Números 24 – OL & YCB

O Livro

Números 24:1-25

1Balaão viu bem que os planos do Senhor eram de abençoar Israel. Por isso, nem sequer foi desta vez procurar adivinhá-los, como fizera antes. Em vez disso, voltou-se logo para o deserto. 2Olhou para os israelitas, que se encontrava lá em baixo, distribuído pelas suas áreas tribais.

E o Espírito de Deus veio sobre ele, 3declarando esta profecia a respeito do povo:

“Balaão, filho de Beor,

o homem que tem os olhos abertos,

4que ouve a palavra de Deus,

e que tem a visão da parte do Todo-Poderoso.

Inclina-se até ao chão, mas tem os olhos abertos:

5Oh! Que alegrias esperam por Israel,

que contentamentos haverá nos lares de Jacob!

6Vejo-os espalhados diante de mim como vales verdes,

como jardins verdejantes à beira de rios,

como aloés plantadas pelo próprio Senhor,

como cedros junto à fonte de água.

7A água corre dos reservatórios deste povo,

e com a água, as searas produzirão muito.

O seu rei revelar-se-á como sendo bem maior do que Agague.

O seu reino será exaltado.

8Deus os tirou do Egito.

Israel tem o poder de um boi selvagem.

Devorará as nações que se lhe opuserem,

esmigalhará os seus ossos em pó,

crivá-los-á de flechas.

9Ali está Israel descansando como um leão, como uma leoa:

Quem ousará perturbá-lo?

Abençoado será quem te abençoar, ó Israel,

e maldito quem te amaldiçoar!”

10O rei Balaque estava cheio de cólera. Brandindo os punhos cerrados de fúria, gritou: “Eu chamei-te para amaldiçoares os meus inimigos e afinal acabas por abençoá-los já por três vezes! 11Fora daqui! Vai lá para donde vieste! Tinha planeado elevar-te a um cargo de grande honra, mas o Senhor privou-te desse privilégio!”

12Balaão replicou: “Não disse eu aos teus delegados 13que mesmo que me dessem um palácio cheio de ouro e prata, não poderia ir além das palavras do Senhor? Não poderia dizer uma só palavra da minha lavra. 14Sim, vou com certeza regressar para donde vim, para a minha terra. Mas primeiro deixa-me dizer-te o que os israelitas vão fazer ao teu povo futuramente.”

A quarta profecia de Balaão

15E disse-lhe mais esta profecia:

“Balaão, o filho de Beor,

é o homem cujos olhos estão abertos,

16que ouve as palavras de Deus,

que conhece os pensamentos do Altíssimo,

que tem a visão da parte do Todo-Poderoso,

que se inclina até ao chão e cujos olhos estão abertos:

17Vejo o futuro de Israel,

vejo bem longe o seu trilho.

Há de aparecer uma estrela vinda de Jacob!

O governante de Israel esmigalhará o povo de Moabe,

e destruirá os filhos de Sete.

18Israel virá a possuir todo o Edom e Seir.

Eles vencerão os seus inimigos.

19De Jacob erguer-se-á um que na sua força

acabará com os sobreviventes da capital.”

A quinta profecia de Balaão

20Em seguida, Balaão virou-se para Amaleque e profetizou ainda:

“Amaleque foi o primeiro das nações,

mas o seu destino será a destruição!”

A sexta profecia de Balaão

21Depois, referindo-se aos queneus disse:

“Sim, estás situada num sítio com toda a segurança,

o teu ninho está posto sobre as rochas!

22Mas os queneus serão também destruídos

e o poderoso exército do rei da Assíria

te levará para longe desta terra!”

A sétima profecia de Balaão

23E concluiu assim estas profecias:

“Ai de nós! Quem poderá viver

quando é Deus quem faz estas coisas?

24Virão até barcos das costas de Chipre,

que oprimirão tanto Eber como a Assíria.

Também eles hão de ser destruídos.”

25Desta forma, se separaram Balaão e Balaque e regressaram cada um ao seu lugar.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Numeri 24:1-25

1Nísinsin yìí nígbà tí Balaamu rí i wí pé ó tẹ́ Ọlọ́run lọ́rùn láti bùkún àwọn Israẹli, kò lo ọ̀nà ìṣoṣó gẹ́gẹ́ bí ti ìgbà ìṣáájú, ṣùgbọ́n ó yí ojú rẹ̀ sí apá aginjù. 2Nígbà tí Balaamu wo ìta ó sì rí Israẹli tí wọ́n pàgọ́ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yà wọn, Ẹ̀mí Ọlọ́run sì bà sórí rẹ̀ 3ó sì bẹ̀rẹ̀ òwe rẹ̀:

“Ó wí pé Balaamu ọmọ Beori,

òwe ẹni tí ojú rẹ̀ mọ́lẹ̀,

4Òwe ẹni tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run,

ẹni tí ó ríran láti ọ̀dọ̀ Olódùmarè,

ẹni tí ó dojúbolẹ̀, tí ojú rẹ̀ sì là:

5“Àgọ́ rẹ ti dára tó, ìwọ Jakọbu,

àti ibùgbé rẹ, ìwọ Israẹli!

6“Gẹ́gẹ́ bí Àfonífojì tí ó tàn jáde,

gẹ́gẹ́ bí ọgbà tí ó wà ní ẹ̀bá odò ńlá,

gẹ́gẹ́ bí igi aloe tí Olúwa gbìn,

gẹ́gẹ́ bí igi kedari tí ó wà lẹ́bàá odò.

7Omi yóò sàn láti inú garawa:

èso wọn yóò ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi.

“Ọba wọn yóò ga ju Agagi lọ;

ìjọba wọn yóò di gbígbéga.

8“Ọlọ́run mú wọn jáde láti Ejibiti wá;

wọ́n ní agbára gẹ́gẹ́ bí i ti àgbáǹréré.

Wọ́n jẹ orílẹ̀-èdè tí ń ṣe ọ̀tá rẹ̀ run,

wọ́n sì fọ́ egungun wọn sí túútúú;

wọ́n ó sì fi ọfà wọn ta wọ́n ní àtapòyọ.

924.9: Gẹ 49.9.Ó tẹríba ó sì dùbúlẹ̀ bí kìnnìún,

bí abo kìnnìún: ta ni ó gbọdọ̀ jí wọn?

“Ìbùkún ni fún ẹni tí ó bùkún fún ọ,

kí ìfibú jẹ́ ti ẹni tí ó fi ọ́ bú!”

10Nígbà náà ni ìbínú Balaki sì dé sí Balaamu. Ó sì fi ọwọ́ lu ọwọ́ ó wí pé, “Mo pè ọ́ láti bú àwọn ọ̀tá mi ṣùgbọ́n o tún bùkún fún wọn nígbà mẹ́ta yìí. 11Nísinsin yìí sálọ sí ibùjókòó rẹ! Èmi ti rò láti sọ ọ́ di ẹni ńlá, ṣùgbọ́n Olúwa tí fà ọ́ sẹ́yìn láti gba èrè yìí.”

12Balaamu dá Balaki lóhùn, “Ǹjẹ́ èmi kò sọ fún àwọn ìránṣẹ́ tí o rán sí mi wí pé, 13‘Kódà bí Balaki bá fún mi ní ààfin rẹ̀ tí ó kún fún fàdákà àti wúrà, èmi kò le ṣe ohunkóhun lọ́wọ́ ara mi, yálà búburú tàbí rere, láti kọjá òfin Olúwa: ohun tí Olúwa bá wí ni èmi ó sọ’? 14Nísinsin yìí mò ń padà lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn mi, ṣùgbọ́n jẹ́ kí èmi kí ó kìlọ̀ fún ọ nítorí nǹkan tí àwọn ènìyàn wọ̀nyí yóò ṣe sí àwọn ènìyàn rẹ ní ọjọ́ iwájú.”

Ọ̀rọ̀-ìjìnlẹ̀ ẹ̀kẹrin Balaamu

15Nígbà náà ni ó bẹ̀rẹ̀ òwe:

“Òwe Balaamu ọmọ Beori,

òwe ẹni tí ojú rẹ̀ ríran kedere,

16Ẹni tó gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ń wí,

tí ó sì mọ ìmọ̀ Ọ̀gá-ògo,

tí ó ríran láti ọ̀dọ̀ Olódùmarè,

ẹni tí ó dọ̀bálẹ̀, tí ojú rẹ̀ sì ṣí:

17“Mo rí i, ṣùgbọ́n kì í ṣe ìsinsin yìí,

Mo kíyèsi, ṣùgbọ́n kò súnmọ́.

Ìràwọ̀ kan yóò jáde láti ọ̀dọ̀ Jakọbu;

yóò yọ jáde láti Israẹli.

Yóò tẹ̀ fọ́ orí Moabu,

yóò sì fọ́ agbárí gbogbo ọmọ Seti.

18Wọn yóò borí Edomu;

yóò ṣẹ́gun Seiri ọ̀tá rẹ̀,

ṣùgbọ́n Israẹli yóò dàgbà nínú agbára.

19Olórí yóò jáde láti Jakọbu

yóò sì pa àwọn tó ṣẹ́kù nínú ìlú náà run.”

Ọ̀rọ̀-ìjìnlẹ̀ ìkẹyìn Balaamu

20Nígbà náà ni Balaamu rí Amaleki ó sì bẹ̀rẹ̀ òwe:

“Amaleki ni àkọ́kọ́ nínú àwọn orílẹ̀-èdè,

ṣùgbọ́n yóò dahoro níkẹyìn.”

21Nígbà náà ní ó rí ará Keni ó sì bẹ̀rẹ̀ òwe:

“Ibùgbé rẹ ní ààbò,

ìtẹ́ rẹ ni a tò sínú àpáta;

22síbẹ̀ ẹ̀yin ará Keni ni yóò di píparun

nígbà tí Asiria bá mú yín ní ìgbèkùn.”

23Nígbà náà ni ó bẹ̀rẹ̀ òwe rẹ̀:

“Háà, ta ni ó lè yè nígbà tí Ọlọ́run bá ṣe èyí?

24Ọkọ̀ yóò wá láti ibùdókọ̀ Kittimu;

wọn yóò ṣẹ́gun Asiria àti Eberi,

ṣùgbọ́n àwọn náà yóò di píparun.”

25Nígbà náà ni Balaamu dìde ó sì padà sí ilé rẹ̀, Balaki sì lọ ní ọ̀nà tirẹ̀.