ìlú ńlá,

èmi rí àwọn tí ìyàn ti sọ di aláàrùn.

Wòlíì àti Àlùfáà

ti lọ sí ilẹ̀ tí wọn kò mọ̀.’ ”

19Ṣé o ti kọ Juda sílẹ̀ pátápátá ni?

Ṣé o ti ṣá Sioni tì?

Èéṣe tí o fi pọ́n wa lójú

tí a kò fi le wò wá sàn?

A ń retí àlàáfíà

ṣùgbọ́n ohun rere kan kò tí ì wá,

ní àsìkò ìwòsàn

ìpayà là ń rí.

20Olúwa, a jẹ́wọ́ ìwà ibi wa

àti àìṣedéédéé àwọn baba wa;

lóòótọ́ ni a ti ṣẹ̀ sí ọ.

21Nítorí orúkọ rẹ má ṣe kórìíra wa;

má ṣe sọ ìtẹ́ ògo rẹ di àìlọ́wọ̀.

Rántí májẹ̀mú tí o bá wa dá

kí o má ṣe dà á.

22Ǹjẹ́ èyíkéyìí àwọn òrìṣà yẹ̀yẹ́ tí àwọn orílẹ̀-èdè le ṣe kí òjò rọ̀?

Ǹjẹ́ àwọsánmọ̀ fúnrarẹ̀ rọ òjò bí?

Rárá, ìwọ ni, Olúwa Ọlọ́run wa.

Torí náà, ìrètí wa wà lọ́dọ̀ rẹ,

nítorí pé ìwọ lo ń ṣe gbogbo nǹkan wọ̀nyí.