Ezequiel 45 – OL & YCB

O Livro

Ezequiel 45:1-25

A divisão da terra

1Ao repartirem a terra pelas tribos de Israel, darão primeiramente uma área ao Senhor como sua porção sagrada. Esta zona deverá ter 12,5 quilómetros de comprimento por 10 quilómetros de largura. Esse solo será sagrado. 2Uma secção dessa terra, com 250 metros quadrados, será atribuída para edificação do templo. Acrescentar-se-lhe-á uma zona adicional de 25 metros em toda a volta que deverá ficar vazia. 3Metade dessa área, isto é, um terreno com 12,5 quilómetros de comprimento e 5 quilómetros de largura, deverá ser separado para o templo. 4Toda essa porção de solo será terra santíssima; será usada pelos sacerdotes que servem no santuário, para as suas casas, ao mesmo tempo que é o sítio do meu templo. 5A zona adstrita a esta, de 12,5 quilómetros de comprimento e de 5 quilómetros de largura, servirá de zona de residência para os levitas que trabalham no templo.

6Adjacente a esse local santo haverá uma secção de terreno de 12,5 quilómetros por 2,5 quilómetros que ficará aberta a toda a gente em Israel.

7Duas zonas especiais da terra serão postas de parte para o príncipe, uma de cada lado desse local santo e dessa secção aberta a todos; confinará com estas no seu comprimento; os seus limites, tanto a ocidente como a oriente, são os mesmos que os das zonas atribuídas às tribos. 8Este será o seu lote. Os meus príncipes não mais oprimirão nem defraudarão o povo. Deverão, portanto, atribuir tudo o que restar da terra do povo, dando uma porção a cada tribo.

9Diz o Senhor Deus aos governantes: Deixem de explorar e correr com o meu povo para fora da terra pela violência, despojando-o dos seus lares. Procurem sempre agir com justiça e honestidade. 10Apliquem a justiça em tudo o que seja medições, balanças ou escalas de medida. 11O homer45.11 Homer. Equivale a 220 litros. será a vossa unidade de base, tanto para medir líquidos como sólidos. As medidas inferiores serão o efa45.11 Efa. Equivale a 22 litros, ou seja, 1/10 do homer. para os sólidos e o bato45.11 Bato. Equivale a 22 litros. para os líquidos. 12A unidade de peso será o siclo45.12 Siclo. Equivale aproximadamente a 11,5 gramas. de prata e valerá sempre vinte geras, e não menos do que isso; cinco siclos valem mesmo cinco siclos e nunca menos; dez siclos são mesmo dez siclos; sessenta siclos equivalem a uma mina45.12 Mina. Equivale aproximadamente a 50 siclos, ou seja, 560 gramas..

Ofertas e dias santos

13As vossas ofertas deverão ser feitas da seguinte maneira: devem dar uma medida em cada sessenta das vossas colheitas de trigo e de cevada. 14Devem dar um por cento do vosso azeite; meçam o azeite com um bato, que é a décima parte do homer, e é igualmente a décima parte do coro45.14 Coro. Equivale a 220 litros, ou seja, 10 batos.. 15Quanto ao gado, por cada duzentas ovelhas dos vossos rebanhos em Israel darão uma. Estas são as ofertas de alimentos, holocaustos e ofertas de paz, para fazer a expiação por aqueles que as trouxerem, diz o Senhor Deus. 16Todo o povo de Israel deverá trazer as suas ofertas ao príncipe de Israel. 17O príncipe terá a obrigação de fornecer ao povo todos os sacrifícios necessários para as celebrações de adoração pública; ofertas pelo pecado, holocaustos, ofertas de vinho, de alimentos e de paz, para fazer expiação pelo povo de Israel. Isto será por altura das festas religiosas, das cerimónias da lua nova, dos sábados e de todas as outras ocasiões semelhantes.

18Diz o Senhor Deus: No primeiro dia de cada ano novo45.18 Primeiro dia do primeiro mês do ano, Abibe ou Nisan. Entre a lua nova do mês de março e o mês de abril. sacrifiquem um novilho, sem defeito, para purificar o templo. 19O sacerdote pegará em parte do sangue desta oferta pelo pecado e pô-lo-á nos umbrais da porta do templo e sobre os quatro cantos da base do altar, e ainda sobre as paredes da entrada do pátio interior. 20Façam isto também no sétimo dia desse mesmo primeiro mês por alguém que tenha pecado por erro ou ignorância; e assim o templo ficará purificado.

21No dia 14 do primeiro mês celebrarão a Páscoa. Durante sete dias comerão pão sem fermento. 22Nesses dias comer-se-á unicamente pão sem fermento. No dia de Páscoa o príncipe fornecerá um novilho para ser apresentado como oferta pelo pecado, por si próprio e pelo povo de Israel. 23E em cada um dos sete dias seguintes dessa celebração devem preparar um holocausto ao Senhor. Esta oferta diária consistirá em sete novilhos e sete carneiros sem qualquer defeito. Um bode será também ofertado diariamente por expiação do pecado. 24O príncipe fornecerá 3,8 litros de grão para oferta de cereais, 22 litros por cada um dos novilhos e carneiros, e 3,8 litros de azeite para acompanhar cada efa de grão.

25Durante os sete dias da festa dos tabernáculos, que se realiza no décimo quinto dia do sétimo mês45.25 Mês de Tisri ou Etanim. Entre a lua nova do mês de setembro e o mês de outubro., o príncipe fornecerá os mesmos sacrifícios para a expiação do pecado; os holocaustos, as ofertas de cereais e as ofertas de azeite.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Esekiẹli 45:1-25

Ilẹ̀ pínpín

1“ ‘Nígbà ti ẹ̀yin bá pín ilẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ogún, ẹ gbọdọ̀ gbé ìpín ilẹ̀ kan kalẹ̀ fún Olúwa gẹ́gẹ́ bí ibi mímọ́, ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ìgbọ̀nwọ́ ni gígùn àti ogún ẹgbẹ̀rún ìgbọ̀nwọ́ ni ìbú; gbogbo agbègbè rẹ̀ yíká ni yóò jẹ́ mímọ́. 2Lára inú èyí, ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta yóò jẹ́ ti ibi mímọ́ ní gígùn, pẹ̀lú ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ní ìbú, ní igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin yíká, àti àádọ́ta ìgbọ̀nwọ́ fún gbangba rẹ̀ yíká. 3Ní agbègbè ibi mímọ́, wọn ya ibi kan sọ́tọ̀ kí ó jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn àti ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ní ìbú. Ní inú rẹ ni ilẹ̀ ti a yà sọ́tọ̀ fún Olúwa yóò wà, ìyẹn ibi mímọ́ jùlọ. 4Yóò jẹ́ ibi mímọ́ lára ilẹ̀ náà fún àwọn àlùfáà, tí ó ń ṣiṣẹ́ ìránṣẹ́ ní ibi mímọ́ àti àwọn tí ó súnmọ́ àlùfáà ní iwájú Olúwa. Ibẹ̀ yóò jẹ ibi tí yóò wà fún ilé gbígbé wọn, bákan náà ni yóò jẹ́ ibi mímọ́ fún ilé Olúwa. 5Agbègbè kan tí ó jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn àti ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá ní ìbú yóò jẹ́ ti àwọn ọmọ Lefi, tí ó ń ṣiṣẹ́ ìránṣẹ́ nínú tẹmpili, gẹ́gẹ́ bi ìní wọn fún ìlú wọn láti máa gbé ibẹ̀.

6“ ‘Ìwọ yóò fi ìlú náà ti agbègbè rẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún márùn-ún ìgbọ̀nwọ́ ni ìbú àti ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn, papọ̀ mọ́ ibi mímọ́ fún àwọn ilé Israẹli gẹ́gẹ́ bí ìní: yóò jẹ́ ti gbogbo ilé Israẹli.

7“ ‘Àwọn ọmọ-aládé ni yóò bá ibi mímọ́ pààlà ní ẹ̀gbẹ́ kọ̀ọ̀kan agbègbè tí ó jẹ ibi mímọ́ àti ohun tí ó jẹ́ ti ìlú. Yóò fẹ̀ sẹ́yìn sí ìhà ìwọ̀-oòrùn láti apá ìwọ̀-oòrùn àti si ìlà-oòrùn, láti apá ìlà-oòrùn, gígùn rẹ̀ yóò jẹ́ láti ìwọ̀-oòrùn sí ààlà ìlà-oòrùn, ti ìṣe déédé rẹ̀ yóò jẹ́ ti ọ̀kan lára àwọn ìpín ẹ̀yà. 8Ilẹ̀ yìí ni yóò jẹ́ ìpín rẹ̀ ní Israẹli. Àwọn ọmọ-aládé mìíràn kò ní rẹ́ àwọn ènìyàn mi jẹ mọ́, ṣùgbọ́n wọn yóò jẹ́ kí àwọn ilé Israẹli gba ilẹ̀ wọn gẹ́gẹ́ bi ẹ̀yà wọn.

9“ ‘Èyí yìí ni Olúwa Olódùmarè wí: Ẹ̀yin ti rìn jìnnà tó, Ẹ̀yin ọmọ-aládé tí Israẹli! Ẹ fi ìwà ipá àti ìrẹ́jẹ yín sílẹ̀ kí ẹ̀yin sì ṣe èyí tí ó tọ́ àti èyí tí ó yẹ. Ẹ dáwọ́ gbígbà ní ọwọ́ àwọn ènìyàn mi dúró, ni Olúwa Ọlọ́run wí. 10Kí ẹ̀yin kì ó lo òṣùwọ̀n tó tọ́ àti efa títọ́ àti bati títọ́. 11Efa àti bati gbọdọ̀ jẹ́ bákan náà, kí bati tí ó gba ìdámẹ́wàá homeri, àti efa ìdámẹ́wàá homeri: Homeri ni kí ó jẹ́ òṣùwọ̀n tí ẹ̀yin yóò lò fún méjèèjì. 12Ṣékélì ní kí o gba ogún gera. Ogún ṣékélì pẹ̀lú ṣékélì márùn-dínlọ́gbọ̀n pẹ̀lú ṣékélì mẹ́ẹ̀ẹ́dógún yóò jẹ́ minas kan.

Ọrẹ àti àwọn ọjọ́ mímọ́

13“ ‘Èyí yìí ni ẹ̀bùn pàtàkì tí ẹ gbọdọ̀ ṣe: efa kẹfà láti inú homeri ọkà kọ̀ọ̀kan àti efa kẹfà láti inú homeri barle kọ̀ọ̀kan. 14Ìpín òróró tí a júwe, tí a fi bati wọ́n, ni ìdámẹ́wàá bati láti inú kórì (èyí tí ó gba ìdámẹ́wàá bati tàbí homeri kan, fún ìdámẹ́wàá bati jẹ́ bákan náà sì homeri kan.) 15Bákan náà ni ọ̀dọ́-àgùntàn kan láti inú agbo ẹran, láti inú igba, láti inú pápá oko tútù Israẹli, fún ọrẹ ẹbọ jíjẹ, àti fún ọrẹ ẹbọ sísun, àti fún ọrẹ ẹbọ ìdúpẹ́ láti ṣe ìwẹ̀nùmọ́ fún àwọn ènìyàn, ní Olúwa Olódùmarè wí. 16Gbogbo ènìyàn ni ilẹ̀ náà ni yóò kópa nínú ẹ̀bùn pàtàkì fún ìlò àwọn ọmọ-aládé ni Israẹli. 17Yóò jẹ́ ojúṣe ọmọ-aládé láti pèsè ọrẹ ẹbọ sísun, ọrẹ ẹbọ jíjẹ àti ọrẹ ẹbọ mímu níbi àsè gbogbo, ti oṣù tuntun àti ní àwọn ọjọ́ ìsinmi ni gbogbo àjọ̀dún tí a yàn ní ilé Israẹli. Òun yóò pèsè ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, ọrẹ ẹbọ jíjẹ, ọrẹ ẹbọ sísun àti ọrẹ ẹbọ ìdàpọ̀, láti ṣe ètùtù fún ilé Israẹli.

18“ ‘Èyí yìí ní Olúwa Olódùmarè wí: Ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù kìn-ín-ní ìwọ yóò mú akọ màlúù aláìlábàwọ́n kì o sì sọ ilé Ọlọ́run di mímọ́. 19Àlùfáà ni yóò mú díẹ̀ nínú ẹ̀jẹ̀ ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, kí o sì fi si ẹnu ìlẹ̀kùn ilé Ọlọ́run, àti sí ara àwọn ìlẹ̀kùn tí ó wà ní àgbàlá ti inú. 20Ìwọ yóò ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ní ọjọ́ keje oṣù fún àwọn tí ó dá ẹ̀ṣẹ̀ àìmọ̀ọ́mọ̀dá tàbí nínú àìmọ̀kan; nítorí náà, ìwọ yóò ṣe ìwẹ̀nùmọ́ fún ilé Ọlọ́run.

21“ ‘Ní ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kìn-ín-ní ní ìwọ yóò ṣe àjọ ìrékọjá, àsè ọjọ́ méje, àsìkò yìí ní ẹ̀yin yóò jẹ àkàrà tí kò ni ìwúkàrà. 22Ní ọjọ́ náà ní ọmọ-aládé yóò pèsè akọ màlúù gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ fún ara rẹ̀ àti fún gbogbo ènìyàn ni ilẹ̀ náà. 23Ní ojoojúmọ́ ni àárín ọjọ́ méje àsè ni òun yóò pèsè akọ màlúù méje àti àgbò méje tí kò ní àbùkù gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ sísun sí Olúwa, àti akọ ewúrẹ́ fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀. 24Òun yóò sì pèsè efa gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ jíjẹ. Efa kan fún akọ màlúù kọ̀ọ̀kan àti efa kan fún àgbò kọ̀ọ̀kan, pẹ̀lú hínì òróró kan fún efa kan.

25“ ‘Láàrín ọjọ́ méje àsè náà, tí ó bẹ̀rẹ̀ ní ọjọ́ kẹ́ẹ̀dógún oṣù keje, òun yóò tún pèsè ohun kan náà fún ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, ọrẹ ẹbọ sísun, ọrẹ ẹbọ ohun jíjẹ, àti fún òróró.