อิสยาห์ 37 – TNCV & YCB

Thai New Contemporary Bible

อิสยาห์ 37:1-38

คำพยากรณ์ว่าเยรูซาเล็มจะได้รับการช่วยกู้

(2พกษ.19:1-13)

1เมื่อกษัตริย์เฮเซคียาห์ทรงได้ยินเช่นนั้นก็ทรงฉีกฉลองพระองค์ สวมผ้ากระสอบ แล้วเสด็จเข้าสู่พระวิหารขององค์พระผู้เป็นเจ้า 2พระองค์ทรงใช้เจ้ากรมวังเอลียาคิม ราชเลขาเชบนา และบรรดาปุโรหิตอาวุโสให้ไปพบผู้เผยพระวจนะอิสยาห์บุตรอาโมศ ทุกคนล้วนสวมชุดผ้ากระสอบ 3พวกเขากล่าวกับอิสยาห์ว่า “เฮเซคียาห์ตรัสดังนี้ว่า วันนี้เป็นวันแห่งความทุกข์ระทม การประณามหยามเหยียด และความอับอาย เหมือนเมื่อทารกพร้อมจะเกิด แต่ผู้เป็นแม่ไม่มีแรงจะเบ่งออกมา 4บางทีพระยาห์เวห์พระเจ้าของท่านจะทรงได้ยินถ้อยคำของแม่ทัพ ซึ่งกษัตริย์อัสซีเรียเจ้านายของเขาใช้ให้มาหมิ่นประมาทพระเจ้าผู้ทรงพระชนม์อยู่ และพระองค์จะทรงลงโทษเขาเนื่องด้วยถ้อยคำที่พระยาห์เวห์พระเจ้าของท่านทรงได้ยินนั้น ดังนั้นขอโปรดอธิษฐานเผื่อพวกเราที่เหลืออยู่เพียงหยิบมือนี้ด้วยเถิด”

5เมื่อข้าราชบริพารของกษัตริย์เฮเซคียาห์มาพบอิสยาห์ 6อิสยาห์ก็กล่าวกับพวกเขาว่า “จงไปบอกนายของท่านว่า ‘องค์พระผู้เป็นเจ้าตรัสดังนี้ว่า อย่ากลัวสิ่งที่ได้ยิน คือถ้อยคำซึ่งลูกน้องของกษัตริย์อัสซีเรียได้หมิ่นประมาทเรา 7จงฟังเถิด! เรากำลังจะบันดาลวิญญาณอย่างหนึ่งในตัวเขา เพื่อเมื่อเขาได้ยินรายงานบางอย่าง เขาจะกลับไปยังประเทศของตน และเราจะให้เขาตายด้วยดาบที่นั่น’ ”

8ฝ่ายแม่ทัพอัสซีเรียได้ข่าวว่ากษัตริย์ของตนเสด็จออกจากลาคีชแล้ว ก็ถอนทัพไป และพบพระองค์กำลังรบอยู่กับเมืองลิบนาห์

9แล้วเซนนาเคอริบได้รับรายงานว่าทีรหะคาห์กษัตริย์ชาวคูช37:9 คือ ตอนบนของลุ่มแม่น้ำไนล์แห่งอียิปต์ยกทัพจะมาสู้รบกับพระองค์ เมื่อได้ยินดังนั้นพระองค์จึงทรงส่งคนกลับมาแจ้งแก่เฮเซคียาห์ว่า 10“จงไปบอกกษัตริย์เฮเซคียาห์แห่งยูดาห์ดังนี้ว่า อย่ายอมให้พระเจ้าซึ่งเจ้าพึ่งพานั้นหลอกลวงเจ้าเมื่อพระองค์ตรัสว่า ‘เยรูซาเล็มจะไม่ตกอยู่ในมือกษัตริย์อัสซีเรีย’ 11เจ้าก็รู้ดีว่าบรรดากษัตริย์อัสซีเรียได้ทำอะไรแก่ประเทศทั้งปวงบ้าง กษัตริย์เหล่านั้นได้ทำลายล้างทุกสิ่งทุกอย่างราบคาบ แล้วเจ้าจะได้รับการช่วยกู้หรือ? 12บรรดาพระของชนชาติต่างๆ ที่บรรพบุรุษของเราได้ทำลายล้างไปนั้นได้ช่วยกอบกู้พวกเขาไว้หรือ อย่างพระทั้งหลายของโกซาน ฮาราน เรเซฟ และชาวเอเดนในเทลอัสสาร์? 13ไหนล่ะกษัตริย์ฮามัท กษัตริย์อารปัด กษัตริย์เสฟารวาอิม เฮนา และอิฟวาห์?”

คำอธิษฐานของเฮเซคียาห์

(2พกษ.19:14-19)

14เมื่อเฮเซคียาห์ทรงรับสาส์นฉบับนี้และอ่านจบ ก็เสด็จไปยังพระวิหารขององค์พระผู้เป็นเจ้าและทรงคลี่สาส์นนั้นออกต่อหน้าองค์พระผู้เป็นเจ้า 15แล้วเฮเซคียาห์ทรงอธิษฐานต่อองค์พระผู้เป็นเจ้าว่า 16“ข้าแต่พระยาห์เวห์ผู้ทรงฤทธิ์พระเจ้าแห่งอิสราเอล ผู้ประทับอยู่บนพระที่นั่งระหว่างเครูบ พระองค์ผู้เดียวทรงเป็นพระเจ้าเหนือมวลอาณาจักรของโลก พระองค์ทรงสร้างฟ้าสวรรค์และแผ่นดินโลก 17ข้าแต่องค์พระผู้เป็นเจ้า ขอทรงเงี่ยพระกรรณสดับฟัง ข้าแต่องค์พระผู้เป็นเจ้า ขอทรงทอดพระเนตรและสดับฟังถ้อยคำทั้งสิ้นซึ่งเซนนาเคอริบส่งมาสบประมาทพระเจ้าผู้ทรงพระชนม์อยู่

18“ข้าแต่องค์พระผู้เป็นเจ้า เป็นความจริงที่ว่าบรรดากษัตริย์อัสซีเรียได้ทำลายล้างชนชาติทั้งปวงนี้ และแผ่นดินของพวกเขา 19และได้เผาทำลายพระของพวกเขาทิ้งเพราะพระเหล่านั้นไม่ใช่พระเจ้า เป็นเพียงแต่ไม้และหินที่ทำขึ้นด้วยมือมนุษย์ 20บัดนี้ข้าแต่พระยาห์เวห์พระเจ้าของข้าพระองค์ทั้งหลาย ขอทรงช่วยข้าพระองค์ทั้งหลายให้พ้นจากเงื้อมมือของเขา เพื่อมวลอาณาจักรในโลกนี้จะได้รู้ว่า พระยาห์เวห์พระองค์แต่เพียงผู้เดียวเท่านั้นทรงเป็นพระเจ้า37:20 ฉบับ MT. ว่าพระองค์แต่เพียงผู้เดียวเท่านั้นที่ทรงเป็นพระยาห์เวห์(ดู2พกษ.19:19)

เซนนาเคอริบจะล่มจม

(2พกษ.19:20-37; 2พศด.32:20-21)

21จากนั้นอิสยาห์บุตรอาโมศจึงให้นำความมาทูลเฮเซคียาห์ว่า “พระยาห์เวห์พระเจ้าแห่งอิสราเอลตรัสดังนี้ว่า เพราะเจ้าได้อธิษฐานเรื่องกษัตริย์เซนนาเคอริบแห่งอัสซีเรียต่อเรา 22องค์พระผู้เป็นเจ้าจึงตรัสถึงเขาดังนี้ว่า

“ธิดาพรหมจารีแห่งศิโยน37:22 คือ ชาวเยรูซาเล็ม

ดูหมิ่นและเยาะเย้ยเจ้า

ธิดาแห่งเยรูซาเล็ม37:22 คือ ชาวเยรูซาเล็ม

ส่ายหน้าเมื่อเจ้าเตลิดหนี

23ใครนะที่เจ้าเย้ยหยันและลบหลู่?

เจ้าขึ้นเสียง

และทำตาหยิ่งยโสใส่ใคร?

ก็องค์บริสุทธิ์แห่งอิสราเอลน่ะสิ!

24เจ้าใช้ผู้สื่อสารของเจ้า

มากล่าววาจาลบหลู่องค์พระผู้เป็นเจ้า

และเจ้าได้กล่าวว่า

‘ด้วยรถม้าศึกมากมายของข้า

ข้าได้ขึ้นไปถึงบรรดายอดเขาสูง

สู่สุดยอดแห่งเลบานอน

ข้าได้โค่นบรรดาสนซีดาร์ที่สูงที่สุด

และต้นสนที่ดีเยี่ยมที่สุด

ข้าได้ขึ้นไปถึงยอดที่สูงที่สุด

คือป่าอันอุดมสมบูรณ์ที่สุด

25ข้าได้ขุดบ่อน้ำหลายบ่อในต่างแดน37:25 ฉบับ MT. ไม่มีวลีว่าในต่างแดน(ดู2พกษ.19:24)

และดื่มน้ำที่นั่น

ด้วยส้นเท้าของข้า

ลำธารทั้งหลายของอียิปต์ก็แห้งเหือด’

26“เจ้าไม่เคยได้ยินเลยหรือ?

เราได้บัญชาไว้ตั้งนานมาแล้ว

เราได้วางแผนไว้ตั้งแต่อดีต

และบัดนี้เราก็ทำให้เป็นไปตามนั้น

คือให้เจ้าพิชิตเมืองป้อมปราการทั้งหลาย

ทำให้กลายเป็นกองหิน

27ชาวเมืองเหล่านั้นหมดอำนาจ

ถดถอยและอับอาย

พวกเขาเหมือนพืชในทุ่งนา

เหมือนหน่ออ่อนเขียวสด

เหมือนหญ้างอกขึ้นบนหลังคา

ถูกแดดแผดเผา37:27 สำเนา MT. บางฉบับว่าและทุ่งหญ้าขั้นบันได(ดู2พกษ.19:26)ก่อนจะโตขึ้นมา

28“แต่เรารู้จักเจ้าดี

ไม่ว่าความเป็นมาหรือความเป็นไปของเจ้า

และรู้ที่เจ้าฉุนเฉียวใส่เรา

29เพราะเจ้าเกรี้ยวกราดใส่เรา

และเพราะวาจาโอหังของเจ้าเข้าหูเรา

เราจะเอาเบ็ดเกี่ยวจมูกของเจ้า

และเอาบังเหียนใส่ปากของเจ้า

และเราจะทำให้เจ้าหันกลับไป

ตามเส้นทางที่เจ้ามา

30“เฮเซคียาห์เอ๋ย นี่จะเป็นหมายสำคัญแก่เจ้าคือ

“ปีนี้เจ้าจะกินพืชพันธุ์ที่งอกขึ้นเอง

และปีที่สองก็จะกินพืชพันธุ์ที่ออกผลตามมา

แต่ในปีที่สาม จงหว่านและเก็บเกี่ยว

จงทำสวนองุ่นและกินผลของมัน

31ประชากรยูดาห์ที่เหลืออยู่เพียงหยิบมือนั้น

จะหยั่งรากและเกิดผลอีกครั้งหนึ่ง

32เพราะจะมีคนที่เหลือรอดอยู่หยิบมือหนึ่งมาจากเยรูซาเล็ม

และผู้รอดชีวิตกลุ่มหนึ่งจะมาจากภูเขาศิโยน

ความกระตือรือร้นของพระยาห์เวห์ผู้ทรงฤทธิ์

จะกระทำให้สำเร็จตามนี้

33“ฉะนั้นองค์พระผู้เป็นเจ้าตรัสถึงกษัตริย์อัสซีเรียดังนี้ว่า

“เขาจะไม่ได้เข้ามาในเมืองนี้

หรือยิงธนูที่นี่

เขาจะไม่มาถือโล่อยู่หน้าเมือง

หรือสร้างเชิงเทินล้อมโจมตีมัน

34เขามาทางไหนก็จะกลับไปทางนั้น

เขาจะไม่ได้เข้ามาในเมืองนี้”

องค์พระผู้เป็นเจ้าประกาศดังนั้น

35“เราจะปกป้องและช่วยเมืองนี้ไว้

เพื่อเห็นแก่เราเองและเห็นแก่ดาวิดผู้รับใช้ของเรา!”

36แล้วทูตสวรรค์ขององค์พระผู้เป็นเจ้าก็ออกไปประหารคนในค่ายของอัสซีเรีย 185,000 คน วันรุ่งขึ้นเมื่อผู้คนตื่นขึ้น ก็เห็นซากศพเกลื่อนกลาด! 37กษัตริย์เซนนาเคอริบแห่งอัสซีเรียจึงทรงให้รื้อค่ายและถอนทัพกลับไปยังเมืองนีนะเวห์และประทับอยู่ที่นั่น

38วันหนึ่งขณะที่ทรงนมัสการอยู่ในวิหารของพระนิสรอคของพระองค์ อัดรัมเมเลคและชาเรเซอร์โอรสของพระองค์เองได้ปลงพระชนม์พระองค์ด้วยดาบ แล้วหนีไปยังดินแดนอารารัต และเอสารฮัดโดนโอรสอีกองค์หนึ่งของพระองค์ขึ้นครองราชย์แทน

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Isaiah 37:1-38

A sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ìdáǹdè Jerusalẹmu

1Nígbà tí ọba Hesekiah gbọ́ èyí, ó fa aṣọ rẹ̀ ya, ó sì fi aṣọ ọ̀fọ̀ bo ara rẹ̀, ó sì wọ inú tẹmpili Olúwa lọ. 2Òun sì rán Eliakimu alákòóso ààfin, Ṣebna akọ̀wé, àti aṣíwájú àwọn àlùfáà, gbogbo wọn nínú aṣọ ọ̀fọ̀ lọ sí ọ̀dọ̀ wòlíì Isaiah ọmọ Amosi. 3Wọ́n sọ fún un pé, “Báyìí ni Hesekiah wí: ọjọ́ òní jẹ́ ọjọ́ ìbànújẹ́, ìbáwí àti ẹ̀gàn gẹ́gẹ́ bí ìgbà ìbí àwọn ọmọdé tí kò sì ṣí agbára láti bí wọn. 4Ó lè jẹ́ pé Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò gbọ́ ọ̀rọ̀ ọ̀gágun ẹni tí ọ̀gá rẹ̀ ọba Asiria ti rán láti fi Ọlọ́run alààyè ṣe ẹlẹ́yà, àti pé òun ni yóò bá a wí nítorí àwọn ọ̀rọ̀ tí Olúwa Ọlọ́run rẹ ti gbọ́. Nítorí náà gbàdúrà fún àwọn tí ó ṣẹ́kù tí wọ́n sì wà láààyè.”

5Nígbà tí àwọn ìjòyè ọba Hesekiah dé ọ̀dọ̀ Isaiah, 6Isaiah sọ fún wọn pé, “Ẹ sọ fún ọ̀gá yín pé, ‘Ohun tí Olúwa sọ nìyìí: Má ṣe bẹ̀rù ohun tí ẹ ti gbọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ tí ọba Asiria tí ó wà nínú ìdè ti fi sọ̀rọ̀-òdì sí mi. 7Tẹ́tí sílẹ̀! Èmi yóò fi ẹ̀mí kan sínú rẹ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi jẹ́ pé bí o bá ti gbọ́ ìròyìn kan, òun yóò padà sí orílẹ̀-èdè rẹ̀, níbẹ̀ ni n ó sì ti jẹ́ kí wọn ké e lulẹ̀ pẹ̀lú idà.’ ”

8Nígbà tí ọ̀gágun gbọ́ pé ọba Asiria ti fi Lakiṣi sílẹ̀, ó padà sẹ́yìn, ó sì bá ọba tí ń bá Libina jà.

9Ní àkókò yìí Sennakeribu gbọ́ ìròyìn kan pé Tirakah ará Kuṣi ọba Ejibiti ń jáde bọ̀ wá bá òun jà. Nígbà tí ó gbọ́ èyí, ó rán oníṣẹ́ sí Hesekiah pẹ̀lú ọ̀rọ̀ wọ̀nyí: 10“Ẹ sọ fún Hesekiah ọba Juda pé: Má ṣe jẹ́ kí òrìṣà tí ìwọ gbẹ́kẹ̀lé tàn ọ́ jẹ nígbà tí ó sọ pé, ‘a kì yóò jọ̀wọ́ Jerusalẹmu fún ọba Asiria.’ 11Dájúdájú, ìwọ ti gbọ́ ohun tí ọba Asiria ti ṣe sí àwọn orílẹ̀-èdè, tí ó pa wọ́n run pátápátá. Ǹjẹ́ a ó ha dá ọ nídè bí? 12Ǹjẹ́ àwọn òrìṣà àwọn orílẹ̀-èdè tí àwọn baba ńlá mi parun ha gbà wọ́n sílẹ̀ bí àwọn òrìṣà Gosani, Harani, Reṣefu àti àwọn ènìyàn Edeni tí wọ́n wà ní Teli-Assari? 13Níbo ni ọba Hamati wà, ọba Arpadi, ọba ìlú Sefarfaimi tàbí Hena tàbí Iffa?”

Àdúrà Hesekiah

14Hesekiah gba ìwé náà lọ́wọ́ àwọn oníṣẹ́ ó sì kà á. Lẹ́yìn náà ni ó gòkè lọ sí tẹmpili Olúwa ó sì tẹ́ ìwé náà sílẹ̀ níwájú Olúwa. 15Hesekiah sì gbàdúrà sí Olúwa: 16Olúwa àwọn ọmọ-ogun, Ọlọ́run Israẹli, tí ó gúnwà láàrín àwọn kérúbù, ìwọ nìkan ni Ọlọ́run lórí i gbogbo ìjọba orílẹ̀ ayé. Ìwọ ti dá ọ̀run àti ayé. 17Tẹ́tí sílẹ̀, ìwọ Olúwa, kí o gbọ́, ya ojú rẹ, Ìwọ Olúwa, kí o rí i; tẹ́tí sí gbogbo ọ̀rọ̀ tí Sennakeribu rán láti fi àbùkù kan Ọlọ́run alààyè.

18“Òtítọ́ ni Olúwa pé àwọn ọba Asiria ti sọ àwọn ènìyàn àti ilẹ̀ wọn di asán. 19Wọ́n ti da àwọn òrìṣà wọn sínú iná wọ́n sì ti pa wọ́n run, nítorí àwọn wọ̀nyí kì í ṣe ọlọ́run bí kò ṣe igi àti òkúta lásán, tí a ti ọwọ́ ènìyàn ṣe. 20Nísinsin yìí, ìwọ Olúwa, Ọlọ́run wa, gbà wá lọ́wọ́ rẹ̀, tí ó fi jẹ́ pé gbogbo ìjọba ilẹ̀ ayé yóò fi mọ̀ pé Ìwọ, Ìwọ nìkan, Olúwa ni Ọlọ́run.”

Ìṣubú Sennakeribu

21Lẹ́yìn náà Isaiah ọmọ Amosi rán iṣẹ́ kan sí Hesekiah: “Èyí ni ohun tí Olúwa, Ọlọ́run Israẹli sọ pé: Nítorí pé ìwọ ti gbàdúrà sí mi nípa Sennakeribu ọba Asiria, 22èyí ni ọ̀rọ̀ tí Olúwa ti sọ nípa rẹ̀:

“Wúńdíá ọmọbìnrin Sioni

ti kẹ́gàn rẹ, ó sì ti fi ọ ṣe ẹlẹ́yà.

Ọmọbìnrin Jerusalẹmu

ti mi orí rẹ̀ bí ó ti ń sálọ.

23Ta ni ìwọ ti bú tí ìwọ sì ti sọ̀rọ̀-òdì sí?

Sí ta ní ìwọ ti gbé ohùn rẹ sókè

tí o sì gbé ojú rẹ sókè ní ìgbéraga?

Sí Ẹni Mímọ́ Israẹli!

24Nípa àwọn ìránṣẹ́ rẹ

Ìwọ ti sọ̀rọ̀ búburú sí Olúwa.

Tì wọ sì wí pé,

‘Pẹ̀lú ọ̀pọ̀ kẹ̀kẹ́ mi

ni èmi sì fi dé orí àwọn òkè ńlá,

sí ibi gíga jùlọ Lebanoni.

Èmi a sì ké igi kedari gíga rẹ̀ lulẹ̀,

àti ààyò igi firi rẹ̀.

Èmi ti dé ibi rẹ̀ tí ó ga jùlọ,

igbó rẹ̀ tí ó dára jùlọ.

25Èmi ti gbẹ́ kànga ní ilẹ̀ àjèjì

mo sì mu omi ní ibẹ̀,

pẹ̀lú àtẹ́lẹsẹ̀ mi

Èmi ti gbẹ́ gbogbo omi àwọn odò Ejibiti.’

26“Ṣé o kò tí ì gbọ́?

Tipẹ́tipẹ́ ni mo ti fìdí rẹ̀ mulẹ̀.

Láti ìgbà pípẹ́ ni mo ti ṣètò rẹ̀;

ní àkókò yìí ni mo mú wá sí ìmúṣẹ,

pé o ti sọ àwọn ìlú olódi di

àkójọpọ̀ àwọn òkúta

27Àwọn ènìyàn, tí agbára ti wọ̀ lẹ́wù,

ni wọ́n banújẹ́ tí a sì dójútì.

Wọ́n dàbí ohun ọ̀gbìn nínú pápá,

gẹ́gẹ́ bí ọ̀jẹ̀lẹ̀ èhíhù tuntun,

gẹ́gẹ́ bí i koríko tí ó ń hù lórí òrùlé,

tí ó jóná kí ó tó dàgbàsókè.

28“Ṣùgbọ́n mo mọ ibi tí o wà

àti ìgbà tí o wá tí o sì lọ

àti bí inú rẹ ṣe ru sí mi.

29Nítorí pé inú rẹ ru sí mi

àti nítorí pé orí kunkun rẹ ti

dé etí ìgbọ́ mi,

Èmi yóò fi ìwọ̀ mi sí ọ ní imú,

àti ìjẹ mi sí ọ lẹ́nu,

èmi yóò sì jẹ́ kí o padà

láti ọ̀nà tí o gbà wá.

30“Èyí ni yóò ṣe ààmì fún ọ Ìwọ Hesekiah:

“Ní ọdún yìí, ìwọ yóò jẹ ohun tí ó hù fúnrarẹ̀,

àti ní ọdún kejì ohun tí ó jáde láti ara rẹ.

Ṣùgbọ́n ní ọdún kẹta, ẹ gbìn kí ẹ sì kórè,

ẹ gbin ọgbà àjàrà kí ẹ sì jẹ èso wọn.

31Lẹ́ẹ̀kan sí i, àṣẹ́kù láti ilé Juda

yóò ta gbòǹgbò nísàlẹ̀ yóò sì ṣo èso lókè.

32Nítorí láti Jerusalẹmu ni àwọn àṣẹ́kù yóò ti wá,

àti láti òkè Sioni ni ikọ̀ àwọn tí ó sálà.

Ìtara Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni yóò mú èyí ṣẹ.

33“Nítorí náà, èyí ni ohun tí Olúwa wí nípa ọba Asiria:

“Òun kì yóò wọ ìlú yìí wá

tàbí ta ẹyọ ọfà kan níhìn-ín

Òun kì yóò wá síwájú rẹ pẹ̀lú asà

tàbí kí ó kó dágunró sílẹ̀ fún un.

34Nípa ọ̀nà tí ó gbà wá náà ni yóò padà lọ;

òun kì yóò wọ inú ìlú yìí,”

ni Olúwa wí.

35“Èmi yóò dáàbò bo ìlú yìí èmi ó sì gbà á là,

nítorí mi àti nítorí Dafidi ìránṣẹ́ mi!”

36Lẹ́yìn náà ni angẹli Olúwa jáde lọ ó sì pa ọ̀kẹ́ mẹ́sàn-án ó lé ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ènìyàn ní i ibùdó àwọn Asiria. Nígbà tí àwọn ènìyàn yìí jí ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì gbogbo wọn ti dòkú! 37Nítorí náà Sennakeribu ọba Asiria fọ́ bùdó ó sì pẹsẹ̀dà. Òun sì padà sí Ninefe, ó sì dúró síbẹ̀.

38Ní ọjọ́ kan, bí ó ti ń jọ́sìn nínú tẹmpili Nisroki òrìṣà rẹ̀, àwọn ọmọ rẹ̀ Adrameleki àti Ṣareseri gé e lulẹ̀ pẹ̀lú idà, wọ́n sì sálọ sí ilẹ̀ Ararati. Bẹ́ẹ̀ ni Esarhadoni ọmọ rẹ̀ sì gba ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba.