กันดารวิถี 6 TNCV - Numeri 6 YCB

กันดารวิถี
Elegir capítulo 6

Thai New Contemporary Bible

กันดารวิถี 6:1-27

นาศีร์

1องค์พระผู้เป็นเจ้าตรัสกับโมเสสว่า 2“จงแจ้งชนอิสราเอลว่า ‘ชายหรือหญิงคนใดถวายสัตย์ปฏิญาณเป็นพิเศษว่าจะเป็นนาศีร์อุทิศตนแด่องค์พระผู้เป็นเจ้า 3เขาต้องงดเครื่องดื่มมึนเมาหรือเหล้าองุ่น น้ำองุ่น ผลองุ่นสดหรือลูกเกด และน้ำส้มสายชูที่ได้จากเหล้าองุ่น 4ตลอดระยะเวลาที่เขาเป็นนาศีร์นั้น เขาจะไม่กินสิ่งใดที่มาจากต้นองุ่น แม้แต่เมล็ดหรือเปลือกองุ่น

5“ ‘ตลอดช่วงนั้นเขาจะไม่ตัดผม เขาต้องรักษาตนให้บริสุทธิ์ เขาจึงต้องไว้ผมยาว 6ตลอดระยะเวลาที่เขาเป็นนาศีร์6:6 ภาษาฮีบรูว่าตลอดระยะเวลาที่เขาแยกตัวออกเช่นเดียวกับข้อ 8 และ 12ถวายแด่องค์พระผู้เป็นเจ้าเขาจะต้องไม่ย่างกรายเข้าใกล้ซากศพ 7แม้ว่าจะเป็นศพของบิดามารดาหรือพี่น้องชายหญิง เขาจะต้องไม่ทำตัวให้เป็นมลทินตามระเบียบพิธี เพราะสัญลักษณ์แห่งการเป็นนาศีร์อยู่บนศีรษะของเขา 8ตลอดระยะเวลาที่เขาเป็นนาศีร์ เขาต้องชำระตัวให้บริสุทธิ์แยกไว้แด่องค์พระผู้เป็นเจ้า

9“ ‘หากมีคนมาตายอยู่ข้างตัวเขาโดยปัจจุบันทันด่วน ทำให้ผมที่เขาถวายปฏิญาณไว้เป็นมลทิน เขาต้องโกนศีรษะในวันชำระตัวคือวันที่เจ็ด 10ในวันที่แปดเขาต้องนำนกเขาหรือนกพิราบรุ่นสองตัวมามอบแก่ปุโรหิตตรงทางเข้าเต็นท์นัดพบ 11ปุโรหิตจะถวายนกตัวหนึ่งเป็นเครื่องบูชาไถ่บาป อีกตัวหนึ่งเป็นเครื่องเผาบูชาเพื่อลบบาปสำหรับผู้นั้น เพราะเขาได้ทำบาปโดยการอยู่ใกล้ซากศพ ในวันเดียวกันนั้นเขาต้องชำระศีรษะถวายอีกครั้ง 12เขาต้องอุทิศตนแด่องค์พระผู้เป็นเจ้าตลอดระยะเวลาที่เขาเป็นนาศีร์ และนำแกะผู้อายุหนึ่งขวบตัวหนึ่งมาเป็นเครื่องบูชาลบความผิด วันอื่นๆ ก่อนหน้านั้นไม่นับ เพราะเขาได้เป็นมลทินตลอดระยะเวลาที่เขาเป็นนาศีร์

13“ ‘เมื่อครบกำหนดการเป็นนาศีร์ตามกฎของนาศีร์แล้ว เขาจะต้องมาที่ทางเข้าเต็นท์นัดพบ 14และถวายสัตว์ที่ไม่มีตำหนิแด่องค์พระผู้เป็นเจ้าคือ ถวายลูกแกะตัวผู้อายุหนึ่งขวบหนึ่งตัวเป็นเครื่องเผาบูชา ลูกแกะตัวเมียอายุหนึ่งขวบหนึ่งตัวเป็นเครื่องบูชาไถ่บาป และแกะผู้อีกหนึ่งตัวเป็นเครื่องสันติบูชา 15พร้อมกับธัญบูชาและเครื่องดื่มบูชา ขนมปังไม่ใส่เชื้อหนึ่งกระจาดอันได้แก่ ขนมปังที่ทำจากแป้งละเอียดเคล้าน้ำมัน และขนมปังแผ่นบางทาด้วยน้ำมัน

16“ ‘ปุโรหิตจะยื่นถวายของเหล่านี้ต่อหน้าองค์พระผู้เป็นเจ้าแล้วถวายเครื่องบูชาไถ่บาปและเครื่องเผาบูชา 17จากนั้นเขาจะถวายขนมปังไม่ใส่เชื้อกระจาดนั้น และแกะตัวผู้เป็นเครื่องสันติบูชาพร้อมด้วยธัญบูชาและเครื่องดื่มบูชาแด่องค์พระผู้เป็นเจ้า

18“ ‘แล้วนาศีร์ต้องโกนผมออกตามที่ปฏิญาณอุทิศตนนั้นที่ทางเข้าเต็นท์นัดพบ และนำผมนั้นไปใส่ในไฟที่เผาเครื่องสันติบูชาอยู่

19“ ‘เมื่อนาศีร์นั้นโกนผมเสร็จแล้ว ปุโรหิตจะนำโคนขาหน้าของแกะผู้ที่ต้มแล้ว ขนมปังไม่ใส่เชื้อ และขนมปังแผ่นบางไม่ใส่เชื้อจากกระจาดนั้นใส่ไว้ในมือของเขา 20แล้วปุโรหิตจะยื่นถวายสิ่งเหล่านั้นต่อหน้าองค์พระผู้เป็นเจ้าเป็นเครื่องบูชายื่นถวาย ทั้งหมดนั้นเป็นของบริสุทธิ์ เป็นส่วนของปุโรหิตพร้อมกับเนื้ออกและโคนขาซึ่งยื่นถวายแด่พระองค์ หลังจากนั้นนาศีร์ผู้นั้นจึงดื่มเหล้าองุ่นได้

21“ ‘ทั้งหมดนี้คือบทบัญญัติของนาศีร์ ผู้ที่ถวายปฏิญาณแด่องค์พระผู้เป็นเจ้าตามการอุทิศตัวของเขา นอกจากนี้เขาจะถวายสิ่งอื่นอีกก็ได้ แต่เขาจะต้องทำตามคำปฏิญาณ ตามกฎของนาศีร์ให้สำเร็จ’ ”

พรจากปุโรหิต

22องค์พระผู้เป็นเจ้าตรัสกับโมเสสว่า 23“จงบอกอาโรนกับบุตรชายว่า ‘นี่เป็นวิธีที่เจ้าจะอวยพรชนอิสราเอล จงกล่าวแก่พวกเขาดังนี้

24“ ‘ “ขอองค์พระผู้เป็นเจ้าทรงอำนวยพร

และทรงพิทักษ์รักษาท่าน

25ขอให้พระพักตร์ขององค์พระผู้เป็นเจ้าทอแสงเหนือท่าน

ขอพระองค์ทรงเมตตากรุณาท่าน

26ขอองค์พระผู้เป็นเจ้าทรงโปรดปรานท่าน6:26 หรือองค์พระผู้เป็นเจ้าทรงหันพระพักตร์มาหาท่าน

และประทานสันติสุขแก่ท่าน” ’

27“ดังนั้นอาโรนกับบุตรชายจะประทับนามของเราเหนืออิสราเอล และเราจะอวยพรพวกเขา”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Numeri 6:1-27

Òfin fún àwọn Nasiri

1Olúwa sọ fún Mose pé: 2“Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé: ‘Bí ọkùnrin tàbí obìnrin kan bá jẹ́ ẹ̀jẹ́ pàtàkì, ẹ̀jẹ́ ìyara-ẹni-sọ́tọ̀ sí Olúwa nípa àìgé irun orí (Nasiri): 36.3: Lk 1.15.Irú ẹni bẹ́ẹ̀ gbọdọ̀ yàgò fún wáìnì tàbí ọtí líle, ọtí wáìnì kíkan àti àwọn ohun mímu mìíràn tó bá kan. Kò gbọdọ̀ mu èso àjàrà tàbí kí ó jẹ èso àjàrà tútù tàbí gbígbẹ. 4Níwọ́n ìgbà tí ó sì jẹ́ Nasiri, ní kò gbọdọ̀ jẹ ohunkóhun tí a fi èso àjàrà ṣe, ìbá à ṣe kóró tàbí èèpo rẹ̀.

5“ ‘Ní gbogbo ìgbà ẹ̀jẹ́ ìyàsọ́tọ̀ rẹ̀ yìí, kí abẹ kankan má ṣe kàn án ní orí. Ó gbọdọ̀ jẹ́ mímọ́ títí tí àkókò ìyàsọ́tọ̀ rẹ̀ sí Olúwa yóò fi pé; ó gbọdọ̀ jẹ́ kí irun orí rẹ̀ gùn.

6“ ‘Ní gbogbo àkókò ìyàsọ́tọ̀ rẹ̀ sí Olúwa kò gbọdọ̀ súnmọ́ òkú ènìyàn. 7Ìbá à ṣe òkú baba, àti ìyá rẹ̀, ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ọkùnrin tàbí obìnrin tàbí àbúrò rẹ̀, kò gbọdọ̀ sọ ara rẹ̀ di aláìmọ́ nítorí wọn, nítorí pé ààmì ìyàsọ́tọ̀ rẹ̀ sí Ọlọ́run wà ní orí rẹ̀. 8Ní gbogbo àsìkò ìyàsọ́tọ̀ rẹ̀ yìí, ó jẹ́ mímọ́ sí Olúwa.

9“ ‘Bí ẹnìkan bá kú ní ọ̀dọ̀ rẹ̀ ní òjijì, tí ó sì ba irun rẹ̀ tó yà sọ́tọ̀ jẹ́; ó gbọdọ̀ gé irun rẹ̀ ní ọjọ́ ìwẹ̀nùmọ́ rẹ̀ èyí tí í ṣe ọjọ́ keje. 10Ní ọjọ́ kẹjọ, yóò mú àdàbà méjì àti ọmọ ẹyẹlé méjì wá sọ́dọ̀ àlùfáà ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé. 11Àlùfáà yóò fi ọ̀kan rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti èkejì fún ẹbọ sísun láti fi ṣe ètùtù fún un nítorí pé ó ti ṣẹ̀ nípa wíwà níbi tí òkú ènìyàn wà. Yóò sì ya orí rẹ̀ sí mímọ́ ní ọjọ́ náà gan an. 12Ó gbọdọ̀ ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ sí Olúwa fún àkókò ìyàsọ́tọ̀ rẹ̀, ó sì gbọdọ̀ mú akọ ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan wá gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹ̀bi. Kò sì ní í ka àwọn ọjọ́ ìyàsọ́tọ̀ rẹ̀ ti tẹ́lẹ̀ nítorí pé ó tí ba ara rẹ̀ jẹ́ ní àkókò ìyàsọ́tọ̀ rẹ̀.

136.13-21: Ap 21.24,26.“ ‘Èyí ni òfin fún Nasiri nígbà tí àkókò ìyàsọ́tọ̀ rẹ̀ bá pé. Wọn ó mu wá sí ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé. 14Níbẹ̀ ni yóò ti mú ọrẹ wá fún Olúwa, akọ ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan tí kò ní àbùkù fún ẹbọ sísun àti ẹgbọrọ-àgùntàn ọlọ́dún kan, tí kò ní àbùkù fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, àgbò kan tí kò ní àbùkù fún ọrẹ àlàáfíà, 15pẹ̀lú ọrẹ ohun jíjẹ àti ọrẹ ohun mímu, apẹ̀rẹ̀ àkàrà tí a kò fi ìwúkàrà ṣe, àkàrà tí a fi ìyẹ̀fun dáradára pò mọ́ òróró àti àkàrà fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ tí a fi òróró sọjọ̀ lé lórí.

16“ ‘Àlùfáà yóò gbé gbogbo rẹ̀ wá síwájú Olúwa, yóò sì rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti ẹbọ sísun. 17Àlùfáà yóò fi àgbò náà rú ẹbọ àlàáfíà sí Olúwa, pẹ̀lú apẹ̀rẹ̀ àkàrà tí kò ní ìwúkàrà; yóò rú ẹbọ ohun jíjẹ àti ọrẹ ohun mímu.

18“ ‘Nígbà náà ni Nasiri náà yóò fá irun ìyàsọ́tọ̀ rẹ̀ ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé. Yóò fi irun náà sínú iná tó wà lábẹ́ ẹbọ àlàáfíà.

19“ ‘Lẹ́yìn tí Nasiri bá ti fá irun ìyàsọ́tọ̀ rẹ̀ tan, àlùfáà yóò mú apá àgbò bíbọ̀, àkàrà aláìwú kan àti àkàrà fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ tí kò ní ìwúkàrà láti inú apẹ̀rẹ̀ yóò sì kó gbogbo rẹ̀ lé e lọ́wọ́. 20Àlùfáà yóò fi gbogbo rẹ̀ níwájú Olúwa gẹ́gẹ́ bí ẹbọ fífì, wọ́n jẹ́ mímọ́, wọ́n sì jẹ́ ti àlùfáà pẹ̀lú igẹ̀ tí a fì àti itan tí wọ́n mú wá. Lẹ́yìn èyí, Nasiri náà lè mu wáìnì.

21“ ‘Èyí ni òfin Nasiri tó jẹ́ ẹ̀jẹ́, ọrẹ rẹ̀ sí Olúwa, yóò wà ní ìbámu pẹ̀lú ìyàsọ́tọ̀ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Nasiri, ní àfikún sí àwọn ohun mìíràn tó lágbára láti mú wá. Ó gbọdọ̀ mú ẹ̀jẹ́ tó jẹ́ ṣe gẹ́gẹ́ bí òfin Nasiri.’ ”

Ìbùkún àlùfáà

22Olúwa sọ fún Mose pé, 23“Sọ fún Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ pé, ‘Báyìí ni kí ẹ ṣe máa súre fún àwọn ọmọ Israẹli. Ẹ sọ fún wọn pé:

24“ ‘ “Kí Olúwa bùkún un yín

Kí ó sì pa yín mọ́.

25Olúwa kí o mú ojú rẹ̀ kí ó mọ́lẹ̀ sí i yín lára.

Kí ó sì ṣàánú fún un yín.

26Olúwa bojú wò yín;

Kí ó sì fún un yín ní àlàáfíà.” ’

27“Báyìí ni wọn ó ṣe fi orúkọ mi sára àwọn ọmọ Israẹli, Èmi ó sì bùkún wọn.”