Lukáš 14 – SNC & YCB

Slovo na cestu

Lukáš 14:1-35

Ježíš uzdravuje nemocného vodnatelností

1Jednou v sobotu pozval významný farizej Ježíše do svého domu, aby s ním pojedl. Všichni přítomní pozorně sledovali, zda Ježíš dodrží všechny předpisy zákona. 2V blízkosti Ježíšově se objevil muž postižený těžkou vodnatelností. 3Ježíš se na farizeje a vykladače zákona obrátil s otázkou: „Je dovoleno v sobotu uzdravovat, nebo ne?“ 4To jim zavřelo ústa. Ježíš se muže dotkl, uzdravil ho a poslal pryč. 5Pak jim ještě řekl: „Kdyby někomu z vás spadlo dítě nebo dobytče do jámy, nevytáhli byste ho, i kdyby byla sobota?“ 6A zase nevěděli, co na to odpovědět.

Ježíš hovoří o povyšování se

7Všiml si, jak se někteří hosté snaží zaujmout čestná místa u stolu, a řekl jim: 8-10„Pozve-li vás někdo na svatbu, nesedejte si na přední místa. Mohlo by se totiž stát, že by přišel někdo váženější než vy a bylo by trapné, kdybyste mu se zahanbením museli ustoupit. Není lépe posadit se skromně stranou a nechat hostitele říci: ‚Pojď, příteli, posaď se blíž?‘ To ti bude v očích druhých ke cti. 11Protože každý, kdo vynáší sám sebe, bude pokořen, ale kdo se umí pokořit, ten bude povýšen.“ 12A hostiteli řekl: „Dáváš-li oběd nebo večeři, nezvi své přátele, sourozence, příbuzné či vlivné známé. Oni by zase na oplátku pozvali tebe, aby nezůstali nic dlužni. 13Raději pozvi chudé, zmrzačené, kulhavé a slepé. 14Ti nemají, čím by ti to vynahradili, ale ty budeš mít radost. Takový čin nebude zapomenut ani na věčnosti.“

Ježíš vypráví podobenství o velké hostině

15Jeden z hostů ho slyšel a řekl: „Jaká pocta pro každého, kdo bude pozván ke stolu v Božím království.“ 16Na to mu vyprávěl Ježíš podobenství: „Jeden muž připravoval velkou hostinu a pozval na ni mnoho lidí. 17Když se už přiblížil ten slavnostní den, poslal svého sluhu k pozvaným se vzkazem: ‚Přijďte, vše je uchystáno!‘ 18Ale pozvaní se začali svorně vymlouvat. Jeden řekl: ‚Koupil jsem pole a musím ho jít obhlédnout. Prosím tě, omluv mě u svého pána.‘ 19Druhý řekl: ‚Koupil jsem pět volských spřežení a chci je vyzkoušet. Prosím tě, omluv mě.‘ 20Jiný řekl: ‚Právě jsem se oženil. Uznáš, že teď nemohu přijít.‘ 21Když se sluha vrátil a sdělil vše svému pánovi, ten se rozhněval a nařídil mu: ‚Vyjdi rychle do ulic a na náměstí a pozvi chudé, zmrzačené, slepé a chromé.‘ 22Když se tak stalo, oznámil sluha pánovi: ‚Splnil jsem tvůj příkaz a ještě zbývá místo.‘ 23Pán mu řekl: ‚Prohledej ohrady a příkopy a přiveď všechny tuláky a pobudy, ať se můj dům naplní. Přemluv i ty, kteří by si sami netroufali. 24Ale to vám říkám, žádný z těch pozvaných nevděčníků neokusí nic z mé hostiny.‘ “

Ježíš říká, co znamená být jeho učedníkem

25Když se Ježíš zase vydal na cestu, doprovázely ho davy lidí. Obrátil se k nim a řekl: 26„Kdo se chce ke mně připojit a nemiluje mne víc než svého otce, matku, ženu, děti, bratry a sestry a dokonce víc než sám sebe, nemůže se stát mým učedníkem. 27Kdo není ochoten vzít na sebe těžkosti, které mu nastanou, když mne bude následovat, nemůže být mým učedníkem. 28Kdo chce stavět dům, musí si nejprve udělat rozpočet a odhadnout, bude-li mít dost prostředků na to, aby stavbu dokončil. 29Když tak neučiní, stavbu začne, ale nedokončí ji. Všichni se mu vysmějí a řeknou: 30‚Podívejte se, chtěl stavět, ale nemá na to.‘ 31A když panovníkovi hrozí válka, neporadí se nejprve, zda se může se svými deseti tisíci vojáky postavit proti dvaceti tisícům? 32Nepošle raději mírové poselstvo dříve, než ho nepřítel napadne? 33A tak každý, kdo se chce stát mým učedníkem, ať si dobře rozváží, čeho by se pro mne musel vzdát. 34Sůl je dobrá věc, ale k čemu bude, ztratí-li svou chuť a schopnost bránit hnilobě? 35Ani k hnojení se nehodí, musí se vyhodit. Snažte se pochopit, co vám říkám.“

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Luku 14:1-35

Jesu ní ilé Farisi kan

114.1: Lk 7.36; 11.37; Mk 3.2.Nígbà tí ó wọ ilé ọ̀kan nínú àwọn olórí Farisi lọ ní ọjọ́ ìsinmi láti jẹun, wọ́n sì ń ṣọ́ ọ. 2Sì kíyèsi i, ọkùnrin kan tí ó ní ara wíwú níwájú rẹ̀. 314.3: Mt 12.10; Mk 3.4; Lk 6.9.Jesu sì dáhùn ó wí fún àwọn amòfin àti àwọn Farisi pé, “Ǹjẹ́ ó tọ́ láti mú ni láradá ní ọjọ́ ìsinmi, tàbí kò tọ́?” 4Wọ́n sì dákẹ́. Ó sì mú un, ó mú un láradá, ó sì jẹ́ kí ó lọ.

514.5: Mt 12.11; Lk 13.15.Ó sì dáhùn ó sì wí fún wọn pé, “Ta ni nínú yín tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tàbí màlúù rẹ̀ yóò bọ́ sínú ihò, tí kì yóò sì fà á sókè lójúkan náà ní ọjọ́ ìsinmi?” 6Wọn kò sì lè dá a lóhùn mọ́ sí nǹkan wọ̀nyí.

7Ó sì pa òwe kan fún àwọn tí ó pè é wá jẹun, nígbà tí ó ṣàkíyèsí bí wọ́n ti ń yan ipò ọlá; ó sì wí fún wọn pé: 814.8: Òw 25.6-7; Lk 11.43; 20.46.“Nígbà tí ẹnìkan bá pè ọ́ wá sí ibi ìyàwó, má ṣe jókòó ní ipò ọlá; kí ó má ba à jẹ́ pé, a ó pe ẹni tí ó lọ́lá jù ọ́ lọ. 9Nígbà tí ẹni tí ó pè ọ́ bá dé, a sì wí fún ọ pé, ‘Fún ọkùnrin yìí ní ààyè!’ Ìwọ á sì wá fi ìtìjú mú ipò ẹ̀yìn. 10Ṣùgbọ́n nígbà tí a bá pè ọ́, lọ kí o sì jókòó ní ipò ẹ̀yìn; nígbà tí ẹni tí ó pè ọ́ bá dé, kí ó lè wí fún ọ pé, ‘Ọ̀rẹ́, bọ́ sókè!’ Nígbà náà ni ìwọ ó ní ìyìn lójú àwọn tí ó bá ọ jókòó ti oúnjẹ. 1114.11: Mt 23.12; Lk 18.14; Mt 18.4; 1Pt 5.6.Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá gbé ara rẹ̀ ga, ni a ó rẹ̀ sílẹ̀; ẹnikẹ́ni tí ó bá sì rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀, ni a ó sì gbéga.”

1214.12: Jk 2.2-4.Nígbà náà ni ó sì wí fún alásè tí ó pè é pé, “Nígbà tí ìwọ bá ṣe àsè má ṣe pe àwọn arákùnrin rẹ tàbí àwọn ìbátan rẹ, tàbí àwọn ọlọ́rọ̀ aládùúgbò rẹ̀; nítorí kí wọn má ṣe pè ọ́ padà láti san ẹ̀san padà. 1314.13: Lk 14.21.Ṣùgbọ́n nígbà tí ìwọ bá ṣe àsè, pe àwọn tálákà, àwọn alábùkún ara, àwọn amúnkùn ún, àti àwọn afọ́jú: 14Ìwọ ó sì jẹ́ alábùkún fún; nítorí wọn kò ní ohun tí wọn ó fi san án fún ọ: ṣùgbọ́n a ó san án fún ọ ní àjíǹde, àwọn olóòtítọ́.”

Òwe nípa àsè ńlá

1514.15: If 19.9.Nígbà tí ọ̀kan nínú àwọn tí wọ́n jọ jókòó gbọ́ nǹkan wọ̀nyí, ó wí fún Jesu pé, “Alábùkún ni fún ẹni tí yóò jẹ oúnjẹ àsè ní ìjọba Ọlọ́run!”

1614.16-24: Mt 22.1-10.Jesu dá a lóhùn pé, “Ọkùnrin kan ṣe àsè alẹ́ ńlá, ó sì pe ènìyàn púpọ̀. 17Ó sì rán ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ ní wákàtí àsè alẹ́ náà láti sọ fún àwọn tí a ti pè pé, ‘Ẹ wá; nítorí ohun gbogbo ṣetán!’

18“Gbogbo wọn sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe àwáwí ohun kan. ‘Èkínní wí fún un pé, mo ra ilẹ̀ kan, mo sì fẹ́ lọ wò ó wò, mo bẹ̀ ọ́ ṣe gáfárà fún mi.’

19“Èkejì sì wí pé, ‘Mo ra àjàgà màlúù márùn-ún, mo sì ń lọ wò wọ́n wò: mo bẹ̀ ọ́ ṣe gáfárà fún mi.’

2014.20: De 24.5; 1Kọ 7.33.“Ẹ̀kẹta sì wí pé, ‘Mo ṣẹ̀ṣẹ̀ gbéyàwó, nítorí náà ni èmi kò fi lè wá.’

2114.21: Lk 14.13.“Ọmọ ọ̀dọ̀ náà sì padà dé, ó sọ nǹkan wọ̀nyí fún olúwa rẹ̀. Nígbà náà ni baálé ilé bínú, ó wí fún ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ pé, ‘Jáde lọ sí ìgboro, àti sí òpópó ọ̀nà, kí o sì mú àwọn tálákà, àti àwọn amúnkùn ún, àti àwọn arọ, àti àwọn afọ́jú wá sí ìhín yìí.’

22“Ọmọ ọ̀dọ̀ náà sì wí pé, ‘Olúwa a ti ṣe bí o ti pàṣẹ, ààyè sì ń bẹ síbẹ̀.’

23“Olúwa náà sì wí fún ọmọ ọ̀dọ̀ náà pé, ‘Jáde lọ sí òpópó, àti sí ọ̀nà ọgbà, kí o sì rọ̀ wọ́n láti wọlé wá, kí ilé mi lè kún. 24Nítorí mo wí fún yín, ẹnikẹ́ni nínú àwọn ènìyàn wọ̀nyí tí a ti pè, kì yóò tọ́wò nínú àsè ńlá mi!’ ”

Àmúyẹ láti jẹ ọmọ-ẹ̀yìn

25Àwọn ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn ń bá a lọ; ó sì yípadà, ó sì wí fún wọn pé, 2614.26-27: Mt 10.37-38.“Bí ẹnìkan bá tọ̀ mí wá, tí kò sì kórìíra baba àti ìyá, àti aya, àti ọmọ, àti arákùnrin, àti arábìnrin, àní àti ọkàn ara rẹ̀ pẹ̀lú, kò lè ṣe ọmọ-ẹ̀yìn mi. 2714.27: Mt 16.24; Mk 8.34; Lk 9.23.Ẹnikẹ́ni tí kò bá ru àgbélébùú rẹ̀, kí ó sì máa tọ̀ mí lẹ́yìn, kò lè ṣe ọmọ-ẹ̀yìn mi.

28“Nítorí ta ni nínú yín tí ń pète láti kọ́ ilé ìṣọ́, tí kì yóò kọ́kọ́ jókòó kí ó ṣírò iye owó rẹ̀, bí òun ní tó tí yóò fi parí rẹ̀. 29Kí ó má ba à jẹ́ pé nígbà tí ó bá fi ìpìlẹ̀ ilé sọlẹ̀ tan, tí kò lè parí rẹ̀ mọ́, gbogbo àwọn tí ó rí i a bẹ̀rẹ̀ sí í fi í ṣe ẹlẹ́yà. 30Wí pé, ‘Ọkùnrin yìí bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ ilé, kò sì lè parí rẹ̀.’

31“Tàbí ọba wo ni ó ń lọ bá ọba mìíràn jà, tí kì yóò kọ́kọ́ jókòó, kí ó sì gbèrò bí yóò lè fi ẹgbàárùn-ún pàdé ẹni tí ń mú ẹgbàáwàá bọ̀ wá ko òun lójú? 32Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, nígbà tí onítọ̀hún bá sì wà ní òkèrè, òun a rán ikọ̀ sí i, a sì bẹ̀rẹ̀ àdéhùn àlàáfíà. 3314.33: Lk 18.29-30; Fp 3.7.Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni, ẹnikẹ́ni tí ó wù kí ó ṣe nínú yín, tí kò kọ ohun gbogbo tí ó ní sílẹ̀, kò lè ṣe ọmọ-ẹ̀yìn mi.

3414.34-35: Mt 5.13; Mk 9.49-50; Mt 11.15.“Iyọ̀ dára: ṣùgbọ́n bí iyọ̀ bá di òbu, kín ni a ó fi mú un dùn? 35Kò yẹ fún ilẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò yẹ fún ààtàn; bí kò ṣe pé kí a kó o dànù.

“Ẹni tí ó bá ní etí láti fi gbọ́ kí ó gbọ́.”