Neno: Bibilia Takatifu

Wagalatia 1

1Kutoka kwa Paulo, mtume niliyetumwa, si kutoka kwa watu wala sikuchaguliwa na mwanadamu, bali nimetumwa na Yesu Kristo, na Mungu Baba aliyemfufua Yesu kutoka kwa wafu. 0 Nawahakikishieni mbele za Mungu kuwa ninayowaandikieni si uongo.

Tunawatakieni neema na amani kutoka kwa Mungu Baba na kutoka kwa Bwana wetu Yesu Kristo, ambaye alijitoa kwa ajili ya dhambi zetu ili apate kutuokoa kutoka katika nyakati hizi za uovu. Yeye apewe utukufu milele na milele. Amina.

Nashangaa kuona kwamba mnamwacha upesi hivyo yule aliye waita kwa neema ya Kristo mkaanza kufuata Injili nyingine. Ukweli ni kwamba hakuna Injili nyingine, ila nafahamu kuwa wako watu wanaowavuruga, ambao wanataka kuipotosha Injili ya Kristo. Lakini hata ikiwa ni sisi au ni malaika atokaye mbinguni, kama mtu akiwahubiria Injili ambayo ni tofauti na ile tuliyowahubiria sisi, basi mtu huyo na alaaniwe. Kama tulivyokwisha sema kabla, sasa nasema tena, kwamba mtu ye yote atakayewahubiria Injili tofauti na ile mliyokwishaipokea, basi mtu huyo na alaaniwe.

10 Je, sasa mimi nataka nipate upendeleo kutoka kwa bina damu au kutoka kwa Mungu? Au nataka niwapendeze watu? Kama ningekuwa najaribu kuwapendeza watu, nisingekuwa mtumishi wa

Wito Wa Paulo

11 Ndugu zangu, napenda mfahamu kwamba Injili niliyo wahubi ria siyo Injili ya binadamu. 12 Kwa maana mimi sikuipokea Injili kutoka kwa binadamu, wala sikufundishwa na mtu, bali nili pata mafunuo moja kwa moja kutoka kwa Yesu Kristo. 13 Ninyi mmekwisha sikia juu ya maisha yangu ya zamani nilipokuwa katika dini ya Kiyahudi; jinsi nilivyolitesa kanisa la Mungu na kujaribu kuliangamiza. 14 Nami niliwashinda wengi miongoni mwa Wayahudi wenzangu kwa maana nilikuwa nimejawa na juhudi ya kushika mapo keo ya baba zetu. 15 Lakini yeye aliyenichagua hata kabla sijazaliwa na akaniita kwa neema yake, 16 alipopenda kumdhihiri sha Mwanae kwangu ili nimhubiri miongoni mwa watu wa mataifa, sikushauriana na mtu ye yote. 17 Sikwenda kwanza Yerusalemu kuonana na wale waliokuwa mitume kabla yangu, bali nilikwenda Arabuni, ndipo nikarudi Dameski. 18 Kisha baada ya miaka mitatu nilikwenda Yerusalemu kuo nana na Kefa na nilikaa naye siku kumi na tano. 19 Lakini siku waona wale mitume wengine isipokuwa Yakobo, ndugu yake Bwana. 21 Baadaye nilikwenda sehemu za Siria na Kilikia. 22 Lakini mimi binafsi sikujulikana kwa wakristo wa makanisa ya huko Uyahudi. 23 Ila walisikia wengine wakisema, “Yule mtu ambaye zamani alikuwa akitutesa sasa anahubiri imani ile ile aliyokuwa akitaka kuiangamiza.” 24 Kwa hiyo wakamtukuza Mungu kwa sababu yangu.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Galatia 1

Paulu Aposteli

1Paulu, aposteli tí a rán kì í ṣe láti ọ̀dọ̀ ènìyàn wá, tàbí nípa ènìyàn, ṣùgbọ́n nípa Jesu Kristi àti Ọlọ́run Baba, ẹni tí ó jí i dìde kúrò nínú òkú. Àti gbogbo àwọn arákùnrin tí ó wà pẹ̀lú mi,

Sí àwọn ìjọ ní Galatia:

Oore-ọ̀fẹ́ sí yín àti àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba wá àti Jesu Kristi Olúwa, ẹni tí ó fi òun tìkára rẹ̀ dípò ẹ̀ṣẹ̀ wa, kí ó lè gbà wá kúrò nínú ayé búburú ìsinsin yìí, gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ Ọlọ́run àti Baba wa, ẹni tí ògo wà fún láé àti láéláé. Àmín.

Kò sí ìhìnrere mìíràn

Ó yà mi lẹ́nu pé ẹ tètè yapa kúrò lọ́dọ̀ ẹni tí ó pè yín sínú oore-ọ̀fẹ́ Kristi, sí ìhìnrere mìíràn: Nítòótọ́, kò sí ìhìnrere mìíràn: bí ó tilẹ̀ ṣe pé àwọn kan wà, tí ń yọ yín lẹ́nu, tí wọ́n sì ń fẹ́ yí ìhìnrere Kristi padà. Ṣùgbọ́n bí ó ṣe àwa ni tàbí angẹli kan láti ọ̀run wá, ni ó bá wàásù ìhìnrere mìíràn fún yín ju èyí tí a tí wàásù rẹ̀ fún yín lọ, jẹ́ kí ó di ẹni ìfibú títí láéláé! Bí àwa ti wí ṣáájú, bẹ́ẹ̀ ni mo sì tún wí nísinsin yìí pé: Bí ẹnìkan bá wàásù ìhìnrere mìíràn fún yín ju èyí tí ẹ̀yin tí gbà lọ, jẹ́ kí ó di ẹni ìfibú títí láéláé!

10 Ǹjẹ́ nísinsin yìí, ènìyàn ni èmi ń wá ojúrere rẹ̀ ní tàbí Ọlọ́run? Tàbí ènìyàn ni èmi ń fẹ́ láti wù bí? Bí èmi bá ń fẹ́ láti wu ènìyàn, èmi kò lè jẹ́ ìránṣẹ́ Kristi.

Paulu ẹni tí Ọlọ́run pè

11 Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀, ará, pé ìhìnrere tí mo tí wàásù kì í ṣe láti ipa ènìyàn. 12 N kò gbà á lọ́wọ́ ènìyàn kankan, bẹ́ẹ̀ ni a kò fi kọ́ mi, ṣùgbọ́n mo gbà á nípa ìfihàn láti ọ̀dọ̀ Jesu Kristi.

13 Nítorí ẹ̀yin ti gbúròó ìgbé ayé mi nígbà àtijọ́ nínú ìsìn àwọn Júù, bí mo tí ṣe inúnibíni sí ìjọ ènìyàn Ọlọ́run rékọjá ààlà, tí mo sì lépa láti bà á jẹ́: 14 Mo sì ta ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹlẹgbẹ́ mi yọ nínú ìsìn àwọn Júù láàrín àwọn ìran mi, mo sì ni ìtara lọ́pọ̀lọpọ̀ sì òfin àtọwọ́dọ́wọ́ àwọn baba mi. 15 Ṣùgbọ́n nígbà tí ó wú Ọlọ́run ẹni tí ó yà mí sọ́tọ̀ láti inú ìyá mi wá, tí ó sì pé mi nípa oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀. 16 Láti fi ọmọ rẹ̀ hàn nínú mi, kì èmi lè máa wàásù ìhìnrere rẹ̀ láàrín àwọn aláìkọlà; èmi kò wá ìmọ̀ lọ sọ́dọ̀ ẹnikẹ́ni, 17 bẹ́ẹ̀ ni èmi kò gòkè lọ sì Jerusalẹmu tọ àwọn tí í ṣe aposteli ṣáájú mi: ṣùgbọ́n mo lọ sí Arabia, mo sì tún padà wá sí Damasku.

18 Lẹ́yìn ọdún mẹ́ta, nígbà náà ni mo gòkè lọ sì Jerusalẹmu láti lọ kì Peteru, mo sì gbé ọ̀dọ̀ rẹ̀ ní ìjọ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún, 19 Èmi kò ri ẹlòmíràn nínú àwọn tí ó jẹ́ aposteli, bí kò ṣe Jakọbu arákùnrin Olúwa. 20 Nǹkan tí èmi ń kọ̀wé sí yín yìí, kíyèsi i, níwájú Ọlọ́run èmi kò ṣèké.

21 Lẹ́yìn náà mo sì wá sí agbègbè Siria àti ti Kilikia; 22 Mo sì jẹ́ ẹni tí a kò mọ̀ lójú fún àwọn ìjọ tí ó wà nínú Kristi ni Judea: 23 Wọ́n kàn gbọ́ ìròyìn wí pé, “Ẹni tí ó tí ń ṣe inúnibíni sí wa rí, ní ìsinsin yìí ti ń wàásù ìgbàgbọ́ náà tí ó ti gbìyànjú láti bàjẹ́ nígbà kan rí.” 24 Wọ́n sì yin Ọlọ́run lógo nítorí mi.