Job 13 – NVI & YCB

Nueva Versión Internacional

Job 13:1-28

1»Todo esto lo han visto mis ojos;

lo han captado y entendido mis oídos.

2Yo tengo tanto conocimiento como ustedes;

en nada siento que me aventajen.

3Más bien quisiera hablar con el Todopoderoso;

me gustaría discutir mi caso con Dios.

4Porque ustedes me difaman con mentiras;

¡como médicos no valen nada!

5¡Si tan solo se callaran la boca!

Eso, en ustedes, ya sería sabiduría.

6Ahora les toca escuchar mi defensa;

presten atención a mi alegato.

7¿Se atreverán a decir falsedades en nombre de Dios?

¿Argumentarán en su favor con engaños?

8¿Le harán el favor de defenderlo?

¿Van a resultar sus abogados defensores?

9¿Qué pasaría si él los examinara?

¿Podrían engañarlo como se engaña a la gente?

10Lo más seguro es que él los reprendería

si en secreto se mostraran parciales.

11¿Acaso no les infundiría miedo su esplendor?

¿Y no caería sobre ustedes su terror?

12¡Han memorizado proverbios sin sentido!

¡Se defienden con apologías endebles!

13»¡Cállense la boca, déjenme hablar,

y que venga lo que venga!

14¿Por qué me pongo en peligro

y me juego el pellejo?

15¡Que me mate, en él tengo mi esperanza!13:15 ¡Que me mate … esperanza! Alt. Aunque él me mate, seguiré esperando en él.

Pero en su propia cara defenderé mi conducta.

16En esto radica mi liberación:

en que ningún impío comparecería ante él.

17Presten atención a mis palabras;

presten oído a lo que digo:

18Vean que ya he preparado mi caso

y sé muy bien que seré declarado inocente.

19¿Hay quien pueda presentar cargos contra mí?

Si lo hay, me quedaré callado hasta morir.

20»Concédeme, oh Dios, solo dos cosas

y no tendré que esconderme de ti:

21Quítame la mano de encima

y deja de infundirme temor.

22Llámame a comparecer y te responderé

o déjame hablar y contéstame.

23Enumera mis iniquidades y pecados;

hazme ver mis transgresiones y ofensas.

24¿Por qué no me das la cara?

¿Por qué me tienes por enemigo?

25¿Acosarás a una hoja arrebatada por el viento?

¿Perseguirás a la paja seca?

26Has dictado contra mí penas amargas;

me estás cobrando13:26 cobrando. Lit. heredando. los pecados de mi juventud.

27Me has puesto cadenas en los pies;

vigilas todos mis pasos;

examinas las huellas que dejo al caminar.

28»El hombre se deteriora como algo podrido;

como ropa carcomida por la polilla.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Jobu 13:1-28

Jobu gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run

1“Wò ó, ojú mi ti rí gbogbo èyí rí,

etí mí sì gbọ́, ó sì ti yé mi.

2Ohun tí ẹ̀yin mọ̀, èmi mọ̀ pẹ̀lú,

èmi kò kéré sí i yin.

3Nítòótọ́ èmi ó bá Olódùmarè

sọ̀rọ̀, èmi sì ń fẹ́ bá Ọlọ́run sọ àsọyé.

4Ẹ̀yin fi irọ́ bá mi sọ̀rọ̀,

oníṣègùn lásán ni gbogbo yín.

5Háà! ẹ̀yin kì bá kúkú dákẹ́!

Èyí ni kì bá sì ṣe ọgbọ́n yín.

6Ẹ gbọ́ àwíyé mi nísinsin yìí;

ẹ sì fetísílẹ̀ sí àròyé ẹnu mi.

7Ẹ̀yin fẹ́ sọ ìsọkúsọ fún Ọlọ́run?

Ki ẹ sì fi ẹ̀tàn sọ̀rọ̀ gbè é?

8Ẹ̀yin fẹ́ ṣe ojúsàájú rẹ̀?

Ẹ̀yin fẹ́ gbèjà fún Ọlọ́run?

9Ó ha dára to tí yóò hú àṣírí yín síta,

Tàbí kí ẹ̀yin tàn án bí ẹnìkan ti í tan ẹnìkejì?

10Yóò máa bá yín wí nítòótọ́,

bí ẹ̀yin bá ṣe ojúsàájú ènìyàn níkọ̀kọ̀.

11Ìwà ọlá rẹ̀ kì yóò bà yín lẹ́rù bí?

Ìpayà rẹ̀ kì yóò pá yín láyà?

12Àwọn òwe yín dàbí eérú;

Bẹ́ẹ̀ ni àwọn odi ìlú yin dàbí amọ̀.

13“Ẹ pa ẹnu yín mọ́ kúrò lára mi, kí èmi kí ó lè sọ̀rọ̀,

ki ohun tí ń bọ̀ wá í bá mi, le è máa bọ̀.

14Ǹjẹ́ nítorí kí ni èmi ṣe ń fi eyín mi bu ẹran-ara mi jẹ,

Tí mo sì gbé ẹ̀mí mi lé ara mi lọ́wọ́?

15Bí ó tilẹ̀ pa mí, síbẹ̀ èmi ó máa gbẹ́kẹ̀lé e;

Ṣùgbọ́n èmi ó máa tẹnumọ́ ọ̀nà mi níwájú rẹ̀.

16Èyí ni yóò sì ṣe ìgbàlà mi,

Àgàbàgebè kì yóò wá síwájú rẹ̀.

17Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹnu mi ní ìfarabalẹ̀,

jẹ́ kí ọ̀rọ̀ mí dún ni etí yín.

18Wò ó nísinsin yìí, èmi ti mura ọ̀ràn mi sílẹ̀;

èmi mọ̀ pé a ó dá mi láre.

19Ta ni òun ti yóò bá mi ṣàròyé?

Ǹjẹ́ nísinsin yìí, èmi fẹ́ pa ẹnu mi mọ́,

èmi ó sì jọ̀wọ́ ẹ̀mí mi lọ́wọ́.

20“Ṣùgbọ́n, má ṣe ṣe ohun méjì yìí sí mi,

Nígbà náà ni èmi kì yóò sì fi ara mi pamọ́ kúrò fún ọ:

21Fa ọwọ́ rẹ sẹ́yìn kúrò lára mi,

má sì jẹ́ kí ẹ̀rù rẹ kí ó pá mi láyà.

22Nígbà náà ni kí ìwọ kí ó pè, èmi o sì dáhùn;

Ta ni jẹ́ kí ń máa sọ̀rọ̀, ki ìwọ kí ó sì dá mi lóhùn.

23Mélòó ní àìṣedéédéé àti ẹ̀ṣẹ̀ mi?

Mú mi mọ̀ ìrékọjá àti ẹ̀ṣẹ̀ mi.

24Nítorí kí ni ìwọ ṣe pa ojú rẹ mọ́,

tí o sì yàn mí ní ọ̀tá rẹ?

25Ìwọ ó fa ewé ti afẹ́fẹ́ ń fẹ́ síhìn-ín sọ́hùn-ún ya bi?

Ìwọ a sì máa lépa ìyàngbò?

26Nítorí pé ìwọ kọ̀wé ohun kíkorò sí mi,

o sì mú mi jogún àìṣedéédéé èwe mi.

27Ìwọ kàn àbà mọ́ mi lẹ́sẹ̀ pẹ̀lú,

ìwọ sì ń wò ipa ọ̀nà ìrìn mi ní àwòfín;

nípa fífi ìlà yí gígísẹ̀ mi ká.

28“Bẹ́ẹ̀ ni ènìyàn ń ṣègbé bí ohun ìdíbàjẹ́,

Bi aṣọ tí kòkòrò jẹ.