Isaías 19 – NVI & YCB

Nueva Versión Internacional

Isaías 19:1-25

Profecía contra Egipto

1Profecía contra Egipto:

¡Miren al Señor!

Llega a Egipto montado sobre una nube veloz.

Los ídolos de Egipto tiemblan en su presencia;

el corazón de los egipcios desfallece en su interior.

2«Incitaré a egipcio contra egipcio;

luchará hermano contra hermano,

amigo contra amigo,

ciudad contra ciudad,

reino contra reino.

3Los egipcios quedarán desanimados

y consultarán a los ídolos,

a los espíritus de los muertos,

a las médiums y a los espiritistas,

¡pero yo frustraré sus planes!

4Entregaré a los egipcios

en manos de un amo cruel;

un rey de mano dura los gobernará»,

afirma el Señor, el Señor de los Ejércitos.

5Se agotarán las aguas del Nilo;

árido y reseco quedará el lecho del río.

6Apestarán los canales

y bajará el nivel de los arroyos de Egipto hasta dejarlos completamente secos.

¡Las cañas y los juncos quedarán marchitos!

7A orillas del Nilo,

en la desembocadura del río,

la vegetación perderá su verdor.

Todos los sembrados junto al Nilo

quedarán asolados, dejarán de existir.

8Gemirán y se lamentarán todos los pescadores,

los que lanzan anzuelos en el Nilo;

desfallecerán los que echan redes en el agua.

9Quedarán frustrados los que trabajan el hilo de lino peinado;

perderán la esperanza los tejedores de lino fino.

10Quedarán desalentados los fabricantes de telas;

todos los asalariados se llenarán de angustia.

11Los oficiales de Zoán no son más que unos necios;

los consejeros más sabios dan a Faraón consejos insensatos.

¿Cómo se les ocurre decirle:

«Yo soy uno de los sabios,

discípulo de los antiguos reyes»?

12¿Dónde quedaron tus sabios?

Que te muestren y te hagan saber

lo que el Señor de los Ejércitos

ha planeado contra Egipto.

13Los oficiales de Zoán se han vuelto necios;

los líderes de Menfis se dejaron engañar.

Las piedras angulares de sus pueblos

han hecho que Egipto pierda el rumbo.

14El Señor ha infundido en ellos

un espíritu de desconcierto.

En todo lo que hace Egipto le han hecho perder el rumbo.

Como un borracho en su vómito, Egipto se tambalea.

15Nada puede hacerse por Egipto,

sea cabeza o cola, palmera o junco.

16En aquel día los egipcios se volverán cobardes. Se estremecerán de terror ante la mano amenazante que el Señor de los Ejércitos agita contra ellos. 17La tierra de Judá será un espanto para los egipcios. Por causa de lo que el Señor de los Ejércitos está planeando contra ellos, la sola mención de Judá llenará de espanto a los que oigan este nombre.

18En aquel día habrá en Egipto cinco ciudades que hablarán el idioma de Canaán y que jurarán lealtad al Señor de los Ejércitos. Una de ellas se llamará Ciudad del Sol.19:18 del Sol (mss. hebreos, Qumrán y Vulgata); de la destrucción (TM).

19En aquel día habrá un altar para el Señor en el corazón mismo de Egipto y en su frontera un monumento al Señor. 20Esto servirá en Egipto de señal y testimonio del Señor de los Ejércitos. Cuando ellos clamen al Señor por causa de sus opresores, él les enviará un salvador y defensor que los librará. 21De modo que el Señor se dará a conocer a los egipcios y en aquel día ellos reconocerán al Señor: lo servirán con sacrificios y ofrendas de grano. Harán promesas al Señor y se las cumplirán. 22El Señor herirá a los egipcios con una plaga y, aun hiriéndolos, los sanará. Ellos se volverán al Señor, y él responderá a sus ruegos y los sanará.

23En aquel día habrá un camino desde Egipto hasta Asiria. Los asirios irán a Egipto y los egipcios a Asiria, y unos y otros adorarán juntos. 24En aquel día Israel será, junto con Egipto y Asiria, una bendición en medio de la tierra. 25El Señor de los Ejércitos los bendecirá, diciendo: «Bendito sea Egipto, mi pueblo, y Asiria, obra de mis manos, e Israel, mi heredad».

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Isaiah 19:1-25

Àsọtẹ́lẹ̀ lòdì sí Ejibiti

119.1-25: Jr 46; El 29–32; Sk 14.18-19.Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ tí ó kan Ejibiti:

Kíyèsi i, Olúwa gun àwọsánmọ̀ tí ó yára lẹ́ṣin

ó sì ń bọ̀ wá sí Ejibiti.

Àwọn ère òrìṣà Ejibiti wárìrì níwájú rẹ̀,

ọkàn àwọn ará Ejibiti sì ti domi nínú wọn.

2“Èmi yóò rú àwọn ará Ejibiti sókè sí ara wọn

arákùnrin yóò bá arákùnrin rẹ̀ jà,

aládùúgbò yóò dìde sí aládùúgbò rẹ̀,

ìlú yóò dìde sí ìlú,

ilẹ̀ ọba sí ilẹ̀ ọba.

3Àwọn ará Ejibiti yóò sọ ìrètí nù,

èmi yóò sì sọ èrò wọn gbogbo di òfo;

wọn yóò bá àwọn òrìṣà àti ẹ̀mí àwọn òkú sọ̀rọ̀,

àwọn awoṣẹ́ àti àwọn abókùúsọ̀rọ̀.

4Èmi yóò fi Ejibiti lé agbára

àwọn ìkà amúnisìn lọ́wọ́,

ọba aláìláàánú ni yóò jẹ ọba lé wọn lórí,”

ni Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.

5Gbogbo omi inú odò ni yóò gbẹ,

gbogbo ilẹ̀ àyíká odò ni yóò gbẹ tí yóò sì sáàpá.

6Adágún omi yóò sì di rírùn;

àwọn odò ilẹ̀ Ejibiti yóò máa dínkù

wọn yóò sì gbẹ.

Àwọn koríko odò àti ìrẹ̀tẹ̀ yóò gbẹ,

7àwọn igi ipadò Naili pẹ̀lú,

tí ó wà ní orísun odò,

gbogbo oko tí a dá sí ipadò Naili

yóò gbẹ dànù tí yóò sì fẹ́ dànù

tí kò sì ní sí mọ́.

8Àwọn apẹja yóò sọkún kíkorò,

àti gbogbo àwọn tí ó ń ju ìwọ̀ sínú odò;

odò náà yóò sì máa rùn.

9Àwọn tí ó ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ọ̀gbọ̀ yóò kọminú

àwọn ahunṣọ ọ̀gbọ̀ yóò sọ ìrètí nù.

10Àwọn tí ń ṣiṣẹ́ aṣọ yóò rẹ̀wẹ̀sì,

gbogbo àwọn oníṣẹ́ oṣù ni àìsàn ọkàn yóò ṣe.

11Àwọn oníṣẹ́ Ṣoani ti di aláìgbọ́n,

àwọn ọlọ́gbọ́n olùdámọ̀ràn Farao

ń mú ìmọ̀ràn àìgbọ́n wá.

Báwo ló ṣe lè sọ fún Farao pé,

“Mo jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọlọ́gbọ́n ènìyàn,

ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn àwọn ọba àtijọ́.”

12Níbo ni àwọn ọlọ́gbọ́n ènìyàn rẹ wà báyìí?

Jẹ́ kí wọn fihàn ọ́ kí wọn sì sọ ọ́ di mí mọ̀

ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun

ti pinnu lórí Ejibiti.

13Àwọn ọmọ-aládé Ṣoani ti di aṣiwèrè,

a ti tan àwọn ọmọ-aládé Memfisi jẹ;

àwọn òkúta igun ilé tí í ṣe ti ẹ̀yà rẹ

ti ṣi Ejibiti lọ́nà.

14Olúwa ti da ẹ̀mí òòyì sínú wọn;

wọ́n mú Ejibiti ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n nínú

ohun gbogbo tí ó ń ṣe,

gẹ́gẹ́ bí ọ̀mùtí ti í ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n nínú èébì rẹ̀.

15Kò sí ohun tí Ejibiti le ṣe—

orí tàbí ìrù, ọ̀wá ọ̀pẹ tàbí koríko odò.

16Ní ọjọ́ náà ni àwọn ará Ejibiti yóò dàbí obìnrin. Wọn yóò gbọ̀n jìnnìjìnnì pẹ̀lú ẹ̀rù nítorí ọwọ́ Olúwa àwọn ọmọ-ogun tí a gbé sókè sí wọn. 17Ilẹ̀ Juda yóò sì di ẹ̀rù fún Ejibiti; gbogbo àwọn tí a bá ti dárúkọ Juda létí wọn ni yóò wárìrì, nítorí ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun gbèrò láti ṣe sí wọn.

18Ní ọjọ́ náà ìlú márùn-ún ní ilẹ̀ Ejibiti yóò sọ èdè àwọn ará Kenaani, wọn yóò sì búra àtìlẹ́yìn fún Olúwa àwọn ọmọ-ogun. Ọ̀kan nínú wọn ni a ó sì máa pè ní ìlú ìparun.

19Ní ọjọ́ náà pẹpẹ kan yóò wà fún Olúwa ní àárín gbùngbùn Ejibiti, àti ọ̀wọ́n kan fún Olúwa ní etí bodè rẹ̀. 20Yóò sì jẹ́ ààmì àti ẹ̀rí sí Olúwa àwọn ọmọ-ogun ní ilẹ̀ Ejibiti. Nígbà tí wọ́n bá ké pe Olúwa nítorí àwọn aninilára wọn, yóò rán olùgbàlà àti olùgbèjà kan sí wọn tí yóò sì gbà wọ́n sílẹ̀. 21Báyìí ni Olúwa yóò sọ ara rẹ̀ di mí mọ̀ fún àwọn ará Ejibiti àti ní ọjọ́ náà ni wọn yóò gba Olúwa gbọ́. Wọn yóò sìn ín pẹ̀lú ẹbọ ọrẹ ìyẹ̀fun, wọn yóò jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún Olúwa wọn yóò sì mú un ṣẹ. 22Olúwa yóò fi àjàkálẹ̀-ààrùn kan bá Ejibiti jà; yóò bá wọn jà yóò sì tún wò wọ́n sàn. Wọn yóò yípadà sí Olúwa, Òun yóò sì gbọ́ ẹ̀bẹ̀ wọn yóò sì wò wọ́n sàn.

23Ní ọjọ́ náà òpópónà kan yóò wá láti Ejibiti lọ sí Asiria. Àwọn ará Asiria yóò lọ sí Ejibiti àti àwọn ará Ejibiti lọ sí Asiria. Àwọn ará Ejibiti àti ará Asiria yóò jọ́sìn papọ̀. 24Ní ọjọ́ náà Israẹli yóò di ẹ̀kẹta pẹ̀lú Ejibiti àti Asiria, àní orísun ìbùkún ní ilẹ̀ ayé. 25Olúwa àwọn ọmọ-ogun yóò bùkún wọn yóò wí pé, “Ìbùkún ni fún Ejibiti ènìyàn mi, Asiria iṣẹ́ ọwọ́ mi, àti Israẹli ìní mi.”