پيدايش 26 – PCB & YCB

Persian Contemporary Bible

پيدايش 26:1-35

اسحاق و ابيملک

1روزی قحطی شديدی همانند قحطی زمان ابراهيم سراسر سرزمين كنعان را فرا گرفت. به همين دليل اسحاق به شهر جرار نزد ابيملک، پادشاه فلسطين رفت. 2‏-3خداوند در آنجا بر او ظاهر شده، گفت: «به مصر نرو، در همين جا بمان. اگر سخن مرا شنيده، اطاعت كنی با تو خواهم بود و تو را بسيار بركت خواهم داد و تمامی اين سرزمين را به تو و نسل تو خواهم بخشيد، چنانكه به پدرت ابراهيم وعده داده‌ام. 4نسل تو را چون ستارگان آسمان بی‌شمار خواهم گردانيد و تمامی اين سرزمين را به آنها خواهم داد و همه قومهای جهان از نسل تو بركت خواهند يافت. 5اين كار را به خاطر ابراهيم خواهم كرد، چون او احكام و اوامر مرا اطاعت نمود.»

6پس اسحاق در جرار ماندگار شد. 7وقتی كه مردم آنجا دربارهٔ ربكا از او سؤال كردند، گفت: «او خواهر من است!» چون ترسيد اگر بگويد همسر من است، به خاطر تصاحب زنش او را بكشند، زيرا ربكا بسيار زيبا بود. 8مدتی بعد، يک روز ابيملک، پادشاه فلسطين از پنجره ديد كه اسحاق با زن خود شوخی می‌كند. 9پس ابيملک، اسحاق را نزد خود خوانده، به او گفت: «چرا گفتی ربكا خواهرت است، در حالی كه زن تو می‌باشد؟»

اسحاق در جواب گفت: «چون می‌ترسيدم برای تصاحب او مرا بكشند.»

10ابيملک گفت: «اين چه كاری بود كه با ما كردی؟ آيا فكر نكردی كه ممكن است شخصی با وی همبستر شود؟ در آن صورت ما مقصر می‌شديم.» 11سپس ابيملک به همه اعلام نمود: «هر كس به اين مرد و همسر وی زيان رساند، كشته خواهد شد.»

12اسحاق در جرار به زراعت مشغول شد و در آن سال صد برابر بذری كه كاشته بود درو كرد، زيرا خداوند او را بركت داده بود. 13هر روز بر دارايی او افزوده می‌شد و طولی نكشيد كه او مرد بسيار ثروتمندی شد. 14وی گله‌ها و رمه‌ها و غلامان بسيار داشت به طوری كه فلسطينی‌ها بر او حسد می‌بردند. 15پس آنها چاههای آبی را كه غلامان پدرش ابراهيم در زمان حيات ابراهيم كنده بودند، با خاک پُر كردند. 16ابيملکِ پادشاه نيز از او خواست تا سرزمينش را ترک كند و به او گفت: «به جايی ديگر برو، زيرا تو از ما بسيار ثروتمندتر و قدرتمندتر شده‌ای.»

17پس اسحاق آنجا را ترک نموده، در درهٔ جرار ساكن شد. 18او چاههای آبی را كه در زمان حيات پدرش كَنده بودند و فلسطينی‌ها آنها را پُر كرده بودند، دوباره كَند و همان نامهايی را كه قبلاً پدرش بر آنها نهاده بود بر آنها گذاشت. 19غلامان او نيز چاه تازه‌ای در درهٔ جرار كَنده، در قعر آن به آب روان رسيدند.

20سپس چوپانان جرار آمدند و با چوپانان اسحاق به نزاع پرداخته، گفتند: «اين چاه به ما تعلق دارد.» پس اسحاق آن چاه را عِسِق (يعنی «نزاع») ناميد.

21غلامانِ اسحاق چاه ديگری كَندند و باز بر سر آن مشاجره‌ای درگرفت. اسحاق آن چاه را سِطنه (يعنی «دشمنی») ناميد. 22اسحاق آن چاه را نيز ترک نموده، چاه ديگری كَند، ولی اين بار نزاعی درنگرفت. پس اسحاق آن را رحوبوت (يعنی «مكان») ناميد. او گفت: «خداوند مكانی برای ما مهيا نموده است و ما در اين سرزمين ترقی خواهيم كرد.»

23وقتی كه اسحاق به بئرشبع رفت 24در همان شب خداوند بر وی ظاهر شد و فرمود: «من خدای پدرت ابراهيم هستم. ترسان مباش، چون من با تو هستم. من تو را بركت خواهم داد و به خاطر بندهٔ خود ابراهيم نسل تو را زياد خواهم كرد.» 25آنگاه اسحاق قربانگاهی بنا كرده، خداوند را پرستش نمود. او در همانجا ساكن شد و غلامانش چاه ديگری كندند.

26روزی ابيملکِ پادشاه به اتفاق مشاور خود احوزات و فرماندهٔ سپاهش فيكول از جرار نزد اسحاق آمدند. 27اسحاق از ايشان پرسيد: «چرا به اينجا آمده‌ايد؟ شما كه مرا با خصومت از نزد خود رانديد!»

28‏-29آنان به وی گفتند: «ما آشكارا می‌بينيم كه خداوند با توست و تو را بركت داده است؛ پس آمده‌ايم با تو پيمانی ببنديم. قول بده ضرری به ما نرسانی همانطور كه ما هم ضرری به تو نرسانديم. ما غير از خوبی كاری در حق تو نكرديم و تو را با صلح و صفا روانه نموديم.»

30پس اسحاق مهمانی‌ای برای آنها بر پا نمود و خوردند و آشاميدند. 31صبح روز بعد برخاستند و هر يک از آنها قسم خوردند كه به يكديگر ضرری نرسانند. سپس اسحاق ايشان را به سلامتی به سرزمينشان روانه كرد.

32در همان روز، غلامان اسحاق آمدند و او را از چاهی كه می‌كَندند خبر داده، گفتند كه در آن آب يافته‌اند. 33اسحاق آن را شَبَع (يعنی «سوگند») ناميد و شهری كه در آنجا بنا شد، بئرشبع (يعنی «چاه سوگند») ناميده شد كه تا به امروز به همان نام باقی است.

34عيسو پسر اسحاق در سن چهل سالگی يوديه، دختر بيری حيتّی و بسمه دختر ايلونِ حيتّی را به زنی گرفت. 35اين زنان زندگی را بر اسحاق و ربكا تلخ كردند.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Gẹnẹsisi 26:1-35

Isaaki àti Abimeleki

1Ìyàn kan sì mú ní ilẹ̀ náà, yàtọ̀ fún èyí tí ó mú ní ìgbà ayé Abrahamu, Isaaki sì lọ sọ́dọ̀ Abimeleki ọba àwọn Filistini ni Gerari. 2Olúwa sì fi ara han Isaaki, ó sì wí pé, “Má ṣe sọ̀kalẹ̀ lọ sí Ejibiti: Jókòó ní ilẹ̀ tí èmi ó fún ọ. 326.3,4: Gẹ 22.16-18.Máa ṣe àtìpó ní ilẹ̀ yìí fún ìgbà díẹ̀, èmi ó sì wà pẹ̀lú rẹ, Èmi yóò sì bùkún fún ọ. Nítorí ìwọ àti irú-ọmọ rẹ ni èmi yóò fi gbogbo àwọn ilẹ̀ wọ̀nyí fún, èmi yóò sì fi ìdí ìbúra tí mo ṣe fún Abrahamu baba rẹ múlẹ̀. 4Èmi yóò sọ ìran rẹ di púpọ̀ bí ìràwọ̀ ojú ọ̀run, èmi yóò sì fi gbogbo ilẹ̀ yìí fún irú àwọn ọmọ rẹ, àti nípasẹ̀ irú-ọmọ rẹ ni a ó bùkún fún gbogbo orílẹ̀-èdè ayé, 5nítorí tí Abrahamu gba ohùn mi gbọ́, ó sì pa gbogbo ìkìlọ̀, àṣẹ, ìlànà àti òfin mi mọ́.” 6Nítorí náà Isaaki jókòó ní Gerari.

726.7: Gẹ 12.13; 20.2.Nígbà tí àwọn ọkùnrin ìlú náà bi í léèrè ní ti aya rẹ̀, ó sì wí pé, “Arábìnrin mi ní í ṣe,” nítorí tí ó bẹ̀rù láti jẹ́wọ́ wí pé, “Aya mi ni.” Ó ń rò wí pé, “Kí àwọn ọkùnrin ibẹ̀ náà má ba à pa mí nítorí Rebeka, nítorí tí òun ní ẹwà púpọ̀.”

8Nígbà tí Isaaki sì ti wà níbẹ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọjọ́, Abimeleki ọba Filistini yọjú lójú fèrèsé, ó sì rí Isaaki ń bá Rebeka aya rẹ̀ tage. 9Nígbà náà ni Abimeleki ránṣẹ́ pe Isaaki ó sì wí fun pé, “Nítòótọ́, aya rẹ ni obìnrin yìí í ṣe, èéṣe tí ìwọ fi wí fún wa pé arábìnrin mi ni?”

Isaaki sì fèsì pé, “Nítorí mo rò pé mo le pàdánù ẹ̀mí mi nítorí rẹ̀.”

10Nígbà náà ni Abimeleki dáhùn pé, “Èwo ni èyí tí ìwọ ṣe sí wa yìí? Bí ọ̀kan nínú àwọn ènìyàn wọ̀nyí bá ti bá a lòpọ̀ ńkọ́? Ìwọ ìbá wá mú ẹ̀bi wá sórí wa.”

11Nígbà náà ni Abimeleki pàṣẹ fún gbogbo ènìyàn pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá fọwọ́ kan ọkùnrin yìí tàbí aya rẹ̀ yóò jẹ̀bi ikú.”

12Ní ọdún náà, Isaaki gbin ohun ọ̀gbìn sí ilẹ̀ náà, ó sì kórè rẹ̀ ní ìlọ́po ọgọ́ọ̀rún ni ọdún kan náà, nítorí Ọlọ́run bùkún un. 13Ọkùnrin náà sì di ọlọ́rọ̀ púpọ̀, ọrọ̀ rẹ̀ sì ń pọ̀ si, títí ó fi di ènìyàn ńlá. 14Ó ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹran ọ̀sìn àti agbo ẹran àti àwọn ìránṣẹ́ tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn Filistini ń ṣe ìlara rẹ̀. 15Nítorí náà àwọn ará Filistini ru erùpẹ̀ di gbogbo kànga tí àwọn ìránṣẹ́ Abrahamu baba rẹ̀ ti gbẹ́.

16Nígbà náà ni Abimeleki wí fún Isaaki pé, “Jáde kúrò ní ilẹ̀ wa, nítorí tí ìwọ ti di alágbára púpọ̀ jù wá lọ.”

17Isaaki sì ṣí kúrò níbẹ̀, ó sì pàgọ́ sí Àfonífojì Gerari ó sì ń gbé ibẹ̀. 18Isaaki sì ṣe àtúngbẹ́ àwọn kànga tí Abrahamu baba rẹ̀ ti gbẹ́ nígbà ayé rẹ̀, èyí tí àwọn Filistini ti dí lẹ́yìn ikú Abrahamu baba rẹ̀, ó sì fún wọn lórúkọ tí baba rẹ̀ ti sọ wọ́n tẹ́lẹ̀.

19Àwọn ìránṣẹ́ Isaaki sì gbẹ́ kànga ní àfonífojì náà, wọ́n kan ìsun omi níbẹ̀. 20Ṣùgbọ́n àwọn darandaran Gerari ń bá àwọn darandaran Isaaki jà sí kànga náà pé àwọn ni àwọn ni í. Nítorí náà ni ó fi pe orúkọ kànga náà ní Eseki, nítorí pé wọ́n bá a jà sí kànga náà. 21Àwọn ìránṣẹ́ Isaaki tún gbẹ́ kànga mìíràn, wọ́n sì tún jà nítorí rẹ̀ pẹ̀lú, ó sì sọ orúkọ rẹ̀ ní Sitna (kànga àtakò). 22Ó sì tún kúrò níbẹ̀, ó sì gbẹ́ kànga mìíràn, wọn kò sì jásí èyí rárá, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Rehoboti, ó wí pé, “Nísinsin yìí, Olúwa ti fi ààyè gbà wá, a ó sì gbilẹ̀ si ní ilẹ̀ náà.”

23Láti ibẹ̀, ó kúrò lọ sí Beerṣeba 24Ní òru ọjọ́ tí ó dé ibẹ̀, Olúwa sì fi ara hàn án, ó sì wí pé, “Èmi ni Ọlọ́run Abrahamu baba rẹ: Má ṣe bẹ̀rù nítorí èmi wà pẹ̀lú rẹ, èmi yóò sì bùsi fún ọ, èmi yóò sì sọ iye ìran rẹ di púpọ̀, nítorí Abrahamu ìránṣẹ́ mi.”

25Isaaki sì kọ́ pẹpẹ kan síbẹ̀, ó sì pe orúkọ Olúwa. Níbẹ̀ ni ó pàgọ́ rẹ̀ sí, àwọn ìránṣẹ́ rẹ sì gbẹ́ kànga kan níbẹ̀.

2626.26: Gẹ 21.22.Nígbà náà ni Abimeleki tọ̀ ọ́ wá láti Gerari, àti Ahussati, olùdámọ̀ràn rẹ̀ àti Fikoli, olórí ogun rẹ̀. 27Isaaki sì bi wọ́n léèrè pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin tọ̀ mí wá, níwọ̀n ìgbà tí ẹ̀yin kórìíra mi tí ẹ sì lé mi jáde kúrò lọ́dọ̀ yín?”

28Wọ́n dáhùn pé, “A rí i dájú pé Olúwa wà pẹ̀lú rẹ, nítorí náà ni a fi rò ó wí pé, ó yẹ kí májẹ̀mú kí o wà láàrín àwa àti ìwọ. Jẹ́ kí a ṣe àdéhùn 29pé ìwọ kì yóò ṣe wá ní ibi, bí àwa pẹ̀lú kò ti ṣe ọ́ ní aburú, tí a sì ń ṣe ọ́ dáradára, tí a sì rán ọ jáde ní àlàáfíà láìṣe ọ́ ní ibi, kíyèsi Olúwa sì ti bùkún fún ọ.”

30Isaaki sì ṣe àsè fún wọn, wọn sì jẹ, wọ́n sì mu. 31Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì wọn búra fún ara wọn. Isaaki sì rán wọn lọ, wọ́n sì lọ ní àlàáfíà.

32Ní ọjọ́ náà gan an ni àwọn ìránṣẹ́ Isaaki wá sọ fún un pé àwọn ti kan omi ní kànga kan tí àwọn gbẹ́. 3326.33: Gẹ 21.31.Ó sì pe orúkọ kànga náà ní Ṣiba (kànga májẹ̀mú), títí di òní olónìí, orúkọ ìlú náà ni Beerṣeba.

34Nígbà tí Esau pé ọmọ ogójì ọdún (40) ó fẹ́ ọmọbìnrin kan tí a ń pè ní Juditi, ọmọ Beeri, ará Hiti, ó sì tún fẹ́ Basemati, ọmọ Eloni ará Hiti. 35Fífẹ́ tí a fẹ́ àwọn obìnrin wọ̀nyí jẹ́ ìbànújẹ́ fún Isaaki àti Rebeka.