Neno: Bibilia Takatifu

1 Wathesalonike 1

1Kutoka kwa Paulo, Silvano na Timotheo. Kwa kanisa la Wath esalonike mlio wa Mungu Baba yetu na wa Bwana Yesu Kristo. Tuna watakieni neema na amani.

Shukrani Kwa Imani Ya Wathesalonike

Tunamshukuru Mungu siku zote kwa ajili yenu wote na kuwaom bea pasipo kukoma. Tunakumbuka daima mbele za Mungu Baba yetu, kazi yenu inayotokana na imani, juhudi yenu kubwa katika upendo, na uvumilivu wenu unaotokana na tumaini mlilonalo kwa Bwana wetu Yesu Kristo. Ndugu zetu mnaopendwa na Mungu, tunafahamu kwamba Mungu amewachagua kwa maana Injili yetu haikuwajia kwa maneno matupu bali ilidhihirishwa kwa nguvu na kwa Roho Mtakatifu, mkawa na uhakika kamili. Ninyi mnajua jinsi tulivyoishi pamoja nanyi kwa faida yenu. Nanyi mkatuiga sisi, mkamuiga na Bwana; kwa maana mlilipokea neno kwa furaha mliyopewa na Roho Mtakatifu ingawa mlipata mateso makali. Kwa hiyo mkawa kielelezo kwa waamini wote wa Makedonia na Akaya.

Maana neno la Mungu limeenea kutoka kwenu, sio mpaka Make donia na Akaya tu, bali imani yenu kwa Mungu imejulika na mahali pote. Kwa hiyo hatuhitaji kusema lo lote kuhusu imani yenu; kwa maana wao wenyewe wanaeleza jinsi mlivyotupokea. Wanasimulia jinsi mlivyomgeukia Mungu mkaacha ibada za sanamu, ili kumtumikia Mungu aliye hai na wa kweli; 10 na kumngoja Mwanae kutoka mbin guni, ambaye alimfufua kutoka kwa wafu, yaani Yesu. Yeye anatu komboa kutoka katika ghadhabu ijayo.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

1 Tẹsalonika 1

1Paulu, Sila àti Timotiu.

A kọ ọ́ sí ìjọ tí ó wà ní ìlú Tẹsalonika, àwọn ẹni tí ó jẹ́ ti Ọlọ́run Baba àti ti Olúwa Jesu Kristi.

Kí ìbùkún àti àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba àti Jesu Kristi kí ó jẹ́ tiyín.

Ọpẹ́ fún ìgbàgbọ́ àwọn ará Tẹsalonika

Gbogbo ìgbà ni a máa ń fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run nítorí yín, a sì ń gbàdúrà fún un yín nígbà gbogbo pẹ̀lú. A ń rántí yin ni àìsimi nígbà gbogbo níwájú Ọlọ́run àti Baba nípa iṣẹ́ ìgbàgbọ́ yín, iṣẹ́ ìfẹ́ yín àti ìdúró ṣinṣin ìrètí yín nínú Jesu Kristi Olúwa wa.

Àwa mọ̀ dájúdájú, ẹ̀yin olùfẹ́ wa, wí pé Ọlọ́run ti yàn yín fẹ́ fún ara rẹ̀. Nítorí pé, nígbà tí a mú ìhìnrere tọ̀ yín wà, kò rí bí ọ̀rọ̀ lásán tí kò ní ìtumọ̀ sí i yín, bí kò ṣe pẹ̀lú agbára, pẹ̀lú Ẹ̀mí Mímọ́, pẹ̀lú ìdánilójú tó jinlẹ̀. Bí ẹ̀yin ti mọ irú ènìyàn tí àwa jẹ́ láàrín yín nítorí yín. Tó bẹ́ẹ̀ tí ẹ̀yin pàápàá di aláwòkọ́ṣe wa àti ti Olúwa, ìdí ni pé, ẹ gba ẹ̀rí náà láti ọwọ́ Ẹ̀mí Mímọ́ pẹ̀lú ayọ̀ bí o tilẹ̀ jẹ́ pé, ó mú wàhálà àti ìbànújẹ́ wá fún yín. Tó bẹ́ẹ̀ tí ẹ̀yin pàápàá fi di àpẹẹrẹ fún gbogbo àwọn onígbàgbọ́ tó wà ní agbègbè Makedonia àti Akaia. Ọ̀rọ̀ Olúwa ti gbilẹ̀ níbi gbogbo láti ọ̀dọ̀ yín láti agbègbè Makedonia àti Akaia lọ, ìgbàgbọ́ yín nínú Ọlọ́run tàn káàkiri. Nítorí náà, a kò ni láti ṣẹ̀ṣẹ̀ ń sọ fún wọn nípa rẹ̀. Ṣe ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí i ròyìn fún wa bí ẹ ti gbà wá lálejò. Wọ́n ròyìn fún wa pẹ̀lú pé, ẹ ti yípadà kúrò nínú ìbọ̀rìṣà àti wí pé Ọlọ́run alààyè àti òtítọ́ nìkan ṣoṣo ni ẹ ń sìn, 10 àti láti fi ojú ṣọ́nà fún ìpadàbọ̀ Ọmọ rẹ̀ láti ọ̀run wá, ẹni tí ó jí dìde kúrò nínú òkú, Jesu, ẹni tí ó gbà wá lọ́wọ́ ìbínú tí ń bọ̀.