อิสยาห์ 39 – TNCV & YCB

Thai New Contemporary Bible

อิสยาห์ 39:1-8

คณะทูตจากบาบิโลน

(2พกษ.20:12-19)

1ครั้งนั้นเมโรดัคบาลาดันโอรสของกษัตริย์บาลาดันแห่งบาบิโลนได้ทราบข่าวว่าเฮเซคียาห์ประชวรและบัดนี้ทรงหายเป็นปกติแล้ว ก็ส่งสาสน์และของกำนัลมาให้เฮเซคียาห์ 2เฮเซคียาห์ต้อนรับคณะทูตด้วยความปลาบปลื้มพระทัย และทรงอวดสมบัติทั้งสิ้นในท้องพระคลังให้พวกเขาชม คือเงิน ทอง เครื่องเทศ น้ำมันอย่างดี อาวุธยุทโธปกรณ์ทั้งหมด และทุกสิ่งทุกอย่างที่มี ไม่มีสักสิ่งเดียวในพระราชวังหรือทั่วอาณาจักรที่เฮเซคียาห์ไม่ได้อวด

3แล้วผู้เผยพระวจนะอิสยาห์มาเข้าเฝ้ากษัตริย์เฮเซคียาห์และทูลถามว่า “คนพวกนี้พูดอะไร? และพวกเขามาจากไหน?”

เฮเซคียาห์ตรัสตอบว่า “มาจากบาบิโลนดินแดนอันไกลโพ้น”

4ผู้เผยพระวจนะทูลถามว่า “พวกเขาได้เห็นอะไรในวังของท่านบ้าง?”

เฮเซคียาห์ตรัสตอบว่า “พวกเขาเห็นทุกสิ่งทุกอย่างในวังของเรา ไม่มีสักสิ่งเดียวในท้องพระคลังที่เราไม่ได้ให้พวกเขาดู”

5อิสยาห์จึงกล่าวแก่เฮเซคียาห์ว่า “จงฟังพระดำรัสของพระยาห์เวห์ผู้ทรงฤทธิ์ที่ว่า 6เวลานั้นจะมาถึงอย่างแน่นอน เมื่อทุกอย่างในวังของเจ้าและทุกสิ่งที่บรรพบุรุษของเจ้าได้สะสมไว้จวบจนบัดนี้จะถูกกวาดไปยังบาบิโลน จะไม่มีอะไรเหลือเลย องค์พระผู้เป็นเจ้าตรัสดังนี้ 7และวงศ์วานของเจ้าบางคน เลือดเนื้อเชื้อไขของเจ้าเองจะถูกกวาดต้อนไป ต้องกลายเป็นขันทีอยู่ในวังของกษัตริย์บาบิโลน”

8เฮเซคียาห์ตรัสตอบว่า “พระดำรัสขององค์พระผู้เป็นเจ้าตามที่ท่านว่ามาก็ดีอยู่” เพราะเฮเซคียาห์ดำริว่า “อย่างน้อยก็ยังจะมีความสงบสุขและความมั่นคงปลอดภัยในชั่วอายุของเรา”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Isaiah 39:1-8

Àwọn ikọ̀ ọba láti Babeli

139.1-8: 2Ọb 20.12-19; 2Ki 32.31.Ní àkókò náà ni Merodaki-Baladani ọmọ Baladani ọba Babeli fi ìwé àti ẹ̀bùn ránṣẹ́ sí Hesekiah, nítorí ó gbọ́ pé ó ṣàìsàn ó sì gbádùn. 2Hesekiah gba àwọn ikọ̀ yìí tayọ̀tayọ̀, ó sì fi àwọn nǹkan tí ó wà nínú yàrá ìkẹ́rù sí mọ́ hàn wọ́n—fàdákà, wúrà, ohun olóòórùn dídùn, òróró dídára, gbogbo nǹkan ogun rẹ̀ àti ohun gbogbo tí ó wà nínú ìṣúra rẹ̀ kò sí ohunkóhun tí ó wà nínú ààfin rẹ̀ tàbí ní ìjọba rẹ̀ tí Hesekiah kò fihàn wọ́n.

3Lẹ́yìn náà wòlíì Isaiah lọ sí ọ̀dọ̀ Hesekiah ọba ó sì béèrè pé, “Kí ni àwọn ènìyàn wọ̀nyí wí, níbo ni wọ́n sì ti wá?”

“Láti ilẹ̀ jíjìnnà,” ni èsì Hesekiah. “Wọ́n wá sọ́dọ̀ mi láti Babeli.”

4Wòlíì náà sì béèrè pé, “Kí ni wọ́n rí nínú ààfin rẹ?”

Hesekiah si dáhùn pe “Wọ́n rí gbogbo ohun tí ó wà nínú ààfin mi” ni ìdáhùn Hesekiah. “Kò sí ohun kankan nínú ìṣúra mi tí èmi kò fihàn wọ́n.”

5Lẹ́yìn náà ni Isaiah sọ fún Hesekiah pé, “Gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa àwọn ọmọ-ogun: 6Àsìkò ń bọ̀ nítòótọ́ nígbà tí gbogbo ohun tí ó wà nínú ààfin rẹ, àti ohun gbogbo tí àwọn baba rẹ ti kójọ títí di ọjọ́ òní yóò di kíkó lọ sí Babeli. Ohun kankan kò ní ṣẹ́kù ni Olúwa wí. 7Àti díẹ̀ nínú àwọn àrọ́mọdọ́mọ rẹ, àwọn ẹ̀jẹ̀ àti ẹran-ara rẹ tí a ó bí fún ọ ni a ó kó lọ, wọn yóò sì di ìwẹ̀fà nínú ààfin ọba Babeli.”

8Hesekiah wí fún Isaiah pé “Rere ni ọ̀rọ̀ Olúwa tí ìwọ sọ,” Nítorí ó rò nínú ara rẹ̀ pé, “Àlàáfíà àti òtítọ́ yóò wà ní ìgbà ayé tèmi.”