กันดารวิถี 5 TNCV - Numeri 5 YCB

กันดารวิถี
Elegir capítulo 5

Thai New Contemporary Bible

กันดารวิถี 5:1-31

ความบริสุทธิ์ของค่าย

1องค์พระผู้เป็นเจ้าตรัสกับโมเสสว่า 2“จงสั่งประชากรอิสราเอลให้ส่งคนที่เป็นโรคผิวหนัง5:2 โดยปกติแปลว่า โรคเรื้อน แต่คำภาษาฮีบรูอาจหมายถึงโรคผิวหนังชนิดต่างๆ ไม่จำเป็นต้องหมายถึงโรคเรื้อนเท่านั้นผู้มีสิ่งที่หลั่งออกหรือผู้ที่เป็นมลทินตามระเบียบพิธีเพราะไปแตะต้องซากศพ ออกไปจากค่าย 3ไม่ว่าจะเป็นหญิงหรือชาย จงส่งคนเหล่านี้ออกไปนอกค่าย เพื่อไม่ให้เป็นมลทินแก่ค่ายพักซึ่งเราอยู่ท่ามกลางพวกเขา” 4ชาวอิสราเอลก็ปฏิบัติตามโดยส่งคนเหล่านั้นออกไปนอกค่ายตามที่องค์พระผู้เป็นเจ้าทรงบัญชาโมเสส

การชดใช้เมื่อทำผิด

5องค์พระผู้เป็นเจ้าตรัสกับโมเสสว่า 6“จงแจ้งประชากรอิสราเอลว่า ‘เมื่อหญิงหรือชายใดทำผิดต่อคนอื่นอย่างหนึ่งอย่างใด ผู้นั้นย่อมมีความผิดเพราะไม่ซื่อสัตย์ต่อองค์พระผู้เป็นเจ้า 7เขาจะต้องสารภาพบาปและชดใช้เต็มจำนวนตามความเสียหาย และชดใช้เพิ่มอีกหนึ่งในห้าให้แก่ผู้เสียหาย 8แต่หากผู้เสียหายไม่มีญาติสนิทที่จะรับแทน ค่าชดใช้นั้นเป็นขององค์พระผู้เป็นเจ้าและต้องนำไปมอบแก่ปุโรหิตพร้อมด้วยแกะตัวผู้สำหรับขออภัยโทษบาปให้เขา 9ของถวายอันบริสุทธิ์ทั้งหมดที่ประชากรอิสราเอลนำมามอบแก่ปุโรหิตถือเป็นของปุโรหิต 10ของถวายอันบริสุทธิ์ของแต่ละคนเป็นกรรมสิทธิ์ของเขาเอง แต่สิ่งที่ยกให้ปุโรหิตจะเป็นของปุโรหิต’ ”

ทดสอบภรรยาที่ไม่ซื่อสัตย์

11แล้วองค์พระผู้เป็นเจ้าตรัสกับโมเสสว่า 12“จงแจ้งประชากรอิสราเอลว่า ‘ภรรยาของชายคนใดคบชู้และไม่ซื่อสัตย์ต่อเขา 13โดยไปนอนกับชายอื่นและยังเป็นความลับ ไม่เป็นที่ประจักษ์ต่อสามี (เพราะว่าไม่มีพยานหลักฐานและจับไม่ได้คาหนังคาเขา) 14และถ้าสามีรู้สึกหึงหวง และสงสัยในตัวภรรยาของตน ไม่ว่าภรรยาจะทำผิดหรือไม่ก็ตาม 15เขาจะต้องพาภรรยาและเครื่องบูชาของเธอคือแป้งบาร์เลย์ประมาณ 2 ลิตร5:15 ภาษาฮีบรูว่า หนึ่งในสิบเอฟาห์มาหาปุโรหิตโดยไม่ต้องเคล้าน้ำมันหรือโรยเครื่องหอม เพราะเป็นธัญบูชาเรื่องความหึงหวง และเป็นเครื่องบูชาที่เตือนให้ระลึกถึงความผิด

16“ ‘ปุโรหิตจะพานางมายืนอยู่ต่อหน้าองค์พระผู้เป็นเจ้า 17จากนั้นเขาจะเอาน้ำบริสุทธิ์บรรจุในภาชนะดินเผา ผสมฝุ่นที่พื้นพลับพลาลงในน้ำนั้น 18หลังจากปุโรหิตพานางมายืนอยู่ต่อหน้าองค์พระผู้เป็นเจ้า เขาจะปล่อยผมของนาง และให้นางถือเครื่องบูชาที่เตือนให้ระลึกถึงความผิดและธัญบูชาเรื่องความหึงหวง ในขณะที่ปุโรหิตถือน้ำขมแห่งคำสาป 19ปุโรหิตจะให้นางสาบานตนแล้วพูดกับนางว่า “หากไม่มีชายอื่นหลับนอนกับเจ้า และเจ้าไม่ได้หลงผิด และไม่เป็นมลทินขณะอยู่กินกับสามีของเจ้า ขอให้น้ำขมที่นำคำสาปแช่งมานี้ไม่ทำอันตรายเจ้า 20แต่หากเจ้าหลงผิดขณะที่ยังอยู่กินกับสามี และเจ้าได้ทำตัวให้เป็นมลทินโดยหลับนอนกับชายอื่นที่ไม่ใช่สามี” 21จากนั้นปุโรหิตจะให้นางสาบานว่า “ขอองค์พระผู้เป็นเจ้าทรงทำให้ประชากรของเจ้าสาปแช่งและประณามเจ้าเมื่อพระองค์ทำให้เจ้าแท้งลูกและเป็นหมัน5:21 หรือทำให้ท้องเจ้าบวมและโคนขาเจ้าเสียไปเช่นเดียวกับข้อ 22 และ 27 22ขอให้น้ำนี้นำคำสาปแช่งเข้าสู่ร่างกายของเจ้า ทำให้เจ้าแท้งลูกและเป็นหมัน”

“ ‘แล้วนางต้องกล่าวว่า “อาเมน ขอให้เป็นไปตามนั้นเถิด5:22 ภาษาฮีบรูว่าอาเมน อาเมน

23“ ‘ปุโรหิตจะเขียนคำสาปแช่งเหล่านี้ลงบนหนังสือม้วน แล้วนำมาล้างออกในน้ำขมนี้ 24แล้วปุโรหิตจะให้นางดื่มน้ำขมแห่งคำสาปแช่ง น้ำนี้จะเข้าไปในตัวนางและทำให้นางทุกข์ทรมาน 25ปุโรหิตจะรับธัญบูชาเรื่องความหึงหวงจากมือของนาง นำมายื่นถวายต่อหน้าองค์พระผู้เป็นเจ้า แล้วนำมาที่แท่นบูชา 26ต่อจากนั้นปุโรหิตจะกอบธัญบูชาขึ้นมากำมือหนึ่ง เป็นเครื่องบูชาส่วนอนุสรณ์ เผาบนแท่นบูชา แล้วให้นางดื่มน้ำนี้ 27หากนางได้ทำตัวให้เป็นมลทินและไม่ซื่อสัตย์ต่อสามี เมื่อปุโรหิตให้นางดื่มน้ำที่นำการสาปแช่งมา น้ำจะเข้าไปในตัวของนางและทำให้นางทุกข์ทรมานอย่างแสนสาหัส ทำให้นางเป็นหมันหรือแท้งลูกไป นางจะเป็นที่สาปแช่งในหมู่ประชากรของนาง 28แต่หากนางไม่เป็นมลทินและบริสุทธิ์ ไม่ได้คบชู้ นางจะพ้นผิดและจะสามารถมีลูกได้

29“ ‘นี่คือบทบัญญัติเรื่องความหึงหวง เมื่อภรรยาได้หลงผิดและทำตัวให้เป็นมลทินโดยนอกใจหรือมีชู้ 30หรือเมื่อสามีรู้สึกหึงหวงและสงสัยในตัวภรรยา ปุโรหิตจะนำนางมายืนอยู่ต่อหน้าองค์พระผู้เป็นเจ้าและดำเนินการตามที่กล่าวมาแล้ว 31สามีของนางจะไม่ต้องรับผิดใดๆ แต่นางต้องรับผลเพราะบาปของนาง’ ”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Numeri 5:1-31

Wíwà ní mímọ́ ibùdó

1Olúwa sọ fún Mose pé: 25.2,3: Nu 12.14,15.“Pàṣẹ fún àwọn ọmọ Israẹli pé kí wọn ó lé ẹnikẹ́ni tó bá ní ẹ̀tẹ̀, ìtújáde ara ní oríṣìíríṣìí tàbí ẹni tó jẹ́ aláìmọ́ nípa fífọwọ́ kan òkú. 3Irú ẹni bẹ́ẹ̀ yálà ọkùnrin tàbí obìnrin, ẹ lé wọn jáde kúrò nínú ibùdó kí wọn má ba à ba ibùdó wọn jẹ́ níbi tí èmi ń gbé láàrín wọn” 4Àwọn ọmọ Israẹli sì ṣe bẹ́ẹ̀; wọ́n lé wọn jáde kúrò nínú ibùdó. Wọn ṣe gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti sọ fún Mose.

Ìjẹ́wọ́ àti àtúnṣe

55.5-8: El 22.7-15; Le 6.1-7.Olúwa sọ fún Mose pé: 6“Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli: ‘Nígbà tí ọkùnrin kan tàbí obìnrin kan bá ṣẹ̀ ara wọn lọ́nà kan tàbí òmíràn, tí wọ́n sì ṣe àìṣòótọ́ sí Olúwa, ẹni náà jẹ̀bi. 7Ó gbọdọ̀ jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ tí ó sẹ̀. Ó gbọdọ̀ san ẹ̀san rẹ̀ ní ojú owó, kí ó sì fi ìdámárùn-ún rẹ̀ lé e, kí ó sì fi fún ẹni tí Òun jẹ̀bi rẹ̀. 8Ṣùgbọ́n bí irú ẹni bẹ́ẹ̀ kò bá ní ìbátan tí ó súnmọ́ ọn tí ó lè ṣe àtúnṣe àṣìṣe rẹ̀ náà fún, àtúnṣe náà jẹ́ ti Olúwa, ẹ sì gbọdọ̀ ko fún àlùfáà pẹ̀lú àgbò tí a fi ṣe ètùtù fún ẹni náà 9Gbogbo ọrẹ ohun mímọ́ tí àwọn ọmọ Israẹli bá mú wá fún àlùfáà jẹ́ tirẹ̀. 10Ọrẹ ohun mímọ́ ẹnìkọ̀ọ̀kan jẹ́ ti òun nìkan Ṣùgbọ́n ohunkóhun tó bá fún àlùfáà yóò jẹ́ ti àlùfáà.’ ”

Àyẹ̀wò fún aláìṣòótọ́ ìyàwó

11Olúwa sọ fún Mose wí pé, 12“Bá àwọn ọmọ Israẹli sọ̀rọ̀ kí o sọ fún wọn pé: ‘Bí ìyàwó ọkùnrin kan bá yapa tó sì ṣe àìṣòótọ́ sí i, 13Nípa mímú kí ọkùnrin mìíràn bá a lòpọ̀ tí ó sì fi èyí pamọ́ fún ọkọ rẹ̀, tí a kò si gbá a mú nínú ìwà àìmọ́ rẹ̀ (nítorí pé kò sí ẹlẹ́rìí àti pé wọn kò ká a mọ́ nígbà tí ó ń dẹ́ṣẹ̀ náà). 14Ṣùgbọ́n tí ẹ̀mí owú jíjẹ bá bà lé ọkọ rẹ̀ dé bi pé ó ń funra sí ìyàwó rẹ̀ yìí tí ìyàwó rẹ̀ sì wà ní àìmọ́ nítòótọ́, tàbí tí ẹ̀mí owú bá bà lé ọkùnrin kan tó sì ń jowú ìyàwó rẹ̀ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó wà ní mímọ́, 15nígbà náà ni ọkùnrin yìí yóò mú ìyàwó rẹ̀ lọ sọ́dọ̀ àlùfáà. Ọkùnrin náà yóò sì mú ọrẹ tí a yàn fún obìnrin náà, ìdámẹ́wàá òṣùwọ̀n efa ìyẹ̀fun barle. Kò gbọdọ̀ da òróró sí i, bẹ́ẹ̀ ni kò gbọdọ̀ fi tùràrí dídùn sí i nítorí pé ẹbọ ohun jíjẹ fún owú ni, èyí ti n mú ẹ̀ṣẹ̀ wá sí ìrántí.

16“ ‘Àlùfáà yóò sì mú un wá síwájú Olúwa. 17Àlùfáà yóò sì bu erùpẹ̀ ilẹ̀ àgọ́ sínú omi mímọ́ tó bù láti ìkòkò amọ̀, 18Lẹ́yìn èyí, àlùfáà yóò mú obìnrin náà dúró níwájú Olúwa yóò sì tú irun orí obìnrin náà lé e lọ́wọ́, èyí ni ẹbọ ohun jíjẹ ti owú, àlùfáà fúnrarẹ̀ yóò sì gbé omi kíkorò tí ń mú ègún lọ́wọ́. 19Àlùfáà yóò sì mú obìnrin náà búra, yóò wí pé, “Bí ọkùnrin mìíràn kò bá bá ọ lòpọ̀, tí ó kò sì yapa, tí o kò sì di aláìmọ́ níwọ̀n ìgbà tí ó wà lábẹ́ àṣẹ ọkọ rẹ̀, a jẹ́ pé omi kíkorò tí ń mú ègún wá yìí kò ní ṣe ọ́ níbi. 20Ṣùgbọ́n tí ìwọ bá ti yapa kúrò lọ́dọ̀ ọkọ rẹ, tí o bá ti ba ara rẹ jẹ́ nípa jíjẹ́ kí ọkùnrin tí kì í ṣe ọkọ rẹ bá ọ lòpọ̀,” 21nígbà náà ni àlùfáà yóò mú obìnrin náà búra, yóò sọ fún obìnrin náà pé: “Kí Olúwa sọ ọ́ di ẹni ègún àti ẹni ìbáwí láàrín àwọn ènìyàn rẹ nípa mímú kí itan rẹ jẹrà, kí ikùn rẹ̀ sì wú. 22Ǹjẹ́ kí omi yìí tí ń mú ègún wá wọ inú ara rẹ, kí ó mú ikùn rẹ̀ wú, kí ó sì mú itan rẹ̀ jẹrà dànù.”

“ ‘Obìnrin náà yóò sì wí pé, “Àmín. Bẹ́ẹ̀ ni kó rí.”

23“ ‘Nígbà náà ni àlùfáà yóò kọ ègún yìí sínú ìwé kíká, yóò sì sìn ín sínú omi kíkorò náà. 24Àlùfáà yóò sì mú kí obìnrin náà mu omi kíkorò tí ń mú ègún wá yìí, omi náà yóò wọ inú rẹ̀ yóò sì fa ìrora kíkorò fún obìnrin náà bí ó bá jẹ̀bi. 25Àlùfáà yóò gba ọrẹ ohun jíjẹ owú náà lọ́wọ́ rẹ̀, yóò fì í síwájú Olúwa, yóò sì mú iná sórí pẹpẹ. 26Àlùfáà yóò bu ẹ̀kúnwọ́ kan nínú ọrẹ ohun jíjẹ nàà, yóò sun ún lórí pẹpẹ gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ìrántí lẹ́yìn tí ó ti mú kí obìnrin náà mu omi. 27Bí ó bá ti mú obìnrin yìí mu omi náà, bí ó bá sì jẹ́ pé obìnrin náà ti ba ara rẹ̀ jẹ́, tí ó sì ṣe àìṣòótọ́ sí ọkọ rẹ̀, omi tí ń mú ègún wá, yóò wọ ara rẹ̀, yóò fa ìrora kíkorò fún un, ikùn rẹ̀ yóò wú, itan rẹ̀ yóò sì jẹrà dànù, yóò sì di ẹni ègún láàrín àwọn ènìyàn rẹ̀. 28Ṣùgbọ́n tó bá jẹ́ pé obìnrin náà kò ba ara rẹ̀ jẹ́, tó sì jẹ́ mímọ́, yóò bọ́ nínú ẹ̀bi, yóò sì le bímọ.

29“ ‘Èyí ni òfin owú jíjẹ nígbà tí obìnrin tó wà lábẹ́ ọkọ bá ṣe a ṣe má ṣe, tí ó bá ba ara rẹ̀ jẹ́ 30Tàbí nígbà tí ẹ̀mí owú jíjẹ bá bà lé ọkùnrin kan nítorí pé ó funra sí ìyàwó rẹ̀. Àlùfáà yóò mú obìnrin náà dúró níwájú Olúwa yóò sì ṣe gẹ́gẹ́ bí òfin ti wí fún un. 31Ara ọkọ rẹ̀ mọ́ nínú ẹ̀ṣẹ̀ yìí ṣùgbọ́n obìnrin náà yóò ru ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.’ ”