Mateus 19 – OL & YCB

O Livro

Mateus 19:1-30

O divórcio

(Mc 10.1-12)

1Após ter dado estes ensinos, Jesus saiu da Galileia e dirigiu-se à região da Judeia, na outra margem do Jordão. 2Grandes multidões o seguiam e curou os doentes.

3Alguns fariseus foram ter com Jesus, para o pôr à prova, e perguntaram-lhe se era lícito um marido divorciar-se da mulher por todo e qualquer motivo.

4“Não leem as Escrituras? Nelas está escrito que, desde o princípio, o Criador criou o homem e a mulher.19.4 Gn 1.27. 5Assim, ‘o homem deve deixar o pai e a mãe, para se unir com a sua mulher, e serão os dois como um só’.19.5 Gn 2.24. 6Por conseguinte, não mais serão dois, mas como um só. E nenhum homem separe o que Deus juntou.”

7“Então”, perguntaram os fariseus, “porque é que Moisés mandou dar uma declaração de divórcio à mulher e mandá-la embora?”

8Jesus respondeu-lhes: “Moisés permitiu-vos que mandem embora as vossas mulheres por causa da dureza do vosso coração, mas no início não era assim que sucedia. 9E digo-vos que quem se divorciar da sua mulher, salvo em caso de imoralidade sexual, e se casar com outra, comete adultério.”

10Os discípulos disseram-lhe: “Sendo assim o melhor é não casar!”

11“Nem todos podem aceitar isso; só aqueles a quem Deus ajuda. 12Alguns nascem já incapazes para o casamento e outros são incapacitados pelos homens; alguns outros, ainda, não querem casar-se por causa do reino dos céus. Quem puder aceitar que aceite.”

Jesus e as crianças

(Mc 10.13-16; Lc 18.15-17)

13Traziam crianças a Jesus para que colocasse sobre elas as mãos e orasse, mas os discípulos diziam-lhes que fossem embora. 14Jesus disse-lhes: “Deixem as crianças vir a mim! Não as devem impedir, porque o reino dos céus pertence aos que são como estas crianças.” 15E, colocando as mãos sobre elas, abençoou-as e foi-se embora.

O homem rico

(Mc 10.17-31; Lc 18.18-30)

16Um jovem aproximou-se e fez esta pergunta: “Mestre, que farei de bom para alcançar a vida eterna?”

17“Porque me perguntas acerca do que é bom?”, perguntou-lhe Jesus. “Bom só há um. Se queres entrar na vida, guarda os mandamentos.”

18“Quais?”, perguntou o jovem.

E Jesus respondeu: “Não mates, não adulteres, não roubes, não profiras uma falsa acusação contra outra pessoa, 19honra o teu pai e a tua mãe e ama o teu próximo como a ti mesmo19.19 Êx 20.12-16; Lv 19.18..”

20“Tenho obedecido a todos estes mandamentos”, respondeu o jovem. “Que mais preciso de fazer?”

21“Se queres ser perfeito, vai, vende os teus bens, dá o dinheiro aos pobres e terás um tesouro nos céus. Vem e segue-me!” 22Ao ouvir isto, o rapaz foi-se embora triste, porque era muito rico.

23Jesus disse aos discípulos: “É realmente como vos digo: é quase impossível um rico entrar no reino dos céus! 24É mesmo mais fácil um camelo passar pelo fundo duma agulha do que um rico entrar no reino de Deus!”

25Os discípulos, porém, ao ouvirem isto, ficaram grandemente admirados, dizendo: “Então quem é que neste mundo poderá salvar-se?”

26Jesus olhou para eles e respondeu: “Humanamente falando, ninguém. Mas a Deus tudo é possível.”

27Então, em resposta, Pedro retorquiu-lhe: “Nós deixámos tudo para te seguir. Que proveito tiramos disso?”

28Respondeu-lhe Jesus: “É realmente como vos digo: aqueles de vocês que me seguirem, quando o Filho do Homem se sentar no seu glorioso trono no reino, sentar-se-ão em doze tronos, para julgar as doze tribos de Israel. 29Todo aquele que abandonar a sua casa, irmãos, irmãs, pai, mãe, filhos e terras por minha causa, receberá em recompensa cem vezes tanto, e terá a vida eterna. 30Porém, muitos primeiros virão a ser últimos, e os últimos virão a ser primeiros.”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Matiu 19:1-30

Ìkọ̀sílẹ̀

119.1: Mt 7.28; 11.1; 13.53; 26.1.19.1-9: Mk 10.1-12.Lẹ́yìn tí Jesu ti parí ọ̀rọ̀ yìí, ó kúrò ní Galili. Ó sì yípo padà sí Judea, ó gba ìhà kejì odò Jordani. 2Ọ̀pọ̀ ènìyàn sì ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn, ó sì mú wọn láradá níbẹ̀.

3Àwọn Farisi wá sọ́dọ̀ rẹ̀ láti dán an wò. Wọ́n bi í pé, “Ǹjẹ́ ó tọ̀nà fún ọkùnrin láti kọ ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀ nítorí ohunkóhun?”

4Ó dáhùn ó sì wí fún wọn pé, “Ẹyin kò ti kà á pé ‘ẹni tí ó dá wọn ní ìgbà àtètèkọ́ṣe, Ọlọ́run dá wọn ni ti akọ ti abo.’ 5Ó sì wí fún un pé, ‘Nítorí ìdí èyí ọkùnrin yóò fi baba àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀, òun yóò sì dàpọ̀ mọ́ aya rẹ̀, àwọn méjèèjì yóò sì di ara kan.’ 6Wọn kì í túnṣe méjì mọ́, ṣùgbọ́n ara kan. Nítorí náà, ohun tí Ọlọ́run bá ti so ṣọ̀kan, kí ẹnikẹ́ni má ṣe yà wọ́n.”

719.7: De 24.1-4.Wọ́n bi í pé: “Kí ni ìdí tí Mose fi pàṣẹ pé, ọkùnrin kan lè kọ ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀ nípa fífún un ní ìwé ìkọ̀sílẹ̀?”

8Jesu dáhùn pé, “Nítorí líle àyà yín ni Mose ṣe gbà fún yín láti máa kọ aya yín sílẹ̀. Ṣùgbọ́n láti ìgbà àtètèkọ́ṣe wá, kò rí bẹ́ẹ̀. 9Mo sọ èyí fún yín pé, ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ aya rẹ̀ sílẹ̀, láìṣe pé nítorí àgbèrè, tí ó bá sì fẹ́ ẹlòmíràn, ó ṣe panṣágà.”

10Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wí fún un pé, “Bí ọ̀rọ̀ bá rí báyìí láàrín ọkọ àti aya, kó ṣàǹfààní fún wa láti gbé ìyàwó.”

1119.11: 1Kọ 7.7-9.Jesu dáhùn pé, “Gbogbo ènìyàn kọ́ ló lé gba ọ̀rọ̀ yìí, bí kò ṣe iye àwọn tí a ti fún. 12Àwọn mìíràn jẹ́ akúra nítorí bẹ́ẹ̀ ní a bí wọn, àwọn mìíràn ń bẹ tí ènìyàn sọ wọn di bẹ́ẹ̀; àwọn mìíràn kọ̀ láti gbé ìyàwó nítorí ìjọba ọ̀run. Ẹni tí ó bá lè gbà á kí ó gbà á.”

Àwọn ọmọdé àti Jesu

1319.13-15: Mk 10.13-16; Lk 18.15-17; Mt 18.2-3; 1Kọ 14.20.Lẹ́yìn náà a sì gbé àwọn ọmọ ọwọ́ wá sọ́dọ̀ Jesu, kí ó lè gbé ọwọ́ lé wọn, kí ó sì gbàdúrà fún wọn. Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ bá àwọn tí ó gbé wọn wá wí.

14Ṣùgbọ́n Jesu dáhùn pé, “Ẹ jẹ́ kí àwọn ọmọdé wá sọ́dọ̀ mi, ẹ má ṣe dá wọn lẹ́kun, nítorí irú wọn ni ìjọba ọ̀run.” 15Lẹ́yìn náà, ó gbé ọwọ́ lé wọn, ó sì kúrò níbẹ̀.

Ọ̀dọ́mọkùnrin ọlọ́rọ̀

1619.16-22: Mk 10.17-22; Lk 18.18-23.19.16: Lk 10.25; Le 18.5.Ẹnìkan sì wá ó bí Jesu pé, “Olùkọ́, ohun rere kí ni èmi yóò ṣe, kí èmi kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun?”

17Jesu dá a lóhùn pé, “Èéṣe tí ìwọ fi ń béèrè nípa ohun rere lọ́wọ́ mi. Ẹni kan ṣoṣo ni ó wà tí í ṣe Ẹni rere. Bí ìwọ bá fẹ́ dé ibi ìyè, pa àwọn òfin mọ́.”

1819.18: El 20.12-16; De 5.16-20; Ro 13.9; Jk 2.11.Ọkùnrin náà béèrè pé, “Àwọn wo ni òfin wọ̀nyí?”

Jesu dáhùn pé, “ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ pànìyàn; Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe panṣágà; Ìwọ kò gbọdọ̀ jalè; Ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ́rìí èké’, 19bọ̀wọ̀ fún baba àti ìyá rẹ. ‘Kí o sì fẹ́ aládùúgbò rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.’ ”

20Ọmọdékùnrin náà tún wí pé, “Gbogbo òfin wọ̀nyí ni èmi ti ń pamọ́, kí ni nǹkan mìíràn tí èmi ní láti ṣe?”

2119.21: Lk 12.33; Ap 2.45; 4.34; Mt 6.20.Jesu wí fún un pé, “Bí ìwọ bá fẹ́ di ẹni pípé, lọ ta ohun gbogbo tí ìwọ ní, kí o sì fi owó rẹ̀ tọrẹ fún àwọn aláìní. Ìwọ yóò ní ọrọ̀ ńlá ní ọ̀run. Lẹ́yìn náà, wá láti máa tọ̀ mi lẹ́yìn.”

22Ṣùgbọ́n nígbà tí ọ̀dọ́mọkùnrin náà gbọ́ èyí, ó kúrò níbẹ̀ pẹ̀lú ìbànújẹ́, nítorí ó ní ọrọ̀ púpọ̀.

2319.23-26: Mk 10.23-27; Lk 18.24-27.Nígbà náà, ní Jesu wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín pé, ó ṣòro fún ọlọ́rọ̀ láti wọ ìjọba Ọ̀run.” 24Mo tún wí fún yín pé, “Ó rọrùn fún ìbákasẹ láti wọ ojú abẹ́rẹ́ jù fún ọlọ́rọ̀ láti wọ ìjọba Ọlọ́run.”

25Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn gbọ́ èyí, ẹnu sì yà wọn gidigidi, wọ́n béèrè pé, “Ǹjẹ́ ta ni ó ha le là?”

2619.26: Gẹ 18.14; Jb 42.2.Ṣùgbọ́n Jesu wò wọ́n, ó sì wí fún wọn pé, “Ènìyàn ni èyí ṣòro fún; ṣùgbọ́n fún Ọlọ́run ohun gbogbo ni ṣíṣe.”

2719.27-30: Mk 10.28-31; Lk 18.28-30; Mt 4.18-22.Peteru sì wí fún un pé, “Àwa ti fi ohun gbogbo sílẹ̀, a sì tẹ̀lé ọ, kí ni yóò jẹ́ èrè wa?”

2819.28: Lk 22.30; Mt 20.21; If 3.21.Jesu dáhùn pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín pé, ‘Nígbà ìsọdọ̀tun ohun gbogbo, nígbà tí Ọmọ Ènìyàn yóò jókòó lórí ìtẹ́ tí ó lógo, dájúdájú, ẹ̀yin ọmọ-ẹ̀yìn mi yóò sì jókòó lórí ìtẹ́ méjìlá láti ṣe ìdájọ́ ẹ̀yà Israẹli méjìlá. 29Àti pé ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ilé tàbí arákùnrin tàbí arábìnrin tàbí baba tàbí ìyá tàbí àwọn ọmọ, tàbí ohun ìní rẹ̀ sílẹ̀ nítorí orúkọ mí, yóò gba ọgọọgọ́rùn-ún èrè rẹ̀ láyé, wọn ó sì tún jogún ìyè àìnípẹ̀kun. 30Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ àwọn tí ó síwájú nísinsin yìí ni yóò kẹ́yìn, àwọn tí ó kẹ́yìn ni yóò sì síwájú.’