Atti 27 – PEV & YCB

La Parola è Vita

Atti 27:1-44

Verso Roma

1Quando finalmente fu decisa la partenza per lʼItalia, via mare, Paolo ed altri detenuti furono consegnati a Giulio, un centurione della guardia imperiale. 2Salimmo a bordo di una nave di Abramiti, che doveva fare diversi scali nei porti della provincia dʼAsia, e prendemmo il mare. Devo aggiungere che cʼera con noi anche Aristarco, un Greco di Tessalonica. 3Il giorno dopo, arrivammo a Sidone. Qui Giulio, che era molto gentile con Paolo, gli permise di andare a trovare i suoi amici e di accettare la loro ospitalità. 4Partiti da Sidone, siccome era difficile seguire la rotta, causa i venti contrari, navigammo al riparo dellʼisola di Cipro, 5e costeggiammo le province della Cilicia e della Panfilia. Così arrivammo a Mira di Licia. 6Fu là che il centurione trovò una nave egiziana di Alessandria in partenza per lʼItalia, e su quella ci fece imbarcare.

7-8Dopo aver navigato lentamente per molti giorni, arrivammo, con una certa difficoltà, in vista della città di Cnido. I venti, però, non ci erano favorevoli, e non fu possibile approdare, perciò continuammo a costeggiare lʼisola di Creta in direzione di Capo Salmòne. Dopo aver doppiato con grande difficoltà questo promontorio, giungemmo in una certa località detta «Beiporti», vicino alla città di Lasèa. 9Qui rimanemmo per parecchi giorni. Il tempo non era favorevole ai lunghi viaggi, in quel periodo, poiché era già passata la data del «gran digiuno». Allora Paolo avvertì lʼequipaggio:

10«Amici», disse, «secondo me, proseguire il viaggio in questa stagione può essere molto pericoloso, non solo per il carico e la nave, ma anche per tutti noi!» 11Ma il centurione Giulio, aveva più fiducia nel parere del timoniere e del proprietario della nave, che nelle parole di Paolo. 12Siccome Beiporti non era certo il posto più adatto per passarvi lʼinverno, la maggioranza fu del parere di continuare la rotta, per raggiungere possibilmente Fenice, porto di Creta, dove poi svernare. Fenice era un posto adatto, esposto soltanto a nord-ovest e a sud-ovest.

13Proprio allora si era levata una leggera brezza da sud. Sembrava davvero il giorno perfetto per la partenza. Così, salpate le ancore, ripresero a navigare, tenendosi sempre il più possibile vicino allʼisola di Creta.

14Era iniziata da poco la navigazione, quando improvvisamente, il tempo cambiò e si scatenò sullʼisola un vento impetuoso da nord-est, detto Euroaquilone. 15La nave fu travolta dalla bufera. Dapprincipio cercammo di tornare verso la costa, ma siccome non cʼera niente da fare, ci lasciammo andare alla deriva.

16Passammo rapidamente dietro la isoletta di Clauda, e, a stento, riuscimmo a issare a bordo la scialuppa, che rimorchiavamo dietro la nave. 17Poi i marinai, per precauzione, legarono con delle gómene lo scafo della nave. Per paura di finire sulle coste africane, furono ammainate le vele e così ci trovammo completamente in balìa del vento.

18Il giorno dopo, siccome la situazione peggiorava, lʼequipaggio cominciò a gettare il carico a mare. 19Il terzo giorno, gettarono via con le proprie mani anche le attrezzature. 20Per molti giorni non riuscimmo a vedere né sole né stelle e la terribile tempesta continuava a infuriare su di noi sempre più forte. Avevamo perduto ormai ogni speranza di salvarci.

21Nessuno mangiava da molto tempo. Finalmente Paolo si alzò fra i compagni di viaggio e disse: «Amici, dovevate darmi ascolto e non partire da Creta; avreste evitato tutto questo pericolo e questo danno! 22Ma, coraggio! Nessuno di voi ci lascerà la pelle, soltanto la nave andrà perduta!

23Questa notte, un angelo di Dio, che io servo e al quale appartengo, mi è apparso e mi ha detto: 24“Non avere paura Paolo! Tu dovrai essere processato davanti a Cesare! Cʼè di più, Dio ha ascoltato la tua richiesta e salverà tutti quelli che navigano con te.” 25Perciò, fatevi coraggio! Io credo in Dio: sono sicuro che accadrà come lui mi ha detto! 26Andremo a finire su qualche isola».

27Verso la mezzanotte della quattordicesima notte di tempesta, sbattuti qua e là in mezzo al mare, i marinai ebbero lʼimpressione che la terra fosse vicina. 28Gettarono lo scandaglio e rilevarono circa quaranta metri di profondità. Un poʼ più avanti, scandagliando di nuovo, misurarono circa trenta metri. 29Temendo di finire sugli scogli, gettarono da poppa quattro ancore, aspettando ansiosi che facesse giorno.

30Ma alcuni marinai pensavano di abbandonare la nave e calarono in mare la scialuppa di salvataggio, col pretesto di gettare le ancore da prua. 31Allora Paolo disse ai soldati e al centurione: «Se i marinai abbandonano la nave, morirete tutti!» 32Perciò i soldati tagliarono le corde che sostenevano le scialuppe e le lasciarono cadere in acqua.

33Mentre si aspettava che facesse giorno, Paolo insisteva perché tutti mangiassero: «Sono due settimane che non toccate cibo», diceva, 34«mangiate qualcosa adesso. Dovete farlo se volete salvarvi! Perché nessuno di voi ci rimetterà neppure un capello!»

35Poi prese del pane, ringraziò Dio alla presenza di tutti, lo spezzò e cominciò a mangiare. 36Allora tutti si fecero coraggio e cominciarono a mangiare. 37-38A bordo eravamo in tutto duecentosettantasei. Dopo aver mangiato, lʼequipaggio alleggerì ancora la nave, gettando il frumento a mare.

Naufragio

39Quando si fece giorno, i marinai non riconobbero la costa, ma videro una baia che aveva una spiaggia e decisero di entrarvi con la nave, se fosse stato possibile. 40Tagliarono le gómene delle ancore, abbandonandole in mare, poi sciolsero i legami dei timoni e, alzata al vento la vela maestra, puntarono verso la riva. 41Ma finirono su una lingua di terra, che aveva il mare da entrambi i lati, e la nave sʼincagliò. La prua della nave, che si era incastrata sul fondo, restava immobile, mentre la poppa si sfasciava sotto la violenza del mare.

42I soldati erano del parere dʼuccidere i prigionieri, perché nessuno scappasse a nuoto. 43Ma il centurione Giulio, che voleva salvare Paolo, non fu dʼaccordo. Anzi, ordinò che tutti quelli che sapevano nuotare si gettassero in acqua e raggiungessero la terra ferma, 44mentre gli altri si salvassero, aggrappandosi alle tavole e ai relitti della nave. E fu così che tutti giunsero a terra sani e salvi.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Ìṣe àwọn Aposteli 27:1-44

Paulu wọ ọkọ ojú omi lọ sí Romu

1Bí a sì ti pinnu rẹ̀ pé kí a wọ ọkọ̀ lọ sí Itali, wọn fi Paulu àti àwọn òǹdè mìíràn lé balógun ọ̀rún kan lọ́wọ́, ti a ń pè ní Juliusi, ti ẹgbẹ́ ọmọ-ogun Augustu. 2Nígbà tí a sì wọ ọkọ̀-òkun Adramittiu kan, tí a fẹ́ lọ sí àwọn ìlú ti ó wà létí Òkun Asia, a ṣíkọ̀: Aristarku, ará Makedonia láti Tẹsalonika wà pẹ̀lú wa.

3Ní ọjọ́ kejì, a gúnlẹ̀ sí Sidoni. Juliusi sì ṣe inú rere sì Paulu, ó sì fún un láààyè kí ó máa tọ àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ lọ kí wọn le ṣe ìtọ́jú rẹ̀. 4Nígbà tí a sì kúrò níbẹ̀, a lọ lẹ́bàá Saipurọsi, nítorí tí afẹ́fẹ́ ṣọwọ́ òdì. 5Nígbà tí a ré Òkun Kilikia àti pamfilia kọjá, a gúnlẹ̀ sí Mira ti Likia. 6Níbẹ̀ ni balógun ọ̀rún sì rí ọkọ̀-òkun Alekisandiria kan, ti ń lọ sí Itali; ó sì fi wa sínú rẹ̀. 7Nígbà tí a ń lọ jẹ́jẹ́ ní ọjọ́ púpọ̀, ti a fi agbára káká dé ọ̀kánkán Knidu, àti nítorí tí afẹ́fẹ́ kò fún wa láààyè, a ba ẹ̀bá Krete lọ, lọ́kankán Salmoni; 8Nígbà tí a sì fi agbára káká kọjá rẹ̀, a dé ibi tí a ń pè ní Èbùté Yíyanjú, tí ó súnmọ́ ìlú Lasea.

9Nígbà ti a sì ti sọ ọjọ́ púpọ̀ nù, àti pé ìrìnàjò wa sì ti léwu gan an nítorí nísinsin yìí àwẹ̀ ti kọjá lọ, Paulu dá ìmọ̀ràn. 10Ó sì wí fún wọn pé, “Alàgbà, mo wòye pé ìṣíkọ̀ yìí yóò ní ewu, òfò púpọ̀ yóò sì wá, kì í ṣe kìkì ti ẹrù àti ti ọkọ̀, ṣùgbọ́n ti ọkàn wa pẹ̀lú.” 11Ṣùgbọ́n balógun ọ̀rún gba ti olórí ọkọ̀ àti ti ọlọ́kọ̀ gbọ́, ju ohun wọ̀nyí tí Paulu wí lọ. 12Àti nítorí pé èbúté náà kò rọrùn láti lo àkókò òtútù níbẹ̀, àwọn púpọ̀ sí dámọ̀ràn pé, kí a lọ kúrò níbẹ̀, bóyá wọn ó lè làkàkà dé Fonike, tí i ṣe èbúté Krete ti ó kọjú sí òsì ìwọ̀-oòrùn, àti ọ̀tún ìwọ̀-oòrùn, láti lo àkókò òtútù níbẹ̀.

Ìjì ojú omi

13Nígbà tí afẹ́fẹ́ gúúsù sì ń fẹ́ jẹ́jẹ́, tí wọn ṣe bí ọwọ́ àwọn tẹ ohun tí wọn ń wá, wọ́n ṣíkọ̀, wọn ń gba ẹ̀bá Krete lọ. 14Kò sì pẹ́ lẹ́yìn náà ni ìjì ti a ń pè ni Eurakuilo fẹ́ lù erékùṣù náà. 15Nígbà ti ó sì ti gbé ọkọ̀-òkun náà, ti kò sì lè dojúkọ ìjì yìí, a fi i sílẹ̀, ó ń gbá a lọ. 16Nígbà tí ó sì gbá a lọ lábẹ́ erékùṣù kan tí a ń pè Kauda, ó di iṣẹ́ púpọ̀ kí a tó lè súnmọ́ ìgbàjá ààbò. 17Nígbà tí wọ́n sì gbé e sókè, wọn sa agbára láti dí ọkọ̀-òkun náà nísàlẹ̀, nítorí tí wọ́n ń bẹ̀rù kí á máa ba à gbé wọn sórí iyanrìn dídẹ̀, wọn fi ìgbokùn sílẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni a sì ń gbá wa kiri. 18Bí a sì ti ń ṣe làálàá gidigidi nínú ìjì náà, ni ọjọ́ kejì wọn kó ẹrù-ọkọ̀ dà sí omi láti mú ọkọ̀ fẹ́rẹ̀; 19Ní ọjọ́ kẹta, wọ́n fi ọwọ́ ara wọn kó ohun èlò ọkọ̀ dànù. 20Nígbà tí oòrùn àti ìràwọ̀ kò si hàn lọ́jọ́ púpọ̀, tí ìjì náà kò sì mọ níwọ̀n fún wa, àbá àti là kò sí fún wa mọ́.

21Nígbà tí wọ́n wà ní àìjẹun lọ́jọ́ púpọ̀, nígbà náà Paulu dìde láàrín wọn, o wí pé “Alàgbà, ẹ̀yin bá ti gbọ́ tèmi kí a má ṣe ṣíkọ̀ kúrò ní Krete, ewu àti òfò yìí kì ìbá ti bá wa. 22Ǹjẹ́ nísinsin yìí mó gbà yín níyànjú, kí ẹ tújúká; nítorí kí yóò sí òfò ẹ̀mí nínú yín, bí kò ṣe ti ọkọ̀. 23Nítorí angẹli Ọlọ́run, ẹni tí èmi jẹ́ tirẹ̀, àti ẹni ti èmi ń sìn, ó dúró tì mi ni òru àná. 24Ó wí pé, ‘Má bẹ̀rù, Paulu; ìwọ kò lè ṣàìmá dúró níwájú Kesari: Sì wò ó, Ọlọ́run ti fi gbogbo àwọn ti ó bá ọ wọ ọkọ̀ pọ̀ fún ọ.’ 25Ǹjẹ́ nítorí náà, alàgbà, ẹ dárayá: nítorí mo gba Ọlọ́run gbọ́ pé, yóò rí bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ bí a ti sọ fún mi. 26Ṣùgbọ́n a ó gbá wa jù sí erékùṣù kan.”

Rírì ọkọ̀

27Ṣùgbọ́n nígbà tí ó di òru ọjọ́ kẹrìnlá, bí a ti ń gbé wa kọjá lọ láàrín Òkun Adria, láàrín ọ̀gànjọ́ àwọn atukọ̀ funra pé, àwọn súnmọ́ etí ilẹ̀ kan: 28Nígbà tí wọ́n sì wọn Òkun, wọ́n rí i ó jì ní ogún ìgbọ̀nwọ́, nígbà tì í wọ́n sún síwájú díẹ̀, wọ́n sì tún wọn Òkun, wọn rí i pé ó jì ni ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún. 29Nígbà tí wọ́n bẹ̀rù kí wọn má ṣe rọ́ lu orí òkúta, wọ́n sọ ìdákọ̀ró mẹ́rin sílẹ̀ ni ìdí ọkọ̀, wọ́n ń retí ojúmọ́. 30Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn atukọ̀ ń wá ọ̀nà láti sá kúrò nínú ọkọ̀, tí wọ́n sì ti sọ àwọn ọkọ̀ kéékèèkéé kalẹ̀ sí ojú Òkun, bí ẹni pé wọn ń fẹ́ sọ ìdákọ̀ró sílẹ̀ níwájú ọkọ̀. 31Paulu wí fún balógun ọ̀rún àti fún àwọn ọmọ-ogun pé, “Bí kò ṣe pé àwọn wọ̀nyí bá dúró nínú ọkọ̀ ẹ̀yin kí yóò lè là!” 32Nígbà náà ni àwọn ọmọ-ogun gé okùn àwọn ọkọ̀ kéékèèkéé, wọ́n jù ú sílẹ̀ kí ó ṣubú sọ́hùn-ún.

33Nígbà tí ilẹ̀ ń mọ́ bọ̀, Paulu bẹ gbogbo wọn kí wọn jẹun díẹ̀, ó wí pé, “Òní ni ó di ìjẹrìnlá tí ẹ̀yin ti ń retí, ti ẹ kò dẹ́kun gbígbààwẹ̀, tí ẹ kò sì jẹun. 34Nítorí náà mo bẹ̀ yín, kí ẹ jẹun díẹ̀, nítorí èyí ni fún ìgbàlà yín: nítorí irun kan kí yóò gé kúrò lórí ẹnìkan nínú yín.” 35Nígbà tí ó sì wí nǹkan wọ̀nyí, tí ó sì mú àkàrà, ó dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run níwájú gbogbo wọn: nígbà tí ó si bù ú, ó bẹ̀rẹ̀ sí i jẹ. 36Nígbà náà ni gbogbo wọ́n sì dárayá, àwọn pẹ̀lú sì gba oúnjẹ, 37Gbogbo wa tí ń bẹ nínú ọkọ̀-òkun náà sì jẹ́ ọ̀rìnlúgba ènìyàn ó-dínmẹ́rin (276). 38Nígbà tí wọn jẹun yó tan, wọn bẹ̀rẹ̀ sí mu ọkọ̀-òkun náà fúyẹ́, nípa kíkó alikama dà sí omi.

39Nígbà tí ilẹ̀ sí mọ́, wọn kò mọ́ ilẹ̀ náà; ṣùgbọ́n wọn rí apá odò kan tí ó ní èbúté, níbẹ̀ ni wọ́n gbèrò, bóyá ó le ṣe é ṣe láti mu ọkọ̀ gúnlẹ̀. 40Nígbà tí wọ́n sì gé ìdákọ̀ró kúrò, wọn jù wọn sínú Òkun, lẹ́sẹ̀kan náà wọn tú ìdè-ọkọ̀, wọn sì ta ìgbokùn iwájú ọkọ̀ sí afẹ́fẹ́, wọn sì wakọ̀ kọjú sí etí Òkun. 41Nígbà tí wọ́n sì dé ibi tí Òkun méjì pàdé, wọn fi orí ọkọ̀ sọlẹ̀: iwájú rẹ̀ sì kàn mọ́lẹ̀ ṣinṣin, ó dúró, kò lè yí, ṣùgbọ́n agbára rírú omi bẹ̀rẹ̀ sí fọ́ ìdí ọkọ̀ náà.

42Èrò àwọn ọmọ-ogun ni ki a pa àwọn òǹdè, kí ẹnikẹ́ni wọn má ba à wẹ̀ jáde sálọ. 43Ṣùgbọ́n balógun ọ̀rún ń fẹ́ gba Paulu là, ó kọ èrò wọn, ó sì pàṣẹ fún àwọn tí ó lè wẹ̀ kí wọn bọ́ sí Òkun lọ sì ilẹ̀. 44Àti àwọn ìyókù, òmíràn lórí pátákó, àti òmíràn lórí àwọn igi tí ó ya kúrò lára ọkọ̀. Bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe tí gbogbo wọn yọ, ní àlàáfíà dé ilẹ̀.