Jeremias 7 – OL & YCB

O Livro

Jeremias 7:1-34

Religião falsa é inútil

1Então o Senhor disse a Jeremias: 2“Vai até à entrada do templo do Senhor e dá esta mensagem ao povo: Ó Judá, ouve a mensagem de Deus! Ouçam-na, todos vocês que aqui vêm para adorar! 3O Senhor dos exércitos, o Deus de Israel, diz: Apesar de tudo, se deixarem os vossos maus caminhos, deixar-vos-ei ficar na vossa terra. 4Mas não se deixem enganar nem ser iludidos por aqueles que vos dizem: ‘Este é o templo do Senhor! É o templo do Senhor! É o templo do Senhor! Estamos em segurança!’ 5Só sob estas condições é que poderão ficar: Se acabarem com os vossos maus pensamentos e com os vossos maus procedimentos, se forem honestos uns para com os outros. 6Se pararem de explorar os órfãos, as viúvas e os estrangeiros, se pararem com os assassínios e o derramamento de sangue, e deixarem de adorar ídolos, como fazem agora, para o vosso próprio mal. 7Então, e só então, vos deixarei ficar nesta terra que dei aos vossos antepassados para que a possuíssem para sempre.

8Pensam vocês que, devido ao facto do templo estar aqui, nunca hão de sofrer? Não sejam loucos, enganando-se a vós mesmos! 9Como é que podem pensar que continuando a roubar, a matar, a cometer adultérios, a mentir, a adorar a Baal e a todos esses novos deuses estranhos que arranjaram, podem continuar a vir aqui? 10Como podem pôr-se diante de mim no meu templo e cantar: ‘Estamos salvos, somos livres!’, só para poderem voltar, de consciência descansada, a cometer as mesmas abominações? 11Acaso consideram esta minha casa, este templo que tem o meu nome, uma caverna de salteadores? O que eu tenho visto é entrar aqui toda a espécie de maldades!

12Vão até Silo, a povoação que logo no princípio honrei com o meu nome, e vejam o que lhe fiz, por causa de toda a maldade do meu povo de Israel. 13E agora, diz o Senhor, farei a mesma coisa aqui, por causa de toda a maldade que têm praticado. Vezes sem conta vos falei sobre isto, chamando-vos sempre a atenção, mas recusaram ouvir-me ou sequer responder-me. 14Sim, com certeza destruirei este templo tal como fiz em Silo! Este templo que tem o meu nome e no qual confiam para obter socorro, este lugar que vos dei e aos vossos antepassados. 15Mandar-vos-ei para o exílio, como aconteceu com os vossos irmãos, o povo de Efraim.

16Não ores mais por este povo, Jeremias! Não chores por ele, não faças oração a favor dele, rogando-me que o ajude, pois não te ouvirei! 17Não vês o que estão a fazer nas ruas de Jerusalém e nas cidades de Judá? 18Não admira que seja tão grande a minha ira! Vê como as crianças vão buscar lenha para os pais acenderem o fogo, a fim das mulheres poderem amassar a farinha e fazer bolos para oferecerem à Rainha dos Céus e a todos os outros seus ídolos a que chamam deuses! 19Pergunta o Senhor: será só a mim que eles ferem? Não será também a eles próprios, aviltando-se dessa maneira com coisas tão vergonhosas?

20Por isso, assim diz o Senhor Deus: Derramarei a minha cólera, sim, a minha fúria sobre este lugar! Gente, animais, árvores e demais vegetação serão consumidos pelo fogo inextinguível da minha severidade.

21O Senhor dos exércitos, o Deus de Israel, diz: Para longe com todos os vossos holocaustos e ofertas! 22Não foi nem ofertas nem holocaustos que pedi aos vossos pais, quando os conduzi para fora do Egito. Não era esse o aspeto essencial daquilo que lhes ordenava. 23O que eu lhes dizia era: Obedeçam-me e eu serei o vosso Deus e vocês serão o meu povo! Façam simplesmente o que eu vos disse e tudo vos correrá bem!

24Mas não quiseram ouvir-me e continuaram a fazer tudo o que lhes apetecia, seguindo o curso dos seus próprios pensamentos rebeldes e perversos. Foi assim que recuaram, em vez de progredirem. 25Desde o dia em que os vossos pais deixaram o Egito, até agora, continuei a enviar-lhes os meus profetas. 26Mas não estiveram na disposição de os ouvir e nem sequer fizeram um esforço! São duros, obstinados e rebeldes! Piores ainda do que os seus pais!

27Diz-lhes tudo o que lhes farei, mas não esperes que te ouçam. Grita bem alto os teus avisos, mas não contes que te respondam. 28Diz-lhes: Esta é uma nação que recusa obedecer ao Senhor, seu Deus, que se recusa a ser ensinada, e assim continua a viver uma mentira.

29Ó Jerusalém, rapa a tua cabeça de vergonha e chora sozinha sobre as montanhas, porque o Senhor rejeitou e esqueceu esta geração, por causa da sua ira!

O vale da Matança

30O povo de Judá pecou perante os meus olhos, diz o Senhor. Puseram as suas abominações ali mesmo, no meu próprio templo, poluindo-o. 31Construíram um altar chamado Tofete, no vale de Ben-Hinom7.31 Também chamado de vale do filho de Hinom. Situado a sudeste de Jerusalém., e ali queimaram no fogo os seus próprios filhos e filhas, em sacrifícios aos seus deuses, uma coisa tão terrível que nem sequer me passava pela mente, e que nunca teria permitido. 32Vem o tempo, diz o Senhor, em que o nome do vale não será mais Tofete ou vale de Ben-Hinom, mas vale da Matança. Porque haverá ali tantos mortos a enterrar que nem se acharão sepulcros que cheguem para pôr todos os corpos. 33Terão de amontoar os cadáveres no vale; os corpos deste povo servirão de pasto às aves de rapina e aos animais selvagens e não haverá ninguém para os enxotar. 34Acabarei com as alegres canções e os risos que se ouvem nas ruas de Jerusalém e nas cidades de Judá, assim como com as vozes dos noivos e das noivas. Porque a terra ficará numa desolação.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Jeremiah 7:1-34

Ẹ̀sìn àìṣòótọ́ kò níláárí

1Èyí ni ọ̀rọ̀ tó tọ Jeremiah wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa. 2“Dúró ní ẹnu-ọ̀nà ilé Olúwa kí o sì kéde ọ̀rọ̀ yí:

“ ‘Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa gbogbo ẹ̀yin ará Juda tí ń gba ọ̀nà yí wọlé láti wá sin Olúwa. 3Èyí ni ọ̀rọ̀ tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run Israẹli wí: Tún àwọn ọ̀nà yín ṣe, èmi yóò sì jẹ́ kí ẹ gbé ilẹ̀ yìí. 4Má ṣe gba ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn gbọ́ kí ẹ sì wí pé, “Èyí ni tẹmpili Olúwa ilé tẹmpili Olúwa, ilé tẹmpili Olúwa!” 5Bí ẹ̀yin bá tún ọ̀nà yín àti iṣẹ́ yín ṣe nítòótọ́, tí ẹ sì ń bá ara yín lò ní ọ̀nà tó tọ́. 6Bí ẹ kò bá fi ara ni àwọn àlejò, àwọn ọmọ aláìní baba àti àwọn opó tí ẹ kò sì ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀ ní ibí yìí, bí ẹ kò bá sì tọ ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn sí ìpalára ara yín. 7Nígbà náà ni èmi yóò jẹ́ kí ẹ gbé ìbí yìí, nílẹ̀ tí mo fún àwọn baba ńlá yín títí láé. 8Ẹ wò ó, ẹ ń gba ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn tí kò níláárí gbọ́.

9“ ‘Ẹ̀yin yóò ha jalè, kí ẹ pànìyàn, kí ẹ ṣe panṣágà, kí ẹ búra èké, kí ẹ sun tùràrí sí Baali, kí ẹ sì tọ ọlọ́run mìíràn tí ẹ̀yin kò mọ̀ lọ? 10Nígbà náà ni kí ó wá dúró ní iwájú nínú ilé yìí tí a fi orúkọ mi pè, “Kí ẹ wá wí pé àwa yè,” àwa yè láti ṣe gbogbo àwọn nǹkan ìríra wọ̀nyí bí? 117.11: Mt 21.13; Mk 11.17; Lk 19.46.Ṣé ilé yìí, tí a fi orúkọ mi pè ti di ihò àwọn ọlọ́ṣà lọ́dọ̀ yín ni? Èmi ti ń wò ó! ni Olúwa wí.

12“ ‘Ẹ lọ nísinsin yìí sí Ṣilo níbi ti mo kọ́ fi ṣe ibùgbé fún orúkọ mi, kí ẹ sì rí ohun tí mo ṣe sí i nítorí ìwà búburú Israẹli tí í ṣe ènìyàn mi. 13Nígbà tí ẹ̀yin ń ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí ni èmi bá a yín sọ̀rọ̀ léraléra ni Olúwa wí ẹ̀yin kò gbọ́, èmi pè yín, ẹ̀yin kò dáhùn 14Nítorí náà, èmi yóò ṣe ohun tí mo ṣe sí Ṣilo sí ilé náà tí a fi orúkọ mi pè, ilé tẹmpili nínú èyí tí ẹ ní ìgbẹ́kẹ̀lé, ààyè tí mo fún ẹ̀yin àti àwọn baba yín. 15Èmi yóò tú kúrò ní iwájú mi gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣe sí àwọn arákùnrin yín, àwọn ará Efraimu.’

16“Nítorí náà má ṣe gbàdúrà fún àwọn ènìyàn wọ̀nyí tàbí kí o bẹ̀bẹ̀ fún wọn; ma ṣe bẹ̀ mí, nítorí èmi kì yóò tẹ́tí sí ọ. 17Ṣé ìwọ kò rí ohun tí wọ́n ń ṣe ní àwọn ìlú Juda àti ní òpópó Jerusalẹmu? 18Àwọn ọmọ ṣa igi jọ, àwọn baba fi iná sí i, àwọn ìyá sì po ìyẹ̀fun láti ṣe àkàrà fún ayaba ọ̀run, wọ́n tú ẹbọ ọrẹ mímu sí àwọn ọlọ́run àjèjì láti ru bínú mi sókè. 19Ṣùgbọ́n ṣe èmi ni wọ́n fẹ́ mú bínú? ni Olúwa wí. Ǹjẹ́ kì í ṣe pé wọ́n kúkú ń pa ara wọn lára sí ìtìjú ara wọn?

20“ ‘Nítorí náà, èyí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè wí: Èmi yóò tú ìbínú àti ìrunú mi sí orílẹ̀ yìí ènìyàn àti ẹranko, igi, pápá àti èso orí ilẹ̀, yóò sì jó tí kò ní ṣe é pa.

21“ ‘Èyí ni Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun, Ọlọ́run Israẹli wí: Tẹ̀síwájú kí ẹ kó ẹbọ sísun yín àti àwọn ẹbọ yòókù papọ̀ kí ẹ̀yin kí ó sì jẹ ẹran wọ́n fúnrayín. 22Ní tòsí nígbà tí mo mú àwọn baba ńlá yín jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti tí mo sì bá wọn sọ̀rọ̀. N kò pàṣẹ fún wọn lórí ẹbọ sísun lásán. 23Mo pàṣẹ fún wọn báyìí pé: Gbọ́ tèmi, èmi yóò sì jẹ́ Ọlọ́run yín ẹ̀yin yóò sì jẹ́ ènìyàn mi. Máa rìn ní ojú ọ̀nà tí mo pàṣẹ fún yín, kí ó lè dára fún yín. 24Ṣùgbọ́n wọn kò gbọ́, wọn kò sì fetísílẹ̀ dípò èyí wọ́n ń tẹ̀ sí ọ̀nà agídí ọkàn wọn. Dípò kí wọn tẹ̀síwájú wọ́n ń rẹ̀yìn. 25Láti ìgbà tí àwọn baba ńlá yín ti jáde ní Ejibiti títí di òní, ni èmi ti ń rán àwọn ìránṣẹ́ mi, àwọn wòlíì sí yín. 26Wọn kò gbọ́ wọn kò sì fetísílẹ̀. Wọ́n wa ọrùn le, wọn wa ọrùn kì, wọ́n sì hu ìwà ìbàjẹ́ ju àwọn baba ńlá wọn.’

27“Nígbà tí ìwọ bá sọ gbogbo èyí fún wọn, wọn kì yóò gbọ́ tirẹ̀, nígbà tí ìwọ bá sì pè wọ́n, wọn kì yóò dáhùn. 28Nítorí náà, sọ fún wọn pé ‘Èyí ni orílẹ̀-èdè tí kò gbọ́ ti Olúwa Ọlọ́run rẹ̀ tàbí kí ó ṣe ìgbọ́ràn sí ìbáwí. Ọ̀rọ̀ òtítọ́ kò sí ní ètè wọn.

29“ ‘Gé irun yín kí ẹ sì dàánù, pohùnréré ẹkún lórí òkè, nítorí Olúwa ti kọ ìran yìí tí ó wà lábẹ́ ìbínú rẹ̀ sílẹ̀.

Àfonífojì ìparun

30“ ‘Àwọn ènìyàn Juda ti ṣe búburú lójú mi, ni Olúwa wí. Wọ́n ti to àwọn ère ìríra wọn jọ sí ilé tí a fi orúkọ mi pè wọ́n sì ti sọ ọ́ di àìmọ́. 31Wọ́n ti kọ́ àwọn ibi gíga ti Tofeti ní Àfonífojì Beni-Hinnomu láti sun àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin wọn nínú iná èyí tí èmi kò pàṣẹ tí kò sì wá sí ọkàn mi. 32Nítorí náà kíyèsára ọjọ́ ń bọ̀, ni Olúwa wí, nígbà tí àwọn ènìyàn kò ní pè é ní Tafeti tàbí Àfonífojì ti Beni-Hinnomu; ṣùgbọ́n yóò ma jẹ Àfonífojì Ìparun, nítorí wọn yóò sin òkú sí Tofeti títí kò fi ní sí ààyè mọ́ 33Nígbà náà ni òkú àwọn ènìyàn wọ̀nyí yóò di oúnjẹ fún àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run àti ẹranko ilẹ̀, kò sì ní sí ẹnìkan tí yóò dẹ́rùbà wọ́n. 347.34: If 18.23.Èmi yóò mú òpin bá ìró ayọ̀ àti ìdùnnú àti ohùn àwọn tọkọtaya ní àwọn ìlú Juda àti ní ìgboro Jerusalẹmu, nítorí tí ilẹ̀ náà yóò di ahoro.