Neno: Bibilia Takatifu

Waebrania 1

Ukuu Wa Mwana Wa Mungu

1Hapo zamani Mungu alisema na baba zetu mara nyingi na kwa namna mbali mbali kwa kuwatumia manabii. Lakini katika siku hizi za mwisho, amesema na sisi kwa njia ya Mwanae, ambaye alim chagua kuwa mrithi wa vitu vyote. Na kwa njia ya Mwanae, Mungu aliumba ulimwengu. Yeye Mwana ni mng’ao wa utukufu wa Mungu na chapa halisi ya nafsi yake, naye huudumisha na kuuendeleza ulim wengu kwa neno lake lenye nguvu. Alipokwisha kuwapatia wanadamu utakaso wa dhambi, alikaa upande wa kulia wa Mungu Mwenyezi aliye juu. Kwa hiyo Mwana alikuwa mkuu zaidi kuliko malaika, kama ambavyo jina alilorithi kwa Mungu ni kuu kuliko jina la malaika ye yote.

Kwa maana ni malaika gani ambaye Mungu aliwahi kumwambia: “Wewe ni mwanangu; leo hii nimekuzaa”? Au tena: “Mimi nita kuwa Baba yake na yeye atakuwa Mwanangu”? Na tena Mungu ana pomleta mwanae, mzaliwa wa kwanza ulimwenguni, anasema: “Malaika wote wa Mungu wamwabudu yeye.” Anapozungumza juu ya malaika anasema: “Anawafanya malaika wake kuwa upepo, watumishi wake kuwa ndimi za moto.” Lakini kuhusu Mwana, anasema: “Kiti chako cha enzi, Wewe Mungu, kitadumu milele na milele, na haki takuwa fimbo ya ufalme wako. Umependa haki na kuchukia uovu. Kwa hiyo Mungu, Mungu wako, amekuchagua wewe na kukuweka juu ya wenzako kwa kukupaka mafuta ya furaha.” 10 Pia anasema: “Hapo mwanzo , Wewe Bwana, uliweka misingi ya ulimwengu, na mbingu ni kazi ya mikono yako. 11 Vyote vitaangamia lakini wewe unadumu; vyote vitachakaa kama nguo, nawe 12 utavikunja kama vazi na kuvibadilisha. Bali wewe hubadiliki, na miaka yako haitakwisha kamwe. ” 13 Lakini ni malaika gani amewahi kumwambia, “Keti kulia kwangu mpaka niwafanye adui zako kuwa kiti cha kuwekea miguu yako”? 14 Malaika ni nani basi? Wao ni roho wa utumishi waliotumwa kuwahudumia wale watakaopokea wokovu.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Heberu 1

Ọmọ tí o ṣe pàtàkì fún àwọn Angẹli

1Ní ìgbà àtijọ́, Ọlọ́run bá àwọn baba ńlá wa sọ̀rọ̀ láti ẹnu àwọn wòlíì ní ọ̀pọ̀ ìgbà àti ní onírúurú ọ̀nà, ṣùgbọ́n ní ìgbà ìkẹyìn yìí Ọlọ́run ń bá wa sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ Ọmọ rẹ̀ Jesu Kristi, ẹni tí ó fi ṣe ajogún ohun gbogbo, nípasẹ̀ ẹni tí ó dá gbogbo ayé yìí àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú rẹ̀: Ọmọ tí í ṣe ìtànṣán ògo Ọlọ́run àti àwòrán òun tìkára rẹ̀, tí ó sì ń fi ọ̀rọ̀ agbára rẹ̀ mú ohun gbogbo dúró: Lẹ́yìn tí ó ti ṣe ìwẹ̀nù ẹ̀ṣẹ̀ wa tan, ó wá jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún Ọláńlá ní òkè. Nítorí náà, ó sì ti fi bẹ́ẹ̀ di ẹni tí ó ga ní ipò ju angẹli lọ, bí ó ti jogún orúkọ èyí tí ó tayọ̀ tiwọn.

Nítorí kò sí ọ̀kan nínú àwọn angẹli tí Ọlọ́run fi ìgbà kan sọ fún pé:

“Ìwọ ni ọmọ mi;
    lónìí ni mo bí ọ”?

Àti pẹ̀lú pé;

“Èmi yóò jẹ́ baba fún un,
    Òun yóò sì jẹ́ ọmọ mi”?

Àti pẹ̀lú, nígbà tí Ọlọ́run rán àkọ́bí rẹ̀ wá si ayé wa yìí. Ó pàṣẹ pé,

“Ẹ jẹ́ kí gbogbo àwọn angẹli Ọlọ́run foríbalẹ̀ fún un.”

Àti nípa ti àwọn angẹli, ó wí pé;

“Ẹni tí ó dá àwọn angẹli rẹ̀ ní ẹ̀mí,
    àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ní ọwọ́ iná.”

Ṣùgbọ́n ó sọ nípa tí Ọmọ rẹ̀ pé,

“Ìtẹ́ rẹ, Ọlọ́run, láé àti láéláé ni,
    ọ̀pá aládé òdodo ni ọ̀pá ìjọba rẹ.
Ìwọ fẹ́ òdodo, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kórìíra iṣẹ́ búburú;
nítorí èyí ni Ọlọ́run, àní Ọlọ́run rẹ ṣe fi ààmì òróró ayọ̀ yàn ọ
    tí ó gbé ọ ju àwọn ẹgbẹ́ rẹ lọ.”

10 Ó tún sọ pé,

“Ní àtètèkọ́ṣe, ìwọ Olúwa, ìwọ fi ìdí ayé sọlẹ̀,
    àwọn ọ̀run sì jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ ara rẹ.
11 Wọn yóò ṣègbé, ṣùgbọ́n ìwọ yóò wà síbẹ̀
    gbogbo wọn ni yóò di àkísà bí ẹ̀wù.
12 Ní kíká ni ìwọ yóò ká wọn bí aṣọ,
    bí ìpààrọ̀ aṣọ ni a ó sì pààrọ̀ wọn.
Ṣùgbọ́n ìwọ fúnrarẹ̀ kì yóò yípadà
    àti pé ọdún rẹ kì yóò ní òpin.”

13 Èwo nínú àwọn angẹli ní a gbọ́ pé Ọlọ́run fi ìgbà kan wí fún pé,

“Jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi
    títí èmi yóò fi sọ àwọn ọ̀tá rẹ
    di àpótí ìtìsẹ̀ rẹ”?

14 Kì í ha á ṣe ẹ̀mí tí ń jíṣẹ́ ni àwọn angẹli í ṣe bí; tí a rán lọ síta láti máa ṣiṣẹ́ fún àwọn tí yóò jogún ìgbàlà?