Ezequiel 8 – NVI & YCB

Nueva Versión Internacional

Ezequiel 8:1-18

Idolatría en el Templo

1En el día quinto del mes sexto del año sexto, yo estaba sentado en mi casa, junto con los ancianos de Judá. De pronto, el Señor puso su mano sobre mí.

2Entonces miré y vi una figura de aspecto humano: de la cintura para abajo, ardía como fuego; de la cintura para arriba, brillaba como el metal refulgente. 3Aquella figura extendió lo que parecía ser una mano y me tomó del cabello. El Espíritu me sostuvo entre la tierra y el cielo y, en visiones de Dios, me llevó a la parte norte de Jerusalén, hasta la entrada de la puerta interior, que es donde está el ídolo que provoca los celos de Dios. 4Allí estaba la gloria del Dios de Israel, como la visión que yo había visto en el campo.

5Y Dios me dijo: «Hijo de hombre, levanta la vista hacia el norte». Yo miré en esa dirección y en la entrada misma, al norte de la puerta del altar, vi el ídolo que provoca los celos de Dios.

6También me dijo: «Hijo de hombre, ¿ves las grandes abominaciones que cometen los israelitas en este lugar y que me hacen alejarme de mi santuario? Pues verán aún abominaciones peores».

7Después me llevó a la entrada del atrio. En el muro había una abertura. 8Entonces me dijo: «Hijo de hombre, cava en el muro». Yo cavé en el muro y me encontré con una puerta.

9Entonces me dijo: «Entra y observa las abominaciones detestables que allí se cometen». 10Yo entré y, a lo largo del muro, vi grabadas todo tipo de figuras de reptiles y de otros animales impuros y de todos los ídolos de Israel. 11Setenta ancianos israelitas estaban de pie frente a los ídolos, rindiéndoles culto. Entre ellos se encontraba Jazanías, hijo de Safán. Cada uno tenía en la mano un incensario, de ellos subía una fragante nube de incienso.

12Y él me dijo: «Hijo de hombre, ¿ves lo que hacen los ancianos israelitas en los oscuros nichos de sus ídolos? Andan diciendo: “El Señor no nos ve. El Señor abandonó esta tierra”». 13Y añadió: «Ya los verás cometer mayores abominaciones».

14Luego me llevó a la entrada del Templo del Señor, a la puerta que da hacia el norte. Allí estaban unas mujeres sentadas que lloraban por el dios Tamuz. 15Entonces Dios me dijo: «Hijo de hombre, ¿ves esto? Pues aún los verás cometer mayores abominaciones».

16Y me llevó al atrio interior del Templo. A la entrada del Templo, entre el vestíbulo y el altar, había unos veinticinco hombres que estaban mirando hacia el oriente y adoraban al sol, de espaldas al Templo del Señor.

17Me dijo: «Hijo de hombre, ¿ves esto? ¿Tan poca cosa le parece a Judá cometer tales abominaciones aquí que también ha llenado la tierra de violencia y no deja de provocarme? ¡Mira cómo me enardecen, pasándose por la nariz sus pestilentes ramos! 18Por eso, voy a actuar con furor. No les tendré piedad ni compasión. Por más que me imploren a gritos, ¡no los escucharé!».

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Esekiẹli 8:1-18

Ìbọ̀rìṣà nínú ilé Olúwa

1Ní ọjọ́ karùn-ún, oṣù kẹfà ọdún kẹfà bí mo ṣe jókòó nílé mi pẹ̀lú àwọn àgbàgbà Juda níwájú mi, ọwọ́ Olúwa Olódùmarè bà lé mi níbẹ̀. 2Nígbà tí mo wò, mo rí ohun kan tí ó jọ ènìyàn. Láti ibi ìbàdí rẹ lọ sísàlẹ̀ dàbí iná, láti ibi ìbàdí yìí sókè sì mọ́lẹ̀ bí idẹ tó ń kọ mọ̀nà. 3Ó na ohun tó dàbí ọwọ́ jáde, ó fi gba mi ní irun orí mú, Ẹ̀mí sì gbé mi sókè sí agbede-méjì ayé àti ọ̀run, ó sì mú mi lọ rí ìran Ọlọ́run, mo sì lọ sí Jerusalẹmu, ṣí ìlẹ̀kùn ẹnu-ọ̀nà òde àríwá níbi tí ère owú tí ó ń mú ni bínú wá níwájú mi, 4Sì kíyèsi i, ògo Ọlọ́run Israẹli wà níbẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ìran ti mo rí ni pẹ̀tẹ́lẹ̀.

5Ó sì sọ fún mi pé, “Ọmọ ènìyàn, gbójú sókè sí ìhà àríwá.” Èmi náà sì gbójú sókè sí ìhà àríwá mo sì rí ère tí ó ń mú ni jowú ní ẹnu-ọ̀nà ibi pẹpẹ.

6Ó sì wí fún mi pé, “Ọmọ ènìyàn, ṣé o rí ohun tí wọ́n ń ṣe ohun ìríra ńlá tí ilé Israẹli ń ṣe, láti lé mi jìnnà réré sí ibi mímọ́ mi? Ṣùgbọ́n ìwọ yóò tún rí àwọn ìríra ńlá tó tóbi jù èyí lọ.”

7Ó mú mi wá sí ẹnu-ọ̀nà àgbàlá. Mo wò ó, mo sì rí ihò kan lẹ́gbẹ̀ẹ́ ògiri. 8Nígbà náà ló sọ fún mi pé, “Ọmọ ènìyàn, gbẹ́ inú ògiri náà,” Nígbà tí mo sì gbẹ́ inú ògiri, mo rí ìlẹ̀kùn kan.

9Ó sì wí fún mi pé, “Wọlé kí ìwọ kí ó rí ohun ìríra búburú tí wọ́n ń ṣe níbẹ̀.” 10Mo wọlé, mo sì rí àwòrán oríṣìíríṣìí ẹranko tí ń fà nílẹ̀ àti àwọn ẹranko ìríra àti gbogbo òrìṣà ilẹ̀ Israẹli tí wọ́n yà sára ògiri. 11Níwájú wọn ni àádọ́rin (70) ọkùnrin tó jẹ́ àgbàgbà ilé Israẹli dúró sí, Jaaṣaniah ọmọ Ṣafani sì dúró sí àárín wọn. Ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sì mú àwo tùràrí lọ́wọ́, òórùn sì ń tú jáde.

12Ó sọ fún mi pé, “Ọmọ ènìyàn, ṣé o ti rí ohun tí àwọn àgbàgbà ilé Israẹli ń ṣe nínú òkùnkùn, olúkúlùkù ní yàrá òrìṣà rẹ̀? Wọ́n ní, ‘Olúwa kò rí wa; Olúwa ti kọ̀ ilé náà sílẹ̀.’ ” 13Ó tún sọ fún mi pé, “Ìwọ yóò rí wọn tí wọ́n ń ṣe àwọn ohun ìríra tó burú jù bẹ́ẹ̀ lọ.”

14Ó mú mi wá sí ẹnu-ọ̀nà ilé Olúwa tó wà ní ìhà àríwá, mo sì rí àwọn obìnrin tó jókòó, tí wọ́n sí ẹnu-ọ̀nà ilé Olúwa tó wà ní ìhà àríwá, mo sì rí àwọn obìnrin tó jókòó, tí wọ́n sì ń ṣọ̀fọ̀ fún Tamusi. 15Ó sọ fún mi pé, “Ṣé ìwọ rí báyìí, ọmọ ènìyàn? Ìwọ yóò tún rí ìríra tó ga jù èyí lọ.”

16Ó mú mi wá sí ibi àgbàlá ilé Olúwa, ní ẹnu-ọ̀nà tẹmpili Olúwa, wọn kọjú sí ìlà-oòrùn, wọ́n sì ń foríbalẹ̀ fún oòrùn ní apá ìlà-oòrùn.

17Ó sì wí fún mi, “Ṣé ìwọ ti rí èyí ọmọ ènìyàn? Ǹjẹ́ ohun kékeré ni fún ilé Juda láti ṣe àwọn ohun ìríra tí wọn ń ṣe níbi yìí? Ṣé o tún yẹ kí wọ́n fi ìwà ipá kún ilẹ̀ kí wọn sì máa mú mi bínú ní gbogbo ìgbà? Wò wọn bi wọn ṣe n fi ẹ̀ka wọn sínú inú wọn. 18Nítorí náà, èmi yóò fi ìbínú bá wọn wí; èmi kò ní i dá wọn sí bẹ́ẹ̀ ni èmi kò sì ní fojú àánú wò wọ́n. Bí wọ́n tilẹ̀ ń pariwo sí mi létí, èmi kò ní fetí sí wọn.”