Lucas 13 – OL & YCB

O Livro

Lucas 13:1-35

Chamada ao arrependimento

1Por esse tempo, contaram a Jesus que Pilatos tinha mandado matar alguns judeus da Galileia, enquanto ofereciam sacrifícios no templo em Jerusalém. 2“Pensam, por acaso, que esses eram mais pecadores do que os outros homens da Galileia?”, perguntou-lhes. 3“E que foi por isso que sofreram a morte? Não perceberam que também vocês se perderão se não se arrependerem? 4E os dezoito homens que morreram quando a torre de Siloé desabou sobre eles? Terá sido porque seriam os piores pecadores que havia em Jerusalém? 5Sem dúvida que não! Também vocês se perderão se não se arrependerem!”

6Jesus apresentou-lhes então a seguinte parábola: “Certo homem plantou uma figueira na sua quinta e muitas vezes ia ver se tinha fruto, ficando sempre desapontado. 7Por fim, disse ao empregado que a cortasse: ‘Há três anos que espero e não brotou um único figo! Para que me hei de ralar mais com esta figueira? O espaço que ocupa podemos nós utilizar para qualquer outra coisa.’

8‘Dá-lhe uma nova oportunidade’, respondeu o empregado. ‘Deixa-a ficar mais um ano que eu vou dedicar-lhe cuidados especiais e pôr-lhe adubo com abundância. 9Se conseguirmos figos no próximo ano, tanto melhor; se não, então corto-a.’ ”

Uma aleijada é curada no sábado

10Um sábado, estava Jesus a ensinar numa sinagoga, 11quando viu uma mulher que andava curvada, sem se poder endireitar, havia dezoito anos, por estar possuída por um espírito maligno. 12Jesus chamou-a para junto de si. “Mulher, estás curada da tua doença!” 13Tocou-a e imediatamente pôde endireitar-se. E ela glorificava e agradecia a Deus.

14Todavia, o líder da sinagoga local ficou muito zangado, porque Jesus tinha efetuado aquela cura no sábado. “Há seis dias da semana para trabalhar”, bradou ele à multidão. “Nesses dias e não no sábado é que se deve vir em busca de cura!”

15Mas o Senhor respondeu: “És um hipócrita! Tu trabalhas ao sábado! Ao sábado não desatas o gado no estábulo e não o levas a beber? 16E será condenável que, lá porque é sábado, eu liberte, após dezoito anos de cativeiro de Satanás, esta filha de Abraão?” 17Isto envergonhou os seus inimigos. E todo o povo se alegrava com as maravilhas que fazia.

Ilustrações da semente de mostarda e do fermento

(Mt 13.31-32; Mc 4.30-32)

18Começou então novamente a instruí-los acerca do reino de Deus: “Com que se parece o reino e como posso explicá-lo? 19É como uma semente de mostarda que um homem planta na sua horta; depois cresce e transforma-se num arbusto em cujos ramos as aves do céu fazem os seus ninhos.”

20Outra vez ele perguntou: “A que compararei o reino de Deus? 21Pode ser comparado ao fermento que uma mulher misturou em três medidas de farinha, até toda ela levedar.”

A porta estreita

(Mt 7.13-14, 22-23; 8.11-12)

22Jesus ia de cidade em cidade e de localidade em localidade, ensinando pelo caminho e avançando sempre para Jerusalém. 23Alguém lhe perguntou: “É verdade que só poucos é que serão salvos?” Ele respondeu:

24“É estreita a porta do céu. Esforcem-se por entrar, porque muitos tentarão fazê-lo. 25Mas quando o dono da casa tiver trancado a porta, será já tarde. Se ficarem do lado de fora, ainda que batendo e suplicando: ‘Senhor, abre-nos a porta!’, ele contudo responderá: ‘Não vos conheço nem sei de onde vêm!’ 26E dir-lhe-ão: ‘Mas nós comemos contigo e ensinaste nas nossas ruas.’ 27Tornará a responder: ‘Não vos conheço nem sei de onde vêm. Afastem-se da minha presença, pois todos vocês são praticantes da injustiça!’

28E haverá choro e ranger de dentes, ao verem Abraão, Isaque, Jacob e todos os profetas dentro do reino de Deus, mas vocês são lançados fora. 29Então virá gente do Este e do Oeste, do Norte e do Sul e sentar-se-ão no reino de Deus. 30E notem que há últimos que virão a ser primeiros, e primeiros que virão a ser últimos.”

Jesus em Jerusalém

(Mt 23.37-39)

31Nesse momento, alguns fariseus disserem-lhe: “Retira-te daqui se queres continuar vivo, porque Herodes anda à tua procura!” 32Ao que Jesus respondeu:

“Digam a essa raposa que continuarei a expulsar demónios e a operar curas milagrosas hoje e amanhã; e no terceiro dia chegarei ao meu destino. 33Sim, hoje, amanhã e depois de amanhã devo prosseguir o meu caminho! Porque não ficaria bem a um profeta de Deus ser morto noutro local que não em Jerusalém!

Jesus tem pena de Jerusalém

34Jerusalém, Jerusalém, cidade que mata os profetas de Deus e apedreja todos aqueles que ele lhe envia! Quantas vezes quis juntar os teus filhos como uma galinha junta os pintainhos debaixo das asas, mas vocês não me deixaram. 35Agora a vossa casa fica ao abandono. Lembrem-se do que vos digo: nunca mais me tornarão a ver senão quando disserem, ‘bendito aquele que vem em nome do Senhor!’ ”13.35 Sl 118.26.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Luku 13:1-35

Ẹ ronúpìwàdà kí ẹ má bà á ṣègbé

1Àwọn kan sì wá ní àkókò náà tí ó sọ ti àwọn ará Galili fún un, ẹ̀jẹ̀ ẹni tí Pilatu dàpọ̀ mọ́ ẹbọ wọn. 213.2: Jh 9.1-3.Jesu sì dáhùn ó wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ṣe bí àwọn ará Galili wọ̀nyí ṣe ẹlẹ́ṣẹ̀ ju gbogbo àwọn ará Galili lọ, nítorí wọ́n jẹ irú ìyà bá-wọ̀n-ọn-nì? 3Mo wí fún yín, bẹ́ẹ̀ kọ́: bí kò ṣe pé ẹ̀yin pẹ̀lú ronúpìwàdà, gbogbo yín ni yóò ṣègbé bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́. 4Tàbí àwọn méjì-dínlógún, tí ilé ìṣọ́ ní Siloamu wó lù, tí ó sì pa wọ́n, ẹ̀yin ṣe bí wọ́n ṣe ẹlẹ́ṣẹ̀ ju gbogbo àwọn ènìyàn tí ń bẹ ní Jerusalẹmu lọ? 5Mo wí fún yín, bẹ́ẹ̀ kọ́: bí kò ṣe pé ẹ̀yin ronúpìwàdà, gbogbo yín ni yóò ṣègbé bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́.”

613.6-9: Mt 21.18-20; Mk 11.12-14,20-21.Ó sì pa òwe yìí fún wọn pé: “Ọkùnrin kan ní igi ọ̀pọ̀tọ́ kan tí a gbìn sí ọgbà àjàrà rẹ̀; ó sì dé, ó ń wá èso lórí rẹ̀, kò sì rí nǹkan. 713.7: Mt 3.10; 7.19; Lk 3.9.Ó sì wí fún olùṣọ́gbà rẹ̀ pé, ‘Sá à wò ó, láti ọdún mẹ́ta ni èmi ti ń wá í wo èso lórí igi ọ̀pọ̀tọ́ yìí, èmi kò sì rí nǹkan: ké e lulẹ̀; èéṣe tí ó fi ń gbilẹ̀ lásán pẹ̀lú?’

8“Ó sì dáhùn ó wí fún un pé, ‘Olúwa, jọ̀wọ́ rẹ̀ ní ọdún yìí pẹ̀lú, títí èmi ó fi tu ilẹ̀ ìdí rẹ̀ yíká, títí èmi ó sì fi bu ìlẹ̀dú sí i: 9Bí ó bá sì so èso, o dara bẹ́ẹ̀: bí kò bá sì so, ǹjẹ́ lẹ́yìn èyí nì kí ìwọ kí ó ké e lulẹ̀.’ ”

A mú obìnrin arọ láradá ní ọjọ́ ìsinmi

10Ó sì ń kọ́ni nínú Sinagọgu kan ní ọjọ́ ìsinmi. 11Sì kíyèsi i, obìnrin kan wà níbẹ̀ tí ó ní ẹ̀mí àìlera, láti ọdún méjì-dínlógún wá, ẹni tí ó tẹ̀ tán, tí kò le gbé ara rẹ̀ sókè bí ó ti wù kí ó ṣe. 12Nígbà tí Jesu rí i, ó pè é sí ọ̀dọ̀, ó sì wí fún un pé, “Obìnrin yìí, a tú ọ sílẹ̀ lọ́wọ́ àìlera rẹ.” 13Ó sì fi ọwọ́ rẹ̀ lé e: Lójúkan náà a sì ti sọ ọ́ di títọ́, ó sì ń yin Ọlọ́run lógo.

1413.14: Ek 20.9-10; Lk 6.6-11; 14.1-6; Jh 5.1-18.Olórí Sinagọgu sì kún fún ìrunú, nítorí tí Jesu mú ni láradá ní ọjọ́ ìsinmi, ó sì wí fún ìjọ ènìyàn pé, ọjọ́ mẹ́fà ní ń bẹ tí a fi í ṣiṣẹ́: nínú wọn ni kí ẹ̀yin kí ó wá kí á ṣe dídá ara yín, kí ó má ṣe ní ọjọ́ ìsinmi.

1513.15: Lk 7.13; 14.5; Mt 12.11.Nígbà náà ni Olúwa dáhùn, ó sì wí fún un pé, “Ẹ̀yin àgàbàgebè, olúkúlùkù yín kì í tú màlúù tàbí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ kúrò ní ibùso, kì í sì í fà á lọ mu omi ní ọjọ́ ìsinmi. 1613.16: Lk 19.9.Kò sì yẹ kí a tú obìnrin yìí tí í ṣe ọmọbìnrin Abrahamu sílẹ̀ ní ìdè yìí ní ọjọ́ ìsinmi, ẹni tí Satani ti dè, sá à wò ó láti ọdún méjì-dínlógún yìí wá?”

17Nígbà tí ó sì wí nǹkan wọ̀nyí, ojú ti gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀: gbogbo ìjọ ènìyàn sì yọ̀ fún ohun ìyanu gbogbo tí ó ṣe.

Òwe irúgbìn tó kéré jùlọ àti ohun tí n mú ìyẹ̀fun wú

1813.18-19: Mt 13.31-32; Mk 4.30-32.Ó sì wí pé, “Kín ni ìjọba Ọlọ́run jọ? Kín ni èmi ó sì fiwé? 19Ó dàbí hóró musitadi, tí ọkùnrin kan mú, tí ó sì sọ sínú ọgbà rẹ̀; tí ó sì hù, ó sì di igi ńlá; àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run sì ń gbé orí ẹ̀ka rẹ̀.”

2013.20-21: Mt 13.33.Ó sì tún wí pé, “Kín ni èmi ìbá fi ìjọba Ọlọ́run wé? 21Ó dàbí ìwúkàrà, tí obìnrin kan mú, tí ó fi sínú òṣùwọ̀n ìyẹ̀fun mẹ́ta, títí gbogbo rẹ̀ ó fi di wíwú.”

Ọ̀nà tóóró

2213.22: Lk 9.51; 17.11; 18.31; 19.11.Ó sì ń la àárín ìlú àti ìletò lọ, ó ń kọ́ni, ó sì ń rìn lọ sí Jerusalẹmu. 2313.23-24: Mt 7.13-14; Jh 10.7.Ẹnìkan sì bi í pé, Olúwa, díẹ̀ ha kọ ni àwọn tí a ó gbàlà?

Ó sì wí fún wọn pé, 24“Ẹ làkàkà láti gba ojú ọ̀nà tóóró wọlé: nítorí mo wí fún yín, ènìyàn púpọ̀ ni yóò wá ọ̀nà láti wọ̀ ọ́, wọn kì yóò sì lè wọlé. 2513.25: Mt 25.10-12.Nígbà tí baálé ilé bá dìde lẹ́ẹ̀kan fùú, tí ó bá sí ti ìlẹ̀kùn, ẹ̀yin ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í dúró lóde, tí ẹ ó máa kan ìlẹ̀kùn, wí pé, ‘Olúwa, Olúwa, ṣí i fún wa!’

“Òun ó sì dáhùn wí fún yín pé, ‘Èmi kò mọ̀ ibi tí ẹ̀yin ti wá.’ Bẹ́ẹ̀ ni èmi kò mọ̀ yín.

2613.26-27: Mt 7.21-23; 25.41; Lk 6.46.“Nígbà náà ni ẹ̀yin ó bẹ̀rẹ̀ sí wí pé, ‘Àwa ti jẹ, àwa sì ti mu níwájú rẹ, ìwọ sì kọ́ni ní ìgboro ìlú wa.’

27“Òun ó sì wí pé, ‘Èmi wí fún yín èmi kò mọ̀ ibi tí ẹ̀yin ti wá; ẹ lọ kúrò lọ́dọ̀ mi gbogbo ẹ̀yin tí ń ṣiṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀.’

2813.28-29: Mt 8.11-12.“Níbẹ̀ ni ẹkún àti ìpahínkeke yóò wà, nígbà tí ẹ̀yin ó rí Abrahamu, àti Isaaki, àti Jakọbu, àti gbogbo àwọn wòlíì, ní ìjọba Ọlọ́run, tí a ó sì ti ẹ̀yin sóde. 29Wọn ó sì ti ilẹ̀ ìlà-oòrùn, àti ìwọ̀-oòrùn wá, àti láti àríwá, àti gúúsù wá, wọn ó sì jókòó ní ìjọba Ọlọ́run. 3013.30: Mt 19.30; Mk 10.31.Sì wò ó, àwọn ẹni ẹ̀yìn ń bẹ tí yóò di ẹni iwájú, àwọn ẹni iwájú ń bẹ tí yóò di ẹni ẹ̀yìn.”

Jesu káàánú fún Jerusalẹmu

31Ní wákàtí kan náà, díẹ̀ nínú àwọn Farisi tọ̀ ọ́ wá, wọ́n sì wí fún un pé, “Jáde, kí ìwọ sì lọ kúrò níhìn-ín yìí: nítorí Herodu ń fẹ́ pa ọ́.”

3213.32: Hb 2.10; 7.28.Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ lọ, kí ẹ̀yin sì sọ fún kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ náà pé, ‘Kíyèsi i, èmi ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde, èmi ń ṣe ìmúláradá lónìí àti lọ́la, àti ní ọjọ́ mẹ́ta èmi ó ṣe àṣepé.’ 33Ṣùgbọ́n èmi kò jẹ́ má rìn lónìí, àti lọ́la, àti ní ọ̀túnla: dájúdájú wòlíì kan ki yóò ṣègbé lẹ́yìn odi Jerusalẹmu.

3413.34-35: Mt 23.37-39; Lk 19.41.“Jerusalẹmu, Jerusalẹmu, ìwọ tí o pa àwọn wòlíì, tí o sì sọ òkúta lu àwọn tí a rán sí ọ pa; nígbà mélòó ni èmi ń fẹ́ ràgà bo àwọn ọmọ rẹ, bí àgbébọ̀ adìyẹ ti í ràgà bo àwọn ọmọ rẹ̀ lábẹ́ apá rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò fẹ́! 3513.35: Jr 22.5; Sm 118.26; Lk 19.38.Sá wò ó, a fi ilé yín sílẹ̀ fún yín ní ahoro. Lóòtítọ́ ni mo sì wí fún yín, ẹ̀yin kì yóò sì rí mi títí yóò fi di àkókò tí ẹ̀yin ó wí pé, ‘Olùbùkún ni ẹni tí ó ń bọ̀ wá ní orúkọ Olúwa.’ ”