ปัญญาจารย์ 12 – TNCV & YCB

Thai New Contemporary Bible

ปัญญาจารย์ 12:1-14

1เจ้าจงระลึกถึงพระผู้สร้างของเจ้า

ตลอดวันเวลาที่เจ้ายังเยาว์วัย

ก่อนยามทุกข์ลำเค็ญจะมาถึง

และปีเดือนเหล่านั้นใกล้เข้ามา เมื่อเจ้าจะพูดว่า

“ฉันไม่เห็นชื่นชมอะไรในชีวิต”

2ก่อนดวงอาทิตย์และแสงสว่าง

ดวงจันทร์และดวงดาวจะมืดมัวลง

ก่อนเมฆจะหวนกลับมาภายหลังฝน

3เมื่อคนเฝ้าเรือนตัวสั่น

และชายฉกรรจ์ค้อมตัวลง

เมื่อคนโม่แป้งหยุดโม่เพราะเหลืออยู่ไม่กี่คน

และบรรดาผู้ที่มองผ่านหน้าต่างเริ่มมองเห็นไม่ชัด

4เมื่อประตูที่เปิดสู่ถนนนั้นถูกปิดไป

และเสียงโม่เบาลง

เมื่อคนเราตื่นขึ้นยามแว่วเสียงนกร้อง

แต่เสียงเพลงทั้งปวงของพวกมันก็แผ่วลง

5เมื่อคนเรากลัวความสูง

และกลัวภัยอันตรายในท้องถนน

เมื่อต้นอัลมอนด์ผลิดอก

ตั๊กแตนลากขาเดินไป

และความปรารถนาไม่ถูกปลุกเร้าอีกต่อไป

เมื่อนั้นมนุษย์ก็ไปสู่บ้านนิรันดร์ของตน

และคนไว้ทุกข์เดินไปตามถนน

6จงระลึกถึงพระองค์ ก่อนที่สายเงินจะขาดผึง

หรือชามทองคำจะแตก

ก่อนที่คนโทจะแหลกละเอียดที่น้ำพุ

หรือล้อหักเสียที่บ่อน้ำ

7เมื่อนั้นธุลีดินจะกลับคืนสู่แผ่นดินที่มันจากมา

และจิตวิญญาณกลับคืนสู่พระเจ้าผู้ประทานให้

8ปัญญาจารย์12:8 หรือผู้นำของชุมชนเช่นเดียวกับข้อ 9กล่าวว่า “อนิจจัง! อนิจจัง! ทุกสิ่งล้วนอนิจจัง!”

บทสรุป

9ปัญญาจารย์นั้นไม่เพียงแต่เฉลียวฉลาด แต่ยังถ่ายทอดความรู้ให้แก่ประชาชนอีกด้วย เขาใคร่ครวญ ค้นคว้า และรวบรวมสุภาษิตต่างๆ ไว้ให้เป็นระบบ 10เขาเสาะหาถ้อยคำที่เหมาะเจาะ สิ่งที่เขาเขียนนั้นเที่ยงตรงและเป็นจริง 11วาจาของปราชญ์เหมือนประตัก ประมวลภาษิตของเขาเหมือนตะปูตรึงแน่น ซึ่งองค์พระผู้เลี้ยงประทานให้ 12ลูกเอ๋ย จงระวังสิ่งที่ต่อเติมเสริมแต่งไปกว่านั้น จะทำหนังสือมากๆ ก็ไม่มีจบสิ้นและเรียนมากก็เหนื่อยกาย

13บัดนี้ก็ได้ฟังกันมาหมดสิ้นแล้ว

บทสรุปก็คือ

จงยำเกรงพระเจ้าและรักษาพระบัญญัติของพระองค์

เพราะนี่เป็นหน้าที่ทั้งหมดของมนุษย์

14เพราะพระเจ้าจะทรงพิพากษาการกระทำทุกอย่าง

รวมถึงทุกสิ่งที่ปกปิดไว้

ไม่ว่าดีหรือชั่ว

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Oniwaasu 12:1-14

1Rántí Ẹlẹ́dàá rẹ

ní ọjọ́ èwe rẹ,

nígbà tí ọjọ́ ibi kò tí ì dé

àti tí ọdún kò tí ì ní súnmọ́ etílé, nígbà tí ìwọ yóò wí pé,

“Èmi kò ní ìdùnnú nínú wọn”

2Kí oòrùn àti ìmọ́lẹ̀

àti òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀ tó ṣókùnkùn,

àti kí àwọsánmọ̀ tó padà lẹ́yìn òjò;

3Nígbà tí olùṣọ́ ilé yóò wárìrì

tí àwọn ọkùnrin alágbára yóò tẹríba,

nígbà tí àwọn tí ó ń lọ dákẹ́ nítorí pé wọn kò pọ̀,

tí àwọn tí ń wo òde láti ojú fèrèsé yóò ṣókùnkùn;

4Nígbà tí ìlẹ̀kùn sí ìgboro yóò tì

tí ariwo ọlọ yóò dákẹ́;

nígbà tí àwọn ènìyàn yóò dìde sí ariwo àwọn ẹyẹ

ṣùgbọ́n gbogbo orin wọn yóò máa lọ ilẹ̀.

5Nígbà tí ènìyàn yóò bẹ̀rù ibi gíga

àti ti ìfarapa ní ìgboro;

nígbà tí igi almondi yóò tanná

àti tí ẹlẹ́ǹgà yóò wọ́ ara rẹ̀ lọ

tí ìfẹ́ kò sì ní ru sókè mọ́

nígbà náà ni ènìyàn yóò lọ ilé rẹ́ ayérayé

tí àwọn aṣọ̀fọ̀ yóò máa rìn kiri ìgboro.

6Rántí rẹ̀ kí okùn fàdákà tó já,

tàbí kí ọpọ́n wúrà tó fọ́;

kí iṣà tó fọ́ níbi ìsun,

tàbí kí àyíká kẹ̀kẹ́ kí ó tó kán níbi kànga.

7Tí erùpẹ̀ yóò sì padà sí ilẹ̀ ibi tí ó ti wà,

tí ẹ̀mí yóò sì padà sọ́dọ̀ Ọlọ́run tí ó fi í fún ni.

8“Asán! Asán!” ni Oniwaasu wí.

“Gbogbo rẹ̀ asán ni!”

Òpin gbogbo ọrọ̀

9Kì í ṣe wí pé Oniwaasu jẹ́ ọlọ́gbọ́n nìkan, ṣùgbọ́n ó tún kọ́ àwọn ènìyàn ní ìmọ̀. Ó rò ó dáradára ó sì ṣe àwárí, ó sì gbé ọ̀pọ̀lọpọ̀ òwe kalẹ̀ lẹ́sẹẹsẹ. 10Oniwaasu wádìí láti rí àwọn ọ̀rọ̀ tí ó tọ̀nà, ohun tí ó kọ sì dúró ṣinṣin ó sì jẹ́ òtítọ́.

11Ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n dàbí ẹ̀gún, àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ wọn sì dàbí ìṣó tí a kàn pọ̀ dáradára, tí olùṣọ́-àgùntàn kan fi fún ni. 12Àti síwájú láti inú èyí, Ọmọ mi, gba ìmọ̀ràn.

Nínú ìwé púpọ̀, òpin kò sí, ìwé kíkà púpọ̀ a máa mú ara ṣàárẹ̀.

13Nísinsin yìí,

òpin gbogbo ọ̀rọ̀ tí a gbọ́ ni pé:

Bẹ̀rù Ọlọ́run, kí o sì pa òfin rẹ̀ mọ́,

nítorí èyí ni ojúṣe gbogbo ènìyàn.

14Nítorí Ọlọ́run yóò ṣe ìdájọ́ olúkúlùkù iṣẹ́

àti ohun ìkọ̀kọ̀,

kì bá à ṣe rere kì bá à ṣe búburú.